Jóṣúà
17 Kèké+ wá mú ẹ̀yà Mánásè,+ torí òun ni àkọ́bí Jósẹ́fù.+ Torí pé ọkùnrin ogun ni Mákírù+ àkọ́bí Mánásè, tó sì jẹ́ bàbá Gílíádì, ó gba Gílíádì àti Báṣánì.+ 2 Kèké sì mú àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè yòókù ní ìdílé-ìdílé, ó mú àwọn ọmọ Abi-ésérì,+ àwọn ọmọ Hélékì, àwọn ọmọ Ásíríélì, àwọn ọmọ Ṣékémù, àwọn ọmọ Héfà àti àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà. Àwọn ni àtọmọdọ́mọ Mánásè ọmọ Jósẹ́fù, àwọn ọkùnrin ní ìdílé-ìdílé.+ 3 Àmọ́ Sélóféhádì,+ ọmọ Héfà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírù, ọmọ Mánásè kò bímọ ọkùnrin, obìnrin nìkan ló bí, orúkọ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sì nìyí: Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 4 Wọ́n wá lọ bá àlùfáà Élíásárì,+ Jóṣúà ọmọ Núnì àti àwọn ìjòyè, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà ló pàṣẹ fún Mósè pé kó fún wa ní ogún láàárín àwọn arákùnrin wa.”+ Torí náà, ó fún wọn ní ogún láàárín àwọn arákùnrin bàbá wọn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.+
5 Ilẹ̀ mẹ́wàá ló tún kan Mánásè yàtọ̀ sí ilẹ̀ Gílíádì àti Báṣánì, tó wà ní òdìkejì* Jọ́dánì,+ 6 torí pé àwọn ọmọbìnrin Mánásè náà gba ogún pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ilẹ̀ Gílíádì sì wá di ti àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè yòókù.
7 Ààlà Mánásè bẹ̀rẹ̀ láti Áṣérì dé Míkímẹ́tátì,+ tó dojú kọ Ṣékémù,+ ààlà náà sì lọ sí apá gúúsù,* dé ilẹ̀ àwọn tó ń gbé ní Ẹ́ń-Tápúà. 8 Ilẹ̀ Tápúà+ di ti Mánásè, àmọ́ àwọn àtọmọdọ́mọ Éfúrémù ló ni Tápúà tó wà ní ààlà Mánásè. 9 Ààlà náà gba ìsàlẹ̀ lọ sí Àfonífojì Kánà, lápá gúúsù dé àfonífojì náà. Àwọn ìlú Éfúrémù wà láàárín àwọn ìlú Mánásè,+ ààlà Mánásè sì wà ní àríwá àfonífojì náà, ó wá parí sí òkun.+ 10 Éfúrémù ló ni apá gúúsù, Mánásè ló ni apá àríwá, òkun sì ni ààlà rẹ̀,+ wọ́n* dé Áṣérì lápá àríwá, wọ́n sì dé Ísákà lápá ìlà oòrùn.
11 Ní ilẹ̀ Ísákà àti Áṣérì, wọ́n fún Mánásè ní Bẹti-ṣéánì àti àwọn àrọko rẹ̀,* Íbíléámù+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Ẹ́ń-dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀, àwọn tó ń gbé Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn tó ń gbé Mẹ́gídò àti àwọn àrọko rẹ̀, mẹ́ta nínú àwọn ibi tó ga.
12 Àmọ́ àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè ò lè gba àwọn ìlú yìí; àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé ilẹ̀ yìí.+ 13 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fipá kó àwọn ọmọ Kénáánì ṣiṣẹ́ àṣekára,+ àmọ́ wọn ò lé wọn kúrò* pátápátá.+
14 Àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù sọ fún Jóṣúà pé: “Kí ló dé tí o fi kèké yan ilẹ̀ kan,+ tí o sì fún wa* ní ìpín kan ṣoṣo pé kó jẹ́ ogún wa? Èèyàn púpọ̀ ni wá, torí Jèhófà ti bù kún wa títí di báyìí.”+ 15 Jóṣúà fún wọn lésì pé: “Tó bá jẹ́ pé ẹ pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, ẹ lọ sínú igbó, kí ẹ sì ṣán ibì kan fún ara yín níbẹ̀, ní ilẹ̀ àwọn Pérísì+ àti àwọn Réfáímù,+ tó bá jẹ́ pé agbègbè olókè Éfúrémù+ ti kéré jù fún yín.” 16 Àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù wá sọ pé: “Agbègbè olókè náà ò lè gbà wá, gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì tó sì ń gbé ní ilẹ̀ àfonífojì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun+ tó ní dòjé irin,* ìyẹn àwọn tó wà ní Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀* àti àwọn tó wà ní Àfonífojì Jésírẹ́lì.”+ 17 Jóṣúà wá sọ fún ilé Jósẹ́fù, ó sọ fún Éfúrémù àti Mánásè pé: “Èèyàn púpọ̀ ni yín, ẹ sì lágbára gan-an. Kì í ṣe ilẹ̀ kan péré la máa fi kèké pín fún yín,+ 18 àmọ́ agbègbè olókè náà tún máa di tiyín.+ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé igbó ni, ẹ máa ṣán an, ibẹ̀ ló sì máa jẹ́ ìkángun ilẹ̀ yín. Torí ẹ máa lé àwọn ọmọ Kénáánì kúrò níbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára, wọ́n sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ní dòjé irin.”*+