ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kíróníkà

      • Wọ́n gbé Àpótí wá láti Kiriati-jéárímù (1-14)

        • Ọlọ́run pa Úsà (9, 10)

1 Kíróníkà 13:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 15:25

1 Kíróníkà 13:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 35:2

1 Kíróníkà 13:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 7:2
  • +1Sa 14:18

1 Kíróníkà 13:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti Ṣíhórì.”

  • *

    Tàbí “àbáwọlé Hámátì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:2, 8
  • +1Sa 6:21-7:1; 2Sa 6:1, 2; 1Kr 15:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2005, ojú ìwé 10

1 Kíróníkà 13:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:9, 12
  • +Ẹk 25:22; Nọ 7:89; 1Sa 4:4; 2Sa 6:2

1 Kíróníkà 13:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 37:5
  • +2Sa 6:3-8

1 Kíróníkà 13:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aro.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:20
  • +1Kr 25:1
  • +2Kr 5:13

1 Kíróníkà 13:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 4:15
  • +Le 10:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2005, ojú ìwé 26-27

1 Kíróníkà 13:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “inú Dáfídì bà jẹ́.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ìbínú Ru sí Úsà.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2005, ojú ìwé 11

1 Kíróníkà 13:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 6:9-11

1 Kíróníkà 13:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:27; 39:5

Àwọn míì

1 Kíró. 13:11Kr 15:25
1 Kíró. 13:2Nọ 35:2
1 Kíró. 13:31Sa 7:2
1 Kíró. 13:31Sa 14:18
1 Kíró. 13:5Nọ 34:2, 8
1 Kíró. 13:51Sa 6:21-7:1; 2Sa 6:1, 2; 1Kr 15:3
1 Kíró. 13:6Joṣ 15:9, 12
1 Kíró. 13:6Ẹk 25:22; Nọ 7:89; 1Sa 4:4; 2Sa 6:2
1 Kíró. 13:7Ẹk 37:5
1 Kíró. 13:72Sa 6:3-8
1 Kíró. 13:8Ẹk 15:20
1 Kíró. 13:81Kr 25:1
1 Kíró. 13:82Kr 5:13
1 Kíró. 13:10Nọ 4:15
1 Kíró. 13:10Le 10:1, 2
1 Kíró. 13:122Sa 6:9-11
1 Kíró. 13:14Jẹ 30:27; 39:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kíróníkà 13:1-14

Kíróníkà Kìíní

13 Dáfídì fọ̀rọ̀ lọ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún pẹ̀lú gbogbo àwọn aṣáájú.+ 2 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ fún gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì pé: “Tí ó bá dára lójú yín tí Jèhófà Ọlọ́run wa sì fọwọ́ sí i, ẹ jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin wa tó kù ní gbogbo agbègbè Ísírẹ́lì àti sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú+ wọn pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko wọn, kí wọ́n lè wá dara pọ̀ mọ́ wa. 3 Kí a sì gbé Àpótí+ Ọlọ́run wa pa dà.” Nítorí wọn kò bójú tó o nígbà ayé Sọ́ọ̀lù.+ 4 Gbogbo ìjọ náà fara mọ́ ọn pé àwọn á ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó tọ́ lójú gbogbo àwọn èèyàn náà. 5 Torí náà, Dáfídì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ láti odò* Íjíbítì títí dé Lebo-hámátì,*+ kí wọ́n lè gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù.+

6 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì lọ sí Báálà,+ sí Kiriati-jéárímù ti Júdà, kí wọ́n lè gbé Àpótí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ wá láti ibẹ̀, ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù,+ ibi tí a ti ń ké pe orúkọ rẹ̀. 7 Àmọ́, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun,+ wọ́n gbé e wá láti ilé Ábínádábù. Úsà àti Áhíò sì ń darí kẹ̀kẹ́ náà.+ 8 Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Ọlọ́run tòótọ́ tọkàntara pẹ̀lú orin, háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì+ àti síńbálì*+ pẹ̀lú kàkàkí.+ 9 Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Kídónì, Úsà na ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá Àpótí náà mú, torí màlúù náà mú kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú dé. 10 Ni ìbínú Jèhófà bá ru sí Úsà, Ó pa á nítorí pé ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá Àpótí+ náà mú, torí náà, ó kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.+ 11 Àmọ́ inú bí Dáfídì* nítorí pé ìbínú Jèhófà ru sí Úsà; wọ́n sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà* títí di òní yìí.

12 Torí náà, ẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́ ba Dáfídì ní ọjọ́ yẹn, ó sì sọ pé: “Ṣé ọ̀dọ̀ mi ló yẹ kí n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá?”+ 13 Dáfídì kò gbé Àpótí náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì, àmọ́ ó ní kí wọ́n gbé e lọ sí ilé Obedi-édómù ará Gátì. 14 Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sì wà ní agbo ilé Obedi-édómù, oṣù mẹ́ta ló fi wà ní ilé rẹ̀, Jèhófà sì ń bù kún agbo ilé Obedi-édómù àti gbogbo ohun tó ní.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́