ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 7/1 ojú ìwé 13-14
  • Ṣé Wọ́n Ti Rí Ọkọ̀ Nóà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Wọ́n Ti Rí Ọkọ̀ Nóà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ìwádìí Wọn Ṣeé Fọkàn Tán?
  • Ìkún-Omi Mánigbàgbé Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Èèyàn Mẹ́jọ La Ìparun Já
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Nóà Kan Áàkì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Nóà Kan Ọkọ̀ Áàkì
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 7/1 ojú ìwé 13-14

Ṣé Wọ́n Ti Rí Ọkọ̀ Nóà?

Ọ̀PỌ̀ ìgbà la máa ń gbọ́ ìròyìn nípa bí wọ́n ṣe ń wá ọkọ̀ Nóà. Ìdí táwọn èèyàn sì fi ń fẹ́ láti rí ọkọ̀ náà ò ṣàjèjì. Àṣeyọrí tí ò láfiwé ló máa jẹ́ lágbo àwọn awalẹ̀pìtàn, tí wọ́n bá lè rí ọkọ̀ ńlá tí Nóà àti ìdílé ẹ̀ wọ̀ nígbà Ìkún-omi tó wáyé lọ́dún 2370 sí ọdún 2369 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Pẹ̀lú gbogbo ìsapá táwọn awalẹ̀pìtàn ti ń ṣe látọdún yìí wá, wọ́n ṣì wà lẹ́nu wíwá ọkọ̀ náà. Kí ni wọ́n ti wá rí gan-an pẹ̀lú gbogbo ìméfò àti ìwádìí tí wọ́n ti ń ṣe?

Bíbélì jẹ́ ká lóye pé, ọkọ̀ Nóà “gúnlẹ̀ sórí òkè ńlá Árárátì.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:4) Ní àgbègbè Árárátì lápá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Tọ́kì, nítòsí ààlà orílẹ̀-èdè Àméníà àti Ìráànì, òkè kan wà níbẹ̀ tó ga ju àwọn òkè tó kù lọ, òkè yìí làwọn èèyàn wá mọ̀ sí Òkè Árárátì.

Onírúurú ìrìn-àjò ìwádìí táwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣe lọ sí àgbègbè Árárátì láti lọ wá ọkọ̀ Nóà ti gbé onírúurú èrò tó fani lọ́kàn mọ́ra dìde, àmọ́ kò tíì sí ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Àwọn fọ́tò tí wọ́n yà láti òfuurufú, àwọn pákó tó ní ọ̀dà bítúmẹ́nì lára tí wọ́n rí, àtàwọn nǹkan míì táwọn èèyàn ń sọ pé àwọn rí ti jẹ́ kó túbọ̀ máa wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti rí ẹ̀rí tó dájú pé wọ́n ti rí ọkọ̀ náà lóòótọ́. Àmọ́ ìwádìí yẹn ò rọrùn rárá. Ibì kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń sọ pé àwọn ti rí ọkọ̀ náà wà ní nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún lórí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Árárátì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ náà kì í sábà fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèrè láyè láti lọ sórí òkè náà torí rògbòdìyàn àwọn olóṣèlú.

Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń hára gàgà láti rí ọkọ̀ náà ló ń fẹ́ káwọn tó ń ṣèwádìí túbọ̀ máa wá sórí òkè yẹn. Wọ́n gbà pé apá kan ọkọ̀ náà ṣì máa wà lábẹ́ yìnyín lórí Òkè Árárátì, níwọ̀n bí yìnyín ti máa ń bo òkè náà jálẹ̀ ọdún. Wọ́n ní àyàfi tí oòrùn bá mú dáadáa nígbà ẹ̀rùn làwọn èèyàn tó lè rí ọkọ̀ áàkì yẹn.

Àwọn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn kan ti sọ ti jẹ́ kó dà bíi pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ọ̀gbẹ́ni Josephus, tó jẹ́ òpìtàn àwọn Júù tó gbé láyé ní ọ̀rúndún kìíní, sọ̀rọ̀ nípa onírúurú àwọn òpìtàn ayé ìgbàanì kan tí wọ́n sọ pé àwọn fojú ara àwọn rí ọkọ̀ áàkì Nóà lórí Òkè Árárátì. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé àwọn èèyàn sábà máa ń mú lọ sílé lára àwọn pákó ọkọ̀ náà tí Nóà fi ọ̀dà bítúmẹ́nì bò. Ọ̀gbẹ́ni Berossus, òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Bábílónì kan tó gbé láyé ní ọ̀rúndún kẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni wà lára àwọn tí Josephus fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ.

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, Ọ̀gbẹ́ni George Hagopian, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Àméníà sọ nǹkan kan tó fani lọ́kàn mọ́ra nípa ọkọ̀ náà. Ó ní òun àti mọ̀lẹ́bí bàbá òun kan ti jọ lọ wo ọkọ̀ náà nígbà kan rí láàárín ọdún 1900 sí 1925, òún sì rántí pé òun gun òkè sára ọkọ̀ náà. Ọdún 1972 ni Hagopian kú, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn ṣì ń jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì ń jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wọ́n láti fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ọkọ̀ náà.

Ṣé Ìwádìí Wọn Ṣeé Fọkàn Tán?

Ṣóhun kan wà tó lè mú ká gbà pé àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ọkọ̀ Nóà tàbí pé wọ́n ṣì máa rí i lọ́jọ́ iwájú? Tí wọ́n bá tiẹ̀ rí i, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kó dà bíi pé ìwádìí yẹn ò fi taratara jóòótọ́. Má gbàgbé pé Bíbélì ò sọ ọ̀ọ́kán ibi tí ọkọ̀ áàkì yẹn dúró sí gan-an lórí àwọn òkè tó wà ní àgbègbè Árárátì bí omi yẹn ti ń gbẹ lọ. Ó kàn wúlẹ̀ mẹ́nu ba “òkè ńlá Árárátì” ni.

Ohun táwọn tó ń ṣèwádìí àtàwọn tó ń méfò sábà máa ń ṣe ni pé kí wọ́n fojú sí èyí tó ga jù lọ lára àwọn òkè tó wà ní àgbègbè Árárátì. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ ò sọ ní pàtó pé Ọlọ́run jẹ́ kí ọkọ̀ áàkì náà dúró sórí Òkè Árárátì, ìyẹn òkè tá a wá mọ̀ sí òkè tó tutù nini, tó sì ga fíofío, tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún [16,000] ẹsẹ̀ bàtà.a Má gbàgbé pé ọ̀pọ̀ oṣù ni Nóà àti ìdílé ẹ̀ fi gbé nínú ọkọ̀ áàkì yìí lẹ́yìn tó gúnlẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 8:4, 5) Kò dájú pé lẹ́yìn tí ìdílé Nóà àtàwọn ẹranko yẹn jáde nínú ọkọ̀ náà, wọ́n wá sọ̀kalẹ̀ láti ṣóńṣó orí òkè bíi tàwọn tó máa ń lọ ṣeré ìdárayá lórí òkè. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orí ilẹ̀ ibi tí ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sí jẹ́ ibi tó rọrùn láti dé ju báwọn kan tó ń ṣèwádìí lóde òní ṣe rò lọ, síbẹ̀ kó ṣì ga tó ibi tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì 8:4, 5 sọ pé ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sí. Tó bá sì jẹ́ pé ibòmíì lágbègbè Árárátì ni ọkọ̀ náà dúró sí, ṣé kò ti ní jẹrà kó sì ti dàwátì láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn?

Yàtọ̀ síyẹn, nǹkan kan wà tó ń kọni lóminú nínú ohun táwọn oníròyìn máa ń sọ nígbà míì nípa ipa pàtàkì tí wọ́n retí pé kí ìwádìí wọn kó lórí ìjọsìn. Ẹnì kan tó jẹ́ òléwájú láwùjọ àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé táwọn bá rí ọkọ̀ áàkì náà, ìyẹn “á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn túbọ̀ fìdí múlẹ̀ . . . ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì máa di onígbàgbọ́.” Níbi àpérò kan táwọn oníròyìn ṣe lọ́dún 2004, ọ̀gbẹ́ni yẹn sọ pé àwárí ọkọ̀ áàkì yìí ló máa jẹ́ “ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ látìgbà tí Kristi ti jíǹde.” Àmọ́ ṣe ni wọ́n fagi lé ìwádìí tó fẹ́ dáwọ́ lé.

Ṣé lóòótọ́ ni pé ṣíṣàwárí ọkọ̀ áàkì tí Nóà kàn ló máa fìdí ìgbàgbọ́ múlẹ̀ tàbí pé ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn èèyàn nígbàgbọ́? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ojúlówó ìgbàgbọ́ ò sinmi lórí àwọn nǹkan tá a lè fojú rí tàbí tá a lè fọwọ́ kàn. (2 Kọ́ríńtì 5:7) Àwọn kan ń ṣiyèméjì débi pé wọ́n máa ń rin kinkin pé táwọn ò bá tíì fojú àwọn rí àwọn ẹ̀rí kan, àwọn ò lè gbà pé òótọ́ ni àwọn ìtàn kan tó wà nínú Bíbélì. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sí bí ẹ̀rí tẹ́ ẹ bá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe lè pọ̀ tó tí wọ́n á fi gbà pé òótọ́ ni. Jésù alára sọ pé àwọn èèyàn kan ò ní gbà pé òótọ́ lọ́rọ̀ Ọlọ́run, kódà tí wọ́n bá rí òkú tó jíǹde!— Lúùkù 16:31.

Yàtọ̀ síyẹn, ojúlówó ìgbàgbọ́ ò sinmi lórí kéèyàn ṣáà ti gba nǹkan kan gbọ́ o; ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ gbọ́dọ̀ wà. (Hébérù 11:1) Ṣé ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà tó lè mú káwọn èèyàn onílàákàyè gba ìtàn Bíbélì nípa Ìkún-omi gbọ́? Dájúdájú, ó wà. Jésù Kristi sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Nóà wọ ọkọ̀ áàkì, ìkún omi sì dé.” (Lúùkù 17:26, 27) Kò tún sí ẹ̀rí míì tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ ju èyí lọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ọ̀run ni Jésù wà kó tó wá sáyé. (Jòhánù 8:58) Ó fojú ara ẹ̀ rí bí Nóà ṣe kan ọkọ̀ áàkì yẹn, ó sì tún rí Ìkún-omi náà. Ẹ̀rí wo ló wá jọ èyí tó ṣeé gbára lé nígbà náà? Ṣé ẹ̀rí tí Jésù, ẹni tó fojú ara ẹ̀ rí Ìkún-omi yẹn, tó jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé láìkù síbì kan, tó sì ti fẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run mú wá ni? Àbí èyí tí kò dájú pé àwọn olùṣèwádìí máa rí mú jáde níbi tí wọ́n ti ń wá àwọn àfọ́kù pákó tọ́jọ́ ẹ̀ ti pẹ́ lórí òkè tó ti di yìnyín gbagidi? Tó o bá ronú lórí ẹ̀ lọ́nà yìí, wàá rí i pé ẹ̀rí tá a ní pé lóòótọ́ ni Nóà kan ọkọ̀ áàkì pọ̀ lọ jàńtìrẹrẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lọ́dún 1840, òkè kan bẹ̀rẹ̀ sí í tú àwọn nǹkan gbígbóná jáde, ìgbà táwọn nǹkan gbígbóná yẹn sì tutù tán, ó di òkè ńlá tí wọ́n ń pè ní Òkè Árárátì lóde òní. Ó ga ju pẹ̀tẹ́ẹ̀sì alájà ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [1,600] lọ, yìnyín sì máa ń bo òkè yìí jálẹ̀ ọdún.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Ṣé ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà láti fi hàn pé òótọ́ ni ìtàn Bíbélì nípa Ìkún-omi?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Jésù Kristi sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Nóà wọ ọkọ̀ áàkì, ìkún omi sì dé”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́