Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 14
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 14
Orin 50 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 30 ìpínrọ̀ 10 sí 18 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 16-18 (8 min.)
No. 1: 2 Àwọn Ọba 17:12-18 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Lo Ṣe Lè Ka Bíbélì Kó sì Yé Ọ Dáadáa?—igw ojú ìwé 32 (5 min.)
No. 3: Báwo Ni A Ṣe Lè Jẹ́ Kí ‘Ojú Wa Mú Ọ̀nà Kan’?—Mát. 6:22, 23 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”—Ìṣe 20:24.
10 min: “Jẹ́rìí Kúnnákúnná sí Ìhìn Rere.” Àsọyé tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí àti ìwé Jíjẹ́rìí, orí 1, ìpínrọ̀ 1 sí 11.—Ìṣe 20:24.
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Wàásù ní Ìpínlẹ̀ Tí Wọ́n Ti Ń Ṣiṣẹ́ Ajé.” Ìjíròrò. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn alápá méjì kan. Ní apá àkọ́kọ́, akéde kan fẹ́ wàásù fún ẹnì kan tó ń ṣòwò, àmọ́ kò lo ìfòyemọ̀. Lẹ́yìn náà, akéde yìí tún àṣefihàn náà ṣe, lọ́tẹ̀ yìí ó lo ìfòyemọ̀. Lẹ́yìn àṣefihàn náà, ní kí àwọn ará sọ ìdí tí àṣefihàn kejì fi gbéṣẹ́ ju ti àkọ́kọ́ lọ.
Orin 96 àti Àdúrà