ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 27
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àjàgà Bábílónì (1-11)

      • Ọlọ́run ní kí Sedekáyà fi ara rẹ̀ sábẹ́ Bábílónì (12-22)

Jeremáyà 27:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 27

Jeremáyà 27:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 25:12, 13; Ọbd 1
  • +Jer 48:1; Isk 25:8, 9
  • +Jer 49:1, 2; Isk 25:2
  • +Ais 23:1; Jer 47:4; Isk 26:3
  • +Ais 23:4; Isk 28:21; Joẹ 3:4

Jeremáyà 27:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹni tí ó tọ́ lójú mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 4:17

Jeremáyà 27:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:9; 28:14; 43:10; Da 2:37, 38

Jeremáyà 27:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 137:8; Jer 50:14, 27; Da 5:26, 30
  • +Jer 25:12, 14; 51:11

Jeremáyà 27:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àìsàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 26:7, 8

Jeremáyà 27:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “sinmi.”

Jeremáyà 27:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:17; 1Kr 3:15; Jer 37:1
  • +Jer 38:2, 20

Jeremáyà 27:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:7
  • +2Ọb 25:3
  • +Jer 21:9; Isk 14:21

Jeremáyà 27:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 28:1, 2, 11; 37:19
  • +Jer 14:14; 23:21; 28:15; 29:8, 9; Isk 13:6

Jeremáyà 27:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 20:6; 29:21; Isk 13:3

Jeremáyà 27:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:11, 13; 2Kr 36:7; Jer 28:1-3; Da 1:1, 2
  • +Jer 14:13

Jeremáyà 27:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:11; 38:17

Jeremáyà 27:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Jeremáyà 27:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Òkun bàbà tó wà ní tẹ́ńpìlì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:15; 2Ọb 25:17; 2Kr 4:11, 12; Jer 52:21
  • +1Ọb 7:23
  • +1Ọb 7:27; 2Ọb 25:16; 2Kr 4:11, 14

Jeremáyà 27:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:14, 15; 2Kr 36:10; Jer 24:1; Da 1:2, 3

Jeremáyà 27:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Jeremáyà 27:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:13, 14; 2Kr 36:18; Jer 52:17, 18; Da 5:3
  • +Ẹsr 1:7; 5:14

Àwọn míì

Jer. 27:3Isk 25:12, 13; Ọbd 1
Jer. 27:3Jer 48:1; Isk 25:8, 9
Jer. 27:3Jer 49:1, 2; Isk 25:2
Jer. 27:3Ais 23:1; Jer 47:4; Isk 26:3
Jer. 27:3Ais 23:4; Isk 28:21; Joẹ 3:4
Jer. 27:5Da 4:17
Jer. 27:6Jer 25:9; 28:14; 43:10; Da 2:37, 38
Jer. 27:7Sm 137:8; Jer 50:14, 27; Da 5:26, 30
Jer. 27:7Jer 25:12, 14; 51:11
Jer. 27:8Isk 26:7, 8
Jer. 27:122Ọb 24:17; 1Kr 3:15; Jer 37:1
Jer. 27:12Jer 38:2, 20
Jer. 27:132Ọb 25:7
Jer. 27:132Ọb 25:3
Jer. 27:13Jer 21:9; Isk 14:21
Jer. 27:14Jer 28:1, 2, 11; 37:19
Jer. 27:14Jer 14:14; 23:21; 28:15; 29:8, 9; Isk 13:6
Jer. 27:15Jer 20:6; 29:21; Isk 13:3
Jer. 27:162Ọb 24:11, 13; 2Kr 36:7; Jer 28:1-3; Da 1:1, 2
Jer. 27:16Jer 14:13
Jer. 27:17Jer 27:11; 38:17
Jer. 27:191Ọb 7:15; 2Ọb 25:17; 2Kr 4:11, 12; Jer 52:21
Jer. 27:191Ọb 7:23
Jer. 27:191Ọb 7:27; 2Ọb 25:16; 2Kr 4:11, 14
Jer. 27:202Ọb 24:14, 15; 2Kr 36:10; Jer 24:1; Da 1:2, 3
Jer. 27:222Ọb 25:13, 14; 2Kr 36:18; Jer 52:17, 18; Da 5:3
Jer. 27:22Ẹsr 1:7; 5:14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 27:1-22

Jeremáyà

27 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jèhóákímù ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, Jeremáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí látọ̀dọ̀ Jèhófà: 2 “Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí, ‘Ṣe àwọn ọ̀já àti àwọn ọ̀pá àjàgà fún ara rẹ, kí o sì fi wọ́n sí ọrùn rẹ. 3 Lẹ́yìn náà, fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọba Édómù,+ ọba Móábù,+ ọba àwọn ọmọ Ámónì,+ ọba Tírè+ àti ọba Sídónì+ nípasẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ tó wá sí Jerúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà ọba Júdà. 4 Ní kí wọ́n sọ fún ọ̀gá wọn, pé:

“‘“Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ohun tí ẹ ó sọ fún àwọn ọ̀gá yín rèé, 5 ‘Èmi ni mo dá ayé, èèyàn àti ẹranko tó wà lórí ilẹ̀ nípa agbára ńlá mi àti nípa apá mi tí mo nà jáde, mo sì ti fún ẹni tí mo fẹ́.*+ 6 Ní báyìí, mo ti fi gbogbo ilẹ̀ yìí lé ọwọ́ ìránṣẹ́ mi, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì, kódà mo ti fún un ní àwọn ẹran inú igbó kí wọ́n lè máa sìn ín. 7 Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa sin òun àti ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ọmọ rẹ̀, títí di àkókò tí ìjọba rẹ̀ máa dópin,+ tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá yóò sì sọ ọ́ di ẹrú wọn.’+

8 “‘“‘Tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba èyíkéyìí bá kọ̀ láti sin Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì, tí kò sì fi ọrùn rẹ̀ sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, ńṣe ni màá fìyà jẹ orílẹ̀-èdè yẹn nípa idà,+ ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn,’* ni Jèhófà wí, ‘títí màá fi run wọ́n láti ọwọ́ rẹ̀.’

9 “‘“‘Torí náà, ẹ má fetí sí àwọn wòlíì yín, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín, àwọn onídán yín àti àwọn oníṣẹ́ oṣó yín, tí wọ́n ń sọ fún yín pé: “Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì.” 10 Nítorí èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, kí ẹ lè lọ jìnnà kúrò lórí ilẹ̀ yín, kí n lè fọ́n yín ká, kí ẹ sì ṣègbé.

11 “‘“‘Àmọ́, orílẹ̀-èdè tó bá fi ọrùn rẹ̀ sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, tí ó sì sìn ín, ni màá jẹ́ kó dúró* sórí ilẹ̀ rẹ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘láti máa ro ó, kí ó sì máa gbé orí rẹ̀.’”’”

12 Mo tún bá Ọba Sedekáyà+ ti Júdà sọ̀rọ̀ lọ́nà kan náà pé: “Ẹ mú ọrùn yín wá sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, kí ẹ sì sin òun àti àwọn èèyàn rẹ̀, kí ẹ lè máa wà láàyè.+ 13 Kí ló dé tí ẹ ó fi jẹ́ kí idà,+ ìyàn+ àti àjàkálẹ̀ àrùn+ pa yín bí Jèhófà ti sọ nípa orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Bábílónì? 14 Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó ń sọ fún yín pé, ‘Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì,’+ nítorí èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+

15 “‘Nítorí mi ò rán wọn,’ ni Jèhófà wí, ‘ṣùgbọ́n wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi, kí n lè fọ́n yín ká, kí ẹ sì ṣègbé, ẹ̀yin àti àwọn wòlíì tó ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.’”+

16 Mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn èèyàn yìí pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yín tó ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, pé: “Ẹ wò ó! Àwọn nǹkan èlò ilé Jèhófà ni a ó kó pa dà láti Bábílónì láìpẹ́!”+ nítorí èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+ 17 Ẹ má fetí sí wọn. Ẹ sin ọba Bábílónì kí ẹ sì máa wà láàyè.+ Kí ló dé tí ìlú yìí fi máa di àwókù? 18 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé wòlíì ni wọ́n, tí ọ̀rọ̀ Jèhófà sì wà lẹ́nu wọn, ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí wọ́n bẹ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, pé kí wọ́n má ṣe kó àwọn nǹkan èlò tó ṣẹ́ kù ní ilé Jèhófà àti ní ilé* ọba Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.’

19 “Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí nípa àwọn òpó,+ Òkun,*+ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti àwọn nǹkan èlò tó ṣẹ́ kù nínú ìlú yìí, 20 èyí tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ò kó lọ nígbà tó mú Jekonáyà ọmọ Jèhóákímù, ọba Júdà, láti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì pẹ̀lú gbogbo àwọn èèyàn pàtàkì Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+ 21 Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nípa àwọn nǹkan èlò tó ṣẹ́ kù ní ilé Jèhófà àti ní ilé* ọba Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù nìyí: 22 ‘“Bábílónì ni a ó kó wọn wá,+ ibẹ̀ sì ni wọ́n á máa wà títí di ọjọ́ tí màá yí ojú mi sí wọn,” ni Jèhófà wí. “Ìgbà náà ni màá mú wọn pa dà wá, tí màá sì mú wọn bọ̀ sípò ní ibí yìí.”’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́