ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 33
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Mánásè di ọba Júdà (1-9)

      • Mánásè ronú pìwà dà ìwà búburú rẹ̀ (10-17)

      • Ikú Mánásè (18-20)

      • Ámọ́nì di ọba Júdà (21-25)

2 Kíróníkà 33:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 1:10
  • +2Ọb 21:1

2 Kíróníkà 33:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:2-6

2 Kíróníkà 33:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:1, 4
  • +Di 4:19; 2Ọb 23:5

2 Kíróníkà 33:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 16:10, 11
  • +Di 12:11; 2Kr 6:6

2 Kíróníkà 33:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:36; 7:12

2 Kíróníkà 33:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 16:1, 3
  • +Joṣ 15:8, 12; 2Ọb 23:10
  • +Le 19:26
  • +Le 20:6; Di 18:10, 11

2 Kíróníkà 33:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:6
  • +2Ọb 21:7-9; 23:27; 2Kr 7:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2021, ojú ìwé 4

2 Kíróníkà 33:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:24; Joṣ 24:8; 2Ọb 21:11, 16

2 Kíróníkà 33:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:15, 16

2 Kíróníkà 33:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “wọ́n mú Mánásè ní ibi tó jin kòtò.”

2 Kíróníkà 33:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú.”

2 Kíróníkà 33:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:18
  • +Da 4:25

2 Kíróníkà 33:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:9; 2Kr 32:2, 5
  • +2Kr 32:30
  • +Ne 3:3
  • +2Kr 27:1, 3

2 Kíróníkà 33:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:1, 7
  • +2Ọb 21:1, 4, 5

2 Kíróníkà 33:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 29:18
  • +Le 3:1
  • +Le 7:12

2 Kíróníkà 33:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 33:12, 13
  • +2Ọb 21:2, 9
  • +2Ọb 21:3, 7

2 Kíróníkà 33:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:18, 19

2 Kíróníkà 33:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 1:10
  • +2Ọb 21:19-24

2 Kíróníkà 33:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 33:1, 2
  • +2Ọb 21:1, 7

2 Kíróníkà 33:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 8:12
  • +2Kr 33:12, 13

2 Kíróníkà 33:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 12:20; 2Kr 25:27

2 Kíróníkà 33:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 25:1, 3
  • +2Ọb 21:25, 26

Àwọn míì

2 Kíró. 33:1Mt 1:10
2 Kíró. 33:12Ọb 21:1
2 Kíró. 33:22Ọb 21:2-6
2 Kíró. 33:32Ọb 18:1, 4
2 Kíró. 33:3Di 4:19; 2Ọb 23:5
2 Kíró. 33:42Ọb 16:10, 11
2 Kíró. 33:4Di 12:11; 2Kr 6:6
2 Kíró. 33:51Ọb 6:36; 7:12
2 Kíró. 33:62Ọb 16:1, 3
2 Kíró. 33:6Joṣ 15:8, 12; 2Ọb 23:10
2 Kíró. 33:6Le 19:26
2 Kíró. 33:6Le 20:6; Di 18:10, 11
2 Kíró. 33:72Ọb 23:6
2 Kíró. 33:72Ọb 21:7-9; 23:27; 2Kr 7:16
2 Kíró. 33:9Le 18:24; Joṣ 24:8; 2Ọb 21:11, 16
2 Kíró. 33:102Kr 36:15, 16
2 Kíró. 33:13Ais 1:18
2 Kíró. 33:13Da 4:25
2 Kíró. 33:142Sa 5:9; 2Kr 32:2, 5
2 Kíró. 33:142Kr 32:30
2 Kíró. 33:14Ne 3:3
2 Kíró. 33:142Kr 27:1, 3
2 Kíró. 33:152Ọb 21:1, 7
2 Kíró. 33:152Ọb 21:1, 4, 5
2 Kíró. 33:162Kr 29:18
2 Kíró. 33:16Le 3:1
2 Kíró. 33:16Le 7:12
2 Kíró. 33:192Kr 33:12, 13
2 Kíró. 33:192Ọb 21:2, 9
2 Kíró. 33:192Ọb 21:3, 7
2 Kíró. 33:202Ọb 21:18, 19
2 Kíró. 33:21Mt 1:10
2 Kíró. 33:212Ọb 21:19-24
2 Kíró. 33:222Kr 33:1, 2
2 Kíró. 33:222Ọb 21:1, 7
2 Kíró. 33:23Jer 8:12
2 Kíró. 33:232Kr 33:12, 13
2 Kíró. 33:242Ọb 12:20; 2Kr 25:27
2 Kíró. 33:252Kr 25:1, 3
2 Kíró. 33:252Ọb 21:25, 26
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 33:1-25

Kíróníkà Kejì

33 Ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Mánásè+ nígbà tó jọba, ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+

2 Ó ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, torí pé ó ń ṣe àwọn ohun ìríra bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ ti wó lulẹ̀,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe àwọn òpó òrìṣà.* Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+ 4 Ó tún mọ àwọn pẹpẹ sí ilé Jèhófà,+ níbi tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Inú Jerúsálẹ́mù ni orúkọ mi yóò máa wà títí láé.”+ 5 Ó mọ àwọn pẹpẹ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sí àgbàlá méjì nínú ilé Jèhófà.+ 6 Ó sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná+ ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù;+ ó ń pidán,+ ó ń woṣẹ́, ó ń ṣe oṣó, ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.

7 Ó gbé ère gbígbẹ́ tó ṣe wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́,+ ilé tí Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ fún Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Inú ilé yìí àti ní Jerúsálẹ́mù, tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ni màá fi orúkọ mi sí títí láé.+ 8 Mi ò tún ní ṣí ẹsẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo yàn fún àwọn baba ńlá wọn, tí wọ́n bá ṣáà ti rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn, ìyẹn gbogbo Òfin, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ látọwọ́ Mósè.” 9 Mánásè ń ṣi Júdà àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù lọ́nà nìṣó, ó ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa run kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+

10 Jèhófà bá Mánásè àti àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ títí, àmọ́ wọn ò gbọ́.+ 11 Nítorí náà, Jèhófà mú kí àwọn olórí ọmọ ogun ọba Ásíríà wá gbéjà kò wọ́n, wọ́n fi ìwọ̀ mú Mánásè,* wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà méjì dè é, wọ́n sì mú un lọ sí Bábílónì. 12 Nínú ìdààmú tó bá a, ó bẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pé kó ṣíjú àánú wo òun,* ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀. 13 Ó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sì mú kí àánú ṣe Ọlọ́run, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un pa dà sí Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀.+ Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.+

14 Lẹ́yìn náà, ó mọ ògiri ẹ̀yìn òde sí Ìlú Dáfídì+ lápá ìwọ̀ oòrùn Gíhónì+ ní àfonífojì títí dé Ẹnubodè Ẹja,+ ó mọ ọ́n yí ká dé Ófélì,+ ó sì mú kí ó ga gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ó yan àwọn olórí ọmọ ogun sí gbogbo àwọn ìlú olódi ní Júdà. 15 Lẹ́yìn ìyẹn, ó mú àwọn ọlọ́run àjèjì àti ère òrìṣà kúrò ní ilé Jèhófà + àti gbogbo àwọn pẹpẹ tó mọ sí òkè ilé Jèhófà+ àti sí Jerúsálẹ́mù, ó sì ní kí wọ́n kó wọn dà nù sí ẹ̀yìn òde ìlú. 16 Ó tún ṣètò pẹpẹ Jèhófà,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ àti àwọn ẹbọ ìdúpẹ́+ lórí rẹ̀, ó sì sọ fún Júdà pé kí wọ́n máa sin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 17 Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ lórí àwọn ibi gíga, àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run wọn nìkan ni wọ́n ń rúbọ sí.

18 Ní ti ìyókù ìtàn Mánásè àti àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwọn aríran tí wọ́n bá a sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ìtàn àwọn ọba Ísírẹ́lì. 19 Bákan náà, àdúrà rẹ̀+ àti bí Ọlọ́run ṣe gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti ìwà àìṣòótọ́ rẹ̀,+ àwọn ibi tó kọ́ ibi gíga sí, tó sì gbé àwọn òpó òrìṣà*+ àti àwọn ère gbígbẹ́ sí kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n wà lákọsílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àwọn aríran rẹ̀. 20 Níkẹyìn, Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀; Ámọ́nì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.+

21 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ámọ́nì+ nígbà tó jọba, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 22 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, bí Mánásè bàbá rẹ̀ ti ṣe;+ Ámọ́nì rúbọ sí gbogbo àwọn ère gbígbẹ́ tí Mánásè bàbá rẹ̀ ṣe,+ ó sì ń sìn wọ́n. 23 Àmọ́ kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà+ bí Mánásè bàbá rẹ̀ ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;+ kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Ámọ́nì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. 24 Níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn,+ wọ́n sì pa á nínú ilé rẹ̀. 25 Àmọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tó dìtẹ̀ mọ́ Ọba Ámọ́nì,+ wọ́n sì fi Jòsáyà+ ọmọ rẹ̀ jọba ní ipò rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́