ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí Fáráò (1-16)

      • Ọlọ́run yóò fi Íjíbítì ṣe èrè fún Bábílónì (17-21)

Ìsíkíẹ́lì 29:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:17, 19; 43:10, 11; Isk 31:2

Ìsíkíẹ́lì 29:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Nínú ẹsẹ yìí àti àwọn tó tẹ̀ lé e, “Náílì” ń tọ́ka sí odò yẹn gangan àti àwọn odò tó ṣàn jáde látinú rẹ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:25; Isk 31:18
  • +Isk 32:2
  • +Isk 29:9

Ìsíkíẹ́lì 29:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 80

Ìsíkíẹ́lì 29:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:33
  • +Isk 32:4

Ìsíkíẹ́lì 29:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “koríko etí omi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 36:6; Jer 37:5-7; Isk 17:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 78

Ìsíkíẹ́lì 29:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìbàdí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 17:5

Ìsíkíẹ́lì 29:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:14; Isk 30:4; 32:12

Ìsíkíẹ́lì 29:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó ti sọ pé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 43:11-13
  • +Isk 29:3

Ìsíkíẹ́lì 29:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 30:12
  • +Jer 44:1
  • +Isk 30:6, 7

Ìsíkíẹ́lì 29:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 31:12; 32:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 8

Ìsíkíẹ́lì 29:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:19
  • +Isk 30:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 8

Ìsíkíẹ́lì 29:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:25, 26

Ìsíkíẹ́lì 29:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:13, 14; Isk 30:14

Ìsíkíẹ́lì 29:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 30:13
  • +Isk 32:2

Ìsíkíẹ́lì 29:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:2; 36:4, 6; Jer 2:18; 37:5-7

Ìsíkíẹ́lì 29:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:9; 27:3, 6
  • +Isk 26:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 8-9

Ìsíkíẹ́lì 29:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 43:10, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 9

Ìsíkíẹ́lì 29:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, láti gbógun ti Tírè.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 30:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 9

Ìsíkíẹ́lì 29:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti fún ilé Ísírẹ́lì lókun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 2:10; Lk 1:69

Àwọn míì

Ìsík. 29:2Jer 25:17, 19; 43:10, 11; Isk 31:2
Ìsík. 29:3Jer 46:25; Isk 31:18
Ìsík. 29:3Isk 32:2
Ìsík. 29:3Isk 29:9
Ìsík. 29:5Jer 25:33
Ìsík. 29:5Isk 32:4
Ìsík. 29:6Ais 36:6; Jer 37:5-7; Isk 17:17
Ìsík. 29:7Jer 17:5
Ìsík. 29:8Jer 46:14; Isk 30:4; 32:12
Ìsík. 29:9Jer 43:11-13
Ìsík. 29:9Isk 29:3
Ìsík. 29:10Isk 30:12
Ìsík. 29:10Jer 44:1
Ìsík. 29:10Isk 30:6, 7
Ìsík. 29:11Isk 31:12; 32:13
Ìsík. 29:12Jer 46:19
Ìsík. 29:12Isk 30:23
Ìsík. 29:13Jer 46:25, 26
Ìsík. 29:14Jẹ 10:13, 14; Isk 30:14
Ìsík. 29:15Isk 30:13
Ìsík. 29:15Isk 32:2
Ìsík. 29:16Ais 30:2; 36:4, 6; Jer 2:18; 37:5-7
Ìsík. 29:18Jer 25:9; 27:3, 6
Ìsík. 29:18Isk 26:7
Ìsík. 29:19Jer 43:10, 12
Ìsík. 29:20Isk 30:9, 10
Ìsík. 29:211Sa 2:10; Lk 1:69
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 29:1-21

Ìsíkíẹ́lì

29 Ní ọdún kẹwàá, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kejìlá, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀ pé: 2 “Ọmọ èèyàn, yíjú sọ́dọ̀ Fáráò ọba Íjíbítì, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sórí rẹ̀ àti sórí gbogbo Íjíbítì.+ 3 Sọ pé: ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

“Èmi yóò bá ọ jà, ìwọ Fáráò ọba Íjíbítì,+

Ẹran ńlá inú àwọn odò Náílì* rẹ̀,+

Tó sọ pé, ‘Èmi ni mo ni odò Náílì mi.

Ara mi ni mo ṣe é fún.’+

 4 Àmọ́ èmi yóò fi ìwọ̀ kọ́ ẹnu rẹ, màá sì mú kí ẹja inú odò Náílì rẹ lẹ̀ mọ́ àwọn ìpẹ́ rẹ.

Èmi yóò mú ọ jáde láti inú odò Náílì rẹ pẹ̀lú gbogbo ẹja inú odò Náílì tó lẹ̀ mọ́ àwọn ìpẹ́ rẹ.

 5 Èmi yóò pa ọ́ tì sínú aṣálẹ̀, ìwọ àti gbogbo ẹja odò Náílì rẹ.

Orí pápá gbalasa ni wàá ṣubú sí, wọn ò ní kó ọ jọ, wọn ò sì ní ṣà ọ́ jọ.+

Màá fi ọ́ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko orí ilẹ̀ àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.+

 6 Gbogbo àwọn tó ń gbé Íjíbítì á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,

Torí wọn ò lè ti ilé Ísírẹ́lì lẹ́yìn mọ́, wọn ò yàtọ̀ sí pòròpórò* lásán.+

 7 Ìwọ fọ́ nígbà tí wọ́n dì ọ́ lọ́wọ́ mú,

O sì mú kí èjìká wọn ya.

Ìwọ ṣẹ́ nígbà tí wọ́n fi ara tì ọ́,

O sì mú kí ẹsẹ̀* wọn di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.”+

8 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Màá fi idà bá ọ jà,+ màá sì pa èèyàn àti ẹranko inú rẹ run. 9 Ilẹ̀ Íjíbítì yóò pa run, yóò sì di ahoro;+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, torí o ti sọ pé,* ‘Èmi ni mo ni odò Náílì; èmi ni mo ṣe é.’+ 10 Torí náà, màá bá ìwọ àti odò Náílì rẹ jà, màá mú kí ilẹ̀ Íjíbítì dá páropáro kó sì gbẹ, yóò di ahoro,+ láti Mígídólì+ dé Síénè,+ títí dé ààlà Etiópíà. 11 Èèyàn tàbí ẹran ọ̀sìn kankan kò ní fi ẹsẹ̀ rin ibẹ̀ kọjá,+ ẹnikẹ́ni ò sì ní gbé ibẹ̀ fún ogójì (40) ọdún. 12 Èmi yóò mú kí ilẹ̀ Íjíbítì di ahoro ju àwọn ilẹ̀ yòókù lọ, àwọn ìlú rẹ̀ yóò sì ṣófo ju àwọn ìlú yòókù lọ fún ogójì (40) ọdún;+ màá tú àwọn ará Íjíbítì ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀.”+

13 “‘Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Lẹ́yìn ogójì (40) ọdún, èmi yóò pa dà kó àwọn ará Íjíbítì jọ láti àárín àwọn èèyàn tí wọ́n tú ká sí;+ 14 Èmi yóò mú àwọn ẹrú Íjíbítì pa dà wá sí ilẹ̀ Pátírọ́sì,+ ilẹ̀ tí wọ́n ti wá, wọ́n á sì di ìjọba tí kò já mọ́ nǹkan kan níbẹ̀. 15 Íjíbítì yóò rẹlẹ̀ ju àwọn ìjọba yòókù lọ, kò ní jọba lé àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́,+ màá sì mú kí wọ́n kéré débi pé wọn ò ní lè tẹ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lórí ba.+ 16 Ilé Ísírẹ́lì ò tún ní gbára lé Íjíbítì mọ́,+ àmọ́ ṣe ló máa rán wọn létí pé wọ́n ṣàṣìṣe nígbà tí wọ́n ní kí àwọn ará Íjíbítì ran àwọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.”’”

17 Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kìíní, Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Ọmọ èèyàn, Nebukadinésárì*+ ọba Bábílónì mú kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣiṣẹ́ kára láti gbógun ti Tírè.+ Gbogbo orí wọn pá, gbogbo èjìká wọn sì bó. Àmọ́ òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kò gba owó iṣẹ́ kankan fún gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lórí Tírè.

19 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Èmi yóò fún Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ yóò kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ, yóò sì kó ọ̀pọ̀ ẹrù rẹ̀, yóò kó o bọ̀ láti ogun; ìyẹn yóò sì jẹ́ èrè fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀.’

20 “‘Torí iṣẹ́ tó ṣe fún mi, èmi yóò fún un ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi ṣe èrè iṣẹ́ àṣekára tó ṣe láti gbógun tì í,’*+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.

21 “Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò mú kí ìwo kan hù jáde fún ilé Ísírẹ́lì,*+ èmi yóò sì fún ọ láǹfààní láti sọ̀rọ̀ láàárín wọn; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́