ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Àwọn ẹran tó mọ́ àti àwọn tó jẹ́ aláìmọ́ (1-47)

Léfítíkù 11:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹran tó ń rìn lórí ilẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:4-6; Isk 4:14

Léfítíkù 11:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:7, 8

Léfítíkù 11:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 30:26

Léfítíkù 11:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/15/1992, ojú ìwé 4

Léfítíkù 11:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 65:4; 66:3, 17

Léfítíkù 11:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 10:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 12/2020, ojú ìwé 2

Léfítíkù 11:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:9, 10

Léfítíkù 11:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “alààyè ọkàn.”

Léfítíkù 11:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:3

Léfítíkù 11:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 39:27, 30
  • +Di 14:12-19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Léfítíkù 11:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbogbo kòkòrò.”

Léfítíkù 11:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 3:4; Mk 1:6

Léfítíkù 11:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 14:46, 47; 15:8; 17:15; 22:4-6

Léfítíkù 11:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 14:2, 8; 15:2, 5; Nọ 19:10

Léfítíkù 11:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:7, 8

Léfítíkù 11:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 17:15, 16
  • +Le 5:2

Léfítíkù 11:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 66:17

Léfítíkù 11:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:19
  • +Le 11:24; 22:4, 5

Léfítíkù 11:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Léfítíkù 11:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:12

Léfítíkù 11:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:23, 24; Nọ 19:11, 16

Léfítíkù 11:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 17:15; 22:3, 8; Di 14:21; Isk 4:14; 44:31

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2005, ojú ìwé 27

Léfítíkù 11:41

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:21

Léfítíkù 11:42

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:3

Léfítíkù 11:43

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 20:25

Léfítíkù 11:44

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:2
  • +Ẹk 19:6; Le 19:2; Di 14:2; 1Tẹ 4:7
  • +1Pe 1:15, 16; Ifi 4:8

Léfítíkù 11:45

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:7; 29:46; Ho 11:1
  • +Ẹk 22:31; Nọ 15:40; Di 7:6
  • +Le 20:7, 26; Joṣ 24:19; 1Sa 2:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 23

Léfítíkù 11:46

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “alààyè ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Léfítíkù 11:47

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 20:25; Isk 44:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Àwọn míì

Léf. 11:2Di 14:4-6; Isk 4:14
Léf. 11:4Di 14:7, 8
Léf. 11:5Owe 30:26
Léf. 11:7Ais 65:4; 66:3, 17
Léf. 11:8Iṣe 10:14
Léf. 11:9Di 14:9, 10
Léf. 11:11Di 14:3
Léf. 11:13Job 39:27, 30
Léf. 11:13Di 14:12-19
Léf. 11:22Mt 3:4; Mk 1:6
Léf. 11:24Le 14:46, 47; 15:8; 17:15; 22:4-6
Léf. 11:25Le 14:2, 8; 15:2, 5; Nọ 19:10
Léf. 11:26Di 14:7, 8
Léf. 11:28Le 17:15, 16
Léf. 11:28Le 5:2
Léf. 11:29Ais 66:17
Léf. 11:31Di 14:19
Léf. 11:31Le 11:24; 22:4, 5
Léf. 11:33Le 15:12
Léf. 11:39Le 11:23, 24; Nọ 19:11, 16
Léf. 11:40Le 17:15; 22:3, 8; Di 14:21; Isk 4:14; 44:31
Léf. 11:41Le 11:21
Léf. 11:42Di 14:3
Léf. 11:43Le 20:25
Léf. 11:44Ẹk 20:2
Léf. 11:44Ẹk 19:6; Le 19:2; Di 14:2; 1Tẹ 4:7
Léf. 11:441Pe 1:15, 16; Ifi 4:8
Léf. 11:45Ẹk 6:7; 29:46; Ho 11:1
Léf. 11:45Ẹk 22:31; Nọ 15:40; Di 7:6
Léf. 11:45Le 20:7, 26; Joṣ 24:19; 1Sa 2:2
Léf. 11:47Le 20:25; Isk 44:23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
  • 47
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 11:1-47

Léfítíkù

11 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Àwọn ohun alààyè tó wà ní ayé* tí ẹ lè jẹ+ nìyí: 3 Ẹ lè jẹ gbogbo ẹran tí pátákò rẹ̀ là, tí pátákò rẹ̀ ní àlàfo, tó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.

4 “‘Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹran yìí tó ń jẹ àpọ̀jẹ tàbí àwọn tí pátákò wọn là: ràkúnmí máa ń jẹ àpọ̀jẹ, àmọ́ pátákò rẹ̀ kò là. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín.+ 5 Bákan náà, gara orí àpáta  + máa ń jẹ àpọ̀jẹ, àmọ́ pátákò rẹ̀ kò là. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. 6 Ehoro pẹ̀lú máa ń jẹ àpọ̀jẹ, àmọ́ pátákò rẹ̀ kò là. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. 7 Bákan náà ni ẹlẹ́dẹ̀,+ torí pátákò rẹ̀ là, ó sì ní àlàfo, àmọ́ kì í jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. 8 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ẹran wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fara kan òkú wọn. Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.+

9 “‘Èyí tí ẹ lè jẹ nínú gbogbo ohun tó wà nínú omi nìyí: Ẹ lè jẹ+ ohunkóhun tó wà nínú omi tó ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́, ì báà jẹ́ inú òkun tàbí inú odò ló wà. 10 Àmọ́ ohunkóhun tó wà nínú òkun àti odò tí kò ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́, nínú gbogbo ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn àti gbogbo ohun alààyè* míì tó wà nínú omi, ohun ìríra ló jẹ́ fún yín. 11 Àní ohun ìríra ni wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ fún yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ẹran wọn,+ kí ẹ sì ka òkú wọn sí ohun ìríra. 12 Ohun ìríra ni gbogbo ohun tó wà nínú omi tí kò ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́ jẹ́ fún yín.

13 “‘Àwọn ẹ̀dá tó ń fò tí ẹ máa kà sí ohun ìríra nìyí; ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n, torí ohun ìríra ni wọ́n jẹ́: ẹyẹ idì,+ idì ajẹja, igún dúdú,+ 14 àwòdì pupa àti gbogbo onírúurú àwòdì dúdú, 15 gbogbo onírúurú ẹyẹ ìwò, 16 ògòǹgò, òwìwí, ẹyẹ àkẹ̀ àti gbogbo onírúurú àṣáǹwéwé, 17 òwìwí kékeré, ẹyẹ àgò, òwìwí elétí gígùn, 18 ògbùgbú, ẹyẹ òfú, igún, 19 ẹyẹ àkọ̀, gbogbo onírúurú ẹyẹ wádòwádò, àgbìgbò àti àdán. 20 Kí gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn,* tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn jẹ́ ohun ìríra fún yín.

21 “‘Nínú àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn, tó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tó ní tete lókè ẹsẹ̀ wọn láti máa fi tọ lórí ilẹ̀ nìkan ni ẹ lè jẹ. 22 Èyí tí ẹ lè jẹ nínú wọn nìyí: onírúurú eéṣú tó máa ń ṣí kiri, àwọn eéṣú míì tó ṣeé jẹ,+ ìrẹ̀ àti tata. 23 Gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ yòókù tó ń gbá yìn-ìn, tó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin jẹ́ ohun ìríra fún yín. 24 Ẹ lè fi nǹkan wọ̀nyí sọ ara yín di aláìmọ́. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 25 Kí ẹnikẹ́ni tó bá gbé òkú èyíkéyìí lára wọn fọ aṣọ rẹ̀;+ onítọ̀hún yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.

26 “‘Ẹranko èyíkéyìí tí pátákò rẹ̀ là, àmọ́ tí kò sí àlàfo ní pátákò rẹ̀, tí kì í sì í jẹ àpọ̀jẹ, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún yín. Gbogbo ẹni tó bá fara kàn wọ́n yóò di aláìmọ́.+ 27 Gbogbo ohun alààyè tó ń fi àtẹ́lẹsẹ̀ rìn nínú àwọn ohun tó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn yóò jẹ́ aláìmọ́ fún yín. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́. 28 Kí ẹni tó bá gbé òkú wọn fọ aṣọ rẹ̀,+ yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.

29 “‘Àwọn ẹ̀dá tó ń rákò lórí ilẹ̀, tó jẹ́ aláìmọ́ fún yín nìyí: ẹ̀lírí, eku,+ gbogbo onírúurú aláǹgbá, 30 ọmọńlé, awọ́nríwọ́n, aláàmù, ọlọ́yọ̀ọ́ǹbẹ́rẹ́ àti ọ̀gà. 31 Aláìmọ́+ ni àwọn ẹ̀dá tó ń rákò yìí jẹ́ fún yín. Gbogbo ẹni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+

32 “‘Tí wọ́n bá kú, ohunkóhun tí wọ́n bá já bọ́ lé yóò di aláìmọ́, ì báà jẹ́ ohun èlò onígi, aṣọ, awọ tàbí aṣọ ọ̀fọ̀.* Kí ẹ ri ohun èlò èyíkéyìí tí ẹ bá lò bọnú omi, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́; lẹ́yìn náà, ó máa mọ́. 33 Tí wọ́n bá já bọ́ sínú ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, kí ẹ fọ́ ọ túútúú, ohunkóhun tó bá sì wà nínú rẹ̀ yóò di aláìmọ́.+ 34 Tí omi tó wà nínú ohun èlò náà bá kan oúnjẹ èyíkéyìí, yóò di aláìmọ́. Ohun mímu èyíkéyìí tó bá sì wà nínú ohun èlò náà yóò di aláìmọ́. 35 Ohunkóhun tí òkú wọn bá já bọ́ lé yóò di aláìmọ́. Ì báà jẹ́ ààrò tàbí àdògán kékeré, ṣe ni kí ẹ fọ́ ọ túútúú. Wọ́n ti di aláìmọ́, aláìmọ́ ni wọ́n sì máa jẹ́ fún yín. 36 Ìsun omi àti kòtò omi nìkan ni yóò máa jẹ́ mímọ́, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́. 37 Tí òkú wọn bá já bọ́ sórí irúgbìn tí ẹ fẹ́ gbìn, irúgbìn náà ṣì jẹ́ mímọ́. 38 Àmọ́ tí ẹ bá da omi sórí irúgbìn kan, tí apá kan lára òkú wọn sì já bọ́ sórí rẹ̀, aláìmọ́ ni irúgbìn náà jẹ́ fún yín.

39 “‘Tí ẹranko tí ẹ máa ń jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkú rẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 40 Kí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ lára òkú rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tó bá gbé òkú rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 41 Gbogbo ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn ní ayé jẹ́ ohun ìríra.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. 42 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran èyíkéyìí tó ń fi àyà fà, ẹran èyíkéyìí tó ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn ní ayé, tí wọ́n ní ẹsẹ̀ púpọ̀, torí ohun ìríra+ ni wọ́n jẹ́. 43 Ẹ má fi ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń gbá yìn-ìn kó ìríra bá ara yín,* ẹ má fi wọ́n kó èérí bá ara yín, kí ẹ má bàa di aláìmọ́.+ 44 Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ gbọ́dọ̀ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì di mímọ́,+ torí mo jẹ́ mímọ́.+ Torí náà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ sọ ara yín* di aláìmọ́. 45 Torí èmi ni Jèhófà, tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run,+ ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́,+ torí èmi jẹ́ mímọ́.+

46 “‘Èyí ni òfin tó wà nípa àwọn ẹranko, àwọn ẹ̀dá tó ń fò, gbogbo ohun alààyè* tó wà nínú omi àti gbogbo ẹ̀dá* tó ń gbá yìn-ìn ní ayé, 47 láti fi ìyàtọ̀ sáàárín èyí tí kò mọ́ àti èyí tó mọ́, sáàárín àwọn ohun alààyè tí ẹ lè jẹ àti àwọn tí ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́