ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 37
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ìran àfonífojì tí egungun gbígbẹ kún inú rẹ̀ (1-14)

      • Igi méjì yóò wà pa pọ̀ (15-28)

        • Ọba kan yóò máa ṣàkóso wọn bí orílẹ̀-èdè kan (22)

        • Májẹ̀mú àlàáfíà tí yóò wà títí ayérayé (26)

Ìsíkíẹ́lì 37:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 21:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 113, 118

Ìsíkíẹ́lì 37:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 37:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 113-114

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2016, ojú ìwé 29-30

Ìsíkíẹ́lì 37:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:39; 1Sa 2:6

Ìsíkíẹ́lì 37:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:7; Isk 37:14

Ìsíkíẹ́lì 37:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 115-116

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2016, ojú ìwé 29-31

Ìsíkíẹ́lì 37:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 115-116

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2016, ojú ìwé 29-31

Ìsíkíẹ́lì 37:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “èémí; ẹ̀mí.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 114

Ìsíkíẹ́lì 37:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀mí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 11:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 116-119

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2016, ojú ìwé 29-31

Ìsíkíẹ́lì 37:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 36:10
  • +Ais 49:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 113-114

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2016, ojú ìwé 29-30

Ìsíkíẹ́lì 37:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 66:14
  • +Isk 11:17; Emọ 9:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 113

Ìsíkíẹ́lì 37:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 126:2

Ìsíkíẹ́lì 37:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 32:14, 15; Isk 36:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 117-119

Ìsíkíẹ́lì 37:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 15:9; 30:11
  • +1Ọb 11:31; 12:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2022, ojú ìwé 22

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2018, ojú ìwé 14

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 130-131, 239-240

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2016, ojú ìwé 31-32

Ìsíkíẹ́lì 37:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 11:13; Jer 3:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2022, ojú ìwé 22

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2018, ojú ìwé 14

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 130-131, 239-240

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2016, ojú ìwé 31-32

Ìsíkíẹ́lì 37:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọ èèyàn rẹ.”

Ìsíkíẹ́lì 37:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 50:4; Sek 10:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 133-134

Ìsíkíẹ́lì 37:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:3; Ais 11:12; Jer 16:14, 15; Emọ 9:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 130

Ìsíkíẹ́lì 37:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 3:18; Ho 1:11
  • +Jẹ 49:10; Sm 2:6; Ais 9:6; Jer 23:5; Lk 1:32
  • +Isk 37:19; Sek 10:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 89, 130

Ìsíkíẹ́lì 37:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 2:18; Isk 11:18; Ho 14:8; Sek 13:2
  • +Jer 31:33; Isk 36:28

Ìsíkíẹ́lì 37:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 23:5; 30:9; Ho 3:5; Lk 1:32
  • +Jo 10:16; 1Pe 5:4
  • +Di 30:8-10; Jer 32:39; Isk 36:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 89, 133, 214-215

Ìsíkíẹ́lì 37:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”

  • *

    Tàbí “olórí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 30:3
  • +Joẹ 3:20
  • +Ais 60:21; Emọ 9:15
  • +Isk 34:24; Lk 1:32

Ìsíkíẹ́lì 37:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 34:25
  • +Jer 30:19; Sek 8:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 134

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2010, ojú ìwé 28

    3/1/1991, ojú ìwé 18-19

Ìsíkíẹ́lì 37:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ibùgbé; Ilé.”

  • *

    Tàbí “lórí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:12; Isk 11:19, 20; 43:7; Ho 2:23; Ifi 21:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 134

Ìsíkíẹ́lì 37:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 36:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 134

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1991, ojú ìwé 18-19

Àwọn míì

Ìsík. 37:1Ifi 21:10
Ìsík. 37:2Isk 37:11
Ìsík. 37:3Di 32:39; 1Sa 2:6
Ìsík. 37:5Jẹ 2:7; Isk 37:14
Ìsík. 37:10Ifi 11:11
Ìsík. 37:11Isk 36:10
Ìsík. 37:11Ais 49:14
Ìsík. 37:12Ais 66:14
Ìsík. 37:12Isk 11:17; Emọ 9:14
Ìsík. 37:13Sm 126:2
Ìsík. 37:14Ais 32:14, 15; Isk 36:27
Ìsík. 37:162Kr 15:9; 30:11
Ìsík. 37:161Ọb 11:31; 12:20
Ìsík. 37:17Ais 11:13; Jer 3:18
Ìsík. 37:19Jer 50:4; Sek 10:6
Ìsík. 37:21Di 30:3; Ais 11:12; Jer 16:14, 15; Emọ 9:14
Ìsík. 37:22Jer 3:18; Ho 1:11
Ìsík. 37:22Jẹ 49:10; Sm 2:6; Ais 9:6; Jer 23:5; Lk 1:32
Ìsík. 37:22Isk 37:19; Sek 10:6
Ìsík. 37:23Ais 2:18; Isk 11:18; Ho 14:8; Sek 13:2
Ìsík. 37:23Jer 31:33; Isk 36:28
Ìsík. 37:24Jer 23:5; 30:9; Ho 3:5; Lk 1:32
Ìsík. 37:24Jo 10:16; 1Pe 5:4
Ìsík. 37:24Di 30:8-10; Jer 32:39; Isk 36:27
Ìsík. 37:25Jer 30:3
Ìsík. 37:25Joẹ 3:20
Ìsík. 37:25Ais 60:21; Emọ 9:15
Ìsík. 37:25Isk 34:24; Lk 1:32
Ìsík. 37:26Isk 34:25
Ìsík. 37:26Jer 30:19; Sek 8:5
Ìsík. 37:27Le 26:12; Isk 11:19, 20; 43:7; Ho 2:23; Ifi 21:3
Ìsík. 37:28Isk 36:23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 37:1-28

Ìsíkíẹ́lì

37 Ọwọ́ Jèhófà wà lára mi, Jèhófà sì fi ẹ̀mí rẹ̀ gbé mi lọ sí àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀,+ egungun sì kún ibẹ̀. 2 Ó mú mi yí ibẹ̀ ká, mo sì rí i pé egungun pọ̀ gan-an ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, wọ́n sì gbẹ gidigidi.+ 3 Ó bi mí pé: “Ọmọ èèyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun yìí tún lè ní ìyè?” Mo fèsì pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ni ẹni tó mọ̀.”+ 4 Ó wá sọ fún mi pé: “Sọ tẹ́lẹ̀ sórí àwọn egungun yìí, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà:

5 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn egungun yìí ni pé: “Èmi yóò mú kí èémí wọnú yín, ẹ ó sì di alààyè.+ 6 Màá fi iṣan sára yín, màá sì mú kí ẹ ní ẹran lára. Màá fi awọ bò yín, màá fi èémí sínú yín, ẹ ó sì di alààyè; ẹ ó wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’”

7 Torí náà, mo sọ tẹ́lẹ̀ bó ṣe pa á láṣẹ fún mi. Gbàrà tí mo sọ tẹ́lẹ̀, ariwo kan dún, ó dún bí ìgbà tí nǹkan ń rọ́ gììrì, àwọn egungun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tò pọ̀, egungun so mọ́ egungun. 8 Mo wá rí i tí iṣan àti ẹran bò wọ́n, awọ sì bò wọ́n. Àmọ́ kò tíì sí èémí kankan nínú wọn.

9 Ó wá sọ fún mi pé: “Sọ tẹ́lẹ̀ nípa afẹ́fẹ́. Sọ tẹ́lẹ̀, ọmọ èèyàn, kí o sì sọ fún afẹ́fẹ́ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ìwọ afẹ́fẹ́,* fẹ́ wá láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí o sì fẹ́ lu àwọn èèyàn yìí tí wọ́n pa, kí wọ́n lè di alààyè.”’”

10 Torí náà, mo sọ tẹ́lẹ̀ bó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí* sì wọnú wọn, wọ́n wá di alààyè, wọ́n sì dìde dúró,+ ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an ni wọ́n.

11 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, gbogbo ilé Ísírẹ́lì ni àwọn egungun yìí.+ Wọ́n ń sọ pé, ‘Egungun wa ti gbẹ, a ò sì ní ìrètí mọ́.+ Wọ́n ti pa wá run pátápátá.’ 12 Torí náà, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ̀yin èèyàn mi, èmi yóò ṣí àwọn sàréè yín,+ màá sì jí yín dìde látinú àwọn sàréè yín, èmi yóò sì mú yín wá sórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì.+ 13 Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, ẹ̀yin èèyàn mi, nígbà tí mo bá ṣí àwọn sàréè yín, tí mo sì jí yín dìde látinú àwọn sàréè yín.”’+ 14 ‘Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, ẹ ó sì di alààyè,+ èmi yóò mú kí ẹ máa gbé lórí ilẹ̀ yín; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, mo sì ti ṣe é,’ ni Jèhófà wí.”

15 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 16 “Ìwọ ọmọ èèyàn, mú igi kan, kí o sì kọ ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ pé, ‘Ti Júdà àti ti àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.’*+ Kí o wá mú igi míì, kí o sì kọ ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ pé, ‘Ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀.’*+ 17 Kí o wá mú méjèèjì sún mọ́ra kí wọ́n lè di igi kan ṣoṣo ní ọwọ́ rẹ.+ 18 Tí àwọn èèyàn rẹ* bá sọ fún ọ pé, ‘Ṣé o ò ní sọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí fún wa ni?’ 19 sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú igi Jósẹ́fù, tó wà lọ́wọ́ Éfúrémù àti àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, èmi yóò sì fi wọ́n mọ́ igi Júdà; èmi yóò sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo,+ wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.”’ 20 Kí o di àwọn igi tí o kọ nǹkan sí lára mú kí wọ́n lè rí i.

21 “Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ, èmi yóò kó wọn jọ láti ibi gbogbo, èmi yóò sì mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn.+ 22 Èmi yóò sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà,+ lórí àwọn òkè Ísírẹ́lì, ọba kan ni yóò máa ṣàkóso gbogbo wọn,+ wọn ò sì ní jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní pín sí ìjọba méjì mọ́.+ 23 Wọn ò ní fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* wọn àti àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe àti gbogbo ìṣìnà wọn sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin mọ́.+ Èmi yóò gbà wọ́n nínú gbogbo ìwà àìṣòótọ́ wọn tó mú wọn dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì wẹ̀ wọ́n mọ́. Wọ́n á di èèyàn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn.+

24 “‘“Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ́ ọba wọn,+ gbogbo wọn á sì ní olùṣọ́ àgùntàn kan.+ Wọ́n á máa tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, wọ́n á sì máa rí i pé àwọn ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́.+ 25 Wọn yóò máa gbé lórí ilẹ̀ tí mo fún Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, ibi tí àwọn baba ńlá yín gbé,+ wọn yóò sì máa gbé lórí rẹ̀ títí láé,+ àwọn àti àwọn ọmọ* wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn;+ Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò sì jẹ́ ìjòyè* wọn títí láé.+

26 “‘“Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà;+ májẹ̀mú ayérayé ni màá bá wọn dá. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, màá sọ wọ́n di púpọ̀,+ màá sì fi ibi mímọ́ mi sí àárín wọn títí láé. 27 Àgọ́* mi yóò wà pẹ̀lú* wọn, èmi yóò di Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.+ 28 Àwọn orílẹ̀-èdè á sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà, ni mò ń sọ Ísírẹ́lì di mímọ́ nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà ní àárín wọn títí láé.”’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́