ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 31
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Hẹsikáyà mú ìbọ̀rìṣà kúrò (1)

      • Àwọn èèyàn ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì lẹ́yìn bó ṣe yẹ (2-21)

2 Kíróníkà 31:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:24
  • +Di 7:5; 2Ọb 18:1, 4; 2Kr 14:2, 3; 34:1, 3
  • +Di 12:2
  • +2Kr 23:16, 17
  • +2Kr 30:1, 18

2 Kíróníkà 31:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ibùdó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 24:1
  • +1Kr 23:6
  • +2Kr 8:14
  • +1Kr 23:13, 27-30

2 Kíróníkà 31:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 30:24
  • +Ẹk 29:39
  • +Nọ 28:9
  • +Nọ 10:10
  • +Di 16:16

2 Kíróníkà 31:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kí wọ́n lè fi ara wọn fún òfin Jèhófà pátápátá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:21; Ne 10:38, 39

2 Kíróníkà 31:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:12
  • +Ẹk 22:29; 23:19; Ne 10:37
  • +Owe 3:9

2 Kíróníkà 31:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 27:30; Di 14:28

2 Kíróníkà 31:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:16
  • +Le 23:24

2 Kíróníkà 31:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:8
  • +Mal 3:10

2 Kíróníkà 31:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn yàrá ìjẹun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 10:38, 39; 12:44

2 Kíróníkà 31:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 27:30; Di 14:28

2 Kíróníkà 31:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 26:17, 19
  • +Di 12:5, 6; 16:10
  • +Nọ 18:8
  • +Le 2:10; 7:1

2 Kíróníkà 31:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:19
  • +1Kr 24:1

2 Kíróníkà 31:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 24:4
  • +Nọ 4:2, 3; 8:24; 1Kr 23:24
  • +1Kr 23:6

2 Kíróníkà 31:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 25:33, 34; Nọ 35:2; Joṣ 21:13

2 Kíróníkà 31:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 29:35

Àwọn míì

2 Kíró. 31:1Ẹk 23:24
2 Kíró. 31:1Di 7:5; 2Ọb 18:1, 4; 2Kr 14:2, 3; 34:1, 3
2 Kíró. 31:1Di 12:2
2 Kíró. 31:12Kr 23:16, 17
2 Kíró. 31:12Kr 30:1, 18
2 Kíró. 31:21Kr 24:1
2 Kíró. 31:21Kr 23:6
2 Kíró. 31:22Kr 8:14
2 Kíró. 31:21Kr 23:13, 27-30
2 Kíró. 31:32Kr 30:24
2 Kíró. 31:3Ẹk 29:39
2 Kíró. 31:3Nọ 28:9
2 Kíró. 31:3Nọ 10:10
2 Kíró. 31:3Di 16:16
2 Kíró. 31:4Nọ 18:21; Ne 10:38, 39
2 Kíró. 31:5Nọ 18:12
2 Kíró. 31:5Ẹk 22:29; 23:19; Ne 10:37
2 Kíró. 31:5Owe 3:9
2 Kíró. 31:6Le 27:30; Di 14:28
2 Kíró. 31:7Le 23:16
2 Kíró. 31:7Le 23:24
2 Kíró. 31:10Nọ 18:8
2 Kíró. 31:10Mal 3:10
2 Kíró. 31:11Ne 10:38, 39; 12:44
2 Kíró. 31:12Le 27:30; Di 14:28
2 Kíró. 31:141Kr 26:17, 19
2 Kíró. 31:14Di 12:5, 6; 16:10
2 Kíró. 31:14Nọ 18:8
2 Kíró. 31:14Le 2:10; 7:1
2 Kíró. 31:15Joṣ 21:19
2 Kíró. 31:151Kr 24:1
2 Kíró. 31:171Kr 24:4
2 Kíró. 31:17Nọ 4:2, 3; 8:24; 1Kr 23:24
2 Kíró. 31:171Kr 23:6
2 Kíró. 31:19Le 25:33, 34; Nọ 35:2; Joṣ 21:13
2 Kíró. 31:212Kr 29:35
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 31:1-21

Kíróníkà Kejì

31 Gbàrà tí wọ́n parí gbogbo èyí, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Júdà, wọ́n fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́,+ wọ́n gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀,*+ wọ́n sì wó àwọn ibi gíga+ àti àwọn pẹpẹ+ lulẹ̀ ní gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú Éfúrémù àti Mánásè+ títí wọ́n fi pa wọ́n run pátápátá, lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sí àwọn ìlú wọn, kálukú pa dà sídìí ohun ìní rẹ̀.

2 Nígbà náà, Hẹsikáyà yan àwọn àlùfáà sí àwùjọ wọn,+ ó sì yan àwọn ọmọ Léfì sí àwùjọ wọn,+ ó yan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn,+ láti máa rú ẹbọ sísun, kí wọ́n sì máa rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́, kí wọ́n máa dúpẹ́, kí wọ́n sì máa yin Ọlọ́run ní àwọn ẹnubodè tó wà ní àwọn àgbàlá* Jèhófà.+ 3 Ọba fi apá kan lára ẹrù rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn ẹbọ sísun,+ ìyẹn àwọn ẹbọ òwúrọ̀ àti ti ìrọ̀lẹ́,+ títí kan àwọn ẹbọ sísun fún àwọn Sábáàtì,+ àwọn òṣùpá tuntun+ àti àwọn àjọyọ̀,+ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Jèhófà.

4 Yàtọ̀ síyẹn, ó pàṣẹ fún àwọn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù pé kí wọ́n fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ní apá tó tọ́ sí wọn,+ kí wọ́n lè gbájú mọ́ òfin Jèhófà.* 5 Gbàrà tí ọba pa àṣẹ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkọ́so ọkà, wáìnì tuntun, òróró+ àti oyin pẹ̀lú gbogbo irè oko wá;+ wọ́n mú ìdá mẹ́wàá ohun gbogbo wá ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 6 Bákan náà, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti ti Júdà tó ń gbé ní àwọn ìlú Júdà mú ìdá mẹ́wàá àwọn màlúù àti àgùntàn àti ìdá mẹ́wàá àwọn ohun mímọ́ wá,+ àwọn ohun tí a ti yà sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run wọn. Wọ́n mú wọn wá, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì-òkìtì. 7 Ní oṣù kẹta,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ọrẹ wọn jọ ní òkìtì-òkìtì; wọ́n sì parí rẹ̀ ní oṣù keje.+ 8 Nígbà tí Hẹsikáyà àti àwọn ìjòyè wá, tí wọ́n sì rí àwọn òkìtì ọrẹ náà, wọ́n yin Jèhófà, wọ́n sì súre fún àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì.

9 Hẹsikáyà béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì nípa àwọn òkìtì náà, 10 Asaráyà olórí àlùfáà ilé Sádókù sì sọ fún un pé: “Láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú ọrẹ wá sínú ilé Jèhófà+ ni àwọn èèyàn náà ti ń jẹ àjẹyó, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ló ṣẹ́ kù, nítorí Jèhófà ti bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, ohun tó sì ṣẹ́ kù ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ yìí.”+

11 Ni Hẹsikáyà bá sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣètò àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí*+ ní ilé Jèhófà, wọ́n sì ṣètò wọn. 12 Wọ́n ń mú àwọn ọrẹ wá tinútinú àti ìdá mẹ́wàá+ pẹ̀lú àwọn ohun mímọ́; Konanáyà ọmọ Léfì ni wọ́n fi sídìí gbogbo nǹkan yìí pé kó jẹ́ alábòójútó, Ṣíméì arákùnrin rẹ̀ sì ni igbá kejì. 13 Jéhíélì, Asasáyà, Náhátì, Ásáhélì, Jérímótì, Jósábádì, Élíélì, Isimákáyà, Máhátì àti Bẹnáyà ni àwọn kọmíṣọ́nnà tó ń ran Konanáyà àti Ṣíméì arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọba Hẹsikáyà pa, Asaráyà sì ni alábòójútó ilé Ọlọ́run tòótọ́. 14 Kórè ọmọ Ímúnà, ọmọ Léfì tó jẹ́ aṣọ́bodè lápá ìlà oòrùn+ ló ń bójú tó àwọn ọrẹ àtinúwá+ Ọlọ́run tòótọ́, òun ló sì ń pín ọrẹ tí wọ́n mú wá fún Jèhófà+ àti àwọn ohun mímọ́ jù lọ.+ 15 Àwọn tó wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀ ni Édẹ́nì, Míníámínì, Jéṣúà, Ṣemáyà, Amaráyà àti Ṣẹkanáyà, nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà,+ nínú iṣẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán tí wọ́n ń ṣe, láti máa pín nǹkan lọ́gbọọgba fún àwọn arákùnrin wọn nínú àwọn àwùjọ wọn,+ bí ìpín ẹni ńlá ṣe rí bẹ́ẹ̀ ni ti ẹni kékeré. 16 Èyí jẹ́ àfikún sí ohun tí wọ́n pín fún àwọn ọkùnrin láti ọmọ ọdún mẹ́ta sókè tí orúkọ wọn wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé, tí wọ́n ń wá lójoojúmọ́ láti wá ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ilé Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ àwùjọ tí wọ́n pín wọn sí.

17 Orúkọ àwọn àlùfáà wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn bí wọ́n ṣe wà ní agbo ilé bàbá wọn,+ bíi ti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí wọ́n pín àwùjọ wọn sí.+ 18 Àwọn tó wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé wọn nìyí: gbogbo àwọn ọmọ wọn, àwọn ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti ọmọbìnrin wọn, gbogbo ìjọ wọn lápapọ̀, torí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún ohun tó jẹ́ mímọ́ nítorí wọ́n wà ní ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán, 19 títí kan àwọn àtọmọdọ́mọ Áárónì, ìyẹn àwọn àlùfáà tó ń gbé ní àwọn pápá ibi ìjẹko tó yí ìlú wọn ká.+ Ní gbogbo àwọn ìlú náà, wọ́n yan àwọn ọkùnrin tí á máa pín oúnjẹ fún gbogbo ọkùnrin tó wà nínú ìdílé àwọn àlùfáà àti gbogbo ẹni tí orúkọ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn ọmọ Léfì.

20 Hẹsikáyà ṣe gbogbo nǹkan yìí káàkiri Júdà, ó ń ṣe ohun tó dáa, tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ òdodo níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. 21 Nínú gbogbo iṣẹ́ tó ṣe láti wá Ọlọ́run rẹ̀, bóyá èyí tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́+ tàbí ti Òfin àti àṣẹ, gbogbo ọkàn rẹ̀ ló fi ṣe é, ó sì ṣàṣeyọrí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́