ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 26
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Kí wọ́n mú àkọ́so èso wọn wá (1-11)

      • Ìdá mẹ́wàá kejì (12-15)

      • Ísírẹ́lì jẹ́ ohun ìní pàtàkì fún Jèhófà (16-19)

Diutarónómì 26:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:19; Le 23:10; Nọ 18:8, 12; 2Kr 6:6; 31:5; Owe 3:9

Diutarónómì 26:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:1, 8; 26:3

Diutarónómì 26:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “tó ń kú lọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:5; Ho 12:12
  • +Jẹ 46:3; Iṣe 7:15
  • +Jẹ 46:27
  • +Ẹk 1:7; Di 10:22; Sm 105:24

Diutarónómì 26:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:11

Diutarónómì 26:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:9; 4:31; Iṣe 7:34

Diutarónómì 26:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:6
  • +Ẹk 7:3; Di 4:33, 34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2015, ojú ìwé 4-5

Diutarónómì 26:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:8; Di 8:7, 8; Isk 20:6

Diutarónómì 26:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 26:2

Diutarónómì 26:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:7; 16:14

Diutarónómì 26:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìlóbìí.”

  • *

    Ní Héb., “ẹnubodè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:5, 6; 14:22
  • +Di 14:28, 29; Owe 14:21; 1Jo 3:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 26:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jem 1:27

Diutarónómì 26:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:25
  • +Jẹ 15:18; 26:3
  • +Di 8:7, 8

Diutarónómì 26:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 6:6; 11:1; Sm 119:34; 1Jo 5:3

Diutarónómì 26:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:46
  • +Onw 12:13
  • +Le 19:37

Diutarónómì 26:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ṣeyebíye.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:2; 29:10-13

Diutarónómì 26:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:8
  • +Di 7:6; 28:1, 9

Àwọn míì

Diu. 26:2Ẹk 23:19; Le 23:10; Nọ 18:8, 12; 2Kr 6:6; 31:5; Owe 3:9
Diu. 26:3Jẹ 17:1, 8; 26:3
Diu. 26:5Jẹ 28:5; Ho 12:12
Diu. 26:5Jẹ 46:3; Iṣe 7:15
Diu. 26:5Jẹ 46:27
Diu. 26:5Ẹk 1:7; Di 10:22; Sm 105:24
Diu. 26:6Ẹk 1:11
Diu. 26:7Ẹk 3:9; 4:31; Iṣe 7:34
Diu. 26:8Ẹk 6:6
Diu. 26:8Ẹk 7:3; Di 4:33, 34
Diu. 26:9Ẹk 3:8; Di 8:7, 8; Isk 20:6
Diu. 26:10Di 26:2
Diu. 26:11Di 12:7; 16:14
Diu. 26:12Di 12:5, 6; 14:22
Diu. 26:12Di 14:28, 29; Owe 14:21; 1Jo 3:17
Diu. 26:13Jem 1:27
Diu. 26:15Ẹk 23:25
Diu. 26:15Jẹ 15:18; 26:3
Diu. 26:15Di 8:7, 8
Diu. 26:16Di 6:6; 11:1; Sm 119:34; 1Jo 5:3
Diu. 26:17Le 26:46
Diu. 26:17Onw 12:13
Diu. 26:17Le 19:37
Diu. 26:18Di 14:2; 29:10-13
Diu. 26:19Di 4:8
Diu. 26:19Di 7:6; 28:1, 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 26:1-19

Diutarónómì

26 “Tí o bá wá dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún, tí o ti gbà á, tí o sì ti ń gbé ibẹ̀, 2 kí o mú lára gbogbo ohun* tó bá kọ́kọ́ so ní ilẹ̀ náà, èyí tí o bá kó jọ ní ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, kí o kó o sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+ 3 Kí o lọ bá ẹni tó bá jẹ́ àlùfáà nígbà yẹn, kí o sì sọ fún un pé, ‘Mò ń sọ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ lónìí pé mo ti dé ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wa pé òun máa fún wa.’+

4 “Kí àlùfáà náà wá gba apẹ̀rẹ̀ náà lọ́wọ́ rẹ, kó sì gbé e síwájú pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 5 Kí o kéde níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Ará Arémíà tó ń lọ káàkiri* ni bàbá mi,+ ó lọ sí Íjíbítì,+ ó sì di àjèjì tó ń gbé níbẹ̀, òun àti àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará ilé rẹ̀.+ Àmọ́ ibẹ̀ ló ti di orílẹ̀-èdè ńlá, tó lágbára, tó sì pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 6 Àwọn ọmọ Íjíbítì fìyà jẹ wá, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sọ wá di ẹrú tí wọ́n ń lò nílòkulò.+ 7 A wá bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà, Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, Jèhófà sì gbọ́ ohùn wa, ó rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ wá, bá a ṣe ń dààmú àti bí wọ́n ṣe ń pọ́n wa lójú.+ 8 Níkẹyìn, Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa kúrò ní Íjíbítì, pẹ̀lú apá tó nà jáde,+ àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù, àwọn àmì àtàwọn iṣẹ́ ìyanu.+ 9 Ó mú wa wá sí ibí yìí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ 10 Ní báyìí, mo ti mú àkọ́so èso ilẹ̀ tí Jèhófà fún mi wá.’+

“Kí o kó o síwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì tẹrí ba níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 11 Kí o wá máa yọ̀ torí gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ìwọ àti agbo ilé rẹ, ìwọ àti ọmọ Léfì àti àjèjì tó bá wà láàárín rẹ.+

12 “Tí o bá ti kó gbogbo ìdá mẹ́wàá+ èso ilẹ̀ rẹ jọ tán ní ọdún kẹta, ọdún ìdá mẹ́wàá, kí o fún ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ yó nínú àwọn ìlú* rẹ.+ 13 Kí o wá sọ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ pé, ‘Mo ti kó ìpín mímọ́ kúrò nínú ilé mi, mo sì ti fún ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó,+ bí o ṣe pa á láṣẹ fún mi gẹ́lẹ́. Mi ò tẹ àwọn àṣẹ rẹ lójú, mi ò sì pa wọ́n tì. 14 Mi ò jẹ nínú rẹ̀ nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, mi ò sì mú ìkankan kúrò nínú rẹ̀ nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni mi ò lò lára rẹ̀ torí òkú. Mo fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run mi, mo sì ti ṣe gbogbo ohun tí o pa láṣẹ fún mi. 15 Wá bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, ibi mímọ́ rẹ tí ò ń gbé, kí o sì bù kún àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì àti ilẹ̀ tí o fún wa,+ bí o ṣe búra fún àwọn baba ńlá wa,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.’+

16 “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń pa á láṣẹ fún ọ lónìí pé kí o máa pa àwọn ìlànà àtàwọn ìdájọ́ yìí mọ́. Kí o máa tẹ̀ lé wọn, kí o sì máa fi gbogbo ọkàn rẹ+ àti gbogbo ara* rẹ pa á mọ́. 17 Lónìí, o ti gbọ́ tí Jèhófà kéde pé òun máa di Ọlọ́run rẹ, tí o bá ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí ò ń pa ìlànà rẹ̀ mọ́+ àti àwọn àṣẹ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ rẹ̀,+ tí o sì ń fetí sí ohùn rẹ̀. 18 Jèhófà sì ti gbọ́ ohun tí o kéde lónìí pé o máa di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,*+ bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́ àti pé o máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́, 19 pé òun máa gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tó dá,+ pé òun á mú kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, òun sì máa mú kí o ní òkìkí àti ògo, bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́, tí o bá fi hàn pé o jẹ́ èèyàn mímọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́