ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 30
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Pẹpẹ tùràrí (1-10)

      • Ìkànìyàn àti owó ètùtù (11-16)

      • Bàsíà bàbà láti máa fi wẹ̀ (17-21)

      • Àkànṣe òróró àfiyanni (22-33)

      • Àwọn èròjà tùràrí mímọ́ (34-38)

Ẹ́kísódù 30:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:5
  • +Ẹk 37:25-28

Ẹ́kísódù 30:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 27:1, 2; Le 4:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 10/2020, ojú ìwé 4-5

Ẹ́kísódù 30:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mọ wúrà sí etí rẹ̀.”

Ẹ́kísódù 30:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wúrà tí o mọ sí etí rẹ̀.”

Ẹ́kísódù 30:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 26:33; Heb 9:3
  • +Ẹk 25:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 10/2020, ojú ìwé 4-5

Ẹ́kísódù 30:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 23:13
  • +Ẹk 30:34, 35
  • +Nọ 16:39, 40; 1Sa 2:27, 28; Lk 1:9
  • +Ẹk 27:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/1/1996, ojú ìwé 9

Ẹ́kísódù 30:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/1/1996, ojú ìwé 9

Ẹ́kísódù 30:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 10:1; 2Kr 26:18; Isk 8:11, 12

Ẹ́kísódù 30:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:27; Heb 9:7
  • +Le 16:5, 6, 18, 19

Ẹ́kísódù 30:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 38:25; Nọ 1:2; 2Sa 24:10, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 9/2020, ojú ìwé 5

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2011, ojú ìwé 12

Ẹ́kísódù 30:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

  • *

    Tàbí “ṣékélì mímọ́.”

  • *

    Gérà kan jẹ́ gíráàmù 0.57. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 27:25
  • +2Kr 24:9; Mt 17:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 9/2020, ojú ìwé 5

Ẹ́kísódù 30:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 38:26; Nọ 1:3; 26:1, 2

Ẹ́kísódù 30:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Ẹ́kísódù 30:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Ẹ́kísódù 30:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 38:8; Le 8:11; 1Ọb 7:38
  • +Ẹk 40:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 40

Ẹ́kísódù 30:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:30, 31; Heb 10:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 40

Ẹ́kísódù 30:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/1/1996, ojú ìwé 9

Ẹ́kísódù 30:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 4:6

Ẹ́kísódù 30:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣékélì mímọ́.”

  • *

    Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 3:47

Ẹ́kísódù 30:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “bíi ti ẹni tó máa ń ṣe òróró ìpara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 37:29

Ẹ́kísódù 30:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:9; Nọ 7:1

Ẹ́kísódù 30:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 8:10
  • +Ẹk 29:37

Ẹ́kísódù 30:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 8:12
  • +Nọ 3:2, 3
  • +Ẹk 40:15

Ẹ́kísódù 30:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 37:29; 1Ọb 1:39; Sm 89:20

Ẹ́kísódù 30:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àjèjì,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:37, 38

Ẹ́kísódù 30:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:3, 6

Ẹ́kísódù 30:35

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “bíi ti ẹni tó máa ń ṣe òróró ìpara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 37:29; Sm 141:2; Ifi 5:8
  • +Le 2:13

Ẹ́kísódù 30:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:31, 32

Ẹ́kísódù 30:38

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 10/2020, ojú ìwé 5

Àwọn míì

Ẹ́kís. 30:1Ẹk 40:5
Ẹ́kís. 30:1Ẹk 37:25-28
Ẹ́kís. 30:2Ẹk 27:1, 2; Le 4:7
Ẹ́kís. 30:6Ẹk 26:33; Heb 9:3
Ẹ́kís. 30:6Ẹk 25:22
Ẹ́kís. 30:71Kr 23:13
Ẹ́kís. 30:7Ẹk 30:34, 35
Ẹ́kís. 30:7Nọ 16:39, 40; 1Sa 2:27, 28; Lk 1:9
Ẹ́kís. 30:7Ẹk 27:20
Ẹ́kís. 30:9Le 10:1; 2Kr 26:18; Isk 8:11, 12
Ẹ́kís. 30:10Le 23:27; Heb 9:7
Ẹ́kís. 30:10Le 16:5, 6, 18, 19
Ẹ́kís. 30:12Ẹk 38:25; Nọ 1:2; 2Sa 24:10, 15
Ẹ́kís. 30:13Le 27:25
Ẹ́kís. 30:132Kr 24:9; Mt 17:24
Ẹ́kís. 30:14Ẹk 38:26; Nọ 1:3; 26:1, 2
Ẹ́kís. 30:18Ẹk 38:8; Le 8:11; 1Ọb 7:38
Ẹ́kís. 30:18Ẹk 40:7
Ẹ́kís. 30:19Ẹk 40:30, 31; Heb 10:22
Ẹ́kís. 30:212Kr 4:6
Ẹ́kís. 30:24Nọ 3:47
Ẹ́kís. 30:25Ẹk 37:29
Ẹ́kís. 30:26Ẹk 40:9; Nọ 7:1
Ẹ́kís. 30:29Le 8:10
Ẹ́kís. 30:29Ẹk 29:37
Ẹ́kís. 30:30Le 8:12
Ẹ́kís. 30:30Nọ 3:2, 3
Ẹ́kís. 30:30Ẹk 40:15
Ẹ́kís. 30:31Ẹk 37:29; 1Ọb 1:39; Sm 89:20
Ẹ́kís. 30:33Ẹk 30:37, 38
Ẹ́kís. 30:34Ẹk 25:3, 6
Ẹ́kís. 30:35Ẹk 37:29; Sm 141:2; Ifi 5:8
Ẹ́kís. 30:35Le 2:13
Ẹ́kís. 30:37Ẹk 30:31, 32
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 30:1-38

Ẹ́kísódù

30 “Kí o ṣe pẹpẹ kan láti máa fi sun tùràrí;+ igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe é.+ 2 Kó ní igun mẹ́rin tó dọ́gba, ìgbọ̀nwọ́* kan ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Kí pẹpẹ náà àti àwọn ìwo rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan.+ 3 Kí o fi ògidì wúrà bò ó lókè pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká àti àwọn ìwo rẹ̀; kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká. 4 Kí o fi wúrà ṣe òrùka méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí rẹ̀* ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì tó wà lódìkejì ara wọn, ìyẹn ló máa gba àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi gbé e dúró. 5 Igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, kí o sì fi wúrà bò wọ́n. 6 Kí o gbé e síwájú aṣọ ìdábùú tó wà nítòsí àpótí Ẹ̀rí,+ níwájú ìbòrí tó wà lórí Ẹ̀rí, níbi tí màá ti pàdé rẹ.+

7 “Kí Áárónì+ sun tùràrí onílọ́fínńdà+ lórí rẹ̀,+ kí ó mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ nígbà tó bá ń bójú tó àwọn fìtílà náà+ láràárọ̀. 8 Bákan náà, tí Áárónì bá tan àwọn fìtílà náà ní ìrọ̀lẹ́,* kó sun tùràrí náà. Bí wọ́n á ṣe máa sun tùràrí ní gbogbo ìgbà níwájú Jèhófà jálẹ̀ àwọn ìran yín nìyẹn. 9 Ẹ ò gbọ́dọ̀ sun tùràrí tí kò yẹ + tàbí rú ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ọkà lórí rẹ̀, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ da ọrẹ ohun mímu sórí rẹ̀. 10 Kí Áárónì máa ṣe ètùtù lórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.+ Kí ó mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ti ètùtù+ láti ṣe ètùtù fún un lẹ́ẹ̀kan lọ́dún jálẹ̀ gbogbo ìran yín. Ohun mímọ́ jù lọ ló jẹ́ sí Jèhófà.”

11 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 12 “Nígbàkigbà tí o bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí kálukú mú ohun tí yóò fi ra ẹ̀mí* rẹ̀ pa dà wá fún Jèhófà nígbà ìkànìyàn náà. Èyí ò ní jẹ́ kí ìyọnu kankan ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá forúkọ wọn sílẹ̀. 13 Ohun tí gbogbo àwọn tó bá forúkọ sílẹ̀ máa mú wá nìyí: ààbọ̀ ṣékélì,* kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.*+ Ogún (20) òṣùwọ̀n gérà* ni ṣékélì kan. Ààbọ̀ ṣékélì ni ọrẹ fún Jèhófà.+ 14 Kí gbogbo ẹni tó bá forúkọ sílẹ̀, tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè mú ọrẹ wá fún Jèhófà.+ 15 Kí ọlọ́rọ̀ má ṣe mú ohun tó ju ààbọ̀ ṣékélì* wá, kí aláìní má sì mú ohun tó kéré síyẹn wá láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà kí ẹ lè fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí* yín. 16 Kí o gba owó fàdákà fún ètùtù lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì mú un wá fún iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé, kó lè jẹ́ ohun ìrántí níwájú Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀mí* yín.”

17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 18 “Kí o fi bàbà ṣe bàsíà kan pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀ fún wíwẹ̀;+ kí o gbé e sáàárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, kí o sì bu omi sínú rẹ̀.+ 19 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀.+ 20 Tí wọ́n bá ń lọ sínú àgọ́ ìpàdé tàbí tí wọ́n bá sún mọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́, láti fi iná sun ọrẹ kó sì rú èéfín sí Jèhófà, kí wọ́n lo omi náà kí wọ́n má bàa kú. 21 Kí wọ́n fi wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má bàa kú. Kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà yìí títí lọ, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ jálẹ̀ àwọn ìran wọn.”+

22 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 23 “Lẹ́yìn náà, kí o mú àwọn lọ́fínńdà tó dáa jù: ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n òjíá dídì àti sínámónì dídùn tó jẹ́ ìdajì rẹ̀, ìyẹn igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n àti igba ó lé àádọ́ta (250) ìwọ̀n ewéko kálámọ́sì dídùn 24 àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìwọ̀n kaṣíà, kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́,*+ pẹ̀lú òróró ólífì tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan. 25 Kí o wá fi ṣe òróró àfiyanni mímọ́; kí o ro àwọn èròjà náà pọ̀ dáadáa.*+ Òróró àfiyanni mímọ́ ni yóò jẹ́.

26 “Kí o ta òróró náà sí àgọ́ ìpàdé+ àti àpótí Ẹ̀rí, 27 pẹ̀lú tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti àwọn ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí, 28 pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹ̀lú bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀. 29 Kí o sọ wọ́n di mímọ́ kí wọ́n lè di mímọ́ jù lọ.+ Ẹnikẹ́ni tó bá fara kàn wọ́n ti gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.+ 30 Kí o fi òróró yan Áárónì+ àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ kí o sì sọ wọ́n di mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi.+

31 “Kí o sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Òróró yìí ni yóò máa jẹ́ òróró àfiyanni mímọ́ fún mi ní ìrandíran yín.+ 32 Èèyàn kankan ò gbọ́dọ̀ fi pa ara, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó ní irú èròjà rẹ̀. Ohun mímọ́ ni. Yóò máa jẹ́ ohun mímọ́ fún yín. 33 Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe òróró ìpara tó dà bíi rẹ̀ tàbí tó fi pa ẹni tí kò tọ́ sí* lára, kí ẹ pa ẹni náà, kí ẹ lè mú un kúrò nínú àwọn èèyàn rẹ̀.’”+

34 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú àwọn lọ́fínńdà yìí ní ìwọ̀n kan náà:+ àwọn ẹ̀kán sítákítè, ọ́níkà, gábánọ́mù onílọ́fínńdà àti ògidì oje igi tùràrí. 35 Kí o fi ṣe tùràrí;+ kí o ro àwọn èròjà náà pọ̀ dáadáa,* fi iyọ̀ sí i,+ kó jẹ́ ògidì, kó sì jẹ́ mímọ́. 36 Kí o gún lára rẹ̀, kó sì kúnná, kí o wá bù lára rẹ̀ síwájú Ẹ̀rí nínú àgọ́ ìpàdé, níbi tí màá ti pàdé rẹ. Kó jẹ́ mímọ́ jù lọ fún yín. 37 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe tùràrí tó ní irú èròjà yìí fún ìlò ara yín.+ Kí ẹ kà á sí ohun mímọ́ fún Jèhófà. 38 Tí ẹnikẹ́ni bá ṣe ohun tó jọ ọ́ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, ṣe ni kí ẹ pa ẹni náà, kí ẹ lè mú un kúrò nínú àwọn èèyàn rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́