Àpótí Ìbéèrè
◼ Báwo ni gbogbo wa ṣe lè yẹra fún fífa ìpínyà ọkàn láwọn ìpàdé ìjọ? (Diu. 31:12)
Tá a bá ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà, tá a sì mọyì àwọn ìpàdé ìjọ tó ṣètò fún wa, a óò máa dé lásìkò, a ó sì máa múra tán láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ fún wa. Ó máa dáa gan-an tá a bá jókòó sọ́wọ́ iwájú ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ká lè fi ààyè ìjókòó tó wà lẹ́yìn sílẹ̀ fún àwọn tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ àtàwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n pẹ́ dé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, ó yẹ kí kálukú wa fi àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ wa, irú bíi fóònù, ẹ̀rọ atanilólobó àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀ sípò tí kò ti ní fa ìpínyà ọkàn fún àwùjọ. Kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí ìpínyà ọkàn bí gbogbo wa bá ń ṣohun tó fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.—Oníw. 5:1; Fílí. 2:4.
Bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé, ó máa dáa kí ẹni tó mọ onítọ̀hún tẹ́lẹ̀ jókòó tì í. Èyí máa ṣèrànwọ́ gan-an, pàápàá jù lọ bí onítọ̀hún bá ń tọ́mọ lọ́wọ́. Bá a ṣe ń ṣe àwọn ìpàdé wa lè má tíì mọ́ ìdílé náà lára. Torí náà, ó ṣeé ṣe káwọn òbí tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ mọrírì rẹ̀ gan-an bí wọ́n bá lè jókòó sọ́wọ́ ẹ̀yìn níbi tí wọn ò ti ní fi bẹ́ẹ̀ pín ọkàn àwọn èèyàn níyà tó bá pọn dandan pé kí wọ́n jáde kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba láti lọ bójú tó àwọn ọmọ wọn. (Òwe 22:6, 15) Àwọn ìdílé tí wọ́n ní àwọn ọmọ kéékèèké kò gbọ́dọ̀ jókòó sí yàrá ọ̀tọ̀, níbi tí àwọn ọmọ náà á ti máa pariwo. Ohun tó máa dáa jù ni pé káwọn òbí gbé àwọn ọmọ wọn lọ síta láti bá wọn wí tàbí láti bójú tó ohun tí wọ́n nílò kí wọ́n sì mú wọn wọlé pa dà bí wọ́n bá ṣe tán.
Iṣẹ́ àwọn olùtọ́jú èrò ni láti rí sí i pé àwọn èèyàn fọ̀wọ̀ tó yẹ hàn láwọn ibi ìjọsìn wa. Wọ́n máa ń fi àwọn ìdílé àtàwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n pẹ́ dé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan síbi tí wọ́n máa jókòó sí. Àwọn olùtọ́jú èrò máa ń lo òye nígbà tí wọ́n bá ń fi àwọn ará síbi tí wọ́n á jókòó sí, ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn ará lè gbádùn ìpàdé láìsí ìpínyà ọkàn. Wọ́n máa ń lo òye kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe nígbà tí ohun tó lè fa ìpínyà ọkàn bá ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Bí ọmọ kan bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tó máa pín ọkàn àwọn ará níyà, àwọn olùtọ́jú èrò lè ṣèrànwọ́ tìfẹ́tìfẹ́.
Ó yẹ kí gbogbo àwọn tó ń wá sípàdé máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe kí wọ́n má bàa fa ìpínyà ọkàn níbi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti bó ṣe máa mú ayé tuntun kan tí àlàáfíà àti òdodo ti máa gbilẹ̀ wá.—Héb. 10:24, 25.