Hósíà
9 “Má ṣe yọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì,+
Má sì dunnú bí àwọn èèyàn.
Nítorí pé ìṣekúṣe* ti mú ọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ.+
O ti nífẹ̀ẹ́ owó iṣẹ́ aṣẹ́wó lórí gbogbo ibi ìpakà.+
2 Àmọ́ ibi ìpakà àti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì kò ní fún wọn lóúnjẹ,
Wáìnì tuntun á sì já wọn kulẹ̀.+
3 Wọn kò ní gbé ilẹ̀ Jèhófà mọ́;+
Kàkà bẹ́ẹ̀, Éfúrémù á pa dà sí Íjíbítì,
Wọ́n á sì jẹ ohun àìmọ́ ní Ásíríà.+
Wọ́n dà bí oúnjẹ ọ̀fọ̀;
Gbogbo àwọn tó bá jẹ ẹ́ á sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin.
Nítorí àwọn nìkan* ni oúnjẹ wọn wà fún;
Kò ní wọ ilé Jèhófà.
5 Kí lẹ ó ṣe ní ọjọ́ ìpàdé,*
Ní ọjọ́ àjọyọ̀ Jèhófà?
6 Wò ó! wọ́n á ní láti sá lọ nítorí ìparun.+
Íjíbítì á kó wọn jọ,+ Mémúfísì á sì sin wọ́n.+
Èsìsì ló máa bo àwọn ohun iyebíye tí wọ́n fi fàdákà ṣe,
Àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún á sì wà nínú àgọ́ wọn.
Wòlíì wọn á ya òmùgọ̀, ọkùnrin tó ní ìmísí á sì ya wèrè;
Ìkórìíra tí wọ́n ní sí ọ pọ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pọ̀.”
8 Nígbà kan rí, olùṣọ́ + Éfúrémù ń gbọ́ ti Ọlọ́run mi.+
Àmọ́ ní báyìí, ọ̀nà àwọn wòlíì rẹ̀+ dà bíi pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ;
Ìkórìíra wà ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.
9 Wọ́n ti lọ jìnnà nínú fífa ìparun, bíi ti ìgbà àwọn ará Gíbíà.+
Ó máa rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, á sì fìyà jẹ wọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+
10 “Mo rí Ísírẹ́lì bí ẹni rí èso àjàrà ní aginjù.+
Mo rí àwọn baba ńlá rẹ̀ bí ẹni rí àkọ́so igi ọ̀pọ̀tọ́.
Àmọ́ wọ́n lọ bá Báálì Péórì;+
Wọ́n fi ara wọn fún ohun ìtìjú,*+
Wọ́n di ohun ìríra, wọ́n sì wá dà bí ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́.
11 Ògo Éfúrémù fò lọ bí ẹyẹ;
Kò ní bímọ, kò ní lóyún, kódà ọlẹ̀ kò ní sọ nínú rẹ̀.+
12 Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ wọn dàgbà,
Màá pa wọ́n, tí kò fi ní ku ìkankan;+
Nígbà tí mo bá pa dà lẹ́yìn wọn, wọ́n gbé!+
13 Éfúrémù tí a gbìn sí ibi ìjẹko, dà bíi Tírè+ sí mi;
Ní báyìí, Éfúrémù gbọ́dọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa.”
14 Fún wọn ní ohun tó yẹ kí o fún wọn, Jèhófà;
Fún wọn ní ilé ọmọ tí kò lè gba oyún dúró àti ọmú gbígbẹ.*
15 “Gílígálì + ni gbogbo ìwà ibi wọn ti ṣẹlẹ̀, ibẹ̀ ni mo ti kórìíra wọn.
Màá lé wọn kúrò ní ilé mi nítorí iṣẹ́ ibi wọn.+
Mi ò ní nífẹ̀ẹ́ wọn mọ́;+
Gbogbo olórí wọn ya alágídí.
16 A ó gé Éfúrémù lulẹ̀ bí igi.+
Gbòǹgbò wọn á gbẹ dà nù, wọn ò sì ní lè so èso kankan.
Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, màá pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn.”