LÚÙKÙ
OHUN TÓ WÀ NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ
1
Ó kọ̀wé sí Tìófílọ́sì (1-4)
Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Jòhánù Arinibọmi (5-25)
Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Jésù (26-38)
Màríà lọ kí Èlísábẹ́tì (39-45)
Màríà gbé Jèhófà ga (46-56)
Wọ́n bí Jòhánù, wọ́n sì sọ ọ́ lórúkọ (57-66)
Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ (67-80)
2
Wọ́n bí Jésù (1-7)
Àwọn áńgẹ́lì yọ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn (8-20)
Ìdádọ̀dọ́ àti ìwẹ̀mọ́ (21-24)
Síméónì rí Kristi (25-35)
Ánà sọ̀rọ̀ ọmọ náà (36-38)
Wọ́n pa dà sí Násárẹ́tì (39, 40)
Jésù ọmọ ọdún méjìlá wà nínú tẹ́ńpìlì (41-52)
3
Ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Jòhánù (1, 2)
Jòhánù ń wàásù pé kí wọ́n ṣèrìbọmi (3-20)
Jésù ṣèrìbọmi (21, 22)
Ìlà ìdílé Jésù Kristi (23-38)
4
Èṣù dán Jésù wò (1-13)
Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní Gálílì (14, 15)
Wọn ò tẹ́wọ́ gba Jésù ní Násárẹ́tì (16-30)
Nínú sínágọ́gù ní Kápánáúmù (31-37)
Ó wo ìyá ìyàwó Símónì àtàwọn míì sàn (38-41)
Àwọn èrò rí Jésù ní ibi tó dá (42-44)
5
Wọ́n rí ẹja kó lọ́nà ìyanu; àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́ (1-11)
Ó wo adẹ́tẹ̀ sàn (12-16)
Jésù wo alárùn rọpárọsẹ̀ sàn (17-26)
Jésù pe Léfì (27-32)
Ìbéèrè nípa ààwẹ̀ (33-39)
6
Jésù ni “Olúwa Sábáàtì” (1-5)
Ó wo ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sàn (6-11)
Àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12-16)
Jésù ń kọ́ni, ó sì ń woni sàn (17-19)
Àwọn aláyọ̀ àtàwọn tí a káàánú wọn (20-26)
Nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá (27-36)
Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́ mọ́ (37-42)
Èso igi la fi ń mọ̀ ọ́n (43-45)
Ilé tí wọ́n kọ́ dáadáa; ilé tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ ò lágbára (46-49)
7
Ìgbàgbọ́ ọ̀gágun (1-10)
Jésù jí ọmọkùnrin opó Náínì dìde (11-17)
Ó yin Jòhánù Arinibọmi (18-30)
Ó dá ìran ọlọ́kàn líle lẹ́bi (31-35)
Ó dárí ji obìnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ (36-50)
8
Àwọn obìnrin tó ń tẹ̀ lé Jésù (1-3)
Àpèjúwe afúnrúgbìn (4-8)
Ìdí tí Jésù fi ń lo àwọn àpèjúwe (9, 10)
Ó ṣàlàyé àpèjúwe afúnrúgbìn (11-15)
A kì í bo fìtílà mọ́lẹ̀ (16-18)
Ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ (19-21)
Jésù mú kí ìjì dáwọ́ dúró (22-25)
Jésù lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde sínú ẹlẹ́dẹ̀ (26-39)
Ọmọbìnrin Jáírù; obìnrin kan fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè Jésù (40-56)
9
Ó fún àwọn Méjìlá náà ní ìtọ́ni nípa iṣẹ́ ìwàásù (1-6)
Ìdààmú bá Hẹ́rọ́dù torí Jésù (7-9)
Jésù bọ́ 5,000 èèyàn (10-17)
Pétérù pè é ní Kristi (18-20)
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú Jésù (21, 22)
Ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn (23-27)
A yí Jésù pa dà di ológo (28-36)
Ó wo ọmọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu sàn (37-43a)
Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (43b-45)
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù (46-48)
Ẹni tí kò bá ta kò wá, tiwa ló ń ṣe (49, 50)
Àwọn ará abúlé kan ní Samáríà kọ Jésù (51-56)
Bí a ṣe lè tẹ̀ lé Jésù (57-62)
10
Jésù rán 70 èèyàn jáde (1-12)
Àwọn ìlú tí kò ronú pìwà dà gbé (13-16)
Àwọn 70 náà pa dà dé (17-20)
Jésù yin Baba rẹ̀ torí ó ṣojúure sí àwọn onírẹ̀lẹ̀ (21-24)
Àpèjúwe ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere (25-37)
Jésù lọ sọ́dọ̀ Màtá àti Màríà (38-42)
11
Bí o ṣe lè gbàdúrà (1-13)
Ó fi ìka Ọlọ́run lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde (14-23)
Ẹ̀mí àìmọ́ pa dà wá (24-26)
Ayọ̀ tòótọ́ (27, 28)
Àmì Jónà (29-32)
Fìtílà ara (33-36)
Àwọn ẹlẹ́sìn tó ń ṣe àgàbàgebè gbé (37-54)
12
Ìwúkàrà àwọn Farisí (1-3)
Bẹ̀rù Ọlọ́run, má bẹ̀rù èèyàn (4-7)
Fi hàn pé o wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi (8-12)
Àpèjúwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó jẹ́ òmùgọ̀ (13-21)
Ẹ yéé ṣàníyàn (22-34)
Ṣíṣọ́nà (35-40)
Ìríjú olóòótọ́ àti ìríjú aláìṣòótọ́ (41-48)
Kì í ṣe àlàáfíà, ìpínyà ni (49-53)
Ó yẹ kí wọ́n ṣàyẹ̀wò àkókò (54-56)
Yíyanjú ọ̀rọ̀ (57-59)
13
Ẹ ronú pìwà dà àbí kí ẹ pa run (1-5)
Àpèjúwe igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò so èso (6-9)
Ó ṣèwòsàn fún obìnrin tí ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀ ní Sábáàtì (10-17)
Àpèjúwe hóró músítádì àti ìwúkàrà (18-21)
Ó gba ìsapá láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé (22-30)
Hẹ́rọ́dù, “kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yẹn” (31-33)
Jésù dárò lórí Jerúsálẹ́mù (34, 35)
14
Ó wo ọkùnrin kan tí ara rẹ̀ wú sàn ní Sábáàtì (1-6)
Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tí o bá jẹ́ àlejò (7-11)
Pe àwọn tí kò lè san án pa dà fún ọ (12-14)
Àpèjúwe àwọn àlejò tó ṣàwáwí (15-24)
Ohun tó máa ná ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn (25-33)
Iyọ̀ tí ò lágbára mọ́ (34, 35)
15
Àpèjúwe àgùntàn tó sọ nù (1-7)
Àpèjúwe ẹyọ owó tó sọ nù (8-10)
Àpèjúwe ọmọ tó sọ nù (11-32)
16
Àpèjúwe ìríjú aláìṣòdodo (1-13)
Òfin àti Ìjọba Ọlọ́run (14-18)
Àpèjúwe ọkùnrin ọlọ́rọ̀ àti Lásárù (19-31)
17
Ìkọ̀sẹ̀, ìdáríjì àti ìgbàgbọ́ (1-6)
Àwọn ẹrú tí kò dáa fún ohunkóhun (7-10)
Ó wo adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá sàn (11-19)
Dídé Ìjọba Ọlọ́run (20-37)
18
Àpèjúwe opó tí kò juwọ́ sílẹ̀ (1-8)
Farisí àti agbowó orí (9-14)
Jésù àti àwọn ọmọdé (15-17)
Alákòóso kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ béèrè ìbéèrè (18-30)
Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (31-34)
Alágbe kan tó fọ́jú pa dà ríran (35-43)
19
Jésù lọ sọ́dọ̀ Sákéù (1-10)
Àpèjúwe mínà mẹ́wàá (11-27)
Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnú ìlú (28-40)
Jésù sunkún lórí Jerúsálẹ́mù (41-44)
Jésù fọ tẹ́ńpìlì mọ́ (45-48)
20
Wọ́n béèrè àṣẹ tí Jésù fi ń ṣe nǹkan (1-8)
Àpèjúwe àwọn tó ń dáko, tí wọ́n sì pààyàn (9-19)
Ọlọ́run àti Késárì (20-26)
Ìbéèrè nípa àjíǹde (27-40)
Ṣé ọmọ Dáfídì ni Kristi? (41-44)
Ó kìlọ̀ fún wọn nípa àwọn akọ̀wé òfin (45-47)
21
Ẹyọ owó méjì tí opó aláìní fi sílẹ̀ (1-4)
ÀMÌ OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ (5-36)
Ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ (10, 11)
Àwọn ọmọ ogun máa yí Jerúsálẹ́mù ká (20)
Àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè (24)
Ọmọ èèyàn ń bọ̀ (27)
Àpèjúwe igi ọ̀pọ̀tọ́ (29-33)
Ẹ wà lójúfò (34-36)
Jésù ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì (37, 38)
22
Àwọn àlùfáà gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù (1-6)
Wọ́n múra Ìrékọjá tó gbẹ̀yìn sílẹ̀ (7-13)
Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀ (14-20)
“Èmi àti ẹni tó máa dà mí jọ wà lórí tábìlì” (21-23)
Wọ́n bára wọn jiyàn gidigidi nípa ẹni tó tóbi jù (24-27)
Jésù bá wọn dá májẹ̀mú ìjọba (28-30)
Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun (31-34)
Ìdí tó fi yẹ kí wọ́n múra sílẹ̀; idà méjì (35-38)
Àdúrà Jésù lórí Òkè Ólífì (39-46)
Wọ́n mú Jésù (47-53)
Pétérù sẹ́ Jésù (54-62)
Wọ́n fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ (63-65)
Wọ́n gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (66-71)
23
24
Jésù jíǹde (1-12)
Lójú ọ̀nà tó lọ sí Ẹ́máọ́sì (13-35)
Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn (36-49)
Jésù pa dà sí ọ̀run (50-53)