Jóòbù
28 “Ibì kan wà tí wọ́n ti lè wa fàdákà,
Ibì kan sì wà tí wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́ wà;+
2 Inú ilẹ̀ ni wọ́n ti ń mú irin,
4 Ó gbẹ́ ihò jìnnà sí ibi tí àwọn èèyàn ń gbé,
Láwọn ibi tí wọ́n ti gbàgbé, tó jìnnà síbi táwọn èèyàn ń gbà kọjá;
Àwọn èèyàn kan sọ̀ kalẹ̀, wọ́n sì rọ̀ dirodiro.
5 Oúnjẹ ń hù lórí ilẹ̀;
Àmọ́ nísàlẹ̀, nǹkan ń dà rú, bí ìgbà tí iná ń jó.*
6 Sàfáyà wà nínú òkúta níbẹ̀,
Wúrà sì wà nínú iyẹ̀pẹ̀.
7 Kò sí ẹyẹ aṣọdẹ tó mọ ọ̀nà débẹ̀;
Ojú àwòdì dúdú kò rí i.
8 Àwọn ẹranko ńlá ò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ rí;
Ọmọ kìnnìún ò rìn kiri níbẹ̀.
9 Èèyàn fi ọwọ́ rẹ̀ lu akọ òkúta;
Ó dojú àwọn òkè dé níbi ìpìlẹ̀ wọn.
10 Ó la ọ̀nà sínú àpáta fún omi;+
Ojú rẹ̀ ń rí gbogbo ohun tó ṣeyebíye.
11 Ó ń sé àwọn orísun odò,
Ó sì ń mú àwọn ohun tó pa mọ́ wá sínú ìmọ́lẹ̀.
13 Kò sí èèyàn tó mọ bó ṣe níye lórí tó,+
A ò sì lè rí i ní ilẹ̀ alààyè.
14 Ibú omi sọ pé, ‘Kò sí nínú mi!’
Òkun sì sọ pé, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi!’+
15 Kò ṣeé fi ògidì wúrà rà;
A kò sì lè díwọ̀n fàdákà láti fi pààrọ̀ rẹ̀.+
16 Kò ṣeé fi wúrà Ófírì rà,+
Kò sì ṣeé fi òkúta ónísì tó ṣọ̀wọ́n àti sàfáyà rà.
17 Wúrà àti gíláàsì kò ṣeé fi wé e;
A kò lè fi ohun èlò èyíkéyìí tí wọ́n fi wúrà tó dáa* ṣe pààrọ̀ rẹ̀.+
18 A ò lè mẹ́nu kan iyùn àti òkúta kírísítálì,+
Torí ẹ̀kún àpò ọgbọ́n níye lórí ju àpò tí péálì kún inú rẹ̀.
19 Tópásì + ti Kúṣì kò ṣeé fi wé e;
Ògidì wúrà pàápàá kò lè rà á.
20 Àmọ́ ibo ni ọgbọ́n ti wá,
Ibo sì ni orísun òye?+
21 Ó ti fara sin kúrò lójú gbogbo ohun alààyè,+
Ó sì pa mọ́ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.
22 Ìparun àti ikú sọ pé,
‘Ìròyìn rẹ̀ nìkan ló dé etí wa.’
23 Ọlọ́run mọ bí a ṣe lè rí i;
Òun nìkan ló mọ ibi tó ń gbé,+
24 Torí ó ń wo ayé títí dé àwọn ìkángun rẹ̀,
Ó sì ń rí gbogbo ohun tó wà lábẹ́ ọ̀run.+
25 Nígbà tó fún afẹ́fẹ́ ní agbára,*+
Tó sì díwọ̀n omi,+
26 Nígbà tó gbé ìlànà kalẹ̀ fún òjò,+
Tó sì lànà fún ìjì tó ń sán ààrá nínú ìkùukùu,*+
27 Ó wá rí ọgbọ́n, ó sì ṣàlàyé rẹ̀;
Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò.
28 Ó sì sọ fún èèyàn pé: