Sáàmù
Orin. Orin Dáfídì.
108 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run.
Màá fi gbogbo ara* kọrin, màá sì lo ohun ìkọrin.+
2 Jí, ìwọ ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù.+
Màá jí ní kùtùkùtù.
3 Jèhófà, màá yìn ọ́ láàárín àwọn èèyàn,
Màá sì fi orin yìn ọ́* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.
4 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga gan-an, ó dé ọ̀run,+
Òtítọ́ rẹ sì ga dé sánmà.
5 Gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;
Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+
6 Kí a lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ sílẹ̀,
Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá sílẹ̀, kí o sì dá mi lóhùn.+
7 Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ nínú ìjẹ́mímọ́* rẹ̀ pé:
“Màá yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, màá fi Ṣékémù+ ṣe ogún fún àwọn èèyàn mi,
9 Móábù ni bàsíà tí mo fi ń wẹ ẹsẹ̀.+
Orí Édómù ni màá ju bàtà mi sí.+
Màá kígbe ìṣẹ́gun lórí Filísíà.”+
10 Ta ló máa mú mi wá sí ìlú olódi?
Ta ló máa mú mi lọ sí Édómù?+
11 Ìwọ Ọlọ́run tí o ti kọ̀ wá sílẹ̀ náà ni,
Ìwọ Ọlọ́run wa, tí o kò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.+