Sáàmù
114 Nígbà tí Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì,+
Tí ilé Jékọ́bù jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó ń sọ èdè àjèjì,
2 Júdà di ibi mímọ́ rẹ̀,
Ísírẹ́lì di ibi tó ń ṣàkóso lé lórí.+
Kí ló dé tí o fi yíjú pa dà, ìwọ Jọ́dánì?+
6 Kí ló dé tí ẹ̀yin òkè ńlá fi ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àgbò,
Tí ẹ̀yin òkè kéékèèké sì ń ta bí ọ̀dọ́ àgùntàn?