ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sítà 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sítà

      • Módékáì ṣọ̀fọ̀ (1-5)

      • Módékáì ní kí Ẹ́sítà bá àwọn bẹ ọba (6-17)

Ẹ́sítà 4:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 2:5
  • +Ẹst 3:8-11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 131-132

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2011, ojú ìwé 21-22

Ẹ́sítà 4:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ẹ́sítà 4:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 1:1
  • +2Kr 20:3; Ẹsr 8:21
  • +Da 9:3

Ẹ́sítà 4:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Ẹ́sítà 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 3:9
  • +Ẹst 3:8, 13

Ẹ́sítà 4:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Súsà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 3:14, 15
  • +Ẹst 2:20

Ẹ́sítà 4:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 2:5, 7

Ẹ́sítà 4:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹst 5:1
  • +Ẹst 5:2; 8:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 133

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2011, ojú ìwé 22-23

Ẹ́sítà 4:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 12:22; Ais 54:17
  • +Ẹst 2:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 133

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2011, ojú ìwé 23

Ẹ́sítà 4:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Súsà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 20:3; Ẹsr 8:21
  • +Ẹst 5:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2006, ojú ìwé 10

Àwọn míì

Ẹ́sít. 4:1Ẹst 2:5
Ẹ́sít. 4:1Ẹst 3:8-11
Ẹ́sít. 4:3Ẹst 1:1
Ẹ́sít. 4:32Kr 20:3; Ẹsr 8:21
Ẹ́sít. 4:3Da 9:3
Ẹ́sít. 4:7Ẹst 3:9
Ẹ́sít. 4:7Ẹst 3:8, 13
Ẹ́sít. 4:8Ẹst 3:14, 15
Ẹ́sít. 4:8Ẹst 2:20
Ẹ́sít. 4:10Ẹst 2:5, 7
Ẹ́sít. 4:11Ẹst 5:1
Ẹ́sít. 4:11Ẹst 5:2; 8:4
Ẹ́sít. 4:141Sa 12:22; Ais 54:17
Ẹ́sít. 4:14Ẹst 2:17
Ẹ́sít. 4:162Kr 20:3; Ẹsr 8:21
Ẹ́sít. 4:16Ẹst 5:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́sítà 4:1-17

Ẹ́sítà

4 Nígbà tí Módékáì+ gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ṣe,+ ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì da eérú sórí. Ó wá lọ sí àárín ìlú, ó gbé ohùn sókè, ó sì ń sunkún kíkankíkan. 2 Ó ń lọ títí ó fi dé ẹnubodè ọba, àmọ́ kò wọlé, torí ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọ̀fọ̀* wọ ẹnubodè ọba. 3 Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ láàárín àwọn Júù tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀*+ tí ọ̀rọ̀ ọba àti àṣẹ rẹ̀ ti dé, wọ́n ń gbààwẹ̀,+ wọ́n ń sunkún, wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀ lára wọn sùn sórí aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú.+ 4 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́bìnrin Ẹ́sítà àti àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ wọlé wá, tí wọ́n sì sọ fún un, ìdààmú bá ayaba gidigidi. Ó wá fi aṣọ ránṣẹ́ sí Módékáì, pé kó wọ̀ ọ́ dípò aṣọ ọ̀fọ̀* tó wà lọ́rùn rẹ̀, àmọ́ kò gbà á. 5 Ni Ẹ́sítà bá pe Hátákì, ọ̀kan lára àwọn ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ọba yàn láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún Ẹ́sítà, ó sì ní kó lọ béèrè lọ́wọ́ Módékáì ohun tí èyí túmọ̀ sí àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀.

6 Torí náà, Hátákì lọ bá Módékáì ní gbàgede ìlú tó wà níwájú ẹnubodè ọba. 7 Módékáì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fún Hátákì àti iye owó+ tí Hámánì sọ pé òun máa san sínú ibi ìṣúra ọba kí wọ́n lè pa àwọn Júù run.+ 8 Ó tún fún un ní ẹ̀dà ìwé àṣẹ tí wọ́n gbé jáde ní Ṣúṣánì*+ láti pa wọ́n run. Ó ní kó fi han Ẹ́sítà, kó ṣàlàyé rẹ̀ fún un, kó sì sọ fún un+ pé kó lọ bá ọba láti wá ojú rere rẹ̀, kí òun fúnra rẹ̀ sì bá àwọn èèyàn rẹ̀ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba.

9 Hátákì pa dà, ó sì jíṣẹ́ Módékáì fún Ẹ́sítà. 10 Ẹ́sítà ní kí Hátákì lọ ṣàlàyé fún Módékáì+ pé: 11 “Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ọba àti àwọn èèyàn tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ abẹ́ àṣẹ ọba ló mọ̀ pé, tí ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí bá wọlé lọ bá ọba ní àgbàlá inú+ láìjẹ́ pé ọba pè é, òfin kan ṣoṣo tí wọ́n máa tẹ̀ lé ni pé: Kí wọ́n pa onítọ̀hún; àyàfi tí ọba bá na ọ̀pá àṣẹ wúrà+ sí i ni kò ní kú. Ó sì ti tó ọgbọ̀n (30) ọjọ́ báyìí tí wọn ò tíì pè mí sọ́dọ̀ ọba.”

12 Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Ẹ́sítà fún Módékáì, 13 ó fún Ẹ́sítà lésì pé: “Má rò pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn Júù yòókù kò ní kàn ọ́ torí pé o wà nínú agbo ilé ọba. 14 Tí o bá dákẹ́ ní àkókò yìí, àwọn Júù máa rí ìtura àti ìdáǹdè láti ibòmíì,+ ṣùgbọ́n ìwọ àti ilé bàbá rẹ yóò ṣègbé. Ta ló sì mọ̀ bóyá torí irú àkókò yìí lo fi dé ipò ayaba tí o wà?”+

15 Nígbà náà, Ẹ́sítà fún Módékáì lésì pé: 16 “Lọ, kó gbogbo àwọn Júù tó wà ní Ṣúṣánì* jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀+ nítorí mi. Ẹ má jẹ, ẹ má sì mu fún ọjọ́ mẹ́ta,+ ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi á sì gbààwẹ̀ bákan náà. Màá wọlé lọ sọ́dọ̀ ọba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bá òfin mu, tí mo bá sì máa kú, kí n kú.” 17 Torí náà, Módékáì lọ, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Ẹ́sítà sọ pé kó ṣe.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́