ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Jèhófà bá wọn dá májẹ̀mú ní Hórébù (1-5)

      • Wọ́n tún Òfin Mẹ́wàá sọ (6-22)

      • Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà ní Òkè Sínáì (23-33)

Diutarónómì 5:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5; Heb 9:19, 20

Diutarónómì 5:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:9, 18; Iṣe 7:38

Diutarónómì 5:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:19; Ga 3:19
  • +Ẹk 19:16

Diutarónómì 5:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:3; 20:2

Diutarónómì 5:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti fojú di mí.” Ní Héb., “níṣojú mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:3-6; 2Ọb 17:35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2012, ojú ìwé 23

Diutarónómì 5:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwòrán.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:1; Di 4:15, 16, 23; 27:15; Iṣe 17:29

Diutarónómì 5:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:24; 1Kọ 10:14
  • +Ẹk 34:14; Di 4:24; Ais 42:8; Mt 4:10
  • +Ẹk 34:6, 7

Diutarónómì 5:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “inú rere onífẹ̀ẹ́.”

Diutarónómì 5:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:28; Le 19:12
  • +Ẹk 20:7; Le 24:16

Diutarónómì 5:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 16:23; 20:8-10; 31:13

Diutarónómì 5:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:21

Diutarónómì 5:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnubodè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 16:29
  • +Ne 13:15
  • +Ẹk 23:12
  • +Di 10:17; Ef 6:9

Diutarónómì 5:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:6; Di 4:34

Diutarónómì 5:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 21:15; Le 19:3; Di 27:16; Owe 1:8; Mk 7:10
  • +Ẹk 20:12; Ef 6:2, 3

Diutarónómì 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:6; Ẹk 20:13; Nọ 35:20, 21; Mt 5:21; Ro 13:9

Diutarónómì 5:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:14; 1Kọ 6:18; Heb 13:4

Diutarónómì 5:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:15; Le 19:11; Owe 30:8, 9; 1Kọ 6:10; Ef 4:28

Diutarónómì 5:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:16; 23:1; Le 19:16; Di 19:16-19; Owe 6:16, 19; 19:5

Diutarónómì 5:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 5:28
  • +Ẹk 20:17; Lk 12:15; Ro 7:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2019, ojú ìwé 21-22

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2012, ojú ìwé 7

Diutarónómì 5:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọ̀rọ̀.”

  • *

    Tàbí “àwọsánmà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:9, 18
  • +Ẹk 24:12; 31:18; Di 4:12, 13

Diutarónómì 5:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:18; Heb 12:18, 19

Diutarónómì 5:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:17
  • +Di 4:33, 36

Diutarónómì 5:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”

Diutarónómì 5:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:19; Heb 12:18, 19

Diutarónómì 5:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 18:16, 17

Diutarónómì 5:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:12; Job 28:28; Owe 1:7; Mt 10:28; 1Pe 2:17
  • +Owe 4:4; 7:2; Onw 12:13; Ais 48:18; 1Jo 5:3
  • +Sm 19:8, 11; Jem 1:25

Diutarónómì 5:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 6:3, 25; 8:1
  • +Di 12:32; Joṣ 1:7, 8

Diutarónómì 5:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:12
  • +Di 4:40; 12:28; Ro 10:5

Àwọn míì

Diu. 5:2Ẹk 19:5; Heb 9:19, 20
Diu. 5:4Ẹk 19:9, 18; Iṣe 7:38
Diu. 5:5Ẹk 20:19; Ga 3:19
Diu. 5:5Ẹk 19:16
Diu. 5:6Ẹk 13:3; 20:2
Diu. 5:7Ẹk 20:3-6; 2Ọb 17:35
Diu. 5:8Le 26:1; Di 4:15, 16, 23; 27:15; Iṣe 17:29
Diu. 5:9Ẹk 23:24; 1Kọ 10:14
Diu. 5:9Ẹk 34:14; Di 4:24; Ais 42:8; Mt 4:10
Diu. 5:9Ẹk 34:6, 7
Diu. 5:11Ẹk 22:28; Le 19:12
Diu. 5:11Ẹk 20:7; Le 24:16
Diu. 5:12Ẹk 16:23; 20:8-10; 31:13
Diu. 5:13Ẹk 34:21
Diu. 5:14Ẹk 16:29
Diu. 5:14Ne 13:15
Diu. 5:14Ẹk 23:12
Diu. 5:14Di 10:17; Ef 6:9
Diu. 5:15Ẹk 6:6; Di 4:34
Diu. 5:16Ẹk 21:15; Le 19:3; Di 27:16; Owe 1:8; Mk 7:10
Diu. 5:16Ẹk 20:12; Ef 6:2, 3
Diu. 5:17Jẹ 9:6; Ẹk 20:13; Nọ 35:20, 21; Mt 5:21; Ro 13:9
Diu. 5:18Ẹk 20:14; 1Kọ 6:18; Heb 13:4
Diu. 5:19Ẹk 20:15; Le 19:11; Owe 30:8, 9; 1Kọ 6:10; Ef 4:28
Diu. 5:20Ẹk 20:16; 23:1; Le 19:16; Di 19:16-19; Owe 6:16, 19; 19:5
Diu. 5:21Mt 5:28
Diu. 5:21Ẹk 20:17; Lk 12:15; Ro 7:7
Diu. 5:22Ẹk 19:9, 18
Diu. 5:22Ẹk 24:12; 31:18; Di 4:12, 13
Diu. 5:23Ẹk 20:18; Heb 12:18, 19
Diu. 5:24Ẹk 24:17
Diu. 5:24Di 4:33, 36
Diu. 5:27Ẹk 20:19; Heb 12:18, 19
Diu. 5:28Di 18:16, 17
Diu. 5:29Di 10:12; Job 28:28; Owe 1:7; Mt 10:28; 1Pe 2:17
Diu. 5:29Owe 4:4; 7:2; Onw 12:13; Ais 48:18; 1Jo 5:3
Diu. 5:29Sm 19:8, 11; Jem 1:25
Diu. 5:32Di 6:3, 25; 8:1
Diu. 5:32Di 12:32; Joṣ 1:7, 8
Diu. 5:33Di 10:12
Diu. 5:33Di 4:40; 12:28; Ro 10:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 5:1-33

Diutarónómì

5 Mósè wá pe gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń kéde fún yín lónìí, kí ẹ mọ̀ wọ́n, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́. 2 Jèhófà Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú kan ní Hórébù.+ 3 Àwọn baba ńlá wa kọ́ ni Jèhófà bá dá májẹ̀mú yìí, àwa ni, gbogbo àwa tí a wà láàyè níbí lónìí. 4 Ojúkojú ni Jèhófà bá yín sọ̀rọ̀ ní òkè náà látinú iná.+ 5 Mo dúró láàárín Jèhófà àti ẹ̀yin nígbà yẹn+ kí n lè sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún yín, torí iná náà ń dẹ́rù bà yín, ẹ ò sì lè gun òkè náà lọ.+ Ó sọ pé:

6 “‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+ 7 O ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.*+

8 “‘O ò gbọ́dọ̀ gbẹ́ ère kankan fún ara rẹ+ tàbí kí o ṣe ohun* kan tó dà bí ohunkóhun lókè ọ̀run tàbí ní ayé tàbí nínú omi nísàlẹ̀. 9 O ò gbọ́dọ̀ forí balẹ̀ fún wọn tàbí kí o jẹ́ kí wọ́n sún ọ láti sìn wọ́n,+ torí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ kí o máa sin òun nìkan ṣoṣo,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ, dórí ìran kẹta àti ìran kẹrin àwọn tó kórìíra mi,+ 10 àmọ́ tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀* hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi títí dé ẹgbẹ̀rún ìran wọn, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.

11 “‘O ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò tọ́,+ torí Jèhófà kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá lo orúkọ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́.+

12 “‘Máa pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́, kí o lè yà á sí mímọ́, bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́.+ 13 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi ṣiṣẹ́, kí o sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,+ 14 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ àti èyíkéyìí nínú ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tó ń gbé nínú àwọn ìlú* rẹ,+ kí ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ lè sinmi bíi tìẹ.+ 15 Rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì àti pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi ọwọ́ agbára àti apá rẹ̀ tó nà jáde mú ọ kúrò níbẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi pàṣẹ fún ọ pé kí o máa pa ọjọ́ Sábáàtì mọ́.

16 “‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,+ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn, kí nǹkan sì lè máa lọ dáadáa fún ọ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.+

17 “‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn.+

18 “‘O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.+

19 “‘O ò gbọ́dọ̀ jalè.+

20 “‘O ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké sí ọmọnìkejì rẹ.+

21 “‘O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyàwó ọmọnìkejì rẹ wọ̀ ọ́ lójú.+ O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò ilé ọmọnìkejì rẹ tàbí oko rẹ̀ tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.’+

22 “Àwọn àṣẹ* yìí ni Jèhófà pa fún gbogbo ìjọ yín lórí òkè náà, látinú iná àti ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà+ pẹ̀lú ohùn tó dún ketekete, kò sì fi ohunkóhun kún un; ó wá kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì, ó sì kó o fún mi.+

23 “Àmọ́ gbàrà tí ẹ gbọ́ ohùn tó ń tinú òkùnkùn náà jáde, nígbà tí iná ń jó ní òkè náà,+ gbogbo olórí ẹ̀yà yín àti àwọn àgbààgbà wá sọ́dọ̀ mi. 24 Ẹ wá sọ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ti fi ògo rẹ̀ àti títóbi rẹ̀ hàn wá, a sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ látinú iná.+ Òní la rí i pé Ọlọ́run lè bá èèyàn sọ̀rọ̀ kí onítọ̀hún má sì kú.+ 25 Ṣé ó wá yẹ ká kú ni? Iná ńlá yìí lè jó wa run. Tí a bá ṣì ń gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa, ó dájú pé a máa kú. 26 Nínú gbogbo aráyé,* ta ló tíì gbọ́ ohùn Ọlọ́run alààyè tó ń sọ̀rọ̀ látinú iná bí a ṣe gbọ́ ọ, tí onítọ̀hún ò sì kú? 27 Ìwọ fúnra rẹ ni kí o sún mọ́ ibẹ̀, kí o lè gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa máa sọ, ìwọ lo sì máa sọ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá bá ọ sọ fún wa, a máa gbọ́, a sì máa ṣe é.’+

28 “Jèhófà gbọ́ ohun tí ẹ sọ fún mi, Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Mo ti gbọ́ ohun tí àwọn èèyàn yìí sọ fún ọ. Gbogbo ohun tí wọ́n sọ ló dáa.+ 29 Ì bá mà dáa o, tí wọ́n bá mú kí ọkàn wọn máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo,+ tí wọ́n ń pa gbogbo àṣẹ mi mọ́,+ nǹkan á máa lọ dáadáa fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn títí láé!+ 30 Lọ sọ fún wọn pé: “Ẹ pa dà sínú àwọn àgọ́ yín.” 31 Àmọ́ kí ìwọ dúró sọ́dọ̀ mi, kí n lè sọ gbogbo àṣẹ, ìlànà àti ìdájọ́ tí o máa kọ́ wọn fún ọ, èyí tí wọ́n á máa tẹ̀ lé ní ilẹ̀ tí màá fún wọn pé kó di tiwọn.’ 32 Kí ẹ rí i pé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín gẹ́lẹ́ lẹ̀ ń ṣe.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+ 33 Gbogbo ọ̀nà tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ máa rìn,+ kí ẹ lè máa wà láàyè, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín, kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ máa gbà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́