ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Àwọn ohun àìmọ́ tó ń jáde látinú ẹ̀yà ìbímọ (1-33)

Léfítíkù 15:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹran ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:4; Nọ 5:2

Léfítíkù 15:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:24, 25; 14:46, 47; 17:15; 22:6

Léfítíkù 15:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:2

Léfítíkù 15:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:32, 33

Léfítíkù 15:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 14:8

Léfítíkù 15:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:14

Léfítíkù 15:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:4; Di 23:10, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 23

Léfítíkù 15:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:15; 1Sa 21:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 131

Léfítíkù 15:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 12:2, 5
  • +Le 20:18

Léfítíkù 15:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:4-6

Léfítíkù 15:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:10

Léfítíkù 15:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:19; 20:18

Léfítíkù 15:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 9:20; Lk 8:43
  • +Le 15:19

Léfítíkù 15:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:21

Léfítíkù 15:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:22

Léfítíkù 15:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:13

Léfítíkù 15:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:14
  • +Le 15:14, 15

Léfítíkù 15:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 12:7

Léfítíkù 15:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:30; Nọ 5:3; 19:20

Léfítíkù 15:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:16

Léfítíkù 15:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:19
  • +Le 15:2, 25

Àwọn míì

Léf. 15:2Le 22:4; Nọ 5:2
Léf. 15:5Le 11:24, 25; 14:46, 47; 17:15; 22:6
Léf. 15:11Le 15:2
Léf. 15:12Le 11:32, 33
Léf. 15:13Le 14:8
Léf. 15:14Le 1:14
Léf. 15:16Le 22:4; Di 23:10, 11
Léf. 15:18Ẹk 19:15; 1Sa 21:5
Léf. 15:19Le 12:2, 5
Léf. 15:19Le 20:18
Léf. 15:20Le 15:4-6
Léf. 15:23Le 15:10
Léf. 15:24Le 18:19; 20:18
Léf. 15:25Mt 9:20; Lk 8:43
Léf. 15:25Le 15:19
Léf. 15:26Le 15:21
Léf. 15:27Le 15:22
Léf. 15:28Le 15:13
Léf. 15:29Le 1:14
Léf. 15:29Le 15:14, 15
Léf. 15:30Le 12:7
Léf. 15:31Le 19:30; Nọ 5:3; 19:20
Léf. 15:32Le 15:16
Léf. 15:33Le 15:19
Léf. 15:33Le 15:2, 25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 15:1-33

Léfítíkù

15 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè àti Áárónì lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ohun kan bá ń dà jáde látinú ẹ̀yà ìbímọ* ọkùnrin kan, ohun náà ti sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 3 Ohun tó ń dà jáde lára rẹ̀ ti sọ ọ́ di aláìmọ́, yálà ó ṣì ń dà látinú ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ tàbí ibẹ̀ ti dí, aláìmọ́ ṣì ni.

4 “‘Ibùsùn èyíkéyìí tí ẹni tí ohun kan ń dà jáde lára rẹ̀ bá dùbúlẹ̀ sí yóò di aláìmọ́, ohunkóhun tó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́. 5 Kí ẹni tó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 6 Kí ẹnikẹ́ni tó bá jókòó sórí ohun tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ jókòó lé fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 7 Kí ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ara ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 8 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ bá tutọ́ sára ẹni tó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 9 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ bá jókòó sórí ohun tí wọ́n fi ń jókòó tí wọ́n ń dè mọ́ ẹran, ìjókòó náà máa di aláìmọ́. 10 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ohunkóhun tí onítọ̀hún jókòó lé yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́, kí ẹnikẹ́ni tó bá sì gbé àwọn nǹkan yẹn fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 11 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀+ ò bá tíì fi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, tó wá fọwọ́ kan ẹnì kan, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 12 Tí ẹni tí nǹkan ń dà jáde lára rẹ̀ bá fara kan ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, kí ẹ fọ́ ohun èlò náà túútúú, kí ẹ sì fi omi fọ ohun èlò èyíkéyìí tí wọ́n fi igi ṣe.+

13 “‘Tí ohun tó ń dà náà bá dáwọ́ dúró, tí ẹni náà sì wá mọ́ kúrò nínú rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà kó di mímọ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́.+ 14 Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé+ méjì, kó wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó sì kó wọn fún àlùfáà. 15 Kí àlùfáà sì fi wọ́n rúbọ, kó fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó fi èkejì rú ẹbọ sísun, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà torí ohun tó ń dà jáde lára rẹ̀.

16 “‘Tí ọkùnrin kan bá da àtọ̀, kó fi omi wẹ gbogbo ara rẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 17 Kó fi omi fọ aṣọ èyíkéyìí àti awọ èyíkéyìí tí àtọ̀ bá dà sí, kí ohun náà sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.

18 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá obìnrin kan sùn, tó sì da àtọ̀, kí wọ́n fi omi wẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+

19 “‘Tí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà jáde lára obìnrin kan, kó ṣì jẹ́ aláìmọ́ nínú ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀ fún ọjọ́ méje.+ Ẹnikẹ́ni tó bá fara kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 20 Ohunkóhun tó bá dùbúlẹ̀ lé nígbà tó bá ń ṣe nǹkan oṣù yóò di aláìmọ́, gbogbo ohun tó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́.+ 21 Kí ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 22 Kí ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ohunkóhun tí obìnrin náà jókòó lé fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 23 Tí obìnrin náà bá jókòó sórí ibùsùn tàbí ohunkóhun míì, ẹni tó bá fara kan ohun náà máa jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ 24 Tí ọkùnrin kan bá bá a sùn, tí ìdọ̀tí nǹkan oṣù rẹ̀ sì kàn án lára,+ ọkùnrin náà máa jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, ibùsùn èyíkéyìí tí ọkùnrin náà bá sì dùbúlẹ̀ sí yóò di aláìmọ́.

25 “‘Tí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára obìnrin kan fún ọ̀pọ̀ ọjọ́,+ tó sì jẹ́ pé àkókò tó máa ń rí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tíì tó+ tàbí tí iye ọjọ́ tí ẹ̀jẹ̀ fi dà lára rẹ̀ bá pọ̀ ju iye tó máa ń jẹ́ tó bá ń ṣe nǹkan oṣù, aláìmọ́ ni yóò jẹ́ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ̀jẹ̀ bá fi ń dà lára rẹ̀, bí ìgbà tó ń ṣe nǹkan oṣù. 26 Ibùsùn èyíkéyìí tó bá dùbúlẹ̀ sí nígbà tí ẹ̀jẹ̀ ń dà lára rẹ̀ yóò dà bí ibùsùn tó dùbúlẹ̀ sí nígbà nǹkan oṣù rẹ̀,+ ohunkóhun tó bá sì jókòó lé yóò di aláìmọ́ bíi ti àìmọ́ nǹkan oṣù rẹ̀. 27 Ẹnikẹ́ni tó bá fara kàn wọ́n yóò di aláìmọ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+

28 “‘Àmọ́, tí ohun tó ń dà lára rẹ̀ bá ti dáwọ́ dúró, kó ka ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà kó di mímọ́.+ 29 Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé+ méjì, kó sì mú wọn wá fún àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 30 Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó fi èkejì rú ẹbọ sísun. Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún obìnrin náà níwájú Jèhófà torí ohun àìmọ́ tó ń jáde lára rẹ̀.+

31 “‘Bí o ṣe máa ya àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́tọ̀ kúrò nínú àìmọ́ wọn nìyẹn, kí wọ́n má bàa kú nínú àìmọ́ wọn torí wọ́n sọ àgọ́ ìjọsìn mi tó wà láàárín wọn+ di ẹlẹ́gbin.

32 “‘Èyí ni òfin nípa ọkùnrin tí ohun kan bá ń dà lára rẹ̀, ọkùnrin tó di aláìmọ́ torí àtọ̀ dà lára rẹ̀,+ 33 obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù,+ ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ àti ọkùnrin tó bá obìnrin tó jẹ́ aláìmọ́ sùn.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́