ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sekaráyà 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sekaráyà

      • Ọlọ́run dá àwọn orílẹ̀-èdè tó wà yí ká lẹ́jọ́ (1-8)

      • Ọba Síónì ń bọ̀ (9, 10)

        • Ọba tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ (9)

      • Wọ́n á tú àwọn èèyàn Jèhófà sílẹ̀ (11-17)

Sekaráyà 9:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ni ibi ìsinmi rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:27; Emọ 1:3
  • +Heb 4:13; 1Pe 3:12

Sekaráyà 9:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:23
  • +Ais 23:1; Emọ 1:9, 10
  • +Isk 28:21; Joẹ 3:4
  • +Isk 28:2, 3

Sekaráyà 9:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ilé ààbò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 27:32, 33

Sekaráyà 9:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “lórí òkun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 26:17; 27:26
  • +Isk 28:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2008, ojú ìwé 27

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 255

Sekaráyà 9:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 2:4

Sekaráyà 9:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 1:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1997, ojú ìwé 19

    7/1/1995, ojú ìwé 22-23

Sekaráyà 9:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 60:14
  • +2Sa 5:6, 7; 1Ọb 9:20, 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1997, ojú ìwé 19

    7/1/1995, ojú ìwé 22-23

Sekaráyà 9:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ ogun ẹ̀yìn odi.”

  • *

    Tàbí “aninilára.”

  • *

    Ó ṣe kedere pé, ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ ló ń sọ.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 125:2
  • +Ais 54:14

Sekaráyà 9:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó sì ń ṣẹ́gun; ó sì gbani là.”

  • *

    Tàbí “akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 2:6; Ais 32:1; Jer 23:5; Lk 19:37, 38; Jo 1:49
  • +Mt 11:29
  • +1Ọb 1:33, 34; Mt 21:5, 7; Jo 12:14, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 238

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2012, ojú ìwé 12

    8/15/2011, ojú ìwé 12

    8/1/1999, ojú ìwé 14-15

    3/1/1997, ojú ìwé 30

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 25-27

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 55

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 92-94

Sekaráyà 9:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 9:7
  • +Ẹk 23:31; Sm 2:8; 72:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 92-94

Sekaráyà 9:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 49:9

Sekaráyà 9:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 61:1; Jer 31:17
  • +Ais 61:7

Sekaráyà 9:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tẹ.”

  • *

    Ìyẹn, bí ọfà.

Sekaráyà 9:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 6:5

Sekaráyà 9:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 5:9; Sek 10:5; 12:6
  • +Ẹk 27:2; Le 4:7

Sekaráyà 9:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dáyádémà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 34:22
  • +Ais 62:3; Sef 3:20

Sekaráyà 9:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 25:8; 31:19; Ais 63:7
  • +Ais 62:8; Joẹ 3:18; Emọ 9:13

Àwọn míì

Sek. 9:1Jer 49:27; Emọ 1:3
Sek. 9:1Heb 4:13; 1Pe 3:12
Sek. 9:2Jer 49:23
Sek. 9:2Ais 23:1; Emọ 1:9, 10
Sek. 9:2Isk 28:21; Joẹ 3:4
Sek. 9:2Isk 28:2, 3
Sek. 9:3Isk 27:32, 33
Sek. 9:4Isk 26:17; 27:26
Sek. 9:4Isk 28:18
Sek. 9:5Sef 2:4
Sek. 9:6Emọ 1:8
Sek. 9:7Ais 60:14
Sek. 9:72Sa 5:6, 7; 1Ọb 9:20, 21
Sek. 9:8Sm 125:2
Sek. 9:8Ais 54:14
Sek. 9:9Sm 2:6; Ais 32:1; Jer 23:5; Lk 19:37, 38; Jo 1:49
Sek. 9:9Mt 11:29
Sek. 9:91Ọb 1:33, 34; Mt 21:5, 7; Jo 12:14, 15
Sek. 9:10Ais 9:7
Sek. 9:10Ẹk 23:31; Sm 2:8; 72:8
Sek. 9:11Ais 49:9
Sek. 9:12Ais 61:1; Jer 31:17
Sek. 9:12Ais 61:7
Sek. 9:14Joṣ 6:5
Sek. 9:15Mik 5:9; Sek 10:5; 12:6
Sek. 9:15Ẹk 27:2; Le 4:7
Sek. 9:16Isk 34:22
Sek. 9:16Ais 62:3; Sef 3:20
Sek. 9:17Sm 25:8; 31:19; Ais 63:7
Sek. 9:17Ais 62:8; Joẹ 3:18; Emọ 9:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sekaráyà 9:1-17

Sekaráyà

9 Ìkéde:

“Jèhófà bá ilẹ̀ Hádírákì wí,

Damásíkù gangan ni ọ̀rọ̀ náà kàn,*+

Torí ojú Jèhófà wà lára aráyé+

Àti lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.

 2 Ọ̀rọ̀ náà tún kan Hámátì+ tí wọ́n jọ pààlà

Àti Tírè+ pẹ̀lú Sídónì,+ torí wọ́n gbọ́n féfé.+

 3 Tírè kọ́ odi ààbò* fún ara rẹ̀.

Ó to fàdákà jọ pelemọ bí iyẹ̀pẹ̀

Àti wúrà bí iyẹ̀pẹ̀ ojú ọ̀nà.+

 4 Wò ó! Jèhófà máa gba àwọn ohun ìní rẹ̀,

Yóò sì run àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú òkun;*+

Iná yóò sì jẹ ẹ́ run.+

 5 Áṣíkẹ́lónì á rí i, ẹ̀rù á sì bà á;

Gásà yóò jẹ̀rora,

Bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹ́kírónì, torí pé ìrètí rẹ̀ ti di ìtìjú.

Ọba kan yóò ṣègbé ní Gásà,

Ẹnì kankan kò sì ní gbé ní Áṣíkẹ́lónì.+

 6 Ọmọ àjèjì ni yóò gbé ní Áṣídódì,

Màá sì fòpin sí ìgbéraga ará Filísínì.+

 7 Èmi yóò mú àwọn ohun tí ẹ̀jẹ̀ ti yí kúrò ní ẹnu rẹ̀

Àti àwọn ohun ìríra kúrò láàárín eyín rẹ̀,

Àwọn tó ṣẹ́ kù níbẹ̀ yóò sì di ti Ọlọ́run wa;

Òun yóò dà bí séríkí* ní Júdà,+

Ẹ́kírónì yóò sì dà bí àwọn ará Jébúsì.+

 8 Èmi yóò pàgọ́ bí ẹ̀ṣọ́* fún ilé mi,+

Kí ẹnì kankan má bàa gba ibẹ̀ kọjá tàbí pa dà wá;

Akóniṣiṣẹ́* kankan kò ní gba ibẹ̀ kọjá mọ́,+

Torí mo ti fi ojú mi rí i* báyìí.

 9 Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.

Kígbe ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù.

Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.+

Olódodo ni, ó sì ń mú ìgbàlà bọ̀,*

Ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀,+ ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

Àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+

10 Èmi yóò mú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí wọ́n fi ń jagun kúrò ní Éfúrémù

Àti ẹṣin kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

Ọfà tí wọ́n fi ń jagun kò ní sí mọ́.

Òun yóò sì kéde àlàáfíà fún àwọn orílẹ̀-èdè;+

Yóò jọba láti òkun dé òkun

Àti láti Odò* dé àwọn ìkángun ayé.+

11 Ní ti ìwọ obìnrin, nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú rẹ,

Èmi yóò rán àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ jáde kúrò nínú kòtò tí kò lómi.+

12 Ẹ pa dà síbi ààbò, ẹ̀yin ẹlẹ́wọ̀n tó ní ìrètí.+

Mò ń sọ fún ọ lónìí pé,

‘Ìwọ obìnrin, màá san án pa dà fún ọ ní ìlọ́po méjì.+

13 Torí èmi yóò fa* Júdà bí ọrun mi.

Màá fi Éfúrémù sínú ọrun* náà,

Màá sì jí àwọn ọmọ rẹ, ìwọ Síónì,

Láti dojú kọ àwọn ọmọ rẹ, ìwọ ilẹ̀ Gíríìsì,

Màá sì ṣe ọ́ bí idà jagunjagun.’

14 Ó máa hàn pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn,

Ọfà rẹ̀ á sì jáde lọ bíi mànàmáná.

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò fun ìwo,+

Yóò sì gbéra pẹ̀lú ìjì líle ti gúúsù.

15 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun yóò gbèjà wọn,

Wọn yóò jẹ òkúta kànnàkànnà run, wọn yóò sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.+

Wọ́n á mu, wọ́n á sì pariwo bíi pé wọ́n mu wáìnì;

Wọn yóò kún bí abọ́ tí wọ́n fi ń rúbọ,

Bí àwọn igun pẹpẹ.+

16 Jèhófà Ọlọ́run wọn yóò gbà wọ́n là ní ọjọ́ yẹn,

Àwọn èèyàn rẹ̀, bí agbo àgùntàn;+

Torí wọn yóò dà bí òkúta iyebíye tó wà lára adé* tó ń dán yinrin lórí ilẹ̀ rẹ̀.+

17 Oore rẹ̀ mà pọ̀ o,+

Ó mà lẹ́wà gan-an o!

Ọkà yóò mú kí àwọn géńdé ọkùnrin lágbára,

Wáìnì tuntun yóò sì fún àwọn wúńdíá lókun.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́