ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 38
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Wọ́n ju Jeremáyà sínú kòtò omi (1-6)

      • Ebedi-mélékì gba Jeremáyà sílẹ̀ (7-13)

      • Jeremáyà rọ Sedekáyà pé kó juwọ́ sílẹ̀ (14-28)

Jeremáyà 38:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 37:3
  • +Jer 21:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 55

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2006, ojú ìwé 14-15

Jeremáyà 38:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àìsàn.”

  • *

    Ní Héb., “jáde sí.”

  • *

    Tàbí “á sì sá àsálà fún ọkàn rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:13; 29:18; Isk 7:15
  • +Jer 21:8-10

Jeremáyà 38:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:1, 2; 2Kr 36:17

Jeremáyà 38:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọwọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 26:11

Jeremáyà 38:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 33:1; 37:21; 38:28

Jeremáyà 38:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òṣìṣẹ́ láàfin.”

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:16
  • +Jer 37:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2012, ojú ìwé 31

Jeremáyà 38:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Jeremáyà 38:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 52:6

Jeremáyà 38:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2012, ojú ìwé 31

Jeremáyà 38:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 37:21

Jeremáyà 38:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹni tó dá ọkàn yìí fún wa.”

  • *

    Tàbí “tó ń lépa ọkàn rẹ.”

Jeremáyà 38:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “jáde sí.”

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ yóò máa wà láàyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:9; 27:12

Jeremáyà 38:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “jáde sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:8, 9
  • +2Ọb 25:6; Jer 39:5

Jeremáyà 38:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ.”

Jeremáyà 38:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “jáde sí.”

Jeremáyà 38:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

  • *

    Ní Héb., “Àwọn ọkùnrin tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:3
  • +Ida 1:2

Jeremáyà 38:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:7
  • +Jer 52:8, 13

Jeremáyà 38:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 38:4

Jeremáyà 38:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 37:15

Jeremáyà 38:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 15:20; 32:2; 33:1; 37:21; 39:13, 14
  • +2Ọb 25:8, 9; 2Kr 36:17

Àwọn míì

Jer. 38:1Jer 37:3
Jer. 38:1Jer 21:1, 2
Jer. 38:2Jer 27:13; 29:18; Isk 7:15
Jer. 38:2Jer 21:8-10
Jer. 38:32Ọb 25:1, 2; 2Kr 36:17
Jer. 38:4Jer 26:11
Jer. 38:6Jer 33:1; 37:21; 38:28
Jer. 38:7Jer 39:16
Jer. 38:7Jer 37:13
Jer. 38:9Jer 52:6
Jer. 38:112Ọb 20:13
Jer. 38:13Jer 37:21
Jer. 38:17Jer 21:9; 27:12
Jer. 38:182Ọb 25:8, 9
Jer. 38:182Ọb 25:6; Jer 39:5
Jer. 38:22Jer 39:3
Jer. 38:22Ida 1:2
Jer. 38:232Ọb 25:7
Jer. 38:23Jer 52:8, 13
Jer. 38:25Jer 38:4
Jer. 38:26Jer 37:15
Jer. 38:28Jer 15:20; 32:2; 33:1; 37:21; 39:13, 14
Jer. 38:282Ọb 25:8, 9; 2Kr 36:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 38:1-28

Jeremáyà

38 Ìgbà náà ni Ṣẹfatáyà ọmọ Mátánì, Gẹdaláyà ọmọ Páṣúrì, Júkálì+ ọmọ Ṣelemáyà àti Páṣúrì + ọmọ Málíkíjà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ń sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: 2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹni tó bá dúró sí ìlú yìí ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa.+ Àmọ́, ẹni tó bá fi ara rẹ̀ lé* ọwọ́ àwọn ará Kálídíà á máa wà láàyè, á jèrè ẹ̀mí rẹ̀, á sì wà láàyè.’*+ 3 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ó dájú pé ìlú yìí ni a ó fà lé ọwọ́ àwọn ọmọ ogun ọba Bábílónì, yóò sì gbà á.’”+

4 Àwọn ìjòyè sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, ní kí wọ́n pa ọkùnrin yìí,+ torí bó ṣe máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn* àwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́ kù nínú ìlú yìí àti gbogbo àwọn èèyàn náà nìyẹn, tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Nítorí kì í ṣe àlàáfíà àwọn èèyàn yìí ni ọkùnrin yìí ń wá, bí kò ṣe àjálù wọn.” 5 Ọba Sedekáyà dáhùn pé: “Ẹ wò ó! Ọwọ́ yín ni ọkùnrin náà wà, torí kò sí nǹkan kan tí ọba lè ṣe láti dá yín dúró.”

6 Torí náà, wọ́n mú Jeremáyà, wọ́n sì jù ú sínú kòtò omi Málíkíjà ọmọ ọba, èyí tó wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+ Wọ́n fi okùn sọ Jeremáyà kalẹ̀. Nígbà yẹn, kò sí omi nínú kòtò omi náà, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú ẹrẹ̀ náà.

7 Ebedi-mélékì+ ará Etiópíà, tó jẹ́ ìwẹ̀fà* ní ilé* ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremáyà sínú kòtò omi. Lásìkò yìí, ọba wà níbi tó jókòó sí ní Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì,+ 8 torí náà, Ebedi-mélékì jáde kúrò ní ilé* ọba, ó sì sọ fún ọba pé: 9 “Olúwa mi ọba, ìwà ìkà gbáà ni àwọn ọkùnrin yìí hù sí wòlíì Jeremáyà! Wọ́n ti jù ú sínú kòtò omi, ibẹ̀ ló sì máa kú sí nítorí ìyàn, torí kò sí búrẹ́dì mọ́ ní ìlú yìí.”+

10 Ìgbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedi-mélékì ará Etiópíà pé: “Mú ọgbọ̀n (30) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ láti ibí yìí, kí o sì gbé wòlíì Jeremáyà gòkè láti inú kòtò omi kí ó tó kú.” 11 Torí náà, Ebedi-mélékì kó àwọn ọkùnrin náà, ó sì lọ sí ilé* ọba, sí apá kan lábẹ́ ibi ìṣúra,+ wọ́n sì kó àwọn àkísà àti àwọn àjákù aṣọ níbẹ̀, wọ́n sì fi okùn sọ̀ wọ́n sísàlẹ̀ sí Jeremáyà nínú kòtò omi náà. 12 Ni Ebedi-mélékì ará Etiópíà bá sọ fún Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, fi àwọn àkísà náà àti àwọn àjákù aṣọ náà tẹ́ abíyá rẹ lórí okùn náà.” Jeremáyà sì ṣe bẹ́ẹ̀, 13 wọ́n fi okùn náà fa Jeremáyà jáde, wọ́n sì gbé e gòkè kúrò nínú kòtò omi náà. Jeremáyà sì wà ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.+

14 Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí wòlíì Jeremáyà pé kó wá sọ́dọ̀ òun ní àbáwọlé kẹta, tó wà ní ilé Jèhófà, ọba sì sọ fún Jeremáyà pé: “Ohun kan wà tí mo fẹ́ bi ọ́. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún mi.” 15 Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Tí mo bá sọ fún ọ, ó dájú pé wàá pa mí. Tí mo bá sì fún ọ nímọ̀ràn, o ò ní fetí sí mi.” 16 Torí náà, Ọba Sedekáyà búra ní bòókẹ́lẹ́ fún Jeremáyà pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tó fún wa ní ẹ̀mí wa,* mi ò ní pa ọ́, mi ò sì ní fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn èèyàn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ.”*

17 Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Bí o bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á dá ẹ̀mí rẹ sí,* wọn kò ní dáná sun ìlú yìí, wọn kò sì ní pa ìwọ àti agbo ilé rẹ.+ 18 Àmọ́, bí o kò bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, a ó fa ìlú yìí lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, wọ́n á dáná sun ún,+ o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’”+

19 Ìgbà náà ni Ọba Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé: “Ẹ̀rù àwọn Júù tí wọ́n ti sá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà ń bà mí, nítorí tí wọ́n bá fà mí lé wọn lọ́wọ́, wọ́n lè ṣe mí ṣúkaṣùka.” 20 Ṣùgbọ́n Jeremáyà sọ pé: “Wọn kò ní fà ọ́ lé wọn lọ́wọ́. Jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà lórí ohun tí mò ń sọ fún ọ, nǹkan á lọ dáadáa fún ọ, wàá* sì máa wà láàyè. 21 Àmọ́, bí o bá kọ̀ láti fi ara rẹ lé* wọn lọ́wọ́, ohun tí Jèhófà fi hàn mí nìyí: 22 Wò ó! Gbogbo obìnrin tó ṣẹ́ kù sí ilé* ọba Júdà ni a mú jáde wá sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè ọba Bábílónì,+ wọ́n sì ń sọ pé,

‘Àwọn ọkùnrin tí o fọkàn tán* ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ.+

Wọ́n ti mú kí ẹsẹ̀ rẹ rì sínú ẹrọ̀fọ̀.

Ní báyìí, wọ́n ti sá pa dà lẹ́yìn rẹ.’

23 Gbogbo ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ ni wọ́n á kó wá fún àwọn ará Kálídíà, o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́, àmọ́ ọba Bábílónì+ máa mú ọ, nítorí rẹ sì ni wọ́n á fi dáná sun ìlú yìí.”+

24 Sedekáyà sì sọ fún Jeremáyà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí, kí o má bàa kú. 25 Tí àwọn ìjòyè bá sì gbọ́ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n wá bá ọ, tí wọ́n sì sọ fún ọ pé, ‘Jọ̀wọ́, sọ fún wa, ohun tí o bá ọba sọ. Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún wa, a ò ní pa ọ́.+ Kí ni ọba sọ fún ọ?’ 26 kí o fún wọn lésì pé, ‘Ṣe ni mò ń bẹ ọba pé kó má ṣe dá mi pa dà sí ilé Jèhónátánì láti kú sí ibẹ̀.’”+

27 Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ìjòyè wọlé wá bá Jeremáyà, wọ́n sì bi í ní ìbéèrè. Ó sọ gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ fún un pé kó sọ fún wọn. Torí náà, wọn kò bá a sọ̀rọ̀ mọ́, nítorí ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí òun àti ọba jọ sọ. 28 Jeremáyà kò kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́+ títí di ọjọ́ tí wọ́n gba Jerúsálẹ́mù; ibẹ̀ ló ṣì wà nígbà tí wọ́n gba Jerúsálẹ́mù.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́