ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 39-40
Mósè Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni Tí Jèhófà Fún Un
Mósè tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́ni tí Jèhófà fún wọn lórí bí wọ́n ṣe máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn. Ó yẹ káwa náà máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Jèhófà bá fún wa, ká sì máa ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀. Kódà táwọn ìtọ́ni yẹn ò bá fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lójú wa tàbí tá ò bá mọ ìdí tí wọ́n fi fún wa nírú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀.—Lk 16:10.
Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n bá fún wa nípa bó ṣe yẹ . . .
ká wàásù?
ká múra sílẹ̀ fún ìtọ́jú pàjáwìrì?
ká múra sílẹ̀ kí àjálù tó dé?