ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 43
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àwọn èèyàn ṣàìgbọràn, wọ́n lọ sí Íjíbítì (1-7)

      • Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Jeremáyà ní Íjíbítì (8-13)

Jeremáyà 43:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 41:16; 42:1-3

Jeremáyà 43:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 36:4; 45:1
  • +Jer 38:4, 6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2006, ojú ìwé 19

Jeremáyà 43:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 40:11, 12

Jeremáyà 43:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:10
  • +2Ọb 25:22
  • +2Kr 34:20, 21; Jer 26:24
  • +2Ọb 22:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2006, ojú ìwé 19

Jeremáyà 43:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:14, 16; 44:1; Isk 30:4, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2006, ojú ìwé 19

Jeremáyà 43:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:9; 27:6; Isk 29:19, 20
  • +Da 2:21; 5:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 161

Jeremáyà 43:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:17, 19; 46:13; Isk 29:19; 30:4, 18
  • +Jer 44:13; Isk 5:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 161

Jeremáyà 43:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn tẹ́ńpìlì.”

  • *

    Tàbí “láìséwu.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:25

Jeremáyà 43:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òpó ìrántí onígun mẹ́rin.”

  • *

    Tàbí “Ilé (Tẹ́ńpìlì) Oòrùn,” ìyẹn Hẹlipólísì.

  • *

    Tàbí “àwọn tẹ́ńpìlì.”

Àwọn míì

Jer. 43:2Jer 41:16; 42:1-3
Jer. 43:3Jer 36:4; 45:1
Jer. 43:3Jer 38:4, 6
Jer. 43:5Jer 40:11, 12
Jer. 43:6Jer 39:10
Jer. 43:62Ọb 25:22
Jer. 43:62Kr 34:20, 21; Jer 26:24
Jer. 43:62Ọb 22:8
Jer. 43:7Jer 2:14, 16; 44:1; Isk 30:4, 18
Jer. 43:10Jer 25:9; 27:6; Isk 29:19, 20
Jer. 43:10Da 2:21; 5:18
Jer. 43:11Jer 25:17, 19; 46:13; Isk 29:19; 30:4, 18
Jer. 43:11Jer 44:13; Isk 5:12
Jer. 43:12Jer 46:25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 43:1-13

Jeremáyà

43 Nígbà tí Jeremáyà parí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wọn ní kó sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà, ìyẹn gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wọn fi rán an sí wọn, 2 Asaráyà ọmọ Hóṣáyà àti Jóhánánì+ ọmọ Káréà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin tó jẹ́ agbéraga wá sọ fún Jeremáyà pé: “Irọ́ lò ń pa! Jèhófà Ọlọ́run wa kò rán ọ kí o sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Íjíbítì láti máa gbé ibẹ̀.’ 3 Bárúkù+ ọmọ Neráyà ló ń dẹ ọ́ sí wa láti fi wá lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà, kí wọ́n lè pa wá tàbí kí wọ́n kó wa lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.”+

4 Torí náà, Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn náà kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà pé kí wọ́n dúró sí ilẹ̀ Júdà. 5 Dípò bẹ́ẹ̀, Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun kó gbogbo àṣẹ́kù Júdà tó pa dà láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí a fọ́n wọn ká sí, láti máa gbé ní ilẹ̀ Júdà.+ 6 Wọ́n kó àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọbìnrin ọba, pẹ̀lú gbogbo àwọn* tí Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ fi sílẹ̀ sọ́dọ̀ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì,+ wọ́n sì tún mú wòlíì Jeremáyà àti Bárúkù ọmọ Neráyà. 7 Wọ́n wọ ilẹ̀ Íjíbítì, nítorí wọn kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, wọ́n sì lọ títí dé Tápánẹ́sì.+

8 Nígbà náà, Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀ ní Tápánẹ́sì, ó ní: 9 “Fi ọwọ́ rẹ kó òkúta ńlá, kí o kó wọn pa mọ́ sí ibi onípele tí wọ́n fi bíríkì ṣe tó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé Fáráò ní Tápánẹ́sì níṣojú àwọn ọkùnrin Júù, kí o sì fi amọ̀ bò wọ́n mọ́ ibẹ̀. 10 Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wò ó, màá ránṣẹ́ pe Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ lé orí àwọn òkúta tí mo fi pa mọ́ yìí, á sì na àgọ́ ìtẹ́ rẹ̀ lé wọn lórí.+ 11 Ó máa wọlé, á sì kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ẹni tó bá yẹ fún àjàkálẹ̀ àrùn ni àjàkálẹ̀ àrùn máa pa, ẹni tó bá yẹ fún oko ẹrú ló máa lọ sí oko ẹrú, ẹni tó bá sì yẹ fún idà ni idà máa pa.+ 12 Màá sọ iná sí ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì, ọba náà á sun wọ́n,+ á sì kó wọn lọ sí oko ẹrú. Á da ilẹ̀ Íjíbítì bora bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń da ẹ̀wù bo ara rẹ̀, á sì jáde kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà.* 13 Á fọ́ àwọn òpó* Bẹti-ṣémẹ́ṣì* tó wà nílẹ̀ Íjíbítì sí wẹ́wẹ́, á sì dáná sun ilé* àwọn ọlọ́run Íjíbítì.”’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́