ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 58
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Ààwẹ̀ tó dénú àti èyí tí kò dénú (1-12)

      • Pípa Sábáàtì mọ́ ń múnú ẹni dùn (13, 14)

Àìsáyà 58:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:2; 31:6; 59:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 276-277

Àìsáyà 58:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 29:13; Isk 33:32
  • +Ais 1:14, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 277

Àìsáyà 58:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ìdùnnú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 3:14
  • +Le 16:29
  • +Jer 34:15, 16; Mik 3:2-4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2009, ojú ìwé 29

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 279

Àìsáyà 58:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 279

Àìsáyà 58:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 279

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    11/15/1996, ojú ìwé 5

Àìsáyà 58:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 34:8, 9
  • +Owe 28:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 280-281

Àìsáyà 58:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 41:1; 112:9; Owe 19:17; 22:9
  • +Isk 18:7, 8; Jem 2:15, 16; 1Jo 3:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 281-282

Àìsáyà 58:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 4:18
  • +Ẹk 14:19; Ais 52:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 282

Àìsáyà 58:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 32:6; 59:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 282-284

Àìsáyà 58:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn ìwọ fúnra rẹ.”

  • *

    Tàbí “àwọn ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 15:7, 8
  • +Sm 37:5, 6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 282-284

Àìsáyà 58:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 49:10
  • +Ais 61:11; Jer 31:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 284-285

Àìsáyà 58:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹni tó ń dí àlàfo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 2:5; Jer 31:38
  • +Ais 61:4
  • +Ne 6:1; Emọ 9:11, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 285

Àìsáyà 58:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Tí o bá yí ẹsẹ̀ rẹ pa dà, tí o kò wá.”

  • *

    Tàbí “àwọn ohun tó ń múnú rẹ dùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 13:15; Ais 56:2; Jer 17:21
  • +Di 5:12-14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 285-287

Àìsáyà 58:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbádùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:13
  • +Sm 105:10, 11; Jer 3:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 285-287, 288-289

Àwọn míì

Àìsá. 58:1Ais 1:2; 31:6; 59:13
Àìsá. 58:2Ais 29:13; Isk 33:32
Àìsá. 58:2Ais 1:14, 15
Àìsá. 58:3Mal 3:14
Àìsá. 58:3Le 16:29
Àìsá. 58:3Jer 34:15, 16; Mik 3:2-4
Àìsá. 58:6Jer 34:8, 9
Àìsá. 58:6Owe 28:27
Àìsá. 58:7Sm 41:1; 112:9; Owe 19:17; 22:9
Àìsá. 58:7Isk 18:7, 8; Jem 2:15, 16; 1Jo 3:17
Àìsá. 58:8Owe 4:18
Àìsá. 58:8Ẹk 14:19; Ais 52:12
Àìsá. 58:9Ais 32:6; 59:3
Àìsá. 58:10Di 15:7, 8
Àìsá. 58:10Sm 37:5, 6
Àìsá. 58:11Ais 49:10
Àìsá. 58:11Ais 61:11; Jer 31:12
Àìsá. 58:12Ne 2:5; Jer 31:38
Àìsá. 58:12Ais 61:4
Àìsá. 58:12Ne 6:1; Emọ 9:11, 14
Àìsá. 58:13Ne 13:15; Ais 56:2; Jer 17:21
Àìsá. 58:13Di 5:12-14
Àìsá. 58:14Di 32:13
Àìsá. 58:14Sm 105:10, 11; Jer 3:18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 58:1-14

Àìsáyà

58 “Fi gbogbo ẹnu kígbe; má ṣe dákẹ́!

Gbé ohùn rẹ sókè bíi fèrè.

Kéde ọ̀tẹ̀ àwọn èèyàn mi fún wọn,+

Kí o sọ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jékọ́bù fún wọn.

 2 Wọ́n ń wá mi lójoojúmọ́,

Inú wọn sì ń dùn láti mọ àwọn ọ̀nà mi,

Bíi pé orílẹ̀-èdè olódodo ni wọ́n,

Tí kò sì pa ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run wọn tì.+

Wọ́n béèrè ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́ mi,

Inú wọn ń dùn láti sún mọ́ Ọlọ́run:+

 3 ‘Kí ló dé tí o ò rí i nígbà tí à ń gbààwẹ̀?+

Kí ló sì dé tí o ò kíyè sí i nígbà tí à ń pọ́n ara* wa lójú?’+

Torí ní ọjọ́ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀, ire* ara yín lẹ̀ ń wá,

Ẹ sì ń fìyà jẹ àwọn alágbàṣe yín.+

 4 Aáwọ̀ àti ìjà ló máa ń gbẹ̀yìn ààwẹ̀ yín,

Ẹ sì ń gbáni ní ẹ̀ṣẹ́ ìkà.

Ẹ ò lè gbààwẹ̀ bí ẹ ṣe ń ṣe lónìí, kí a sì gbọ́ ohùn yín ní ọ̀run.

 5 Ṣé ó yẹ kí ààwẹ̀ tí mo fọwọ́ sí rí báyìí,

Bí ọjọ́ tí èèyàn máa pọ́n ara* rẹ̀ lójú,

Tó máa dorí kodò bí koríko etídò,

Kó ṣe ibùsùn rẹ̀ sórí aṣọ ọ̀fọ̀* àti eérú?

Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀ àti ọjọ́ tínú Jèhófà dùn sí nìyí?

 6 Rárá, ààwẹ̀ tí mo fọwọ́ sí nìyí:

Kí ẹ tú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìkà,

Kí ẹ tú ìdè ọ̀pá àjàgà,+

Kí ẹ tú ẹni tí ìyà ń jẹ sílẹ̀,+

Kí ẹ sì kán gbogbo ọ̀pá àjàgà sí méjì;

 7 Ẹ fún ẹni tí ebi ń pa lára oúnjẹ yín,+

Kí ẹ mú aláìní àti ẹni tí kò rílé gbé wá sínú ilé yín,

Kí ẹ fi aṣọ bo ẹni tó wà ní ìhòòhò tí ẹ bá rí i,+

Kí ẹ má sì kẹ̀yìn sí àwọn èèyàn yín.

 8 Ìmọ́lẹ̀ rẹ máa wá tàn bí ọ̀yẹ̀,+

Ìwòsàn rẹ sì máa yára dé.

Òdodo rẹ á máa lọ níwájú rẹ,

Ògo Jèhófà á sì máa ṣọ́ ọ láti ẹ̀yìn.+

 9 O máa pè, Jèhófà sì máa dáhùn;

O máa kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì máa sọ pé, ‘Èmi nìyí!’

Tí o bá mú ọ̀pá àjàgà kúrò láàárín rẹ,

Tí o kò na ìka rẹ, tí o kò sì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ mọ́,+

10 Tí o bá fún ẹni tí ebi ń pa ní ohun tí ìwọ fúnra rẹ* fẹ́,+

Tí o sì tẹ́ àwọn* tí ìyà ń jẹ lọ́rùn,

Ìmọ́lẹ̀ rẹ máa tàn nínú òkùnkùn pàápàá,

Ìṣúdùdù rẹ sì máa dà bí ọ̀sán gangan.+

11 Jèhófà á máa darí rẹ nígbà gbogbo,

Ó sì máa tẹ́ ọ* lọ́rùn, kódà ní ilẹ̀ gbígbẹ;+

Ó máa mú kí egungun rẹ lágbára,

O sì máa dà bí ọgbà tí wọ́n ń bomi rin dáadáa,+

Bí ìsun omi, tí omi rẹ̀ kì í tán.

12 Wọ́n máa tún àwọn àwókù àtijọ́ kọ́ nítorí rẹ,+

O sì máa dá ìpìlẹ̀ àwọn ìran tó ti kọjá pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.+

Wọ́n máa pè ọ́ ní ẹni tó ń tún àwọn ògiri tó ti fọ́ ṣe,*+

Ẹni tó ń ṣe àtúnṣe àwọn ọ̀nà tí wọ́n á máa gbé.

13 Tí o kò bá wá* ire ara rẹ* ní ọjọ́ mímọ́ mi, nítorí Sábáàtì,+

Tí o sì pe Sábáàtì ní ohun tó ń múnú ẹni dùn gidigidi, ọjọ́ mímọ́ Jèhófà, ọjọ́ tó yẹ ká ṣe lógo,+

Tí o sì ṣe é lógo dípò kí o máa wá ire ara rẹ, kí o sì máa sọ ọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀,

14 Nígbà náà, inú rẹ máa dùn gidigidi torí Jèhófà,

Màá sì mú kí o gun àwọn ibi tó ga ní ayé.+

Màá mú kí o jẹ nínú* ogún Jékọ́bù baba ńlá rẹ,+

Torí Jèhófà ti fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ́.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́