ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 24
Ọwọ́ Ẹ Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Ẹ
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere, torí tí àkókò bá tó, a máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.”—GÁL. 6:9.
ORIN 84 Wá Wọn Lọ
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni ọ̀pọ̀ nínú wa máa ń fẹ́ ṣe, àmọ́ tí kò rọrùn?
ṢÉ O ti ní àfojúsùn kan nínú ìjọsìn Jèhófà àmọ́ tó ò ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́?b Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, ó wu Arákùnrin Philip pé kóun máa gbàdúrà déédéé, kí àdúrà òun sì sunwọ̀n sí i, àmọ́ kò rọrùn fún un láti ráyè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wu Arábìnrin Erika náà pé kó máa tètè dé sí ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìpàdé náà ló máa ń pẹ́ dé. Ní ti Arákùnrin Tomáš, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti gbìyànjú pé kóun ka Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ó sọ pé: “Tí mo bá ń ka Bíbélì, mi kì í gbádùn ẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ti gbìyànjú ẹ̀, àmọ́ ìwé Léfítíkù ni mo máa ń dúró sí.”
2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tí ọwọ́ wa ò bá tíì tẹ àwọn ohun tá a fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run?
2 Tó o bá lóhun kan tó o fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, àmọ́ tí ọwọ́ ẹ ò tíì tẹ̀ ẹ́, má rẹ̀wẹ̀sì. Ìdí ni pé àwọn nǹkan kéékèèké téèyàn fẹ́ ṣe náà máa ń gba àkókò àti ìsapá. Bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ fi hàn pé o mọyì àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà, o sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe torí kò retí pé kó o ṣe ju agbára ẹ lọ. (Sm. 103:14; Míkà 6:8) Torí náà, má ṣe lé ohun tó kọjá agbára ẹ. Tó o bá sì ti ní àfojúsùn kan, kí lo lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn àbá díẹ̀ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
MÁA ṢE OHUN TÁÁ JẸ́ KỌ́WỌ́ Ẹ TẸ ÀFOJÚSÙN Ẹ
Gbàdúrà pé kó túbọ̀ máa wù ẹ́ láti ṣohun táá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ (Wo ìpínrọ̀ 3-4)
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa ṣe ohun táá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ?
3 Kọ́wọ́ ẹ tó lè tẹ àfojúsùn ẹ, nǹkan tó o fẹ́ ṣe yẹn gbọ́dọ̀ máa wù ẹ́. Tí nǹkan tó o fẹ́ ṣe yẹn bá ń wù ẹ́ gan-an, á rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ̀ ẹ́. A lè fi bó ṣe ń wù ẹ́ láti ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe wé atẹ́gùn tó ń ti ọkọ̀ ojú omi kan lọ síbi tó ń lọ. Tí atẹ́gùn yẹn ò bá dáwọ́ dúró, ọkọ̀ náà máa débi tó ń lọ. Tí atẹ́gùn náà bá sì fẹ́ dáadáa, á tètè dé ibi tó ń lọ. Lọ́nà kan náà, tí àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe yẹn bá ń wù wá gan-an, á rọrùn fún wa láti ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ̀ ẹ́. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ David lórílẹ̀-èdè El Salvador sọ pé: “Tó bá wù ẹ́ láti ṣe nǹkan kan lóòótọ́, wàá tẹra mọ́ ọn dáadáa. Kódà, o ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́.” Torí náà, kí làwọn nǹkan tó yẹ kó o máa ṣe táá jẹ́ kí àwọn àfojúsùn ẹ túbọ̀ máa wù ẹ́?
4. Tá a bá ń gbàdúrà, kí la lè béèrè lọ́wọ́ Jèhófà? (Fílípì 2:13) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
4 Máa gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ káwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe túbọ̀ máa wù ẹ́. Jèhófà lè fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ. (Ka Fílípì 2:13.) Nígbà míì, a máa ń fẹ́ ṣe àwọn nǹkan kan torí a mọ̀ pé ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn, ìyẹn sì dáa. Àmọ́, ó lè má wù wá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Norina láti orílẹ̀-èdè Uganda nìyẹn. Ó wù ú pé kóun náà máa kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ kò ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀ torí ó gbà pé òun ò mọ̀ọ̀yàn kọ́. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jèhófà lójoojúmọ́ pé kó jẹ́ kó túbọ̀ máa wù mí láti kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yàtọ̀ sí àdúrà tí mò ń gbà, mo ṣèwádìí kí n lè mọ bí mo ṣe lè túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, mo rí i pé ó ti ń wù mí gan-an pé kí n máa kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èèyàn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́dún yẹn.”
5. Kí la lè máa ronú nípa ẹ̀ táá jẹ́ kó túbọ̀ wù wá pé kọ́wọ́ wa tẹ àwọn àfojúsùn wa?
5 Máa ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ. (Sm. 143:5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń ronú lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí i, ìyẹn sì jẹ́ kó pinnu pé òun máa lo gbogbo okun òun lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:9, 10; 1 Tím. 1:12-14) Lọ́nà kan náà, bó o bá ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ tó, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa wù ẹ́ pé kọ́wọ́ ẹ tẹ àwọn àfojúsùn ẹ. (Sm. 116:12) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ran arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Honduras lọ́wọ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ó sọ pé: “Mo máa ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ mi tó. Òun ló jẹ́ kí n máa jọ́sìn láàárín àwọn èèyàn ẹ̀. Ó máa ń bójú tó mi, ó sì ń dáàbò bò mí. Bí mo ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún mi yìí ń mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó sì ń jẹ́ kó túbọ̀ máa wù mí láti ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn ẹ̀.”
6. Kí ni nǹkan míì tó máa jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wá pé kọ́wọ́ wa tẹ àwọn àfojúsùn wa?
6 Máa ronú lórí àǹfààní tó o máa rí tọ́wọ́ ẹ bá tẹ àfojúsùn ẹ. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ran Erika tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́wọ́ tó fi ń tètè dé sípàdé iṣẹ́ ìwàásù. Ó sọ pé: “Mo rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni mò ń pàdánù bí mo ṣe ń pẹ́ dé sípàdé iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́ tí mo bá tètè dé, ó máa ń jẹ́ kí n lè kí àwọn ará, kí n sì wà pẹ̀lú wọn. Ó tún máa jẹ́ kí n gbọ́ àwọn àbá tó máa jẹ́ kí n gbádùn iṣẹ́ ìwàásù lọ́jọ́ yẹn, kí n sì sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ náà.” Erika máa ń ronú lórí àǹfààní tó máa rí tó bá ń tètè dé sípàdé iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn sì jẹ́ kọ́wọ́ ẹ̀ tẹ àfojúsùn náà. Àwọn àǹfààní wo ló yẹ kíwọ náà máa ronú nípa ẹ̀? Tó bá jẹ́ pé àfojúsùn ẹ ni pé kó o túbọ̀ máa ka Bíbélì déédéé, kí àdúrà ẹ sì sunwọ̀n sí i, á dáa kó o ronú lórí bí àwọn nǹkan yẹn ṣe máa mú kí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. (Sm. 145:18, 19) Tó bá jẹ́ pé àfojúsùn ẹ ni pé kó o ní ànímọ́ Kristẹni kan, ronú lórí bíyẹn ṣe máa jẹ́ kí àárín ìwọ àtàwọn míì túbọ̀ gún régé. (Kól. 3:14) Torí náà, á dáa kó o kọ ìdí tó fi ń wù ẹ́ pé kọ́wọ́ ẹ tẹ àwọn àfojúsùn ẹ sílẹ̀, kó o sì máa gbé wọn yẹ̀ wò déédéé. Tomáš tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè sọ pé: “Tí mo bá ti rí i pé ó pọn dandan kọ́wọ́ mi tẹ àwọn àfojúsùn kan, mo máa ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ mi lè tẹ̀ ẹ́.”
7. Kí ló ran Julio àtìyàwó ẹ̀ lọ́wọ́ tí ọwọ́ wọn fi tẹ àfojúsùn wọn?
7 Mú àwọn tó máa jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ lọ́rẹ̀ẹ́. (Òwe 13:20) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ran Julio àtìyàwó ẹ̀ lọ́wọ́ kọ́wọ́ wọn lè tẹ àfojúsùn wọn láti lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù. Julio sọ pé: “Àwọn tó máa jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa la yàn lọ́rẹ̀ẹ́, a sì máa ń sọ nǹkan tá a fẹ́ ṣe fún wọn. Ìdí sì ni pé ọ̀pọ̀ nínú wọn lọwọ́ wọn ti tẹ irú àfojúsùn bẹ́ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, torí náà wọ́n máa ń fún wa láwọn àbá tó máa ràn wá lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń bi wá pé ibo la báṣẹ́ dé lórí àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe, wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí tá a bá fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì.”
TÁ Ò BÁ FẸ́ ṢOHUN TÁÁ JẸ́ KỌ́WỌ́ WA TẸ ÀFOJÚSÙN WA
Máa ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àfojúsùn ẹ (Wo ìpínrọ̀ 8)
8. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ìgbà tó bá wù wá nìkan la máa ń ṣohun táá jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Ká sòótọ́, àwọn ìgbà míì máa ń wà tí kì í wù wá pé ká ṣe nǹkan kan. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí nǹkan tá a lè ṣe kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn wa ni? Rárá o. Àpèjúwe kan rèé: Torí pé atẹ́gùn máa ń lágbára gan-an, ó máa ń ti ọkọ̀ ojú omi lọ síbi tó ń lọ. Síbẹ̀, àwọn ọjọ́ míì máa ń wà tí atẹ́gùn kì í fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ tàbí kó má tiẹ̀ fẹ́ rárá. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé awakọ̀ náà ò ní débi tó ń lọ? Rárá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọkọ̀ kan ní ẹ́ńjìnnì, àwọn míì sì ní àjẹ̀. Awakọ̀ náà lè lo àwọn nǹkan yìí láti wakọ̀ náà débi tó ń lọ. A lè fi bó ṣe ń wù wá láti ṣe nǹkan wé atẹ́gùn, àwọn ọjọ́ kan wà tó lè wù wá láti ṣe nǹkan nípa àfojúsùn wa, àwọn ọjọ́ míì sì wà tó lè má wù wá. Torí náà, tó bá jẹ́ pé ìgbà tó wù wá nìkan la máa ń ṣohun táá jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa, ọwọ́ wa lè má tẹ̀ ẹ́ láé. Síbẹ̀, bí awakọ̀ yẹn ṣe máa ń lo nǹkan míì láti wakọ̀ ẹ̀ débi tó ń lọ, ó yẹ káwa náà túbọ̀ máa ṣohun táá jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa bí ò tiẹ̀ wù wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ní rọrùn, inú wa máa dùn gan-an tọ́wọ́ wa bá tẹ àfojúsùn wa. Torí náà ká tó sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tá a lè ṣe, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè kan tó ṣeé ṣe kó wá sí wa lọ́kàn.
9. Ṣé ó burú téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ̀ lè tẹ àfojúsùn kan tí ò bá tiẹ̀ wù ú? Ṣàlàyé.
9 Jèhófà fẹ́ ká máa fayọ̀ sin òun tọkàntọkàn. (Sm. 100:2; 2 Kọ́r. 9:7) Torí náà, ṣé ó wá yẹ ká máa ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn kan tí ò bá tiẹ̀ wù wá? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó sọ pé: “Mò ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.” (1 Kọ́r. 9:25-27, wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ 27, nwtsty-E) Kódà láwọn ìgbà tí kò wu Pọ́ọ̀lù láti ṣe ohun tó tọ́, ó ṣohun tó tọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un. Ṣé inú Jèhófà dùn sí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà sì bù kún un torí gbogbo ohun tó ṣe.—2 Tím. 4:7, 8.
10. Tá ò bá fẹ́ ṣohun táá jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa, àǹfààní wo la máa rí tá a bá ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ ẹ́?
10 Lọ́nà kan náà, inú Jèhófà máa dùn tó bá rí i pé à ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn kan tí ò bá tiẹ̀ wù wá. Ó mọ̀ pé nígbà míì kì í ṣe torí àfojúsùn wa la ṣe ń ṣiṣẹ́ kára, àmọ́ ìfẹ́ tá a ní sóun la ṣe ń ṣe é. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa bó ṣe bù kún Pọ́ọ̀lù. (Sm. 126:5) Bá a sì ṣe ń rí i tí Jèhófà ń bù kún wa, ohun tá à ń ṣe yẹn lè bẹ̀rẹ̀ sí í wù wá. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lucyna láti Poland sọ pé: “Nígbà míì, kì í wù mí láti lọ wàásù pàápàá tó bá ti rẹ̀ mí. Àmọ́, ayọ̀ mi máa ń pọ̀ gan-an tí mo bá pa dà délé.” Torí náà, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tá a lè ṣe tá ò bá fẹ́ ṣohun táá jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa.
11. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa kó ara wa níjàánu?
11 Gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó o máa kó ara ẹ níjàánu. Ẹni tó bá ń kó ara ẹ̀ níjàánu máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó má bàa ṣe ohun tí ò dáa. Síbẹ̀, a tún gbọ́dọ̀ kó ara wa níjàánu ká lè ṣohun tó dáa, pàápàá tí ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn ò bá rọrùn tàbí tí kò bá wù wá. Máa rántí pé ìkóra-ẹni-níjàánu wà lára àwọn ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní, torí náà bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kó o lè túbọ̀ máa kó ara ẹ níjàánu. (Lúùkù 11:13; Gál. 5:22, 23) David tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ bí àdúrà ṣe ran òun lọ́wọ́ torí pé ó fẹ́ máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Ó sọ pé: “Mo bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n máa kó ara mi níjàánu. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an débi pé mo ṣètò bí mo ṣe fẹ́ máa dá kẹ́kọ̀ọ́, mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé.”
12. Ìlànà wo ló wà nínú Oníwàásù 11:4 tó máa jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa?
12 Má dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan máa dán mọ́rán. Kò dájú pé ìgbà kan máa wà tí gbogbo nǹkan á dán mọ́rán fún wa nínú ayé yìí. Torí náà, tá a bá sọ pé a fẹ́ dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan máa dáa, ọwọ́ wa lè má tẹ àfojúsùn wa. (Ka Oníwàásù 11:4.) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Dayniel sọ pé: “Kò sí bí gbogbo nǹkan ṣe lè dán mọ́rán. Torí náà, kò yẹ ká dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan máa dáa, ṣe ló yẹ ká tètè bẹ̀rẹ̀.” Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Paul ní Uganda sọ ìdí míì tí ò fi yẹ ká máa fi nǹkan falẹ̀. Ó ní: “Tá a bá bẹ̀rẹ̀ láìka gbogbo ìṣòro tó wà níbẹ̀ sí, Jèhófà máa bù kún wa.”—Mál. 3:10.
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi àwọn nǹkan tọ́wọ́ wa lè tètè tẹ̀ bẹ̀rẹ̀?
13 Àwọn nǹkan tọ́wọ́ ẹ lè tètè tẹ̀ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀. A lè rẹ̀wẹ̀sì torí ó lè máa ṣe wá bíi pé ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn ti le jù, ọwọ́ wa ò sì ní lè tẹ̀ ẹ́. Tó bá jẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ nìyẹn, ṣé o lè ronú nípa àwọn àfojúsùn míì tọ́wọ́ ẹ lè tètè tẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ànímọ́ kan ló wù ẹ́ kó o ní, o ò ṣe kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi ànímọ́ náà hàn díẹ̀díẹ̀? Tó bá jẹ́ àfojúsùn ẹ ni pé kó o ká gbogbo Bíbélì parí, á dáa kó o kọ́kọ́ máa fi àkókò díẹ̀ kà á lójoojúmọ́. Kò ṣeé ṣe fún Tomáš tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí láti ka Bíbélì parí lọ́dún kan. Ó wá sọ pé: “Mo rí i pé iye ẹsẹ Bíbélì tí mò ń kà lójoojúmọ́ ti pọ̀ jù. Torí náà, mo pinnu pé màá tún gbìyànjú ẹ̀. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ẹsẹ díẹ̀ ni mo máa ń kà lójoojúmọ́, mo sì máa ń ronú lórí ohun tí mo kà. Bó ṣe di pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn Bíbélì kíkà nìyẹn.” Bí Tomáš ṣe ń gbádùn Bíbélì tó ń kà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi kún iye àkókò tó fi ń kà á. Nígbà tó yá, ó ka gbogbo Bíbélì tán.c
MÁ JẸ́ KÓ SÚ Ẹ TỌ́WỌ́ Ẹ Ò BÁ TÈTÈ TẸ ÀFOJÚSÙN Ẹ
14. Kí làwọn nǹkan tó lè má jẹ́ kọ́wọ́ wa tètè tẹ àfojúsùn wa?
14 Ó bani nínú jẹ́ pé kò sí bá a ṣe ṣiṣẹ́ kára tó tàbí bá a ṣe kó ara wa níjàánu tó, àwọn nǹkan kan ṣì lè mú kọ́wọ́ wa má tètè tẹ àfojúsùn wa. Bí àpẹẹrẹ, “ìgbà àti èèṣì” lè má jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá à ń lé. (Oníw. 9:11) Yàtọ̀ síyẹn, ìṣòro lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ká má sì lókun mọ́. (Òwe 24:10) Torí pé aláìpé ni wá, a lè máa ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ ohun tá à ń lé. (Róòmù 7:23) Gbogbo nǹkan sì lè tojú sú wa. (Mát. 26:43) Torí náà, kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro yìí?
15. Tí ohun kan ò bá jẹ́ kọ́wọ́ wa tètè tẹ ohun tá à ń lé, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ká pa nǹkan náà tì? Ṣàlàyé. (Sáàmù 145:14)
15 Máa rántí pé tóhun kan ò bá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tètè tẹ nǹkan tó ò ń lé, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kó o pa nǹkan náà tì. Bíbélì sọ pé ìṣòro lè dé bá wa léraléra. Àmọ́, ó tún sọ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro náà. (Ka Sáàmù 145:14.) Arákùnrin Philip tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ béèyàn ṣe lè ṣàṣeyọrí, ó ní: “Kì í ṣe iye ìgbà tọ́wọ́ mi ò tẹ ohun tí mò ń lé ni mò ń rò. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí mo ṣe máa ṣiṣẹ́ kára tọ́wọ́ mi á sì tẹ̀ ẹ́ ni mo gbájú mọ́.” Arákùnrin David tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ náà lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tí ohun kan ò bá jẹ́ kọ́wọ́ mi tètè tẹ àfojúsùn mi, mi kì í kà á sí ìṣòro. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo máa ń kà á sóhun táá jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ òun.” Ó dájú pé tó o bá ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àfojúsùn ẹ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, ìyẹn á jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé o fẹ́ ṣohun tóun fẹ́. Wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ ohun tó ò ń lé!
16. Tí ohun kan ò bá jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn wa, kí ló yẹ ká ṣe?
16 Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn nǹkan tí ò jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ. Ronú nípa ohun tí ò jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ ohun tó ò ń lé, kó o wá bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mo lè ṣe àwọn àtúnṣe kan, kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn má bàa ṣẹlẹ̀ mọ́?’ (Òwe 27:12) Nígbà míì, tọ́wọ́ wa ò bá tẹ ohun tá à ń lé, ó lè fi hàn pé kì í ṣe ohun tó yẹ ká fi ṣe àfojúsùn wa nìyẹn. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ẹ ṣe rí nìyẹn, gbé àfojúsùn ẹ yẹ̀ wò, kó o lè mọ̀ bóyá agbára ẹ ká a.d Jèhófà ò ní sọ pé aláṣetì ni ẹ́ tọ́wọ́ ẹ ò bá tẹ àfojúsùn tágbára ẹ ò gbé.—2 Kọ́r. 8:12.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa rántí àwọn nǹkan tá a ti ṣe láṣeyọrí?
17 Máa rántí àwọn nǹkan tó o ti ṣe láṣeyọrí. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín.” (Héb. 6:10) Torí náà, kò yẹ kíwọ náà gbàgbé iṣẹ́ tó o ti ṣe. Ronú nípa àwọn nǹkan tó o ti ṣe láṣeyọrí. Bí àpẹẹrẹ, o lè ti ṣiṣẹ́ kára láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kó o máa sọ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, o sì ti lè ṣèrìbọmi. Bó o ṣe tẹ̀ síwájú, tọ́wọ́ ẹ sì tẹ àwọn àfojúsùn ẹ láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kó o máa tẹ̀ síwájú kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ní.—Fílí. 3:16.
Gbádùn ìrìn àjò náà (Wo ìpínrọ̀ 18)
18. Kí ló yẹ ká máa ṣe bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ àfojúsùn wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
18 Bí inú awakọ̀ òkun kan ṣe máa ń dùn tó bá wakọ̀ dé ibi tó ń lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni inú ẹ máa dùn nígbà tí Jèhófà bá jẹ́ kọ́wọ́ ẹ tẹ àfojúsùn ẹ. Máa rántí pé ọ̀pọ̀ àwọn awakọ̀ òkun máa ń gbádùn ìrìn àjò wọn. Lọ́nà kan náà, bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àfojúsùn ẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, jẹ́ kí inú ẹ máa dùn bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó sì ń bù kún ẹ. (2 Kọ́r. 4:7) Torí náà tó ò bá jẹ́ kó sú ẹ, Jèhófà máa bù kún ẹ lọ́pọ̀lọpọ̀.—Gál. 6:9.
ORIN 126 Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára
a Gbogbo ìgbà ni ètò Ọlọ́run máa ń gbà wá níyànjú láti ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn wa. Ká wá sọ pé a ti ní ohun kan lọ́kàn tá a fẹ́ ṣe, àmọ́ tí ọwọ́ wa ò tíì tẹ̀ ẹ́ ńkọ́? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn àbá tó máa jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àwọn àfojúsùn wa.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Àfojúsùn ni àwọn ìwà àtàwọn nǹkan míì tó o fẹ́ kó sunwọ̀n sí i tàbí àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, tó o sì ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́. Ìyẹn lá jẹ́ kó o ṣe púpọ̀ sí i, kó o sì múnú Jèhófà dùn. Bí àpẹẹrẹ, ó lè wù ẹ́ pé kó o ní ànímọ́ Kristẹni kan tàbí kó o sunwọ̀n sí i nínú ọ̀kan lára àwọn apá ìjọsìn wa bíi kó o máa ka Bíbélì, kó o máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa lọ sóde ìwàásù déédéé.
d Kó o lè mọ púpọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Láti Lè Máa Láyọ̀, Ohun Tọ́wọ́ Rẹ Lè Tẹ̀ Ni Kó O Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2008.