ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Wọ́n dá ilẹ̀ obìnrin ará Ṣúnémù pa dà fún un (1-6)

      • Èlíṣà, Bẹni-hádádì àti Hásáẹ́lì (7-15)

      • Jèhórámù di ọba Júdà (16-24)

      • Ahasáyà di ọba Júdà (25-29)

2 Àwọn Ọba 8:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí ó mú kó sọ jí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 4:32-35
  • +Le 26:19; Di 28:15, 23; 1Ọb 17:1

2 Àwọn Ọba 8:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:2, 3

2 Àwọn Ọba 8:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 2:14, 20, 21; 3:17; 4:4, 7; 6:5-7; 7:1

2 Àwọn Ọba 8:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 4:32-35
  • +Nọ 36:9

2 Àwọn Ọba 8:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 7:8
  • +1Ọb 20:1; 2Ọb 6:24
  • +1Ọb 17:24

2 Àwọn Ọba 8:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:15
  • +1Sa 9:8; 1Ọb 14:2, 3

2 Àwọn Ọba 8:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 8:15

2 Àwọn Ọba 8:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 10:32; 12:17; 13:3; Emọ 1:3
  • +Di 28:63; Emọ 1:13

2 Àwọn Ọba 8:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:15

2 Àwọn Ọba 8:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 8:10

2 Àwọn Ọba 8:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dà á bo ojú rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:8, 10; 2Ọb 11:1; 15:8, 10
  • +1Ọb 19:15

2 Àwọn Ọba 8:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 1:17
  • +1Ọb 22:50; 2Kr 21:3, 5

2 Àwọn Ọba 8:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:28-30
  • +1Ọb 16:32, 33; 21:25
  • +2Ọb 8:26, 27; 2Kr 18:1
  • +2Kr 21:6, 7

2 Àwọn Ọba 8:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “òun á fún Dáfídì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní fìtílà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:10; 2Sa 7:16, 17
  • +1Ọb 11:36; Sm 132:17

2 Àwọn Ọba 8:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 27:40; 2Sa 8:14
  • +1Ọb 22:47; 2Kr 21:8-10

2 Àwọn Ọba 8:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:13; 2Ọb 19:8

2 Àwọn Ọba 8:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:10; 2Kr 21:18-20
  • +1Kr 3:10, 11; 2Kr 21:16, 17; 22:1, 2

2 Àwọn Ọba 8:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 9:29

2 Àwọn Ọba 8:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọmọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 11:1, 13, 16
  • +1Ọb 16:16, 23

2 Àwọn Ọba 8:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:33
  • +2Ọb 8:16, 18; 2Kr 22:3, 4

2 Àwọn Ọba 8:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:38; 1Ọb 22:2, 3
  • +1Ọb 19:17; 2Kr 22:5

2 Àwọn Ọba 8:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó ń ṣàìsàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:17, 18; 1Ọb 21:1; 2Kr 22:6
  • +2Ọb 9:15

Àwọn míì

2 Ọba 8:12Ọb 4:32-35
2 Ọba 8:1Le 26:19; Di 28:15, 23; 1Ọb 17:1
2 Ọba 8:2Joṣ 13:2, 3
2 Ọba 8:42Ọb 2:14, 20, 21; 3:17; 4:4, 7; 6:5-7; 7:1
2 Ọba 8:52Ọb 4:32-35
2 Ọba 8:5Nọ 36:9
2 Ọba 8:7Ais 7:8
2 Ọba 8:71Ọb 20:1; 2Ọb 6:24
2 Ọba 8:71Ọb 17:24
2 Ọba 8:81Ọb 19:15
2 Ọba 8:81Sa 9:8; 1Ọb 14:2, 3
2 Ọba 8:102Ọb 8:15
2 Ọba 8:122Ọb 10:32; 12:17; 13:3; Emọ 1:3
2 Ọba 8:12Di 28:63; Emọ 1:13
2 Ọba 8:131Ọb 19:15
2 Ọba 8:142Ọb 8:10
2 Ọba 8:151Ọb 16:8, 10; 2Ọb 11:1; 15:8, 10
2 Ọba 8:151Ọb 19:15
2 Ọba 8:162Ọb 1:17
2 Ọba 8:161Ọb 22:50; 2Kr 21:3, 5
2 Ọba 8:181Ọb 12:28-30
2 Ọba 8:181Ọb 16:32, 33; 21:25
2 Ọba 8:182Ọb 8:26, 27; 2Kr 18:1
2 Ọba 8:182Kr 21:6, 7
2 Ọba 8:19Jẹ 49:10; 2Sa 7:16, 17
2 Ọba 8:191Ọb 11:36; Sm 132:17
2 Ọba 8:20Jẹ 27:40; 2Sa 8:14
2 Ọba 8:201Ọb 22:47; 2Kr 21:8-10
2 Ọba 8:22Joṣ 21:13; 2Ọb 19:8
2 Ọba 8:241Ọb 2:10; 2Kr 21:18-20
2 Ọba 8:241Kr 3:10, 11; 2Kr 21:16, 17; 22:1, 2
2 Ọba 8:252Ọb 9:29
2 Ọba 8:262Ọb 11:1, 13, 16
2 Ọba 8:261Ọb 16:16, 23
2 Ọba 8:271Ọb 16:33
2 Ọba 8:272Ọb 8:16, 18; 2Kr 22:3, 4
2 Ọba 8:28Joṣ 21:38; 1Ọb 22:2, 3
2 Ọba 8:281Ọb 19:17; 2Kr 22:5
2 Ọba 8:29Joṣ 19:17, 18; 1Ọb 21:1; 2Kr 22:6
2 Ọba 8:292Ọb 9:15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 8:1-29

Àwọn Ọba Kejì

8 Èlíṣà sọ fún ìyá ọmọ tí ó jí dìde* pé:+ “Gbéra, ìwọ àti agbo ilé rẹ, kí o lọ máa gbé ní ilẹ̀ èyíkéyìí tí o bá rí, kí o sì di àjèjì níbẹ̀, nítorí Jèhófà ti kéde ìyàn,+ ọdún méje ni ìyàn yóò sì fi mú ní ilẹ̀ yìí.” 2 Nítorí náà, obìnrin náà dìde, ó sì ṣe ohun tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ. Òun àti agbo ilé rẹ̀ jáde lọ, wọ́n sì lọ ń gbé ní ilẹ̀ àwọn Filísínì+ fún ọdún méje.

3 Nígbà tí ọdún méje parí, obìnrin náà pa dà láti ilẹ̀ àwọn Filísínì, ó sì lọ bẹ ọba nítorí ilé rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀. 4 Nígbà náà, ọba ń bá Géhásì ìránṣẹ́ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ó ní: “Jọ̀wọ́, ròyìn fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Èlíṣà ti ṣe.”+ 5 Bó ṣe ń ròyìn fún ọba nípa bó ṣe jí ẹni tó kú dìde,+ obìnrin tí Èlíṣà jí ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ́dọ̀ ọba, ó wá bẹ̀ ẹ́ nítorí ilé rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀.+ Lójú ẹsẹ̀, Géhásì sọ pé: “Olúwa mi ọba, obìnrin náà nìyí, ọmọ rẹ̀ tí Èlíṣà jí dìde sì nìyí.” 6 Ni ọba bá béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà, ó sì ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọba. Lẹ́yìn náà, ọba yan òṣìṣẹ́ ààfin kan fún un, ó sì sọ fún òṣìṣẹ́ náà pé: “Gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀ àti gbogbo ohun tí oko rẹ̀ mú jáde láti ọjọ́ tó ti kúrò ní ilẹ̀ yìí títí di báyìí ni kí o dá pa dà fún un.”

7 Èlíṣà wá sí Damásíkù+ nígbà tí Bẹni-hádádì+ ọba Síríà ń ṣàìsàn. Torí náà, wọ́n ròyìn fún ọba pé: “Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ ti dé síbí o.” 8 Ọba wá sọ fún Hásáẹ́lì pé:+ “Mú ẹ̀bùn dání, kí o sì lọ bá èèyàn Ọlọ́run tòótọ́.+ Ní kí ó bá mi wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé, ‘Ṣé màá bọ́ lọ́wọ́ àìsàn yìí?’” 9 Hásáẹ́lì lọ bá a, pẹ̀lú ẹ̀bùn lọ́wọ́, gbogbo oríṣiríṣi ohun rere tó wà ní Damásíkù, ogójì (40) ẹrù ràkúnmí. Ó wá dúró níwájú rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọmọ rẹ, Bẹni-hádádì ọba Síríà, rán mi sí ọ láti béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé màá bọ́ lọ́wọ́ àìsàn yìí?’” 10 Èlíṣà dá a lóhùn pé: “Lọ sọ fún un pé, ‘Ó dájú pé ara rẹ máa yá,’ àmọ́ Jèhófà ti fi hàn mí pé ó dájú pé ó máa kú.”+ 11 Ó wá tẹjú mọ́ Hásáẹ́lì títí ojú fi ń tì í. Lẹ́yìn náà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ bú sẹ́kún. 12 Hásáẹ́lì béèrè pé: “Kí ló dé tí olúwa mi fi ń sunkún?” Ó fèsì pé: “Nítorí mo mọ jàǹbá tí o máa ṣe fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.+ Wàá sọ iná sí àwọn ibi olódi wọn, wàá fi idà pa àwọn ààyò ọkùnrin wọn, wàá fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wàá sì la inú àwọn aboyún wọn.”+ 13 Hásáẹ́lì sọ pé: “Báwo ni èmi ìránṣẹ́ rẹ, tí mo jẹ́ ajá lásán-làsàn, ṣe lè ṣe irú nǹkan yìí?” Àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Jèhófà ti fi hàn mí pé wàá di ọba lórí Síríà.”+

14 Lẹ́yìn náà, ó kúrò lọ́dọ̀ Èlíṣà, ó sì pa dà sọ́dọ̀ olúwa rẹ̀, olúwa rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni Èlíṣà sọ fún ọ?” Ó fèsì pé: “Ó sọ fún mi pé dájúdájú ara rẹ máa yá.”+ 15 Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, Hásáẹ́lì mú aṣọ tí wọ́n ń dà bo ibùsùn, ó tẹ̀ ẹ́ bọ omi, ó sì fi bo ojú olúwa rẹ̀ mọ́lẹ̀* títí ó fi kú.+ Hásáẹ́lì sì di ọba ní ipò rẹ̀.+

16 Ní ọdún karùn-ún Jèhórámù+ ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí Jèhóṣáfátì ṣì jẹ́ ọba Júdà, Jèhórámù+ ọmọ Jèhóṣáfátì ọba Júdà, di ọba. 17 Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni nígbà tó jọba, ọdún mẹ́jọ ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. 18 Ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì,+ bí àwọn ọba tó wá láti ilé Áhábù ti ṣe,+ nítorí ọmọ Áhábù ló fi ṣe aya;+ ó sì ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà.+ 19 Àmọ́ Jèhófà ò fẹ́ pa Júdà run nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀,+ torí pé ó ti ṣèlérí fún Dáfídì pé òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ lá máa ṣàkóso*+ títí lọ.

20 Nígbà ayé rẹ̀, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà,+ wọ́n sì fi ọba jẹ lórí ara wọn.+ 21 Nítorí náà, Jèhórámù sọdá lọ sọ́dọ̀ Sáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó dìde ní òru, ó sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Édómù tí wọ́n yí i ká àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin; àwọn ọmọ ogun náà sì sá lọ sínú àgọ́ wọn. 22 Àmọ́ Édómù ṣì ń ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà títí di òní yìí. Líbínà+ pẹ̀lú ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò yẹn.

23 Ní ti ìyókù ìtàn Jèhórámù àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Júdà? 24 Níkẹyìn, Jèhórámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ sí Ìlú Dáfídì.+ Ahasáyà+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

25 Ní ọdún kejìlá Jèhórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Ahasáyà ọmọ Jèhórámù ọba Júdà di ọba.+ 26 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ahasáyà nígbà tó jọba, ọdún kan ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ataláyà+ ọmọ ọmọ* Ómírì+ ọba Ísírẹ́lì. 27 Ó ń ṣe ohun tí àwọn ará ilé Áhábù+ ṣe, ó sì ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ó fẹ́ ìyàwó ní ilé Áhábù.+ 28 Torí náà, ó bá Jèhórámù ọmọ Áhábù lọ láti gbéjà ko Hásáẹ́lì ọba Síríà ní Ramoti-gílíádì,+ ṣùgbọ́n àwọn ará Síríà ṣe Jèhórámù léṣe.+ 29 Nítorí náà, Ọba Jèhórámù pa dà sí Jésírẹ́lì+ kó lè tọ́jú ọgbẹ́ tí àwọn ará Síríà dá sí i lára ní Rámà nígbà tó ń bá Hásáẹ́lì ọba Síríà jà.+ Ahasáyà ọmọ Jèhórámù ọba Júdà lọ wo Jèhórámù ọmọ Áhábù ní Jésírẹ́lì, torí wọ́n ti ṣe é léṣe.*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́