ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Ibi tí Ọlọ́run bá yàn ni kí ẹ ti máa jọ́sìn (1-14)

      • Wọ́n lè jẹ ẹran àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ (15-28)

      • Má ṣe kó sí ìdẹkùn àwọn ọlọ́run míì (29-32)

Diutarónómì 12:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:13

Diutarónómì 12:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:24
  • +Di 7:25
  • +Ẹk 23:13; Joṣ 23:7

Diutarónómì 12:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:3; Di 12:31

Diutarónómì 12:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 7:12

Diutarónómì 12:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:3
  • +Di 14:22
  • +Nọ 18:19; Di 12:11
  • +1Kr 29:9; Ẹsr 2:68
  • +Di 12:17; 15:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 12:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 15:19, 20
  • +Le 23:40; Di 12:12, 18; 14:23, 26; Sm 32:11; 100:2; Flp 4:4

Diutarónómì 12:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun tó rò pé ó tọ́.”

Diutarónómì 12:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:56; 1Kr 23:25

Diutarónómì 12:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 3:17
  • +Di 33:28; 1Ọb 4:25

Diutarónómì 12:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:2; 26:2
  • +Di 14:22, 23

Diutarónómì 12:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnubodè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:26; 1Ọb 8:66; Ne 8:10
  • +Nọ 18:20, 24; Di 10:9; 14:28, 29; Joṣ 13:14

Diutarónómì 12:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 17:3, 4; 1Ọb 12:28

Diutarónómì 12:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 7:12

Diutarónómì 12:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn yín.”

  • *

    Ní Héb., “nínú gbogbo ẹnubodè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:21

Diutarónómì 12:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:4; Le 7:26; 17:10; Iṣe 15:20, 29
  • +Le 17:13; Di 15:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2000, ojú ìwé 30-31

Diutarónómì 12:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnubodè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:22, 23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 12:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnubodè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:11; 14:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 12:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:21; Di 14:27; 2Kr 31:4; Ne 10:38, 39; Mal 3:8

Diutarónómì 12:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó wu ọkàn rẹ pé kó jẹ ẹran.”

  • *

    Tàbí “ní gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:21
  • +Jẹ 15:18; Ẹk 34:24; Di 11:24
  • +Le 11:2-4

Diutarónómì 12:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnubodè.”

  • *

    Tàbí “ní gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:23; 2Kr 7:12

Diutarónómì 12:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 14:4, 5

Diutarónómì 12:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 3:17; Di 12:16
  • +Jẹ 9:4; Le 17:11, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/15/1991, ojú ìwé 31

Diutarónómì 12:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 17:13; Di 15:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2000, ojú ìwé 30-31

Diutarónómì 12:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 17:11
  • +Le 4:29, 30

Diutarónómì 12:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:23; Sm 44:2; 78:55

Diutarónómì 12:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:16; Sm 106:36; Isk 20:28

Diutarónómì 12:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:3, 21; 20:2; Di 18:10-12; Jer 32:35

Diutarónómì 12:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 22:5
  • +Di 4:2; Joṣ 1:7

Àwọn míì

Diu. 12:2Ẹk 34:13
Diu. 12:3Ẹk 23:24
Diu. 12:3Di 7:25
Diu. 12:3Ẹk 23:13; Joṣ 23:7
Diu. 12:4Le 18:3; Di 12:31
Diu. 12:52Kr 7:12
Diu. 12:6Le 1:3
Diu. 12:6Di 14:22
Diu. 12:6Nọ 18:19; Di 12:11
Diu. 12:61Kr 29:9; Ẹsr 2:68
Diu. 12:6Di 12:17; 15:19
Diu. 12:7Di 15:19, 20
Diu. 12:7Le 23:40; Di 12:12, 18; 14:23, 26; Sm 32:11; 100:2; Flp 4:4
Diu. 12:91Ọb 8:56; 1Kr 23:25
Diu. 12:10Joṣ 3:17
Diu. 12:10Di 33:28; 1Ọb 4:25
Diu. 12:11Di 16:2; 26:2
Diu. 12:11Di 14:22, 23
Diu. 12:12Di 14:26; 1Ọb 8:66; Ne 8:10
Diu. 12:12Nọ 18:20, 24; Di 10:9; 14:28, 29; Joṣ 13:14
Diu. 12:13Le 17:3, 4; 1Ọb 12:28
Diu. 12:142Kr 7:12
Diu. 12:15Di 12:21
Diu. 12:16Jẹ 9:4; Le 7:26; 17:10; Iṣe 15:20, 29
Diu. 12:16Le 17:13; Di 15:23
Diu. 12:17Di 14:22, 23
Diu. 12:18Di 12:11; 14:26
Diu. 12:19Nọ 18:21; Di 14:27; 2Kr 31:4; Ne 10:38, 39; Mal 3:8
Diu. 12:201Ọb 4:21
Diu. 12:20Jẹ 15:18; Ẹk 34:24; Di 11:24
Diu. 12:20Le 11:2-4
Diu. 12:21Di 14:23; 2Kr 7:12
Diu. 12:22Di 14:4, 5
Diu. 12:23Le 3:17; Di 12:16
Diu. 12:23Jẹ 9:4; Le 17:11, 14
Diu. 12:24Le 17:13; Di 15:23
Diu. 12:27Le 17:11
Diu. 12:27Le 4:29, 30
Diu. 12:29Ẹk 23:23; Sm 44:2; 78:55
Diu. 12:30Di 7:16; Sm 106:36; Isk 20:28
Diu. 12:31Le 18:3, 21; 20:2; Di 18:10-12; Jer 32:35
Diu. 12:32Joṣ 22:5
Diu. 12:32Di 4:2; Joṣ 1:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 12:1-32

Diutarónómì

12 “Èyí ni àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí ẹ gbọ́dọ̀ rí i pé ẹ̀ ń pa mọ́ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín máa fún yín pé kó di tiyín. 2 Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ máa lé kúrò bá ti sin àwọn ọlọ́run wọn ni kí ẹ pa run pátápátá,+ ì báà jẹ́ lórí àwọn òkè tó ga tàbí lórí àwọn òkè kéékèèké tàbí lábẹ́ igi èyíkéyìí tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀. 3 Kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú,+ kí ẹ dáná sun àwọn òpó òrìṣà* wọn, kí ẹ sì gé ère àwọn ọlọ́run wọn+ tí wọ́n gbẹ́ lulẹ̀, kí orúkọ wọn lè pa rẹ́ kúrò níbẹ̀.+

4 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run yín lọ́nà yẹn.+ 5 Kàkà bẹ́ẹ̀, ibikíbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ wà àti ibi tó bá ń gbé láàárín gbogbo ẹ̀yà yín ni kí ẹ ti máa wá a, ibẹ̀ sì ni kí ẹ máa lọ.+ 6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú àwọn ẹbọ sísun yín wá+ àti àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín àti àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín.+ 7 Ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin àti àwọn agbo ilé yín ti jẹun níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì máa yọ̀ nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ti bù kún yín.

8 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe bí a ṣe ń ṣe níbí lónìí, tí kálukú ń ṣe ohun tó dáa lójú ara rẹ̀,* 9 torí pé ẹ ò tíì dé ibi ìsinmi,+ ẹ ò sì tíì gba ogún tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín. 10 Tí ẹ bá ti sọdá Jọ́dánì,+ tí ẹ sì wá ń gbé ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín pé kó di tiyín, ó dájú pé ó máa mú kí ẹ sinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín tó yí yín ká, ẹ ó sì máa gbé láìséwu.+ 11 Gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ mú wá sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run yín yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà,+ ìyẹn àwọn ẹbọ sísun yín, àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín àti gbogbo ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà. 12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin àti àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ẹrúkùnrin yín, àwọn ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, torí wọn ò fún un ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú yín.+ 13 Kí ẹ rí i pé ẹ ò rú àwọn ẹbọ sísun yín níbòmíì tí ẹ bá rí.+ 14 Ibi tí Jèhófà yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ tó jẹ́ ti ẹ̀yà yín nìkan ni kí ẹ ti rú àwọn ẹbọ sísun yín, ibẹ̀ sì ni kí ẹ ti ṣe gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín.+

15 “Àmọ́ ìgbàkígbà tó bá wù yín* lẹ lè pa ẹran kí ẹ sì jẹ ẹ́,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín bá ṣe bù kún yín tó ní gbogbo ìlú* yín. Ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ àti ẹni tó mọ́ lè jẹ ẹ́, bí ẹ ṣe máa ń jẹ egbin tàbí àgbọ̀nrín. 16 Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀;+ ṣe ni kí ẹ dà á sórí ilẹ̀ bí omi.+ 17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn nǹkan yìí nínú àwọn ìlú* yín: ìdá mẹ́wàá ọkà yín, wáìnì tuntun yín, òróró yín, àwọn àkọ́bí lára ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín,+ èyíkéyìí lára àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá yín àti ọrẹ látọwọ́ yín. 18 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, níbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn,+ ẹ̀yin àti ọmọkùnrin yín, ọmọbìnrin yín, ẹrúkùnrin yín àti ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín; kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé. 19 Kí ẹ rí i pé ẹ ò gbàgbé ọmọ Léfì+ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi ń gbé lórí ilẹ̀ yín.

20 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú kí ilẹ̀ rẹ fẹ̀ sí i,+ bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́,+ tí o wá ń sọ pé, ‘Mo fẹ́ jẹ ẹran,’ torí pé ẹran ń wù ọ́ jẹ,* o lè jẹ ẹ́ nígbàkigbà tó bá wù ọ́.*+ 21 Tí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí+ bá jìnnà sí ọ, kí o pa lára ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran rẹ tí Jèhófà fún ọ, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ, kí o sì jẹ ẹ́ nínú àwọn ìlú* rẹ nígbàkigbà tó bá wù ọ́.* 22 Kí o jẹ ẹ́ bí o ṣe máa ń jẹ egbin àti àgbọ̀nrín;+ ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ àti ẹni tó mọ́ lè jẹ ẹ́. 23 Ṣáà ti pinnu pé o ò ní jẹ ẹ̀jẹ̀,+ má sì yẹ ìpinnu rẹ, torí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí,*+ o ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀mí* pọ̀ mọ́ ẹran. 24 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. Ṣe ni kí o dà á sórí ilẹ̀ bí omi.+ 25 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, torí ò ń ṣe ohun tó tọ́ ní ojú Jèhófà. 26 Àwọn ohun mímọ́ tó jẹ́ tìrẹ àti àwọn ọrẹ tí o jẹ́jẹ̀ẹ́ nìkan ni kí o mú wá tí o bá wá sí ibi tí Jèhófà máa yàn. 27 Ibẹ̀ ni kí o ti rú àwọn ẹbọ sísun rẹ, ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì da ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ rẹ sára pẹpẹ+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n o lè jẹ ẹran rẹ̀.

28 “Rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún ọ yìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ nígbà gbogbo, torí pé ò ń ṣe ohun tó dáa tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.

29 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí o máa lé kúrò run,+ tí o sì wá ń gbé ilẹ̀ wọn, 30 rí i pé o ò kó sí ìdẹkùn lẹ́yìn tí wọ́n bá pa run kúrò níwájú rẹ. Má ṣe béèrè nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe máa ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Ohun tí wọ́n ṣe lèmi náà máa ṣe.’+ 31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+ 32 Gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ rí i pé ẹ tẹ̀ lé.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi kún un, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ yọ kúrò nínú rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́