Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Wàásù ní Ìpínlẹ̀ Tí Wọ́n Ti Ń Ṣiṣẹ́ Ajé
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Torí pé ọ̀pọ̀ wákàtí làwọn èèyàn fi ń ṣiṣẹ́, ohun tó dáa jù tá a lè ṣe láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún wọn ni pé ká lọ wàásù fún wọn níbi iṣẹ́ wọn. A máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé, ó sì máa ń méso rere jáde torí pé a máa ń rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ dáadáa, àwọn tó ń tajà sì máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tó bá ya ìsọ̀ wọn torí pé ojú oníbàárà ni wọ́n fi ń wò wọ́n. Ká lè ṣe àṣeyọrí, ó yẹ́ ká máa lo ìfòyemọ̀, ká sì máa múra lọ́nà tó bójú mu. (2 Kọ́r. 6:3) Torí náà, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn gbọ́dọ̀ máa bójú tó bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé àtàwọn akéde tó lọ ń wàásù níbẹ̀.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín tó ń bọ̀, ẹ ṣe ìdánrawò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ṣókí tẹ́ ẹ máa lò tí ẹ bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé.