ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w19 June ojú ìwé 2-7
  • ‘Ẹ Ṣọ́ra Kí Ẹnikẹ́ni Má Bàa Mú Yín Lẹ́rú!’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Ṣọ́ra Kí Ẹnikẹ́ni Má Bàa Mú Yín Lẹ́rú!’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • SÁTÁNÌ MÚ KÍ WỌ́N BỌ̀RÌṢÀ
  • ỌGBỌ́N Ẹ̀WẸ́ MẸ́TA TÍ SÁTÁNÌ FI DẸKÙN MÚ ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ
  • ÀWỌN ỌGBỌ́N Ẹ̀WẸ́ TÍ SÁTÁNÌ Ń LÒ LÓNÌÍ
  • Ṣọ́ra! Sátánì Fẹ́ Pa Ọ́ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Mọ Ọ̀tá Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Máa Ronú Nípa Irú Ẹni Tó Yẹ Kó O Jẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Sátánì
    Jí!—2013
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
w19 June ojú ìwé 2-7

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 23

‘Ẹ Ṣọ́ra Kí Ẹnikẹ́ni Má Bàa Mú Yín Lẹ́rú!’

“Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má fi ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán mú yín lẹ́rú látinú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn.”​—KÓL. 2:8.

ORIN 96 Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

1. Bó ṣe wà nínú Kólósè 2:4, 8, kí ni Sátánì máa ń lò láti yí èrò wa pa dà?

OHUN tí Sátánì ń fẹ́ ni pé ká kẹ̀yìn sí Jèhófà. Kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ ohun tó ń fẹ́, ó máa ń sapá láti yí èrò wa pa dà. Lédè míì, Sátánì fẹ́ ká máa ronú bíi tòun, ká sì máa ṣe ohun tó fẹ́. Ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí ló sì máa ń lò láti tàn wá jẹ.​—Ka Kólósè 2:4, 8.

2-3. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká fiyè sí ìkìlọ̀ tó wà nínú Kólósè 2:8? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ṣé òótọ́ ni pé Sátánì lè tàn wá jẹ? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ẹ rántí pé àwọn Kristẹni ni ìkìlọ̀ tó wà nínú Kólósè 2:8 wà fún. Kódà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yẹn sí. (Kól. 1:2, 5) Tí Sátánì bá lè tan àwọn Kristẹni kan jẹ nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ó dájú pé ó lè tan àwa náà jẹ lónìí. (1 Kọ́r. 10:12) Kí nìdí? Ìdí ni pé a ti fi Sátánì sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé. Torí náà, bó ṣe máa ṣi àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́nà ló gbájú mọ́. (Ìfi. 12:9, 12, 17) Yàtọ̀ síyẹn, àsìkò táwọn èèyàn burúkú àtàwọn afàwọ̀rajà túbọ̀ ń “burú sí i” là ń gbé yìí.​—2 Tím. 3:1, 13.

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Sátánì ṣe ń sapá láti fi “ìtànjẹ lásán” yí èrò wa pa dà. A máa rí “àwọn àrékérekè” tàbí “ètekéte” mẹ́ta tí Sátánì ń lò. (Éfé. 6:11; àlàyé ìsàlẹ̀) Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè ṣe tó bá jẹ́ pé ọgbọ́n Sátánì ti ń nípa lórí èrò wa. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ọ̀nà tí Sátánì gbà tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ lẹ́yìn tí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́.

SÁTÁNÌ MÚ KÍ WỌ́N BỌ̀RÌṢÀ

4-6. Bí Diutarónómì 11:10-15 ṣe sọ, kí ló yí pa dà nínú bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń dáko nígbà tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí?

4 Sátánì fọgbọ́n tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ kí wọ́n lè bọ̀rìṣà. Lọ́nà wo? Ó mọ̀ pé oúnjẹ ṣe pàtàkì, ohun tó sì fi dẹkùn mú wọn nìyẹn. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ó di dandan kí wọ́n yí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń dáko pa dà. Ìdí sì ni pé nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì, omi tó wá látinú Odò Náílì ni wọ́n fi ń bomi rin oko wọn. Àmọ́ ní Ilẹ̀ Ìlérí, ó dìgbà tí òjò bá rọ̀, tí ìrì sì sẹ̀ kí irúgbìn wọn tó lè rómi mu. (Ka Diutarónómì 11:10-15; Àìsá. 18:4, 5) Torí náà, ó pọn dandan fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti kọ́ ọ̀nà tuntun tí wọ́n á máa gbà dáko. Èyí ò sì rọrùn torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó mọṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe dáadáa ti kú sínú aginjù.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì, ìyẹn sì mú kí wọ́n jọ́sìn Báálì

Báwo ni Sátánì ṣe yí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àgbẹ̀ lérò pa dà? (Wo ìpínrọ̀ 4-6)b

5 Jèhófà ṣàlàyé fáwọn èèyàn rẹ̀ pé Ilẹ̀ Ìlérí náà kò dà bí Íjíbítì tí wọ́n ti kúrò. Ó wá fún wọn ní ìkìlọ̀ kan tó jọ bíi pé kò tan mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀, ó ní: “Kí ẹ rí i pé ẹ ò jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, kí ẹ wá yà bàrá lọ sìn wọ́n tàbí kí ẹ forí balẹ̀ fún wọn.” (Diu. 11:16, 17) Kí nìdí tí Jèhófà fi kìlọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bọ̀rìṣà nígbà tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n á ṣe máa dáko ló ń bá wọn sọ?

6 Jèhófà mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fẹ́ yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká, kí wọ́n lè kọ́ bí wọ́n ṣe ń dáko lágbègbè yẹn. Kò sí àní-àní pé àwọn tó yí wọn ká mọṣẹ́ àgbẹ̀ dáadáa, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn, àmọ́ ewu kan wà níbẹ̀. Òrìṣà Báálì làwọn àgbẹ̀ tó wà nílẹ̀ Kénáánì ń bọ, wọ́n sì gbà pé òun ló ni ojú ọ̀run, tó sì ń fúnni ní òjò. Jèhófà ò fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ gba irọ́ yìí gbọ́, àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kẹ̀yìn sí Jèhófà tí wọ́n sì ń bọ òrìṣà Báálì. (Nọ́ń. 25:3, 5; Oníd. 2:13; 1 Ọba 18:18) Ẹ jẹ́ ká wo ọgbọ́n tí Sátánì fi dẹkùn mú wọn.

ỌGBỌ́N Ẹ̀WẸ́ MẸ́TA TÍ SÁTÁNÌ FI DẸKÙN MÚ ÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ

7. Kí ló dán ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wò ní Ilẹ̀ Ìlérí?

7 Kí ni ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ àkọ́kọ́ tí Sátánì lò? Sátánì mọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fẹ́ kí òjò rọ̀, ohun tó sì fi tàn wọ́n sídìí ìbọ̀rìṣà nìyẹn. Òjò kì í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ ní Ilẹ̀ Ìlérí lọ́wọ́ ìparí April sí September. Torí náà, kí irúgbìn wọn tó lè so dáadáa, ó pọn dandan kí òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ láti nǹkan bí oṣù October. Sátánì wá tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti gbà pé kí òjò tó lè rọ̀ dáadáa, àfi kí wọ́n máa bọ àwọn òrìṣà táwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń bọ. Àwọn tó yí wọn ká gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ètùtù kan káwọn òòṣà tó lè mú kí òjò rọ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà sì ronú pé bíbọ òòṣà yẹn ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí òjò á fi tètè rọ̀, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà Báálì.

8. Kí ni ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kejì tí Sátánì lò? Ṣàlàyé.

8 Sátánì tún lo ọgbọ́n míì fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó kíyè sí i pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà lọ́kàn wọn, ó sì fi dẹkùn mú wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká máa ń ṣèṣekúṣe tó burú jáì tí wọ́n bá ń bọ àwọn òrìṣà wọn. Bí àpẹẹrẹ, àtọkùnrin àtobìnrin wọn ló máa ń ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó nínú tẹ́ńpìlì. Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò rí ohun tó burú nínú kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀, kódà ohun tí wọ́n fi ń ṣayọ̀ nìyẹn! (Diu. 23:17, 18; 1 Ọba 14:24) Àwọn abọ̀rìṣà yẹn gbà pé ohun táwọn ń ṣe ló máa mú kí àwọn òrìṣà wọn bù kún ilẹ̀ náà, kí irúgbìn wọn sì so dáadáa. Ìṣekúṣe táwọn abọ̀rìṣà náà ń ṣe fa ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ra, èyí sì mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà. Kò sí àní-àní pé ṣìnkún báyìí ni wọ́n kó sọ́wọ́ Sátánì.

9. Bó ṣe wà nínú Hósíà 2:16, 17, báwo ni Sátánì ṣe mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàgbé Jèhófà?

9 Kí ni ọgbọ́n kẹta tí Sátánì lò? Ó mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàgbé Jèhófà. Nígbà ayé wòlíì Jeremáyà, Jèhófà sọ pé àwọn wòlíì èké mú káwọn èèyàn òun gbàgbé orúkọ òun “nítorí Báálì.” (Jer. 23:27) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó jọ pé àwọn èèyàn náà ò lo orúkọ Jèhófà mọ́, wọ́n wá fi orúkọ Báálì, tó túmọ̀ sí “Oníǹkan” tàbí “Ọ̀gá” rọ́pò rẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣe yìí mú kó ṣòro fún wọn láti fìyàtọ̀ sáàárín Jèhófà àti Báálì, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í da ìjọsìn Jèhófà pọ̀ mọ́ ti Báálì.​—Ka Hósíà 2:16, 17 àti àlàyé ìsàlẹ̀.

ÀWỌN ỌGBỌ́N Ẹ̀WẸ́ TÍ SÁTÁNÌ Ń LÒ LÓNÌÍ

10. Àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì ń lò lónìí?

10 Àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan náà ni Sátánì ń lò lónìí. Ó máa ń lo ohun tó wu àwọn èèyàn láti dẹkùn mú wọn, ó máa ń lo ìṣekúṣe, ó sì máa ń sapá láti mú káwọn èèyàn gbàgbé Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí èyí tó kẹ́yìn.

11. Báwo ni Sátánì ṣe mú káwọn èèyàn gbàgbé Jèhófà?

11 Sátánì ń mú káwọn èèyàn gbàgbé Jèhófà. Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì Jésù, àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ẹ̀kọ́ èké kọ́ni. (Ìṣe 20:29, 30; 2 Tẹs. 2:3) Àwọn apẹ̀yìndà yìí bẹ̀rẹ̀ sí í mú káwọn èèyàn gbàgbé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn, wọ́n sì fi àwọn ọ̀rọ̀ bí “Olúwa” rọ́pò rẹ̀. Bí wọ́n ṣe fi “Olúwa” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run mú kó ṣòro fáwọn tó ń ka Bíbélì láti rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn “olúwa” míì tí Ìwé Mímọ́ mẹ́nu kàn. (1 Kọ́r. 8:5) Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “Olúwa” fún Jèhófà àti Jésù mú kó ṣòro láti mọ̀ pé àwọn méjèèjì kì í ṣe ẹnì kan náà àti pé ipò wọn yàtọ̀ síra. (Jòh. 17:3) Ìdàrúdàpọ̀ yìí wà lára ohun tó mú kí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tó jẹ́ ẹ̀kọ́ èké gbilẹ̀, ó sì tún mú kí ọ̀pọ̀ máa ronú pé àdììtú ni Ọlọ́run, a ò sì lè mọ irú ẹni tó jẹ́. Ẹ ò rí i pé ìtànjẹ gbáà nìyẹn!​—Ìṣe 17:27.

Àwọ̀ tí wọ́n fi kun pátákó ṣọ́ọ̀ṣì kan fi hàn pé wọ́n fàyè gba kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin, kí obìnrin sì máa fẹ́ obìnrin

Báwo ni Sátánì ṣe ń lo ẹ̀sìn èké láti gbé ìṣekúṣe lárugẹ? (Wo ìpínrọ̀ 12)c

12. Kí ni ẹ̀sìn èké ń gbé lárugẹ? Bó ṣe wà nínú Róòmù 1:28-31, kí ni èyí ti yọrí sí?

12 Sátánì máa ń lo ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láti dẹkùn mú àwọn èèyàn. Láyé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Sátánì lo ẹ̀sìn èké láti gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Ohun tó sì ń ṣe lónìí náà nìyẹn. Ẹ̀sìn èké fàyè gba onírúurú ìṣekúṣe, kódà ohun tí wọ́n fi ń ṣayọ̀ nìyẹn. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni máa lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ ohun tí ìwà yìí ti yọrí sí. (Ka Róòmù 1:28-31.) Lára “àwọn ohun tí kò yẹ” tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn ni gbogbo onírúurú ìṣekúṣe títí kan kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ àti kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀. (Róòmù 1:24-27, 32; Ìfi. 2:20) Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà tó wà nínú Bíbélì!

13. Ọgbọ́n míì wo ni Sátánì máa ń lò?

13 Sátánì máa ń fi ohun tó wù wá dẹkùn mú wa. Ó máa ń wù wá pé ká níṣẹ́ lọ́wọ́ ká lè pèsè fún ìdílé wa. (1 Tím. 5:8) Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyẹn lè gba pé ká lọ sílé ìwé, ká sì fojú sí ẹ̀kọ́ wa dáadáa. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kì í ṣe iṣẹ́ nìkan ni wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ iléèwé, wọ́n tún máa ń kọ́ wọn ní ọgbọ́n orí èèyàn. Wọ́n máa ń sọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé kò sí Ọlọ́run àti pé ìtàn àròsọ lásán ló wà nínú Bíbélì. Wọ́n tún máa ń kọ́ wọn pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n nìkan ni àlàyé tó bọ́gbọ́n mu nípa ibi táwa èèyàn ti wá. (Róòmù 1:21-23) Kò sí àní-àní pé irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ta ko “ọgbọ́n Ọlọ́run.”​—1 Kọ́r. 1:19-21; 3:18-20.

14. Kí ni ọgbọ́n orí èèyàn ń gbé lárugẹ?

14 Ọgbọ́n táwọn èèyàn ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ ta ko àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. “Àwọn iṣẹ́ ti ara” ni ọgbọ́n ayé yìí ń gbé lárugẹ, kì í jẹ́ káwọn èèyàn mú èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run dàgbà. (Gál. 5:19-23) Ó máa ń sọ àwọn èèyàn di agbéraga, wọ́n máa ń ro ara wọn ju bó ti yẹ lọ, ó sì ń mú kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan.” (2 Tím. 3:2-4) Àwọn ìwà yìí yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ànímọ́ bí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù tí Bíbélì gba àwa ìránṣẹ́ Jèhófà níyànjú pé ká ní. (2 Sám. 22:28) Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n lọ sí yunifásítì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi tàwọn èèyàn ayé dípò kí wọ́n máa fojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀kan lára àwọn ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tá a bá kọtí ikún sí ìmọ̀ràn yìí.

Arábìnrin kan wà ní yunifásítì, ó sì fara mọ́ èrò olùkọ́ wọn, torí náà kò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n ń sọ nípàdé, ó sì máa ń ṣàríwísí

Báwo ni ọgbọ́n orí èèyàn ṣe lè yí èrò wa pa dà? (Wo ìpínrọ̀ 14-16)d

15-16. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan?

15 Arábìnrin kan tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sọ pé: “Látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi, ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti gbọ́, tí mo sì ti kà nípa ewu tó wà nínú kéèyàn lọ sí yunifásítì, àmọ́ mi ò kọbi ara sí i rárá. Mo ronú pé ìkìlọ̀ yẹn ò kàn mí.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin náà lẹ́yìn tó lọ sí yunifásítì? Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń tara bọ ẹ̀kọ́ mi máa ń jẹ́ kó rẹ̀ mí gan-an, ọwọ́ mi sì máa ń dí débi pé mi ò kì í ráyè gbàdúrà tó nítumọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀, mi ò kì í ráyè lọ sóde ẹ̀rí, bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò kì í ráyè múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa. Nígbà tí mo wá rí i pé yunifásítì tí mò ń lọ ló ń kó bá àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà, mo rí i pé á dáa kí n wá nǹkan ṣe, mo sì fi ibẹ̀ sílẹ̀.”

16 Àkóbá wo ni yunifásítì tó lọ̀ yẹn ṣe fún un? Ó sọ pé: “Kí n má parọ́, yunifásítì tí mo lọ ti mú kí n máa ṣàríwísí àwọn èèyàn gan-an, pàápàá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi. Ó jẹ́ kí n máa retí ohun tó ju agbára wọn lọ, kí n sì máa ya ara mi sọ́tọ̀. Ó pẹ́ gan-an kí n tó lè yí èrò mi pa dà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n rí i pé ó léwu gan-an téèyàn bá kọtí ikún sí ìkìlọ̀ tí Baba wa ọ̀run ń fún wa nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Mo ti wá rí i pé Jèhófà mọ̀ mí ju bí mo ṣe mọ ara mi lọ. Ká ní mo mọ̀ ni, mi ò bá má lọ sí yunifásítì!”

17. (a) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Pinnu pé o ò ní jẹ́ kí ayé Sátánì fi “ọgbọ́n orí àti ìtànjẹ lásán” mú ẹ lẹ́rú. Máa wà lójúfò nígbà gbogbo kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ tàn ẹ́ jẹ. (1 Kọ́r. 3:18; 2 Kọ́r. 2:11) Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí Sátánì má bàa mú kó o gbàgbé Jèhófà, kó o sì pinnu pé wàá máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, má ṣe jẹ́ kí Sátánì mú kó o ronú pé àwọn ìmọ̀ràn Jèhófà ò wúlò fún ẹ. Àmọ́ tó o bá kíyè sí i pé èrò táyé ń gbé lárugẹ ti ń nípa lórí rẹ ńkọ́, kí lo lè ṣe? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ ká rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú ká borí àwọn ìwà tó ti mọ́ wa lára àti èrò tó ti “fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” lọ́kàn wa.​—2 Kọ́r. 10:4, 5.

ỌGBỌ́NKỌ́GBỌ́N WO NI SÁTÁNÌ Ń LÒ LÁTI . . .

  • mú káwọn èèyàn gbàgbé Jèhófà?

  • mú káwọn èèyàn máa ṣèṣekúṣe?

  • fi ohun táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí dẹkùn mú wọn?

ORIN 49 Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

a Sátánì gbọ́n gan-an, ó sì mọ bí wọ́n ṣe ń tan àwọn èèyàn jẹ. Ó ti mú kí ọ̀pọ̀ máa ronú pé àwọn lómìnira láìmọ̀ pé inú akóló rẹ̀ ni wọ́n wà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa ṣàlàyé díẹ̀ nínú àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì máa ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ.

b ÀWÒRÁN: Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì, ìyẹn mú kí wọ́n jọ́sìn Báálì, kí wọ́n sì ṣèṣekúṣe.

c ÀWÒRÁN: Àwọ̀ tí wọ́n fi kun pátákó ṣọ́ọ̀ṣì kan fi hàn pé wọ́n fàyè gba kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin, kí obìnrin sì máa fẹ́ obìnrin.

d ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan wà ní yunifásítì. Olùkọ́ wọn ń kọ́ wọn pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló lè yanjú ìṣòro aráyé, arábìnrin yìí àtàwọn yòókù sì fara mọ́ èrò rẹ̀. Nígbà tó lọ sípàdé, ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ ò bá a lára mu torí náà kò fọkàn sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́