ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Wọ́n ráhùn pé wọn ò rí omi mu ní Hórébù (1-4)

      • Omi jáde látinú àpáta (5-7)

      • Àwọn ọmọ Ámálékì gbógun ja Ísírẹ́lì, àmọ́ wọn ò borí (8-16)

Ẹ́kísódù 17:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:12
  • +Nọ 33:2
  • +Nọ 33:14

Ẹ́kísódù 17:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 5:19, 21; Nọ 14:2, 3; 20:3
  • +Nọ 14:22; Sm 78:18, 22; 106:14

Ẹ́kísódù 17:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 16:2, 3

Ẹ́kísódù 17:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:20

Ẹ́kísódù 17:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 20:8; Di 8:14, 15; Ne 9:15; Sm 78:15; 105:41; 1Kọ 10:1, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2018, ojú ìwé 13-14

Ẹ́kísódù 17:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Àdánwò.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ìjà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 9:22
  • +Sm 81:7
  • +Di 6:16; Sm 95:8, 9; Heb 3:8, 9

Ẹ́kísódù 17:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 36:12
  • +Di 25:17; 1Sa 15:2

Ẹ́kísódù 17:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 11:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2002, ojú ìwé 9-10

Ẹ́kísódù 17:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 11:15
  • +Ẹk 24:13, 14

Ẹ́kísódù 17:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 11:12

Ẹ́kísódù 17:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 24:20; Di 25:19; 1Kr 4:42, 43

Ẹ́kísódù 17:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Òpó Àmì Mi.”

Ẹ́kísódù 17:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 19:1
  • +1Sa 15:20; Ẹst 9:24

Àwọn míì

Ẹ́kís. 17:1Nọ 33:12
Ẹ́kís. 17:1Nọ 33:2
Ẹ́kís. 17:1Nọ 33:14
Ẹ́kís. 17:2Ẹk 5:19, 21; Nọ 14:2, 3; 20:3
Ẹ́kís. 17:2Nọ 14:22; Sm 78:18, 22; 106:14
Ẹ́kís. 17:3Ẹk 16:2, 3
Ẹ́kís. 17:5Ẹk 7:20
Ẹ́kís. 17:6Nọ 20:8; Di 8:14, 15; Ne 9:15; Sm 78:15; 105:41; 1Kọ 10:1, 4
Ẹ́kís. 17:7Di 9:22
Ẹ́kís. 17:7Sm 81:7
Ẹ́kís. 17:7Di 6:16; Sm 95:8, 9; Heb 3:8, 9
Ẹ́kís. 17:8Jẹ 36:12
Ẹ́kís. 17:8Di 25:17; 1Sa 15:2
Ẹ́kís. 17:9Nọ 11:28
Ẹ́kís. 17:10Joṣ 11:15
Ẹ́kís. 17:10Ẹk 24:13, 14
Ẹ́kís. 17:13Joṣ 11:12
Ẹ́kís. 17:14Nọ 24:20; Di 25:19; 1Kr 4:42, 43
Ẹ́kís. 17:16Ifi 19:1
Ẹ́kís. 17:161Sa 15:20; Ẹst 9:24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 17:1-16

Ẹ́kísódù

17 Gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní aginjù Sínì+ láti ibì kan sí ibòmíì bí Jèhófà ṣe pàṣẹ,+ wọ́n sì pàgọ́ sí Réfídímù.+ Àmọ́ àwọn èèyàn náà ò rí omi mu.

2 Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bá Mósè jà,+ wọ́n sì ń sọ pé: “Fún wa lómi mu.” Àmọ́ Mósè bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá mi jà? Kí ló dé tí ẹ̀ ń dán Jèhófà wò?”+ 3 Síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ àwọn èèyàn náà gan-an níbẹ̀, wọ́n sì ń kùn sí Mósè ṣáá,+ wọ́n ń sọ pé: “Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì kí o lè fi òùngbẹ pa àwa àti àwọn ọmọ wa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa?” 4 Níkẹyìn, Mósè ké pe Jèhófà, ó ní: “Kí ni màá ti ṣe àwọn èèyàn yìí sí? Wọn ò ní pẹ́ sọ mí lókùúta!”

5 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Máa lọ níwájú àwọn èèyàn náà, kí o sì mú lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì dání pẹ̀lú ọ̀pá rẹ tí o fi lu odò Náílì.+ Mú un dání kí o sì máa lọ. 6 Wò ó! Èmi yóò dúró níwájú rẹ lórí àpáta tó wà ní Hórébù. Kí o lu àpáta náà, omi yóò jáde látinú rẹ̀, àwọn èèyàn náà á sì mu ún.”+ Mósè ṣe bẹ́ẹ̀ níṣojú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì. 7 Ó wá pe ibẹ̀ ní Másà*+ àti Mẹ́ríbà,*+ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá a jà àti pé wọ́n dán Jèhófà wò,+ wọ́n ní: “Ṣé Jèhófà wà láàárín wa àbí kò sí?”

8 Àwọn ọmọ Ámálékì+ wá bá Ísírẹ́lì jà ní Réfídímù.+ 9 Ni Mósè bá sọ fún Jóṣúà+ pé: “Bá wa yan àwọn ọkùnrin, kí o sì lọ bá àwọn ọmọ Ámálékì jà. Ní ọ̀la, màá dúró sórí òkè, màá sì mú ọ̀pá Ọlọ́run tòótọ́ dání.” 10 Jóṣúà ṣe ohun tí Mósè sọ fún un,+ ó sì bá àwọn ọmọ Ámálékì jà. Mósè, Áárónì àti Húrì  + wá gun òkè náà lọ.

11 Tí ọwọ́ Mósè bá wà lókè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń borí, àmọ́ tó bá ti lè gbé ọwọ́ rẹ̀ wálẹ̀, àwọn ọmọ Ámálékì á máa borí. 12 Nígbà tí ọwọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ro Mósè, wọ́n gbé òkúta kan sábẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé e. Áárónì àti Húrì wá dúró sí ẹ̀gbẹ́ Mósè lọ́tùn-ún àti lósì, wọ́n bá a gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ọwọ́ rẹ̀ sì dúró gbọn-in títí oòrùn fi wọ̀. 13 Bí Jóṣúà ṣe fi idà ṣẹ́gun Ámálékì àti àwọn èèyàn rẹ̀ nìyẹn.+

14 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé fún ìrántí, kí o sì tún un sọ fún Jóṣúà pé, ‘Màá mú kí wọ́n gbàgbé Ámálékì pátápátá lábẹ́ ọ̀run.’”+ 15 Mósè mọ pẹpẹ kan, ó sì sọ ọ́ ní Jèhófà-nisì,* 16 ó ní: “Torí ó gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Jáà,+ Jèhófà yóò máa gbógun ja Ámálékì láti ìran dé ìran.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́