ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Ó fi Ìrékọjá lọ́lẹ̀ (1-28)

        • Wọ́n máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn (7)

      • Ìyọnu 10: Ó pa àkọ́bí (29-32)

      • Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní ilẹ̀ náà (33-42)

        • 430 ọdún parí (40, 41)

      • Ìtọ́ni fún àwọn tó fẹ́ ṣe Ìrékọjá (43-51)

Ẹ́kísódù 12:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:4; 23:15; Nọ 28:16; Di 16:1

Ẹ́kísódù 12:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:29; 1Kọ 5:7; Ifi 5:6

Ẹ́kísódù 12:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “òun àti aládùúgbò rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Ẹ́kísódù 12:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:18-20; Di 17:1; 1Pe 1:19

Ẹ́kísódù 12:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbogbo ìjọ àpéjọ.”

  • *

    Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 28:16
  • +Ẹk 12:18; Le 23:5; Di 16:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2014, ojú ìwé 22

    12/15/2013, ojú ìwé 17-19

Ẹ́kísódù 12:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 5:7; Heb 11:28

Ẹ́kísódù 12:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:6, 7
  • +Ẹk 13:3; 34:25; Di 16:3; 1Kọ 5:8
  • +Nọ 9:11

Ẹ́kísódù 12:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:15; 22:29, 30; Di 16:4

Ẹ́kísódù 12:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹ di ìbàdí yín lámùrè.”

Ẹ́kísódù 12:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 11:4, 5; 12:29
  • +Nọ 33:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2020, ojú ìwé 5

Ẹ́kísódù 12:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 8:22; 9:4, 26; 10:23; 11:7

Ẹ́kísódù 12:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “kí ẹ ké ẹni tó bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà kúrò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:15; Le 23:6

Ẹ́kísódù 12:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:8

Ẹ́kísódù 12:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:6; Lk 22:1; 1Kọ 5:8

Ẹ́kísódù 12:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:5, 6

Ẹ́kísódù 12:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kí ẹ ké.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 9:14
  • +Di 16:3; 1Kọ 5:7

Ẹ́kísódù 12:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2007, ojú ìwé 31

Ẹ́kísódù 12:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ọmọ àgùntàn tàbí ewúrẹ́.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:16; Nọ 11:16

Ẹ́kísódù 12:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìparun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:28

Ẹ́kísódù 12:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:3

Ẹ́kísódù 12:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 5:10

Ẹ́kísódù 12:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:3, 8; Di 6:6, 7

Ẹ́kísódù 12:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    12/15/1995, ojú ìwé 12

Ẹ́kísódù 12:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ní ilé kòtò omi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:4; Sm 78:51; 105:36
  • +Jẹ 15:14; Ẹk 11:4, 5; Nọ 3:13; Sm 135:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 26

Ẹ́kísódù 12:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 11:6

Ẹ́kísódù 12:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 10:28, 29
  • +Ẹk 3:19, 20; 6:1; 10:8-11; Sm 105:38

Ẹ́kísódù 12:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 10:26

Ẹ́kísódù 12:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:11
  • +Ẹk 10:7

Ẹ́kísódù 12:34

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “abọ́.”

Ẹ́kísódù 12:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:14; Ẹk 3:21; 11:2; Sm 105:37

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/1999, ojú ìwé 30

Ẹ́kísódù 12:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 26

    11/1/1999, ojú ìwé 30

    12/1/1994, ojú ìwé 13

Ẹ́kísódù 12:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 47:11; Ẹk 1:11
  • +Nọ 33:5
  • +Jẹ 12:1, 2; 15:1, 5; 46:2, 3; Ẹk 1:7; Nọ 2:32

Ẹ́kísódù 12:38

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, oríṣiríṣi èèyàn tí wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, títí kan àwọn ará Íjíbítì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 11:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2014, ojú ìwé 20

    4/15/1992, ojú ìwé 8

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 180-181

Ẹ́kísódù 12:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:31

Ẹ́kísódù 12:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:2, 3; 47:27; Iṣe 13:17
  • +Ga 3:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2004, ojú ìwé 26

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 10-103

Ẹ́kísódù 12:41

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbogbo ọmọ ogun Jèhófà.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2016, ojú ìwé 14-15

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 103

Ẹ́kísódù 12:42

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 10-105

Ẹ́kísódù 12:43

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:10

Ẹ́kísódù 12:44

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọ ọ́ nílà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:12, 23

Ẹ́kísódù 12:46

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 9:12; Sm 34:19, 20; Jo 19:33, 36

Ẹ́kísódù 12:48

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọlà.”

  • *

    Tàbí “aláìkọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 9:14

Ẹ́kísódù 12:49

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 24:22; Nọ 15:16

Ẹ́kísódù 12:50

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    12/15/1995, ojú ìwé 12

Ẹ́kísódù 12:51

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun.”

Àwọn míì

Ẹ́kís. 12:2Ẹk 13:4; 23:15; Nọ 28:16; Di 16:1
Ẹ́kís. 12:3Jo 1:29; 1Kọ 5:7; Ifi 5:6
Ẹ́kís. 12:5Le 22:18-20; Di 17:1; 1Pe 1:19
Ẹ́kís. 12:6Nọ 28:16
Ẹ́kís. 12:6Ẹk 12:18; Le 23:5; Di 16:6
Ẹ́kís. 12:71Kọ 5:7; Heb 11:28
Ẹ́kís. 12:8Di 16:6, 7
Ẹ́kís. 12:8Ẹk 13:3; 34:25; Di 16:3; 1Kọ 5:8
Ẹ́kís. 12:8Nọ 9:11
Ẹ́kís. 12:10Le 7:15; 22:29, 30; Di 16:4
Ẹ́kís. 12:12Ẹk 11:4, 5; 12:29
Ẹ́kís. 12:12Nọ 33:4
Ẹ́kís. 12:13Ẹk 8:22; 9:4, 26; 10:23; 11:7
Ẹ́kís. 12:15Ẹk 23:15; Le 23:6
Ẹ́kís. 12:16Le 23:8
Ẹ́kís. 12:17Le 23:6; Lk 22:1; 1Kọ 5:8
Ẹ́kís. 12:18Le 23:5, 6
Ẹ́kís. 12:19Nọ 9:14
Ẹ́kís. 12:19Di 16:3; 1Kọ 5:7
Ẹ́kís. 12:21Ẹk 3:16; Nọ 11:16
Ẹ́kís. 12:23Heb 11:28
Ẹ́kís. 12:24Di 16:3
Ẹ́kís. 12:25Joṣ 5:10
Ẹ́kís. 12:26Ẹk 13:3, 8; Di 6:6, 7
Ẹ́kís. 12:28Heb 11:28
Ẹ́kís. 12:29Nọ 33:4; Sm 78:51; 105:36
Ẹ́kís. 12:29Jẹ 15:14; Ẹk 11:4, 5; Nọ 3:13; Sm 135:8
Ẹ́kís. 12:30Ẹk 11:6
Ẹ́kís. 12:31Ẹk 10:28, 29
Ẹ́kís. 12:31Ẹk 3:19, 20; 6:1; 10:8-11; Sm 105:38
Ẹ́kís. 12:32Ẹk 10:26
Ẹ́kís. 12:33Ẹk 12:11
Ẹ́kís. 12:33Ẹk 10:7
Ẹ́kís. 12:35Jẹ 15:14; Ẹk 3:21; 11:2; Sm 105:37
Ẹ́kís. 12:36Ẹk 3:22
Ẹ́kís. 12:37Jẹ 47:11; Ẹk 1:11
Ẹ́kís. 12:37Nọ 33:5
Ẹ́kís. 12:37Jẹ 12:1, 2; 15:1, 5; 46:2, 3; Ẹk 1:7; Nọ 2:32
Ẹ́kís. 12:38Nọ 11:4
Ẹ́kís. 12:39Ẹk 12:31
Ẹ́kís. 12:40Jẹ 46:2, 3; 47:27; Iṣe 13:17
Ẹ́kís. 12:40Ga 3:17
Ẹ́kís. 12:42Di 16:1
Ẹ́kís. 12:43Le 22:10
Ẹ́kís. 12:44Jẹ 17:12, 23
Ẹ́kís. 12:46Nọ 9:12; Sm 34:19, 20; Jo 19:33, 36
Ẹ́kís. 12:48Nọ 9:14
Ẹ́kís. 12:49Le 24:22; Nọ 15:16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
  • 47
  • 48
  • 49
  • 50
  • 51
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 12:1-51

Ẹ́kísódù

12 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì ní ilẹ̀ Íjíbítì pé: 2 “Oṣù yìí ni yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù fún yín. Òun ni yóò jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ fún yín nínú ọdún.+ 3 Sọ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Lọ́jọ́ kẹwàá oṣù yìí, kí kálukú wọn mú àgùntàn kan+ fún ilé bàbá wọn, àgùntàn kan fún ilé kan. 4 Àmọ́ tí àgùntàn kan bá ti pọ̀ jù fún agbo ilé náà, kí àwọn àti aládùúgbò wọn* tó múlé tì wọ́n jọ pín in nínú ilé wọn, kí wọ́n pín in sí iye èèyàn* tí wọ́n jẹ́. Kí ẹ ṣírò iye ẹran àgùntàn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa jẹ. 5 Kí ara àgùntàn yín dá ṣáṣá,+ kó jẹ́ akọ, ọlọ́dún kan. Ẹ lè mú lára àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́. 6 Kí ẹ máa tọ́jú rẹ̀ títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí,+ kí gbogbo àpéjọ* àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì pa á ní ìrọ̀lẹ́.*+ 7 Kí wọ́n mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì wọ́n ọn sára òpó méjèèjì ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ọ̀nà àwọn ilé tí wọ́n ti jẹ ẹ́.+

8 “‘Kí wọ́n jẹ ẹran náà lálẹ́ yìí.+ Kí wọ́n yan án lórí iná, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú+ àti ewébẹ̀ kíkorò.+ 9 Ẹ má jẹ ẹ́ ní tútù tàbí ní bíbọ̀, ẹ má fi omi sè é, àmọ́ ẹ yan án lórí iná, ẹ yan orí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ àti àwọn nǹkan inú rẹ̀. 10 Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan lára rẹ̀ kù di àárọ̀, àmọ́ tí ìkankan lára rẹ̀ bá ṣẹ́ kù di àárọ̀, kí ẹ fi iná sun ún.+ 11 Bí ẹ ó ṣe jẹ ẹ́ nìyí, ẹ di àmùrè,* ẹ wọ bàtà, kí ẹ mú ọ̀pá yín dání; kí ẹ sì yára jẹ ẹ́. Ìrékọjá Jèhófà ni. 12 Torí màá lọ káàkiri ilẹ̀ Íjíbítì lálẹ́ yìí, màá sì pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì, látorí èèyàn dórí ẹranko;+ màá sì dá gbogbo ọlọ́run Íjíbítì lẹ́jọ́.+ Èmi ni Jèhófà. 13 Ẹ̀jẹ̀ náà yóò jẹ́ àmì yín lára àwọn ilé tí ẹ wà; èmi yóò rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò sì ré yín kọjá, ìyọnu náà ò sì ní pa yín run nígbà tí mo bá kọ lu ilẹ̀ Íjíbítì.+

14 “‘Kí ẹ máa rántí ọjọ́ yìí, kí ẹ sì máa ṣe ayẹyẹ rẹ̀, kó jẹ́ àjọyọ̀ sí Jèhófà jálẹ̀ àwọn ìran yín. Ẹ máa pa àjọyọ̀ náà mọ́, ó ti di òfin fún yín títí láé. 15 Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú.+ Lọ́jọ́ kìíní, kí ẹ mú àpòrọ́ kíkan kúrò ní ilé yín, kí ẹ pa ẹni* tó bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà* láti ọjọ́ kìíní títí dé ìkeje ní Ísírẹ́lì. 16 Ní ọjọ́ kìíní, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣe àpéjọ mímọ́ míì ní ọjọ́ keje. Ẹ má ṣe iṣẹ́ kankan ní àwọn ọjọ́ yìí.+ Ohun tí ẹnì* kọ̀ọ̀kan máa jẹ nìkan ni kí wọ́n sè.

17 “‘Kí ẹ máa ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ torí ní ọjọ́ yìí gangan, èmi yóò mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ* yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí ẹ máa pa ọjọ́ yìí mọ́ jálẹ̀ àwọn ìran yín, ó ti di òfin fún yín títí láé. 18 Kí ẹ jẹ búrẹ́dì aláìwú láti alẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní títí di alẹ́ ọjọ́ kọkànlélógún oṣù náà.+ 19 Kò gbọ́dọ̀ sí àpòrọ́ kíkan nínú ilé yín rárá fún ọjọ́ méje, torí tí ẹnikẹ́ni bá jẹ ohun tó ní ìwúkàrà, yálà àjèjì tàbí ọmọ ìbílẹ̀,+ kí ẹ pa* ẹni* yẹn kúrò nínú àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 20 Ẹ má jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà. Búrẹ́dì aláìwú ni kí ẹ jẹ ní gbogbo ilé yín.’”

21 Mósè yára pe gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ mú àwọn ọmọ ẹran* fún ìdílé yín níkọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa ẹran tí ẹ máa fi rúbọ nígbà Ìrékọjá. 22 Kí ẹ wá ki ìdìpọ̀ ewéko hísópù bọnú ẹ̀jẹ̀ tó wà nínú bàsíà, kí ẹ sì wọ́n ọn sí apá òkè ẹnu ọ̀nà àti sára òpó méjèèjì ilẹ̀kùn náà; kí ẹnì kankan nínú yín má sì jáde ní ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀ títí di àárọ̀. 23 Tí Jèhófà bá wá kọjá kó lè fi ìyọnu kọ lu àwọn ará Íjíbítì, tó sì rí ẹ̀jẹ̀ náà ní apá òkè ẹnu ọ̀nà àti lára òpó rẹ̀ méjèèjì, ó dájú pé Jèhófà yóò ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí ìyọnu ikú* wọnú ilé yín.+

24 “Kí ẹ máa pa àjọ̀dún yìí mọ́, ó ti di àṣẹ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín títí láé.+ 25 Tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí Jèhófà yóò fún yín bó ṣe sọ, kí ẹ máa ṣe àjọyọ̀ yìí.+ 26 Tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín pé, ‘Kí nìdí tí ẹ fi ń ṣe àjọyọ̀ yìí?’+ 27 kí ẹ sọ pé, ‘Ẹbọ Ìrékọjá sí Jèhófà ni, ẹni tó ré ilé àwa ọmọ Ísírẹ́lì kọjá ní Íjíbítì nígbà tó fi ìyọnu kọ lu àwọn ará Íjíbítì, tó sì dá ilé wa sí.’”

Àwọn èèyàn náà tẹrí ba, wọ́n sì wólẹ̀. 28 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè àti Áárónì.+ Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.

29 Nígbà tó di ọ̀gànjọ́ òru, Jèhófà pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ látorí àkọ́bí Fáráò tó wà lórí ìtẹ́ dórí àkọ́bí ẹni tó wà lẹ́wọ̀n* àti gbogbo àkọ́bí ẹranko.+ 30 Fáráò dìde ní òru yẹn, òun àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará Íjíbítì yòókù, igbe ẹkún ńlá sì sọ láàárín àwọn ará Íjíbítì, torí kò sí ilé kankan tí èèyàn ò ti kú.+ 31 Ló bá pe Mósè àti Áárónì+ ní òru, ó sì sọ pé: “Ẹ gbéra, ẹ kúrò láàárín àwọn èèyàn mi, ẹ̀yin àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù. Ẹ lọ sin Jèhófà bí ẹ ṣe sọ.+ 32 Kí ẹ kó àwọn agbo ẹran yín àti ọ̀wọ́ ẹran yín, kí ẹ sì lọ bí ẹ ṣe sọ.+ Àmọ́ kí ẹ súre fún mi.”

33 Àwọn ará Íjíbítì wá ń rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n tètè kúrò ní ilẹ̀ náà.+ Wọ́n sọ pé, “Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, gbogbo wa la máa kú!”+ 34 Torí náà, àwọn èèyàn náà gbé àpòrọ́ ìyẹ̀fun wọn tí kò ní ìwúkàrà, wọ́n fi aṣọ wé ọpọ́n* tí wọ́n fi ń po nǹkan, wọ́n sì gbé e lé èjìká. 35 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí Mósè sọ fún wọn, wọ́n béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti wúrà pẹ̀lú aṣọ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.+ 36 Jèhófà mú kí àwọn èèyàn náà rí ojú rere àwọn ará Íjíbítì, wọ́n fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè, wọ́n sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.+

37 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá kúrò ní Rámésésì,+ wọ́n sì forí lé Súkótù,+ wọ́n tó nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkùnrin tó ń fẹsẹ̀ rìn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọdé.+ 38 Oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ*+ ló tún bá wọn lọ, pẹ̀lú àwọn agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹran ọ̀sìn. 39 Wọ́n wá ń fi àpòrọ́ tí wọ́n mú kúrò ní Íjíbítì ṣe búrẹ́dì aláìwú tó rí ribiti. Kò ní ìwúkàrà, torí ṣe ni wọ́n lé wọn kúrò ní Íjíbítì lójijì débi pé wọn ò ráyè ṣètò oúnjẹ kankan fún ara wọn.+

40 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tó gbé ní Íjíbítì,+ ti lo ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún.+ 41 Ní ọjọ́ yìí tí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún pé ni gbogbo èèyàn Jèhófà tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. 42 Òru yẹn ni wọ́n á ṣe àjọyọ̀ torí pé Jèhófà mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì máa pa òru ọjọ́ yìí mọ́ jálẹ̀ àwọn ìran wọn láti bọlá fún Jèhófà.+

43 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé, “Àṣẹ tí ẹ ó máa tẹ̀ lé nígbà Ìrékọjá nìyí: Àjèjì kankan ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.+ 44 Àmọ́ tí ẹnì kan bá ní ẹrú tó jẹ́ ọkùnrin, tó fi owó rà, kí o dádọ̀dọ́ rẹ̀.*+ Ìgbà yẹn ló tó lè jẹ nínú rẹ̀. 45 Ẹni tó wá gbé láàárín yín àti alágbàṣe kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀. 46 Inú ilé kan ni kí ẹ ti jẹ ẹ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ìkankan nínú ẹran náà kúrò nínú ilé lọ síta, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fọ́ ìkankan nínú egungun rẹ̀.+ 47 Kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ayẹyẹ yìí. 48 Tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín, tó sì fẹ́ ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá láti bọlá fún Jèhófà, kí gbogbo ọkùnrin ilé rẹ̀ dádọ̀dọ́.* Ìgbà yẹn ló lè ṣe ayẹyẹ náà, yóò sì dà bí ọmọ ìbílẹ̀. Àmọ́ aláìdádọ̀dọ́* ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.+ 49 Òfin kan náà ni kí ọmọ ìbílẹ̀ àti àjèjì tó ń gbé láàárín yín máa tẹ̀ lé.”+

50 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè àti Áárónì. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. 51 Ọjọ́ yìí gan-an ni Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́