ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Máàkù 1:1-16:8
  • Máàkù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máàkù
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Máàkù

ÀKỌSÍLẸ̀ MÁÀKÙ

1 Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìn rere nípa Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run: 2 Bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé wòlíì Àìsáyà pé: “(Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi ṣáájú rẹ,* ẹni tó máa ṣètò ọ̀nà rẹ.)+ 3 Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.’”+ 4 Jòhánù Onírìbọmi wà nínú aginjù, ó ń wàásù pé kí àwọn èèyàn ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.+ 5 Gbogbo àwọn tó ń gbé ní agbègbè Jùdíà àti gbogbo Jerúsálẹ́mù máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ń ṣèrìbọmi fún wọn* ní odò Jọ́dánì, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba.+ 6 Jòhánù wọ aṣọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí ṣe, ó sì de àmùrè tí wọ́n fi awọ ṣe mọ́ ìbàdí rẹ̀,+ ó máa ń jẹ eéṣú àti oyin ìgàn.+ 7 Ó sì ń wàásù pé: “Ẹnì kan tó lágbára jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí mi ò tó bẹ̀rẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀.+ 8 Mò ń fi omi batisí yín, àmọ́ ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín.”+

9 Nígbà yẹn, Jésù wá láti Násárẹ́tì ti Gálílì, Jòhánù sì ṣèrìbọmi fún un ní Jọ́dánì.+ 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń jáde látinú omi, ó rí i tí ọ̀run ń pínyà, ẹ̀mí sì ń bọ̀ wá sórí rẹ̀ bí àdàbà.+ 11 Ohùn kan sì dún láti ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”+

12 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀mí sún un láti lọ sínú aginjù. 13 Torí náà, ó lo ogójì (40) ọjọ́ nínú aginjù náà, Sátánì sì dán an wò.+ Ó wà láàárín àwọn ẹran inú igbó, àwọn áńgẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.+

14 Lẹ́yìn tí wọ́n mú Jòhánù, Jésù lọ sí Gálílì,+ ó ń wàásù ìhìn rere Ọlọ́run,+ 15 ó ń sọ pé: “Àkókò tí a yàn ti pé, Ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà,+ kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.”

16 Bó ṣe ń rìn lọ létí Òkun Gálílì, ó rí Símónì àti Áńdérù+ arákùnrin Símónì, tí wọ́n ń ju àwọ̀n wọn sínú òkun,+ torí apẹja ni wọ́n.+ 17 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa tẹ̀ lé mi, màá sì sọ yín di apẹja èèyàn.”+ 18 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa àwọ̀n wọn tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+ 19 Lẹ́yìn tó lọ síwájú díẹ̀ sí i, ó rí Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe,+ 20 ó sì pè wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Torí náà, wọ́n fi Sébédè bàbá wọn sílẹ̀ sínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tẹ̀ lé e. 21 Wọ́n lọ sí Kápánáúmù.

Gbàrà tí Sábáàtì bẹ̀rẹ̀, ó wọnú sínágọ́gù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni.+ 22 Bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yà wọ́n lẹ́nu, torí ṣe ló ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ, kò kọ́ wọn bí àwọn akọ̀wé òfin.+ 23 Ní àkókò yẹn, ọkùnrin kan wà nínú sínágọ́gù wọn, tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú, ó sì kígbe pé: 24 “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù ará Násárẹ́tì?+ Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run ni ọ́!”+ 25 Àmọ́ Jésù bá a wí, ó ní: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò nínú rẹ̀!” 26 Lẹ́yìn tí ẹ̀mí àìmọ́ náà mú kí gìrì gbé ọkùnrin náà, tó sì pariwo gan-an, ó jáde kúrò nínú rẹ̀. 27 Ẹnu ya gbogbo àwọn èèyàn náà débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ láàárín ara wọn pé: “Kí nìyí? Ẹ̀kọ́ tuntun ni o! Ó ń lo agbára tó ní láti pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i.” 28 Torí náà, ìròyìn rẹ̀ yára tàn káàkiri gbogbo agbègbè Gálílì.

29 Wọ́n wá kúrò nínú sínágọ́gù, wọ́n sì lọ sí ilé Símónì àti Áńdérù pẹ̀lú Jémíìsì àti Jòhánù.+ 30 Àìsàn ibà dá ìyá ìyàwó Símónì+ dùbúlẹ̀, wọ́n sì sọ fún un nípa rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 31 Ó lọ bá obìnrin náà, ó dì í lọ́wọ́ mú, ó sì gbé e dìde. Ibà náà sì lọ, obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

32 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn ti wọ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú gbogbo àwọn tó ní àìlera àti àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀;+ 33 gbogbo ìlú sì kóra jọ sí ẹnu ilẹ̀kùn. 34 Torí náà, ó wo ọ̀pọ̀ àwọn tí oríṣiríṣi àìsàn ń yọ lẹ́nu sàn,+ ó sì lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, àmọ́ kì í jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, torí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi.*

35 Ní àárọ̀ kùtù, tí ilẹ̀ ò tíì mọ́, ó dìde, ó jáde lọ síbi tó dá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà níbẹ̀.+ 36 Àmọ́ Símónì àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá a kàn, 37 wọ́n sì rí i, wọ́n wá sọ fún un pé: “Gbogbo èèyàn ti ń wá ọ.” 38 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ síbòmíì, sí àwọn ìlú tó wà nítòsí, kí n lè wàásù níbẹ̀ náà, torí ìdí tí mo ṣe wá nìyí.”+ 39 Ó wá lọ ń wàásù nínú àwọn sínágọ́gù wọn káàkiri gbogbo Gálílì, ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.+

40 Bákan náà, adẹ́tẹ̀ kan wá bá a, ó ń bẹ̀ ẹ́, àní lórí ìkúnlẹ̀, ó sọ fún un pé: “Tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́.”+ 41 Àánú rẹ̀ wá ṣe é, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó wá sọ fún un pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀! Kí o mọ́.”+ 42 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà pòórá lára rẹ̀, ó sì mọ́. 43 Ó wá kìlọ̀ fún un gidigidi, ó sì ní kó máa lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, 44 ó sọ fún un pé: “Rí i pé o ò sọ nǹkan kan fún ẹnikẹ́ni, àmọ́ lọ fi ara rẹ han àlùfáà, kí o sì mú àwọn ohun tí Mósè sọ dání láti wẹ̀ ọ́ mọ́,+ kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+ 45 Àmọ́ lẹ́yìn tó lọ, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn rẹ̀ káàkiri, ó sì ń tan ọ̀rọ̀ náà kiri débi pé Jésù ò lè wọ ìlú mọ́ kí àwọn èèyàn má mọ̀, àmọ́ ó dúró sẹ́yìn ìlú láwọn ibi tó dá. Síbẹ̀, wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá láti ibi gbogbo.+

2 Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó tún wá sí Kápánáúmù, ìròyìn sì tàn káàkiri pé ó ti wà nílé.+ 2 Ọ̀pọ̀ èèyàn wá kóra jọ, débi pé kò sí àyè kankan mọ́ nínú ilé, kódà kò sí àyè lẹ́nu ọ̀nà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ náà fún wọn.+ 3 Wọ́n gbé alárùn rọpárọsẹ̀ kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn mẹ́rin ló gbé e.+ 4 Àmọ́ wọn ò lè gbé e tààràtà dé ọ̀dọ̀ Jésù torí àwọn èrò, nítorí náà, wọ́n ṣí òrùlé ibi tí Jésù wà, wọ́n dá ihò lu síbẹ̀, wọ́n sì gba ojú ihò náà sọ ibùsùn tí alárùn rọpárọsẹ̀ náà dùbúlẹ̀ sí kalẹ̀. 5 Nígbà tí Jésù rí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní,+ ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Ọmọ, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 6 Àwọn akọ̀wé òfin kan wà níbẹ̀, wọ́n jókòó, wọ́n ń rò ó lọ́kàn pé:+ 7 “Kí ló dé tí ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀ báyìí? Ọ̀rọ̀ òdì ló ń sọ. Ta ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini yàtọ̀ sí Ọlọ́run nìkan?”+ 8 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù fòye mọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ pé ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn nìyẹn, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro àwọn nǹkan yìí lọ́kàn yín?+ 9 Èwo ló rọrùn jù, láti sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa rìn’? 10 Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn+ ní àṣẹ láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini láyé—”+ ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: 11 “Mò ń sọ fún ọ, Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.” 12 Ló bá dìde, ó gbé ibùsùn rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì rìn jáde níwájú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sọ pé: “A ò rí irú èyí rí.”+

13 Ó tún jáde lọ sétí òkun, gbogbo àwọn èèyàn náà ń rọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn. 14 Bó ṣe ń kọjá lọ, ó tajú kán rí Léfì ọmọ Áfíọ́sì tó jókòó sí ọ́fíìsì àwọn agbowó orí, ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” Ló bá dìde, ó sì tẹ̀ lé e.+ 15 Lẹ́yìn náà, nígbà tó ń jẹun* nílé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun,* torí pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń tẹ̀ lé e.+ 16 Àmọ́ nígbà tí àwọn akọ̀wé òfin lára àwọn Farisí rí i pé ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àwọn agbowó orí jẹun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ṣé ó máa ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun ni?” 17 Bí Jésù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ fún wọn pé: “Àwọn tó lókun ò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀. Kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”+

18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀. Torí náà, wọ́n wá, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 19 Jésù sọ fún wọn pé: “Tí ọkọ ìyàwó+ bá ṣì wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó, kò sí ohun tó máa mú kí wọ́n gbààwẹ̀, àbí ó wà? Tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, wọn ò lè gbààwẹ̀. 20 Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n máa wá gbààwẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. 21 Kò sí ẹni tó máa rán ègé aṣọ tí kò tíì sún kì mọ́ ara aṣọ àwọ̀lékè tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, aṣọ tuntun náà máa ya kúrò lára èyí tó ti gbó, ó sì máa ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.+ 22 Bákan náà, kò sí ẹni tó máa rọ wáìnì tuntun sínú àpò awọ tó ti gbó. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, wáìnì tuntun máa bẹ́ awọ náà, wáìnì náà máa dà nù, awọ náà sì máa bà jẹ́. Àmọ́ inú àpò awọ tuntun ni wọ́n máa ń rọ wáìnì tuntun sí.”

23 Bó ṣe ń gba oko ọkà kọjá ní Sábáàtì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn erín ọkà* jẹ bí wọ́n ṣe ń lọ.+ 24 Àwọn Farisí wá sọ fún un pé: “Wò ó! Kí ló dé tí wọ́n ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì?” 25 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe rí ni, nígbà tó ṣaláìní, tí ebi sì ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 26 Nínú ìtàn Ábíátárì+ olórí àlùfáà, bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tó sì jẹ àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,* èyí tí kò bófin mu fún ẹnikẹ́ni láti jẹ àfi àwọn àlùfáà,+ tó sì tún fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ lára rẹ̀?” 27 Ó wá sọ fún wọn pé: “A dá Sábáàtì torí èèyàn,+ a ò dá èèyàn torí Sábáàtì. 28 Torí náà, Ọmọ èèyàn ni Olúwa, àní Olúwa Sábáàtì.”+

3 Ó tún wọ inú sínágọ́gù kan, ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sì wà níbẹ̀.+ 2 Wọ́n wá ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì, wọ́n ń wò ó bóyá ó máa wo ọkùnrin náà sàn ní Sábáàtì, kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án. 3 Ó sọ fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé: “Dìde, máa bọ̀ ní àárín.” 4 Lẹ́yìn náà, ó bi wọ́n pé: “Ṣé ó bófin mu ní Sábáàtì láti ṣe rere tàbí láti ṣe ibi, láti gba ẹ̀mí* là tàbí láti pa á?”+ Àmọ́ wọn ò sọ̀rọ̀. 5 Lẹ́yìn tó wò wọ́n yí ká tìbínútìbínú, tí ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi torí pé ọkàn wọn ti yigbì,+ ó sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó na ọwọ́ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. 6 Ni àwọn Farisí bá jáde lọ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù+ gbìmọ̀ pọ̀, kí wọ́n lè pa á.

7 Àmọ́ Jésù kúrò níbẹ̀ lọ sí òkun, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti Gálílì àti Jùdíà sì tẹ̀ lé e.+ 8 Kódà, nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣe, wọ́n wá bá a láti Jerúsálẹ́mù, Ídúmíà, òdìkejì Jọ́dánì àti agbègbè Tírè àti Sídónì. 9 Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bá òun ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan, kí àwọn èrò náà má bàa há òun mọ́. 10 Torí pé ó wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn, gbogbo àwọn tí àìsàn wọn le gan-an ń ṣùrù bò ó kí wọ́n lè fọwọ́ kàn án.+ 11 Nígbàkigbà tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́+ pàápàá bá rí i, wọ́n á wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n á sì ké jáde pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”+ 12 Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òun.+

13 Ó gun òkè kan, ó pe àwọn tó fẹ́ yàn,+ wọ́n sì wá bá a.+ 14 Ó wá kó àwọn méjìlá (12) jọ,* ó tún pè wọ́n ní àpọ́sítélì, àwọn yìí ló máa wà pẹ̀lú rẹ̀, tó sì máa rán lọ wàásù, 15 wọ́n máa ní àṣẹ láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.+

16 Àwọn méjìlá (12)+ tó kó jọ* ni Símónì, tó tún pè ní Pétérù,+ 17 Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin Jémíìsì (ó tún ń pe àwọn yìí ní Bóánágè, tó túmọ̀ sí “Àwọn Ọmọ Ààrá”),+ 18 Áńdérù, Fílípì, Bátólómíù, Mátíù, Tọ́másì, Jémíìsì ọmọ Áfíọ́sì, Tádéọ́sì, Símónì tó jẹ́ Kánánéánì* 19 àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ẹni tó dà á lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Lẹ́yìn náà, ó wọ inú ilé kan, 20 àwọn èrò bá tún kóra jọ, débi pé wọn ò ráyè jẹun pàápàá. 21 Àmọ́ nígbà tí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n jáde lọ, kí wọ́n lè mú un, torí wọ́n ń sọ pé: “Orí rẹ̀ ti yí.”+ 22 Bákan náà, àwọn akọ̀wé òfin, tí wọ́n wá láti Jerúsálẹ́mù ń sọ pé: “Ó ní Béélísébúbù,* agbára alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù ló sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+ 23 Torí náà, lẹ́yìn tó pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi àwọn àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Báwo ni Sátánì ṣe lè lé Sátánì jáde? 24 Tí ìjọba kan bá pínyà sí ara rẹ̀, ìjọba yẹn ò ní lè dúró;+ 25 tí ilé kan bá sì pínyà sí ara rẹ̀, ilé yẹn ò ní lè dúró. 26 Bákan náà, tí Sátánì bá dìde, tó ta ko ara rẹ̀, tó sì pínyà, kò ní lè dúró, ṣe ló máa pa run. 27 Àní, kò sí ẹni tó lè wọ ilé ọkùnrin alágbára, tó máa lè jí àwọn ohun ìní rẹ̀, àfi tó bá kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà mọ́lẹ̀. Ìgbà yẹn ló máa tó lè kó o lẹ́rù nínú ilé rẹ̀. 28 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ohun gbogbo la máa dárí rẹ̀ ji àwọn ọmọ èèyàn, ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tí wọ́n bá dá àti ọ̀rọ̀ òdì èyíkéyìí tí wọ́n bá sọ. 29 Àmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kò lè ní ìdáríjì kankan títí láé,+ àmọ́ ó máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àìnípẹ̀kun.”+ 30 Torí wọ́n ń sọ pé: “Ó ní ẹ̀mí àìmọ́,” ló ṣe sọ èyí.+

31 Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ wá, wọ́n dúró síta, wọ́n sì ní kí ẹnì kan lọ pè é wá.+ 32 Torí àwọn èrò jókòó yí i ká, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ wà níta, wọ́n ń béèrè rẹ.”+ 33 Àmọ́ ó dá wọn lóhùn pé: “Ta ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi?” 34 Ó wá wo àwọn tó jókòó yí i ká, ó sì sọ pé: “Ẹ wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi!+ 35 Ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹni yẹn ni arákùnrin mi, arábìnrin mi àti ìyá mi.”+

4 Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni létí òkun, èrò rẹpẹtẹ sì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Torí náà, ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì jókòó sínú rẹ̀, ó sún kúrò ní etíkun, àmọ́ gbogbo àwọn èrò náà wà ní èbúté, létí òkun.+ 2 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi àpèjúwe kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan,+ bó ṣe ń kọ́ wọn, ó sọ fún wọn pé:+ 3 “Ẹ fetí sílẹ̀. Ẹ wò ó! Afúnrúgbìn jáde lọ fún irúgbìn.+ 4 Bó ṣe ń fún irúgbìn, díẹ̀ já bọ́ sí etí ọ̀nà, àwọn ẹyẹ wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. 5 Àwọn míì já bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyẹ̀pẹ̀, wọ́n sì hù lójú ẹsẹ̀ torí pé iyẹ̀pẹ̀ náà ò jìn.+ 6 Àmọ́ nígbà tí oòrùn ràn, ó jó wọn gbẹ, wọ́n sì rọ torí pé wọn ò ní gbòǹgbò. 7 Àwọn irúgbìn míì já bọ́ sáàárín ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà yọ, wọ́n fún wọn pa, wọn ò sì so èso kankan.+ 8 Àmọ́ àwọn míì bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa, wọ́n dàgbà, wọ́n pọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í so èso, wọ́n ń so ní ìlọ́po ọgbọ̀n (30), ọgọ́ta (60) àti ọgọ́rùn-ún (100).”+ 9 Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Kí ẹni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+

10 Nígbà tó wà ní òun nìkan, àwọn tó yí i ká pẹ̀lú àwọn Méjìlá náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi í nípa àwọn àpèjúwe náà.+ 11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin la jẹ́ kó mọ àṣírí mímọ́+ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ àpèjúwe ni gbogbo nǹkan jẹ́ fún àwọn tó wà ní òde,+ 12 kó lè jẹ́ pé, bí wọ́n tiẹ̀ ń wò, wọ́n lè máa wò, síbẹ̀ kí wọ́n má ṣe rí àti pé bí wọ́n tiẹ̀ ń gbọ́, wọ́n lè gbọ́, síbẹ̀ kó má sì yé wọn; wọn ò sì ní yí pa dà láé, kí wọ́n sì rí ìdáríjì.”+ 13 Bákan náà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ò mọ àpèjúwe yìí, báwo wá lẹ ṣe máa lóye gbogbo àpèjúwe yòókù?

14 “Afúnrúgbìn fún irúgbìn ọ̀rọ̀ náà.+ 15 Torí náà, àwọn yìí ni àwọn tó bọ́ sí etí ọ̀nà, níbi tí a gbin ọ̀rọ̀ náà sí; àmọ́ gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ, Sátánì wá,+ ó sì mú ọ̀rọ̀ tí a gbìn sínú wọn kúrò.+ 16 Bákan náà, àwọn yìí ló bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta; gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á.+ 17 Síbẹ̀, wọn ò ta gbòǹgbò nínú ara wọn, àmọ́ wọ́n ń bá a lọ fúngbà díẹ̀; gbàrà tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n kọsẹ̀. 18 Àwọn míì wà tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún. Àwọn yìí ló ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,+ 19 àmọ́ àníyàn+ ètò àwọn nǹkan yìí,* agbára ìtannijẹ ọrọ̀+ àti ìfẹ́ + gbogbo nǹkan míì gbà wọ́n lọ́kàn, wọ́n fún ọ̀rọ̀ náà pa, kò sì so èso. 20 Níkẹyìn, àwọn tó bọ́ sórí iyẹ̀pẹ̀ tó dáa ni àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n fi ọkàn rere gbà á, tí wọ́n sì ń so èso ní ìlọ́po ọgbọ̀n (30), ọgọ́ta (60) àti ọgọ́rùn-ún (100).”+

21 Ó tún sọ fún wọn pé: “A kì í gbé fìtílà wá, ká wá gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀* tàbí sábẹ́ ibùsùn, àbí? Ṣebí tí wọ́n bá gbé e wá, orí ọ̀pá fìtílà ni wọ́n máa ń gbé e sí?+ 22 Torí kò sí nǹkan tí a fi pa mọ́ tí a kò ní tú síta; kò sí ohun tí a rọra tọ́jú tí kò ní hàn sí gbangba.+ 23 Kí ẹnikẹ́ni tó bá ní etí láti gbọ́, fetí sílẹ̀.”+

24 Ó tún sọ fún wọn pé: “Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ̀ ń gbọ́.+ Òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n la máa fi díwọ̀n fún yín, àní, a máa fi kún un fún yín. 25 Torí ẹnikẹ́ni tó bá ní, a máa fi kún ohun tó ní,+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tí kò bá ní, a máa gba ohun tó ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+

26 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Lọ́nà yìí, Ìjọba Ọlọ́run dà bí ìgbà tí ẹnì kan fún irúgbìn sórí ilẹ̀. 27 Ó sùn ní alẹ́, ó sì dìde ní àárọ̀, irúgbìn náà rú jáde, ó sì dàgbà, àmọ́ kò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀. 28 Ilẹ̀ náà mú èso jáde fúnra rẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun ọ̀gbìn náà kọ́kọ́ yọ, lẹ́yìn náà erín ọkà,* nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èso jáde lódindi nínú erín ọkà. 29 Àmọ́ gbàrà tí èso náà tó kórè, ó ti dòjé bọ̀ ọ́, torí àkókò ìkórè ti dé.”

30 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Kí la lè fi Ìjọba Ọlọ́run wé, àbí àpèjúwe wo la lè fi ṣàlàyé rẹ̀? 31 Ó dà bíi hóró músítádì, tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n gbìn ín sínú ilẹ̀, òun ló kéré jù lọ nínú gbogbo irúgbìn tó wà láyé.+ 32 Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbìn ín, ó dàgbà, ó sì tóbi ju gbogbo ọ̀gbìn oko yòókù lọ, ó yọ àwọn ẹ̀ka ńláńlá, débi pé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run wá ń gbé lábẹ́ òjìji rẹ̀.”

33 Ó fi ọ̀pọ̀ irú àwọn àpèjúwe+ yẹn bá wọn sọ̀rọ̀, débi tí wọ́n lè fetí sílẹ̀ dé. 34 Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìlo àpèjúwe, àmọ́ ó máa ń ṣàlàyé gbogbo nǹkan fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láwọn nìkan.+

35 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká sọdá sí èbúté kejì.”+ 36 Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ní kí àwọn èrò náà máa lọ, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi náà gbé e, bó ṣe wà níbẹ̀, àwọn ọkọ̀ ojú omi míì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 37 Ìjì líle kan tó ń fẹ́ atẹ́gùn gidigidi wá bẹ̀rẹ̀ sí í jà, ìgbì òkun sì ń rọ́ wọnú ọkọ̀ ojú omi náà ṣáá, débi pé omi fẹ́rẹ̀ẹ́ kún inú ọkọ̀ náà.+ 38 Àmọ́ ó wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó ń sùn lórí ìrọ̀rí.* Wọ́n wá jí i, wọ́n sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, ṣé bí a ṣe fẹ́ ṣègbé yìí ò ká ọ lára ni?” 39 Ló bá dìde, ó bá ìjì náà wí, ó sì sọ fún òkun pé: “Ó tó! Dákẹ́ jẹ́ẹ́!”+ Ìjì náà bá rọlẹ̀, gbogbo ẹ̀ sì pa rọ́rọ́. 40 Ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín* tó báyìí? Ṣé ẹ ò tíì ní ìgbàgbọ́ rárá ni?” 41 Àmọ́ ẹ̀rù bà wọ́n lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì sọ fúnra wọn pé: “Ta lẹni yìí gan-an? Ìjì àti òkun pàápàá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.”+

5 Lẹ́yìn náà, wọ́n dé òdìkejì òkun, ní agbègbè àwọn ará Gérásà.+ 2 Gbàrà tí Jésù sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi, ọkùnrin kan tí ẹ̀mí àìmọ́ ń dà láàmú wá pàdé rẹ̀ láti àárín àwọn ibojì.* 3 Àárín àwọn ibojì ló máa ń wà, títí di àkókò yẹn, ẹnì kankan ò lè dè é pinpin, wọn ò lè fi ẹ̀wọ̀n dè é pàápàá. 4 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n dè é, àmọ́ ṣe ló já ẹ̀wọ̀n náà pàrà, tó sì já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ náà sí wẹ́wẹ́; kò sí ẹni tó lágbára láti kápá rẹ̀. 5 Tọ̀sántòru ló ń ké ṣáá láwọn ibojì àti àwọn òkè, ó sì máa ń fi àwọn òkúta ya ara rẹ̀ yánnayànna. 6 Àmọ́ bó ṣe tajú kán rí Jésù ní ọ̀ọ́kán, ó sáré lọ forí balẹ̀ fún un.+ 7 Ó sì ké jáde pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Fi Ọlọ́run búra fún mi pé o ò ní dá mi lóró.”+ 8 Torí Jésù ti ń sọ fún un pé: “Jáde nínú ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́.”+ 9 Àmọ́ Jésù bi í pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó fèsì pé: “Líjíónì lorúkọ mi, torí a pọ̀.” 10 Ó ṣáà ń bẹ Jésù pé kó má ṣe lé àwọn ẹ̀mí náà jáde kúrò ní ilẹ̀ náà.+

11 Ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀wọ́ àwọn ẹlẹ́dẹ̀+ tó pọ̀ ń jẹun níbẹ̀ níbi òkè.+ 12 Torí náà, àwọn ẹ̀mí náà bẹ̀ ẹ́ pé: “Lé wa lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ká lè wọnú wọn.” 13 Torí náà, ó gbà wọ́n láyè. Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bá jáde, wọ́n sì wọnú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ọ̀wọ́ ẹran náà rọ́ kọjá ní etí òkè* sínú òkun, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ni wọ́n, wọ́n sì kú sínú òkun. 14 Àmọ́ àwọn tó ń dà wọ́n sá lọ, wọ́n sì ròyìn rẹ̀ nínú ìlú àti ní ìgbèríko, àwọn èèyàn sì wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀.+ 15 Torí náà, wọ́n wá bá Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà, ẹni tí líjíónì wà nínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó jókòó, ó ti wọṣọ, orí rẹ̀ sì ti wálé, ni ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. 16 Bákan náà, àwọn tí wọ́n rí i ròyìn fún wọn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu náà àti àwọn ẹlẹ́dẹ̀. 17 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jésù pé kó kúrò ní agbègbè wọn.+

18 Bó ṣe ń wọ ọkọ̀ ojú omi, ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu tẹ́lẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí òun tẹ̀ lé e.+ 19 Àmọ́ kò gbà fún un, ṣe ló sọ fún un pé: “Máa lọ sílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà* ti ṣe fún ọ àti bó ṣe ṣàánú rẹ.” 20 Ọkùnrin náà lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kéde gbogbo ohun tí Jésù ṣe fún un ní Dekapólì,* ẹnu sì ya gbogbo èèyàn.

21 Lẹ́yìn tí Jésù tún fi ọkọ̀ ojú omi sọdá sí èbúté tó wà ní òdìkejì, èrò rẹpẹtẹ kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wà létí òkun.+ 22 Ọ̀kan nínú àwọn alága sínágọ́gù, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù wá, nígbà tó sì tajú kán rí i, ó wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 23 Ó bẹ̀ ẹ́ léraléra, ó ní: “Ọmọbìnrin mi kékeré ń ṣàìsàn gidigidi.* Jọ̀ọ́, wá gbé ọwọ́ rẹ lé e+ kí ara rẹ̀ lè yá, kó má sì kú.” 24 Jésù wá tẹ̀ lé e, èrò rẹpẹtẹ sì ń rọ́ tẹ̀ lé e, wọ́n fún mọ́ ọn.

25 Obìnrin kan wà tó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀+ fún ọdún méjìlá (12).+ 26 Ó ti jìyà gan-an* lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ oníṣègùn, ó sì ti ná gbogbo ohun tó ní, àmọ́ kàkà kí ara rẹ̀ yá, ṣe ló ń burú sí i. 27 Nígbà tó gbọ́ ìròyìn nípa Jésù, ó gba àárín èrò wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ 28 torí ó ń sọ ṣáá pé: “Tí mo bá fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi á yá.”+ 29 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gbẹ láú, ó sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àìsàn burúkú tó ń ṣe òun ti lọ.

30 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù mọ̀ ọ́n lára pé agbára+ ti jáde lára òun, ó wá yíjú pa dà láàárín èrò náà, ó sì béèrè pé: “Ta ló fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè mi?”+ 31 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “O rí i tí èrò ń fún mọ́ ọ, o wá ń béèrè pé, ‘Ta ló fọwọ́ kàn mí?’” 32 Ṣùgbọ́n ó ń wò yí ká kó lè rí ẹni tó fọwọ́ kàn án. 33 Ẹ̀rù ba obìnrin náà, jìnnìjìnnì sì bò ó, torí ó ti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun, ó wá wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òótọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. 34 Ó dá a lóhùn pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà,+ kí àìsàn burúkú tó ń ṣe ọ́ sì lọ.”+

35 Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin kan láti ilé alága sínágọ́gù wá, wọ́n sì sọ pé: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú! Kí ló dé tí o ṣì ń yọ Olùkọ́ lẹ́nu?”+ 36 Àmọ́ Jésù fetí kọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ, ó sì sọ fún alága sínágọ́gù náà pé: “Má bẹ̀rù,* ṣáà ti ní ìgbàgbọ́.”+ 37 Kò jẹ́ kí ẹnì kankan tẹ̀ lé òun, àfi Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù arákùnrin Jémíìsì.+

38 Wọ́n sì dé ilé alága sínágọ́gù náà, ó rí i tí ariwo ń sọ, tí àwọn èèyàn ń sunkún, tí wọ́n sì ń pohùn réré ẹkún gidigidi,+ 39 Lẹ́yìn tó wọlé, ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ sì ń pariwo báyìí? Ọmọ náà ò tíì kú, ó ń sùn ni.”+ 40 Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń fi ṣẹlẹ́yà. Àmọ́ lẹ́yìn tó ní kí gbogbo wọn bọ́ síta, ó mú bàbá àti ìyá ọmọ náà àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wọlé síbi tí ọmọ náà wà. 41 Ó wá di ọwọ́ ọmọ náà mú, ó sì sọ fún un pé: “Tàlítà kumì,” tó túmọ̀ sí: “Ọmọbìnrin, mo sọ fún ọ, dìde!”+ 42 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọmọbìnrin náà dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn. (Ọmọ ọdún méjìlá [12] ni.) Lójú ẹsẹ̀, ṣe ni inú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í dùn gidigidi. 43 Àmọ́ ó kìlọ̀ fún wọn léraléra* pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohun tó ṣẹlẹ̀,+ ó sì ní kí wọ́n fún ọmọbìnrin náà ní nǹkan tó máa jẹ.

6 Ó kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí agbègbè ìlú rẹ̀,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀ lé e. 2 Nígbà tó di Sábáàtì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni nínú sínágọ́gù, ẹnu ya ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan yìí?+ Kí nìdí tí a fi fún un ní irú ọgbọ́n yìí, tí a sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí?+ 3 Ṣebí káfíńtà yẹn nìyí,+ ọmọ Màríà,+ tó tún jẹ́ arákùnrin Jémíìsì,+ Jósẹ́fù, Júdásì àti Símónì,+ àbí òun kọ́? Àwọn arábìnrin rẹ̀ sì wà níbí pẹ̀lú wa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọsẹ̀ nítorí rẹ̀. 4 Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: “Wòlíì máa ń níyì, àmọ́ kì í gbayì ní ìlú rẹ̀, láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”+ 5 Torí náà, kò lè ṣe iṣẹ́ agbára kankan níbẹ̀, ó kàn gbé ọwọ́ rẹ̀ lé díẹ̀ lára àwọn aláìsàn, ó sì wò wọ́n sàn. 6 Ó yà á lẹ́nu pé wọn ò nígbàgbọ́. Ó sì lọ yí ká àwọn abúlé náà, ó ń kọ́ni.+

7 Ó wá pe àwọn Méjìlá náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rán wọn jáde ní méjì-méjì,+ ó sì fún wọn láṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí àìmọ́.+ 8 Ó tún pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe gbé ohunkóhun dání fún ìrìn àjò náà, àfi ọ̀pá, kí wọ́n má ṣe gbé oúnjẹ àti àpò oúnjẹ, kí wọ́n má sì kó owó* sínú àmùrè owó wọn,+ 9 àmọ́ kí wọ́n wọ bàtà, kí wọ́n má sì wọ aṣọ méjì.* 10 Bákan náà, ó sọ fún wọn pé: “Ibikíbi tí ẹ bá ti wọ ilé kan, kí ẹ dúró síbẹ̀ títí ẹ máa fi kúrò níbẹ̀.+ 11 Níbikíbi tí wọn ò bá sì ti gbà yín tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, tí ẹ bá ń kúrò níbẹ̀, ẹ gbọn iyẹ̀pẹ̀ tó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ yín dà nù, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.”+ 12 Torí náà, wọ́n gbéra, wọ́n sì ń wàásù pé kí àwọn èèyàn ronú pìwà dà,+ 13 wọ́n lé ẹ̀mí èṣù púpọ̀ jáde,+ wọ́n fi òróró pa àwọn aláìsàn lára, wọ́n sì wò wọ́n sàn.

14 Ọba Hẹ́rọ́dù wá gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, torí òkìkí orúkọ Jésù ti kàn káàkiri, àwọn èèyàn sì ń sọ pé: “A ti jí Jòhánù Onírìbọmi dìde, ìdí nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+ 15 Àmọ́ àwọn míì ń sọ pé: “Èlíjà ni.” Síbẹ̀, àwọn míì ń sọ pé: “Ó dà bí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́.”+ 16 Àmọ́ nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́, ó sọ pé: “Jòhánù tí mo bẹ́ lórí, òun ló ti jíǹde yìí.” 17 Torí Hẹ́rọ́dù fúnra rẹ̀ ti ránṣẹ́ pé kí wọ́n lọ mú Jòhánù, ó sì dè é sínú ẹ̀wọ̀n nítorí Hẹrodíà ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀, torí ó ti fẹ́ obìnrin náà.+ 18 Jòhánù sì ti ń sọ fún Hẹ́rọ́dù pé: “Kò bófin mu fún ọ láti fẹ́ ìyàwó arákùnrin rẹ.”+ 19 Hẹrodíà wá dì í sínú, ó sì fẹ́ pa á, àmọ́ kò rí i ṣe. 20 Hẹ́rọ́dù bẹ̀rù Jòhánù, ó mọ̀ pé olódodo ni, èèyàn mímọ́ sì ni,+ torí náà, ó ń dáàbò bò ó. Lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò mọ ohun tó máa ṣe rárá, síbẹ̀ tayọ̀tayọ̀ ló máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

21 Àmọ́ àyè ṣí sílẹ̀ ní ọjọ́ tí Hẹ́rọ́dù ń ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀.+ Ó se àsè oúnjẹ alẹ́ fún àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọkùnrin tó gbajúmọ̀ jù ní Gálílì.+ 22 Ọmọbìnrin Hẹrodíà wá wọlé, ó jó, ó sì múnú Hẹ́rọ́dù àti àwọn tó ń bá a jẹun* dùn. Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé: “Bi mí ní ohunkóhun tí o bá fẹ́, màá sì fún ọ.” 23 Àní, ó búra fún un pé: “Ohunkóhun tí o bá bi mí, màá fún ọ, títí dórí ìdajì ìjọba mi.” 24 Ọmọbìnrin náà wá jáde lọ, ó sì sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Kí ni kí n béèrè?” Ó sọ pé: “Orí Jòhánù Onírìbọmi.” 25 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọmọbìnrin náà yára wọlé lọ sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ ohun tó fẹ́, ó ní: “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Jòhánù Arinibọmi nínú àwo pẹrẹsẹ ní báyìí.”+ 26 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dun ọba gan-an, kò fẹ́ ṣàìka ohun tó béèrè sí, torí pé ó ti búra àti torí àwọn àlejò rẹ̀.* 27 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọba rán ẹ̀ṣọ́ kan, ó sì pàṣẹ pé kó lọ gbé orí Jòhánù wá. Torí náà, ó lọ, ó bẹ́ ẹ lórí nínú ẹ̀wọ̀n, 28 ó sì gbé orí rẹ̀ wá nínú àwo pẹrẹsẹ. Ó gbé e fún ọmọbìnrin náà, ọmọbìnrin náà sì gbé e fún ìyá rẹ̀. 29 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì.*

30 Àwọn àpọ́sítélì kóra jọ yí Jésù ká, wọ́n sì ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ṣe, tí wọ́n sì fi kọ́ni fún un.+ 31 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá ní ẹ̀yin nìkan, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.”+ Torí ọ̀pọ̀ ló ń wá, tí wọ́n sì ń lọ, wọn ò sì ní àkókò kankan tí ọwọ́ wọn dilẹ̀, kódà, wọn ò ráyè jẹun. 32 Torí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ síbi tó dá, tí àwọn nìkan máa wà.+ 33 Àmọ́ àwọn èèyàn rí wọn bí wọ́n ṣe ń lọ, ọ̀pọ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwọn èèyàn láti gbogbo ìlú sì fi ẹsẹ̀ sáré dé ibẹ̀ ṣáájú wọn. 34 Nígbà tó jáde, ó rí èrò rẹpẹtẹ, àánú wọn sì ṣe é,+ torí wọ́n dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.+ Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.+

35 Ọjọ́ ti ń lọ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ibí yìí dá, ọjọ́ sì ti lọ.+ 36 Ní kí wọ́n máa lọ, kí wọ́n lè lọ sí ìgbèríko àti àwọn abúlé tó wà ní àyíká, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n máa jẹ.”+ 37 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fún wọn ní nǹkan tí wọ́n máa jẹ.” Ni wọ́n bá fèsì pé: “Ṣé ká lọ ra búrẹ́dì igba (200) owó dínárì,* ká sì fún àwọn èèyàn yìí jẹ?”+ 38 Ó sọ fún wọn pé: “Búrẹ́dì mélòó lẹ ní? Ẹ lọ wò ó!” Lẹ́yìn tí wọ́n wò ó, wọ́n sọ pé: “Márùn-ún, pẹ̀lú ẹja méjì.”+ 39 Ó wá sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko tútù ní àwùjọ-àwùjọ.+ 40 Torí náà, wọ́n jókòó* ní àwùjọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti àràádọ́ta. 41 Ó wá mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre.+ Lẹ́yìn náà, ó bu àwọn búrẹ́dì náà sí wẹ́wẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n gbé e síwájú àwọn èèyàn náà, ó sì pín ẹja méjì náà fún gbogbo wọn. 42 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, 43 wọ́n sì kó èyí tó ṣẹ́ kù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá (12), yàtọ̀ sí àwọn ẹja náà.+ 44 Àwọn tó jẹ búrẹ́dì náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin.

45 Láìjáfara, ó mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì ṣáájú rẹ̀ lọ sí etíkun tó wà ní òdìkejì lápá Bẹtisáídà, òun fúnra rẹ̀ sì ní kí àwọn èrò náà máa lọ.+ 46 Lẹ́yìn tó kí wọn pé ó dàbọ̀, ó lọ sórí òkè lọ gbàdúrà.+ 47 Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, ọkọ̀ ojú omi náà ti wà ní àárín òkun, àmọ́ òun nìkan ló wà lórí ilẹ̀.+ 48 Nígbà tó rí i bí wọ́n ṣe ń tiraka láti tukọ̀, torí atẹ́gùn ń dà wọ́n láàmú, ní nǹkan bí ìṣọ́ kẹrin òru,* ó wá sápá ọ̀dọ̀ wọn, ó ń rìn lórí òkun; àmọ́ ó fẹ́* gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá. 49 Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tó ń rìn lórí òkun, wọ́n rò pé: “Ìran abàmì ni!” Wọ́n bá kígbe. 50 Torí gbogbo wọn rí i, ọkàn wọn ò balẹ̀. Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ mọ́kàn le! Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”+ 51 Ó wá wọnú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú wọn, atẹ́gùn náà sì rọlẹ̀. Èyí yà wọ́n lẹ́nu gan-an, 52 torí wọn ò tíì mọ ohun tí búrẹ́dì náà túmọ̀ sí, ọkàn wọn ò sì tíì ní òye.

53 Nígbà tí wọ́n sọdá sórí ilẹ̀, wọ́n dé Jẹ́nẹ́sárẹ́tì, wọ́n sì dá ọkọ̀ náà ró sí tòsí.+ 54 Àmọ́ gbàrà tí wọ́n jáde nínú ọkọ̀ ojú omi náà, àwọn èèyàn dá a mọ̀. 55 Wọ́n sáré yí ká gbogbo agbègbè yẹn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn tó ń ṣàìsàn wá lórí ibùsùn síbi tí wọ́n gbọ́ pé ó wà. 56 Níbikíbi tó bá sì ti wọ àwọn abúlé, ìlú tàbí ìgbèríko, wọ́n máa gbé àwọn aláìsàn sí àwọn ibi tí wọ́n ti ń tajà, wọ́n á sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí wọ́n fọwọ́ kan wajawaja etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán.+ Ara gbogbo àwọn tó fọwọ́ kàn án sì yá.

7 Àwọn Farisí àti àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n wá láti Jerúsálẹ́mù kóra jọ yí i ká.+ 2 Wọ́n sì rí i tí àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, ìyẹn ọwọ́ tí wọn ò wẹ̀.* 3 (Torí àwọn Farisí àti gbogbo àwọn Júù kì í jẹun láìwẹ ọwọ́ wọn títí dé ìgúnpá, wọ́n rin kinkin mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn àtijọ́, 4 tí wọ́n bá sì ti ọjà dé, wọn kì í jẹun àfi tí wọ́n bá wẹ ara wọn. Ọ̀pọ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ míì wà tí wọ́n gbà, tí wọ́n sì rin kinkin mọ́, irú bí ìbatisí àwọn ife, ṣágo àti àwọn ohun èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe.)+ 5 Àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin yìí wá bi í pé: “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn àtijọ́, àmọ́ tí wọ́n ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”+ 6 Ó sọ fún wọn pé: “Bí Àìsáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀yin alágàbàgebè ló rí gẹ́lẹ́, ó kọ ọ́ pé, ‘Àwọn èèyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi.+ 7 Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, torí pé àṣẹ èèyàn ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni.’+ 8 Ẹ pa àṣẹ Ọlọ́run tì, ẹ wá ń rin kinkin mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn èèyàn.”+

9 Ó tún sọ fún wọn pé: “Ẹ̀ ń dọ́gbọ́n kọ àṣẹ Ọlọ́run sílẹ̀ kí ẹ lè máa tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín.+ 10 Bí àpẹẹrẹ, Mósè sọ pé, ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,’+ àti pé, ‘Kí ẹ pa ẹni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí* bàbá tàbí ìyá rẹ̀.’+ 11 Àmọ́ ẹ sọ pé, ‘Tí ọkùnrin kan bá sọ fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Kọ́bánì (ìyẹn, ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run) ni ohunkóhun tí mo ní tó lè ṣe yín láǹfààní,”’ 12 ẹ kì í jẹ́ kó ṣe ohunkóhun fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀ mọ́.+ 13 Ẹ̀ ń tipa bẹ́ẹ̀ fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín, tí ẹ fi lé àwọn èèyàn lọ́wọ́, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.+ Ọ̀pọ̀ irú nǹkan báyìí lẹ sì ń ṣe.”+ 14 Torí náà, ó tún pe àwọn èrò náà jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín, ẹ fetí sí mi, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì yé yín.+ 15 Kò sí ohun kankan tó wá láti òde ara èèyàn tó sì wọnú rẹ̀ tó lè sọ ọ́ di aláìmọ́; àmọ́ àwọn ohun tó ń jáde látinú èèyàn ló ń sọ èèyàn di aláìmọ́.”+ 16* ——

17 Nígbà tó kúrò lọ́dọ̀ àwọn èrò náà, tó wọ inú ilé kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bi í nípa àpèjúwe náà.+ 18 Torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ṣé kò yé ẹ̀yin náà bíi tiwọn ni? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé kò sí ohun kankan tó wá láti òde ara èèyàn tó sì wọnú rẹ̀ tó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, 19 torí pé inú ọkàn rẹ̀ kọ́ ló wọ̀, inú ikùn rẹ̀ ni, ó sì máa yà á jáde sínú kòtò ẹ̀gbin?” Ó tipa bẹ́ẹ̀ kéde pé gbogbo oúnjẹ ló mọ́. 20 Ó tún sọ pé: “Ohun tó ń tinú èèyàn jáde ló ń sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 21 Torí láti inú, láti ọkàn àwọn èèyàn,+ ni àwọn èrò burúkú ti ń wá: ìṣekúṣe,* olè jíjà, ìpànìyàn, 22 àwọn ìwà àgbèrè, ojúkòkòrò, àwọn ìwà burúkú, ẹ̀tàn, ìwà àìnítìjú,* ojú tó ń ṣe ìlara, ọ̀rọ̀ òdì, ìgbéraga àti ìwà òmùgọ̀. 23 Láti inú ni gbogbo nǹkan burúkú yìí ti ń wá, tí wọ́n sì ń sọ èèyàn di aláìmọ́.”

24 Ó gbéra níbẹ̀, ó sì lọ sí agbègbè Tírè àti Sídónì.+ Ó wọ ilé kan níbẹ̀, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa rẹ̀, síbẹ̀ àwọn èèyàn mọ̀. 25 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ní ẹ̀mí àìmọ́ gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì wá wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 26 Ará Gíríìsì ni obìnrin náà, ọmọ* ilẹ̀ Foníṣíà ní Síríà; ó sì ń bẹ̀ ẹ́ ṣáá pé kó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun. 27 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Jẹ́ kí àwọn ọmọ kọ́kọ́ yó ná, torí kò tọ́ ká mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, ká sì jù ú sí àwọn ajá kéékèèké.”+ 28 Àmọ́ obìnrin náà dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni sà, síbẹ̀, àwọn ajá kéékèèké tó wà lábẹ́ tábìlì pàápàá, máa ń jẹ lára èérún tó já bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ kéékèèké.” 29 Ó wá sọ fún un pé: “Torí ohun tí o sọ yìí, máa lọ; ẹ̀mí èṣù náà ti kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”+ 30 Torí náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó sì rí i tí ọmọ kékeré náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, ẹ̀mí èṣù náà ti kúrò lára rẹ̀.+

31 Nígbà tí Jésù pa dà láti agbègbè Tírè, ó gba Sídónì lọ sí Òkun Gálílì, ó gba agbègbè Dekapólì* kọjá.+ 32 Wọ́n mú ọkùnrin adití kan tí kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa wá bá a níbẹ̀,+ wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e. 33 Ó mú ọkùnrin yẹn nìkan kúrò lọ́dọ̀ àwọn èrò náà lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ó ki ìka rẹ̀ bọ etí ọkùnrin náà méjèèjì, lẹ́yìn tó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.+ 34 Ó gbójú sókè ọ̀run, ó mí kanlẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Éfátà,” tó túmọ̀ sí, “Là.” 35 Ni etí ọkùnrin náà bá là,+ kò níṣòro ọ̀rọ̀ sísọ mọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ dáadáa. 36 Àmọ́, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má sọ fún ẹnì kankan,+ síbẹ̀ bó ṣe ń kìlọ̀ fún wọn tó ni wọ́n túbọ̀ ń kéde rẹ̀.+ 37 Lóòótọ́, ẹnu yà wọ́n kọjá sísọ,+ wọ́n sì sọ pé: “Gbogbo nǹkan ló ṣe dáadáa. Ó tiẹ̀ ń mú kí àwọn adití gbọ́ràn, kí àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ sì sọ̀rọ̀.”+

8 Nígbà yẹn, èrò rẹpẹtẹ tún wà, tí wọn ò ní ohunkóhun tí wọ́n máa jẹ. Torí náà, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì sọ fún wọn pé: 2 “Àánú àwọn èèyàn yìí ń ṣe mí,+ torí ọjọ́ kẹta nìyí tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi, tí wọn ò sì ní ohunkóhun tí wọ́n máa jẹ.+ 3 Tí n bá ní kí wọ́n máa lọ sílé láìjẹun,* okun wọn máa tán lójú ọ̀nà, ibi tó jìnnà sì ni àwọn kan lára wọn ti wá.” 4 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé: “Ibo lèèyàn ti máa rí oúnjẹ tó máa tó bọ́ àwọn èèyàn yìí ní àdádó yìí?” 5 Ó wá bi wọ́n pé: “Búrẹ́dì mélòó lẹ ní?” Wọ́n sọ pé: “Méje.”+ 6 Ó sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó sílẹ̀.* Ó wá mú búrẹ́dì méje náà, ó dúpẹ́, ó bù ú, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n pín in, wọ́n sì pín in fún àwọn èrò náà.+ 7 Wọ́n tún ní ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀, lẹ́yìn tó súre sí i, ó ní kí wọ́n pín ìyẹn náà. 8 Wọ́n sì jẹ, wọ́n yó, ohun tó ṣẹ́ kù tí wọ́n kó jọ sì kún apẹ̀rẹ̀ ńlá* méje.+ 9 Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin ló wà níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n máa lọ.

10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì wá sí agbègbè Dámánútà.+ 11 Àwọn Farisí wá bá a níbẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a jiyàn, wọ́n ní kó fún àwọn ní àmì kan láti ọ̀run, kí wọ́n lè dán an wò.+ 12 Torí náà, ẹ̀dùn ọkàn bá a gidigidi nínú ẹ̀mí rẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ló dé tí ìran yìí ń wá àmì?+ Lóòótọ́ ni mo sọ, a ò ní fún ìran yìí ní àmì kankan.”+ 13 Ló bá fi wọ́n sílẹ̀, ó sì tún wọ ọkọ̀ lọ sí èbúté tó wà ní òdìkejì.

14 Àmọ́, wọn ò rántí mú búrẹ́dì dání, wọn ò sì ní nǹkan kan pẹ̀lú wọn nínú ọkọ̀ ojú omi, àfi búrẹ́dì kan ṣoṣo.+ 15 Ó wá kìlọ̀ fún wọn lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀; kí ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù.”+ 16 Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn torí pé wọn ò ní búrẹ́dì kankan. 17 Ó kíyè sí i, ó sì sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń jiyàn torí pé ẹ ò ní búrẹ́dì? Ṣé ẹ ò tíì fòye mọ̀, kó sì yé yín ni? Ṣé ọkàn yín ò tíì ní òye ni? 18 ‘Ẹ ní ojú, síbẹ̀ ṣé ẹ ò ríran ni; àti pé ẹ ní etí, síbẹ̀ ṣé ẹ ò gbọ́ ni?’ Ṣé ẹ ò rántí ni, 19 nígbà tí mo bu búrẹ́dì márùn-ún+ fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ mélòó lẹ kó jọ látinú ohun tó ṣẹ́ kù?” Wọ́n dáhùn pé: “Méjìlá (12).”+ 20 “Nígbà tí mo bu búrẹ́dì méje fún ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ ńlá* mélòó lẹ kó jọ látinú ohun tó ṣẹ́ kù?” Wọ́n sọ fún un pé: “Méje.”+ 21 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé kò tíì yé yín náà ni?”

22 Nígbà náà, wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹtisáídà. Ibẹ̀ làwọn èèyàn ti mú ọkùnrin afọ́jú kan wá bá a, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fọwọ́ kàn án.+ 23 Ó wá fa ọkùnrin afọ́jú náà lọ́wọ́ jáde sẹ́yìn abúlé náà. Lẹ́yìn tó tutọ́ sí ojú rẹ̀,+ ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì bi í pé: “Ṣé o rí nǹkan kan?” 24 Ọkùnrin náà gbójú sókè, ó sọ pé: “Mo rí àwọn èèyàn, àmọ́ wọ́n dà bí igi tó ń rìn káàkiri.” 25 Ló bá tún gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú ọkùnrin náà, ọkùnrin náà wá ríran dáadáa. Ojú rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí í ríran, ó sì ń rí gbogbo nǹkan kedere. 26 Torí náà, ó ní kó máa lọ sílé, ó sọ fún un pé: “Má wọ inú abúlé.”

27 Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá lọ sí àwọn abúlé Kesaríà Fílípì, ó sì ń bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú ọ̀nà pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 28 Wọ́n sọ fún un pé: “Jòhánù Arinibọmi,+ àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà,+ àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì.” 29 Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” Pétérù dá a lóhùn pé: “Ìwọ ni Kristi náà.”+ 30 Ó wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má sọ fún ẹnì kankan nípa òun.+ 31 Bákan náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn pé Ọmọ èèyàn gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀, àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin máa kọ̀ ọ́, wọ́n máa pa á,+ ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló sì máa dìde.+ 32 Àní, gbangba ló ti ń sọ ọ̀rọ̀ yẹn. Àmọ́ Pétérù mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí.+ 33 Ló bá yíjú pa dà, ó wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì bá Pétérù wí, ó ní: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi,* Sátánì! torí èrò èèyàn lò ń rò, kì í ṣe ti Ọlọ́run.”+

34 Lẹ́yìn náà, ó pe àwọn èrò àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó gbé òpó igi oró* rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi.+ 35 Torí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ̀ là máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere máa gbà á là.+ 36 Lóòótọ́, àǹfààní wo ni èèyàn máa rí tó bá jèrè gbogbo ayé, tó sì wá pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀?+ 37 Ká sòótọ́, kí ni èèyàn máa fi dípò ẹ̀mí* rẹ̀?+ 38 Torí ẹnikẹ́ni tó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú ìran alágbèrè* àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, Ọmọ èèyàn náà máa tijú rẹ̀+ nígbà tó bá dé nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́.”+

9 Ó tún sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tó dúró síbí yìí tí kò ní tọ́ ikú wò rárá títí wọ́n á fi kọ́kọ́ rí i tí Ìjọba Ọlọ́run ti dé tagbáratagbára.”+ 2 Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání lọ sí orí òkè kan tó ga fíofío láwọn nìkan. A sì yí i pa dà di ológo níwájú wọn;+ 3 aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tàn yinrin, ó di funfun nini ju bí alágbàfọ̀ èyíkéyìí ní ayé ṣe lè sọ ọ́ di funfun. 4 Bákan náà, Èlíjà àti Mósè fara hàn wọ́n, wọ́n sì ń bá Jésù sọ̀rọ̀. 5 Pétérù wá sọ fún Jésù pé: “Rábì, ó dáa bí a ṣe wà níbí. Torí náà, jẹ́ ká pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” 6 Ní tòótọ́, kò mọ ohun tí ì bá ṣe, torí ẹ̀rù bà wọ́n gan-an. 7 Ìkùukùu* wá kóra jọ, ó ṣíji bò wọ́n, ohùn kan+ sì dún látinú ìkùukùu náà pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́.+ Ẹ fetí sí i.”+ 8 Lójijì, wọ́n wò yí ká, wọn ò sì rí ẹnì kankan pẹ̀lú wọn mọ́, àfi Jésù nìkan.

9 Bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látorí òkè náà, ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má sọ ohun tí wọ́n rí fún ẹnì kankan,+ títí dìgbà tí Ọmọ èèyàn bá jí dìde.+ 10 Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn,* àmọ́ wọ́n ń sọ ohun tí àjíǹde náà túmọ̀ sí láàárín ara wọn. 11 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í bi í pé: “Kí ló dé tí àwọn akọ̀wé òfin fi ń sọ pé Èlíjà + gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?”+ 12 Ó sọ fún wọn pé: “Èlíjà máa kọ́kọ́ wá, ó sì máa mú ohun gbogbo pa dà sí bó ṣe yẹ;+ àmọ́ kí wá nìdí tí a fi kọ ọ́ nípa Ọmọ èèyàn pé ó gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀,+ kí wọ́n sì kàn án lábùkù?+ 13 Ní tòótọ́, mò ń sọ fún yín pé Èlíjà+ ti wá, wọ́n sì ṣe ohun tó wù wọ́n sí i, bí a ṣe kọ ọ́ nípa rẹ̀.”+

14 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù, wọ́n rí èrò rẹpẹtẹ tó yí wọn ká, àwọn akọ̀wé òfin sì ń bá wọn jiyàn.+ 15 Àmọ́ gbàrà tí gbogbo àwọn èrò náà tajú kán rí i, ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì sáré lọ kí i. 16 Ó wá bi wọ́n pé: “Kí ni ẹ̀ ń bá wọn jiyàn lé lórí?” 17 Ọ̀kan lára àwọn èrò náà dá a lóhùn pé: “Olùkọ́, mo mú ọmọkùnrin mi wá sọ́dọ̀ rẹ torí ó ní ẹ̀mí kan tí kò jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀.+ 18 Ní ibikíbi tó bá ti mú un, ṣe ló máa ń gbé e ṣánlẹ̀, á sì máa yọ ìfófòó lẹ́nu, á máa wa eyín pọ̀, kò sì ní lókun mọ́. Mo ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ lé e jáde, àmọ́ wọn ò rí i ṣe.” 19 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́,+ títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín? Títí dìgbà wo ni màá fi máa fara dà á fún yín? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi.”+ 20 Wọ́n bá mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àmọ́ gbàrà tó rí i, ṣe ni ẹ̀mí náà mú kí gìrì mú ọmọ náà lójijì. Lẹ́yìn tó ṣubú lulẹ̀, ó ń yí kiri, ó sì ń yọ ìfófòó lẹ́nu. 21 Jésù wá bi bàbá ọmọ náà pé: “Ó tó ìgbà wo tí nǹkan yìí ti ń ṣe ọmọ yìí?” Ó ní: “Láti kékeré ni, 22 ó máa ń gbé e jù sínú iná àti sínú omi lọ́pọ̀ ìgbà kó lè pa á. Àmọ́ tí o bá lè ṣe ohunkóhun sí i, ṣàánú wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” 23 Jésù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀, ‘Tí o bá lè’! Ó dájú pé ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́.”+ 24 Ojú ẹsẹ̀ ni bàbá ọmọ náà kígbe pé: “Mo ní ìgbàgbọ́! Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!”+

25 Jésù rí i pé èrò rẹpẹtẹ ń yára bọ̀ wá sọ́dọ̀ wọn, ó wá bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sọ fún un pé: “Ìwọ ẹ̀mí tí kò jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀, tó sì di í létí, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò lára rẹ̀, o ò sì gbọ́dọ̀ wọ inú rẹ̀ mọ́!”+ 26 Lẹ́yìn tí ọmọ náà kígbe, tí gìrì náà sì gbé e léraléra, ó jáde, ọmọ náà sì dà bí ẹni tó ti kú, débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ pé: “Ó ti kú!” 27 Àmọ́ Jésù di ọwọ́ rẹ̀ mú, ó gbé e dìde, ó sì dìde. 28 Torí náà, lẹ́yìn tó wọ ilé kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í lóun nìkan pé: “Kí ló dé tí a ò fi lè lé e jáde?”+ 29 Ó sọ fún wọn pé: “Àdúrà nìkan ló lè lé irú èyí jáde.”

30 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sì gba Gálílì kọjá, àmọ́ kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa rẹ̀. 31 Torí ó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń sọ fún wọn pé: “A máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn èèyàn lọ́wọ́, wọ́n sì máa pa á,+ àmọ́ bí wọ́n tiẹ̀ pa á, ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló máa dìde.”+ 32 Àmọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í léèrè.

33 Lẹ́yìn náà, wọ́n dé sí Kápánáúmù. Nígbà tó wà nínú ilé, ó bi wọ́n léèrè pé: “Kí lẹ̀ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?”+ 34 Wọn ò sọ̀rọ̀, torí wọ́n ń jiyàn láàárín ara wọn lójú ọ̀nà nípa ẹni tó tóbi jù. 35 Torí náà, ó jókòó, ó pe àwọn Méjìlá náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, òun ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni ìkẹyìn àti ìránṣẹ́ gbogbo yín.”+ 36 Ó wá mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró ní àárín wọn; ó fi ọwọ́ gbá a mọ́ra, ó sì sọ fún wọn pé: 37 “Ẹnikẹ́ni tó bá gba irú ọmọ kékeré+ yìí nítorí orúkọ mi gba èmi náà; ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí, kì í ṣe èmi nìkan ló gbà, àmọ́ ó tún gba Ẹni tó rán mi.”+

38 Jòhánù sọ fún un pé: “Olùkọ́, a rí ẹnì kan tó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a sì gbìyànjú láti dá a dúró, torí kì í tẹ̀ lé wa.”+ 39 Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹ má gbìyànjú láti dá a dúró, torí kò sí ẹni tó máa fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ agbára kankan tó máa lè yára sọ ohunkóhun tí kò dáa nípa mi. 40 Torí ẹnikẹ́ni tí kò bá ta kò wá, tiwa ló ń ṣe.+ 41 Ẹnikẹ́ni tó bá fún yín ní ife omi mu torí pé ẹ jẹ́ ti Kristi,+ lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé kò ní pàdánù èrè rẹ̀.+ 42 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí tó ní ìgbàgbọ́ kọsẹ̀, ó sàn ká so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, irú èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí, ká sì jù ú sínú òkun.+

43 “Tí ọwọ́ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀ pẹ́nrẹ́n, gé e kúrò. Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní aláàbọ̀ ara ju kí o wọnú Gẹ̀hẹ́nà* pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì, sínú iná tí kò ṣeé pa.+ 44* —— 45 Tí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò. Ó sàn fún ọ láti jogún ìyè ní arọ ju kí a jù ọ́ sínú Gẹ̀hẹ́nà*+ pẹ̀lú ẹsẹ̀ méjèèjì. 46* —— 47 Tí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, sọ ọ́ nù.+ Ó sàn fún ọ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run ní olójú kan ju kí a jù ọ́ sínú Gẹ̀hẹ́nà*+ pẹ̀lú ojú méjèèjì, 48 níbi tí ìdin kì í ti í kú, tí a kì í sì í pa iná.+

49 “Nítorí a gbọ́dọ̀ fi iná dun kálukú bí iyọ̀.+ 50 Iyọ̀ dáa, àmọ́ tí iyọ̀ bá sọ adùn rẹ̀ nù pẹ́nrẹ́n, kí lẹ máa fi mú òun fúnra rẹ̀ dùn?+ Ẹ ní iyọ̀ nínú ara yín,+ kí ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín yín.”+

10 Ó gbéra níbẹ̀ wá sí ààlà ilẹ̀ Jùdíà ní òdìkejì Jọ́dánì, àwọn èrò tún kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn, bó ṣe máa ń ṣe.+ 2 Àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n fẹ́ dán an wò, wọ́n sì bi í bóyá ó bófin mu fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀.+ 3 Ó dá wọn lóhùn pé: “Kí ni Mósè pa láṣẹ fún yín?” 4 Wọ́n sọ pé: “Mósè fàyè gba ká kọ ìwé ẹ̀rí láti lé e lọ, ká sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”+ 5 Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Torí pé ọkàn yín le+ ló ṣe kọ àṣẹ yìí fún yín.+ 6 Ṣùgbọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, ‘Ó dá wọn ní akọ àti abo.+ 7 Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀,+ 8 àwọn méjèèjì á sì di ara kan,’+ tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. 9 Torí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”+ 10 Nígbà tí wọ́n tún wà nínú ilé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí. 11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè,+ ó ti da obìnrin náà, 12 tí obìnrin kan bá sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, lẹ́yìn tó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó ti ṣe àgbèrè.”+

13 Àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè fọwọ́ kàn wọ́n, àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bá wọn wí.+ 14 Nígbà tí Jésù rí èyí, inú bí i, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má sì dá wọn dúró, torí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irú wọn.+ 15 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹnikẹ́ni tí kò bá gba Ìjọba Ọlọ́run bí ọmọdé kò ní wọnú rẹ̀.”+ 16 Ó wá gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.+

17 Bó ṣe ń lọ, ọkùnrin kan sáré wá, ó sì kúnlẹ̀ síwájú rẹ̀, ó bi í pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 18 Jésù sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.+ 19 O mọ àwọn àṣẹ náà pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ o ò gbọ́dọ̀ lu jìbìtì,+ bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.’”+ 20 Ọkùnrin náà sọ fún un pé: “Olùkọ́, gbogbo nǹkan yìí ni mo ti ń ṣe láti ìgbà ọ̀dọ́ mi.” 21 Jésù wò ó, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó wá sọ fún un pé, “Ohun kan wà tí o ò tíì ṣe: Lọ, kí o ta àwọn ohun tí o ní, kí o fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run; kí o wá máa tẹ̀ lé mi.”+ 22 Àmọ́ inú ọkùnrin náà ò dùn torí èsì tó fún un, ó sì fi ìbànújẹ́ kúrò, torí ohun ìní rẹ̀ pọ̀.+

23 Lẹ́yìn tí Jésù wò yí ká, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wo bó ṣe máa ṣòro tó fún àwọn olówó láti wọ Ìjọba Ọlọ́run!”+ 24 Àmọ́ ohun tó sọ ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́nu. Jésù wá sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ wo bó ṣe ṣòro tó láti wọ Ìjọba Ọlọ́run! 25 Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run.”+ 26 Ẹnu túbọ̀ yà wọ́n, wọ́n sì sọ fún un* pé: “Ta ló máa wá lè rígbàlà?”+ 27 Jésù wò wọ́n tààrà, ó sì sọ pé: “Lójú èèyàn, kò ṣeé ṣe, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run, torí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+ 28 Pétérù wá sọ fún un pé: “Wò ó! A ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ti tẹ̀ lé ọ.”+ 29 Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kò sí ẹni tó fi ilé tàbí àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, ìyá, bàbá, àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá sílẹ̀ nítorí mi àti nítorí ìhìn rere,+ 30 tí kò ní gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100) àwọn ilé, àwọn arákùnrin, àwọn arábìnrin, àwọn ìyá, àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni ní báyìí+ àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.* 31 Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ máa di ẹni ìkẹyìn, àwọn ẹni ìkẹyìn sì máa di ẹni àkọ́kọ́.”+

32 Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà sí Jerúsálẹ́mù, Jésù ń lọ níwájú wọn, ẹnu yà wọ́n, àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé e bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù. Ló bá tún pe àwọn Méjìlá náà sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí i fún wọn, ó ní:+ 33 “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un, wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, 34 àwọn yìí máa fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n máa tutọ́ sí i lára, wọ́n máa nà án, wọ́n á sì pa á, àmọ́ ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ló máa dìde.”+

35 Jémíìsì àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè,+ wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, a fẹ́ kí o ṣe ohunkóhun tí a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ fún wa.”+ 36 Ó sọ fún wọn pé: “Kí lẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?” 37 Wọ́n fèsì pé: “Gbà wá láyè ká jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú ògo rẹ.”+ 38 Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ ò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè. Ṣé ẹ lè mu ife tí mò ń mu àbí a lè batisí yín bí a ṣe ń batisí mi?”+ 39 Wọ́n sọ fún un pé: “A lè mu ún.” Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa mu ife tí mò ń mu, a sì máa batisí yín bí a ṣe ń batisí mi.+ 40 Àmọ́ èmi kọ́ ló máa sọ ẹni tó máa jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi tàbí sí òsì mi, ṣùgbọ́n ó máa wà fún àwọn tí a ti ṣètò rẹ̀ fún.”

41 Nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bínú sí Jémíìsì àti Jòhánù.+ 42 Àmọ́ Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn tí wọ́n kà sí* àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, àwọn èèyàn ńlá wọn sì máa ń lo àṣẹ lórí wọn.+ 43 Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín,+ 44 ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú gbogbo yín. 45 Torí Ọmọ èèyàn pàápàá kò wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kó sì fi ẹ̀mí* rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”+

46 Wọ́n wá dé Jẹ́ríkò. Àmọ́ bí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, Báátíméù (ọmọ Tíméù), afọ́jú tó ń ṣe agbe, jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà.+ 47 Nígbà tó gbọ́ pé Jésù ará Násárẹ́tì ni, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe, ó sì ń sọ pé: “Ọmọ Dáfídì,+ Jésù, ṣàánú mi!”+ 48 Ni ọ̀pọ̀ èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, wọ́n ní kó dákẹ́, àmọ́ ṣe ló túbọ̀ ń kígbe pé: “Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 49 Torí náà, Jésù dúró, ó sì sọ pé: “Ẹ pè é wá sọ́dọ̀ mi.” Wọ́n wá pe ọkùnrin afọ́jú náà, wọ́n sọ fún un pé: “Mọ́kàn le! Dìde; ó ń pè ọ́.” 50 Ló bá bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ dà nù, ó fò dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Jésù. 51 Jésù wá sọ fún un pé: “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ọkùnrin afọ́jú náà sọ fún un pé: “Rábónì,* jẹ́ kí n pa dà ríran.” 52 Jésù sì sọ fún un pé: “Máa lọ. Ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pa dà ríran,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e lójú ọ̀nà.

11 Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, Bẹtifágè àti Bẹ́tánì + ní Òkè Ólífì, ó rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde,+ 2 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, bí ẹ bá ṣe ń wọ ibẹ̀, ẹ máa rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* kan tí wọ́n so, èyí tí èèyàn kankan ò jókòó lé rí títí di báyìí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú un wá síbí. 3 Tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe èyí?’ kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò ó, ó sì máa fi ránṣẹ́ pa dà síbí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.’” 4 Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí wọ́n so sí ẹnu ilẹ̀kùn, níta lójú ọ̀nà, wọ́n sì tú u.+ 5 Àmọ́ àwọn kan lára àwọn tó dúró síbẹ̀ sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?” 6 Ohun tí Jésù sọ fún wọn gẹ́lẹ́ ni wọ́n fi dá wọn lóhùn, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.

7 Wọ́n mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ náà wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí rẹ̀, ó sì jókòó sórí rẹ̀.+ 8 Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà, àmọ́ àwọn míì gé àwọn ẹ̀ka igi tó ní ewé látinú pápá.+ 9 Àwọn tó ń lọ níwájú àti àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn sì ń kígbe ṣáá pé: “A bẹ̀ ọ́, gbà là!+ Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!*+ 10 Ìbùkún ni fún Ìjọba Dáfídì bàbá wa tó ń bọ̀!+ A bẹ̀ ọ́, gbà là, ní ibi gíga lókè!” 11 Ó wọ Jerúsálẹ́mù, ó sì lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó wo ohun gbogbo yí ká, àmọ́ torí pé ọjọ́ ti lọ, ó jáde lọ sí Bẹ́tánì pẹ̀lú àwọn Méjìlá náà.+

12 Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n ń kúrò ní Bẹ́tánì, ebi ń pa á.+ 13 Ó wá tajú kán rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tó ní ewé lọ́ọ̀ọ́kán, ó sì lọ wò ó bóyá òun máa rí nǹkan kan lórí rẹ̀. Àmọ́, nígbà tó débẹ̀, kò rí nǹkan kan àfi ewé, torí kì í ṣe àsìkò èso ọ̀pọ̀tọ́. 14 Torí náà, ó sọ fún un pé: “Kí ẹnì kankan má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.”+ Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń gbọ́.

15 Wọ́n wá dé Jerúsálẹ́mù. Ó wọnú tẹ́ńpìlì níbẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn tó ń tajà àti àwọn tó ń rajà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì dojú tábìlì àwọn tó ń pààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tó ń ta àdàbà,+ 16 kò sì jẹ́ kí ẹnì kankan gbé ohun èlò gba tẹ́ńpìlì kọjá. 17 Ó ń kọ́ wọn, ó sì ń sọ fún wọn pé: “Ṣebí a ti kọ ọ́ pé, ‘A ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè’?+ Àmọ́ ẹ ti sọ ọ́ di ihò àwọn olè.”+ 18 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa pa á;+ àmọ́ wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, torí pé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ya gbogbo àwọn èèyàn náà lẹ́nu.+

19 Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, wọ́n kúrò nínú ìlú náà. 20 Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń kọjá lọ ní àárọ̀ kùtù, wọ́n rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ti gbẹ láti gbòǹgbò rẹ̀.+ 21 Pétérù rántí rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Rábì, wò ó! igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o gégùn-ún fún ti gbẹ.”+ 22 Jésù fèsì pé: “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. 23 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ tí kò sì ṣiyèméjì nínú ọkàn rẹ̀, àmọ́ tó ní ìgbàgbọ́ pé ohun tí òun sọ máa rí bẹ́ẹ̀, ó máa rí bẹ́ẹ̀ fún un.+ 24 Ìdí nìyí tí mo fi ń sọ fún yín pé, gbogbo ohun tí ẹ bá gbàdúrà fún, tí ẹ sì béèrè, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, ó sì máa jẹ́ tiyín.+ 25 Nígbà tí ẹ bá dúró láti gbàdúrà, ẹ dárí ji ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkóhun lòdì sí, kí Baba yín tó wà ní ọ̀run náà lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.”+ 26* ——

27 Wọ́n tún wá sí Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe ń rìn nínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà wá, 28 wọ́n sì bi í pé: “Àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Àbí ta ló fún ọ ní àṣẹ yìí pé kí o máa ṣe àwọn nǹkan yìí?”+ 29 Jésù sọ fún wọn pé: “Èmi náà á bi yín ní ìbéèrè kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, màá wá sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín. 30 Ṣé láti ọ̀run ni ìrìbọmi tí Jòhánù+ ṣe fún àwọn èèyàn ti wá àbí látọ̀dọ̀ èèyàn?* Ẹ dá mi lóhùn.”+ 31 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn, wọ́n ní: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ pé, ‘Kí ló wá dé tí ẹ ò gbà á gbọ́?’ 32 Àmọ́, ṣé a lè sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn’?” Wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èrò, torí gbogbo àwọn yìí gbà pé wòlíì ni Jòhánù lóòótọ́.+ 33 Nítorí náà, wọ́n dá Jésù lóhùn pé: “A ò mọ̀.” Jésù wá sọ fún wọn pé: “Èmi náà ò ní sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín.”

12 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ọkùnrin kan gbin àjàrà,+ ó sì ṣe ọgbà yí i ká, ó gbẹ́ ẹkù sí ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì, ó sì kọ́ ilé gogoro kan;+ ó wá gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.+ 2 Nígbà tí àsìkò tó, ó rán ẹrú kan lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà pé kó gbà lára àwọn èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ wọn. 3 Àmọ́ wọ́n mú un, wọ́n lù ú, wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo. 4 Ó tún rán ẹrú míì sí wọn àmọ́ wọ́n lù ú ní orí, wọ́n sì kàn án lábùkù.+ 5 Ó rán ẹlòmíì, wọ́n sì pa á, ó tún rán ọ̀pọ̀ àwọn míì, wọ́n lu àwọn kan nínú wọn, wọ́n sì pa àwọn míì. 6 Ẹnì kan tó ṣẹ́ kù ni ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.+ Òun ló rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’ 7 Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí.+ Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ogún rẹ̀ sì máa di tiwa.’ 8 Torí náà, wọ́n mú un, wọ́n pa á, wọ́n sì jù ú sí ìta ọgbà àjàrà náà.+ 9 Kí ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà máa ṣe? Ó máa wá, ó máa pa àwọn tó ń dáko náà, á sì gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì.+ 10 Ṣé ẹ ò ka ìwé mímọ́ yìí rí ni, pé: ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé.*+ 11 Ọ̀dọ̀ Jèhófà* ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?”+

12 Ni wọ́n bá fẹ́ mú un,* àmọ́ wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èrò, torí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń fi àpèjúwe náà bá wí. Torí náà, wọ́n fi sílẹ̀, wọ́n sì lọ.+

13 Lẹ́yìn náà, wọ́n rán àwọn kan lára àwọn Farisí àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù lọ bá a, kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un.+ 14 Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n sọ fún un pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, o kì í wá ojúure ẹnikẹ́ni, torí kì í ṣe ìrísí àwọn èèyàn lò ń wò, àmọ́ ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́. Ṣé ó bófin mu* láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu? 15 Ṣé ká san án àbí ká má san án?” Ó rí i pé alágàbàgebè ni wọ́n, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń dán mi wò? Ẹ mú owó dínárì* kan wá fún mi kí n wò ó.” 16 Wọ́n mú ọ̀kan wá, ó sì sọ fún wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta nìyí?” Wọ́n sọ fún un pé: “Ti Késárì ni.” 17 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì,+ àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ Ẹnu sì yà wọ́n sí i.

18 Àwọn Sadusí, tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde,+ wá bi í pé:+ 19 “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé tí arákùnrin ẹnì kan bá kú, tó sì fi ìyàwó sílẹ̀ àmọ́ tí kò bímọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.+ 20 Arákùnrin méje wà. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, àmọ́ nígbà tó kú, kò fi ọmọ kankan sílẹ̀. 21 Ẹnì kejì fẹ́ obìnrin náà, àmọ́ ọkùnrin náà kú láìbímọ, ohun kan náà ló sì ṣẹlẹ̀ sí ẹni kẹta. 22 Àwọn méjèèje ò fi ọmọ kankan sílẹ̀. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obìnrin náà kú. 23 Nígbà àjíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí àwọn méjèèje ló ti fi ṣe aya.” 24 Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣebí ìdí tí ẹ fi ṣàṣìṣe nìyẹn, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run?+ 25 Torí tí wọ́n bá jíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+ 26 Àmọ́ ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ ò tíì kà á nínú ìwé Mósè ni, nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, pé Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?+ 27 Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè. Ẹ mà ṣàṣìṣe o.”+

28 Ọ̀kan nínú àwọn akọ̀wé òfin tó wá, tó gbọ́ tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀, tó sì mọ̀ pé ó ti dá wọn lóhùn lọ́nà tó dáa, bi í pé: “Èwo ni àkọ́kọ́* nínú gbogbo àṣẹ?”+ 29 Jésù dáhùn pé: “Àkọ́kọ́ ni, ‘Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, Jèhófà* Ọlọ́run wa, Jèhófà* kan ṣoṣo ni, 30 kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ.’+ 31 Ìkejì ni, ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’+ Kò sí àṣẹ míì tó tóbi ju àwọn yìí lọ.” 32 Akọ̀wé òfin náà sọ fún un pé: “Olùkọ́, ohun tí o sọ dáa, ó sì bá òtítọ́ mu, ‘Ọ̀kan ṣoṣo ni Òun, kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan;+ 33 kí èèyàn fi gbogbo ọkàn, gbogbo òye àti gbogbo okun nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀, kó sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ bí ara rẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an ju gbogbo odindi ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ.”+ 34 Jésù rí i pé ìdáhùn rẹ̀ mọ́gbọ́n dání, ó wá sọ fún un pé: “O ò jìnnà sí Ìjọba Ọlọ́run.” Àmọ́ kò sẹ́ni tó láyà láti tún bi í ní ìbéèrè mọ́.+

35 Bí Jésù ṣe ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, ó sọ pé: “Kí nìdí tí àwọn akọ̀wé òfin fi sọ pé ọmọ Dáfídì ni Kristi?+ 36 Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́,+ Dáfídì fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.”’+ 37 Dáfídì fúnra rẹ̀ pè é ní Olúwa, báwo ló ṣe wá jẹ́ ọmọ rẹ̀?”+

Èrò rẹpẹtẹ náà ń gbádùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. 38 Bó ṣe ń kọ́ni, ó sọ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n fẹ́ máa rìn kiri nínú aṣọ ńlá, tí wọ́n sì fẹ́ kí wọ́n máa kí wọn níbi ọjà,+ 39 wọ́n fẹ́ ìjókòó iwájú* nínú àwọn sínágọ́gù àti ibi tó lọ́lá jù níbi oúnjẹ alẹ́.+ 40 Wọ́n ń jẹ ilé* àwọn opó run, wọ́n sì ń gba àdúrà tó gùn láti ṣe ojú ayé.* Ìdájọ́ tó le* gan-an ni àwọn yìí máa gbà.”

41 Ó wá jókòó síbi tó ti ń rí àwọn àpótí ìṣúra ní ọ̀ọ́kán,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wo bí àwọn èrò ṣe ń fi owó sínú àwọn àpótí ìṣúra náà, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì ń fi ẹyọ owó púpọ̀ síbẹ̀.+ 42 Opó kan tó jẹ́ aláìní wá, ó sì fi ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an* síbẹ̀.+ 43 Torí náà, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ohun tí opó aláìní yìí fi sílẹ̀ ju ti gbogbo àwọn yòókù tó fi owó sínú àwọn àpótí ìṣúra.+ 44 Torí gbogbo wọn fi síbẹ̀ látinú àjẹṣẹ́kù wọn, àmọ́ òun, láìka pé kò ní lọ́wọ́,* ó fi gbogbo ohun tó ní síbẹ̀, gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.”+

13 Bó ṣe ń jáde nínú tẹ́ńpìlì, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “Olùkọ́, wò ó! àwọn òkúta àti ilé yìí mà wuni o!”+ 2 Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Ṣé o rí àwọn ilé ńlá yìí? Ó dájú pé wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì níbí, láìwó o palẹ̀.”+

3 Bó ṣe jókòó sórí Òkè Ólífì níbi tó ti lè rí tẹ́ńpìlì náà ní ọ̀ọ́kán, Pétérù, Jémíìsì, Jòhánù àti Áńdérù wá bi í ní òun nìkan pé: 4 “Sọ fún wa, ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì ìgbà tí gbogbo nǹkan yìí máa wá sí òpin?”+ 5 Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnì kankan má ṣì yín lọ́nà.+ 6 Ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá ní orúkọ mi, wọ́n á sọ pé, ‘Èmi ni ẹni náà,’ wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. 7 Bákan náà, tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun, tí ẹ sì gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun, ẹ má bẹ̀rù; àwọn nǹkan yìí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, àmọ́ òpin ò tíì dé.+

8 “Torí orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba;+ ìmìtìtì ilẹ̀ máa wà láti ibì kan dé ibòmíì; àìtó oúnjẹ náà máa wà.+ Àwọn nǹkan yìí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ wàhálà tó ń fa ìrora.+

9 “Ní tiyín, ẹ máa ṣọ́ra yín. Àwọn èèyàn máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́,+ wọ́n máa lù yín nínú àwọn sínágọ́gù,+ ẹ sì máa dúró níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.+ 10 Bákan náà, a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.+ 11 Tí wọ́n bá sì ń mú yín lọ láti fà yín léni lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn ṣáájú nípa ohun tí ẹ máa sọ; àmọ́ ohunkóhun tí a bá fún yín ní wákàtí yẹn ni kí ẹ sọ, torí kì í ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí mímọ́ ni.+ 12 Bákan náà, arákùnrin máa fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, bàbá máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọmọ, àwọn ọmọ máa dìde sí àwọn òbí, wọ́n sì máa pa wọ́n.+ 13 Gbogbo èèyàn sì máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.+ Àmọ́ ẹni tó bá fara dà á* dé òpin+ máa rí ìgbàlà.+

14 “Àmọ́ tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro,+ tó dúró ní ibi tí kò yẹ (kí òǹkàwé lo òye), nígbà náà, kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.+ 15 Kí ẹni tó wà lórí ilé má sọ̀ kalẹ̀ tàbí kó wọlé lọ mú ohunkóhun kúrò nínú ilé rẹ̀; 16 kí ẹni tó wà ní pápá má sì pa dà sí àwọn ohun tó wà lẹ́yìn láti mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀. 17 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o!+ 18 Ẹ máa gbàdúrà kó má lọ bọ́ sí ìgbà òtútù; 19 torí àwọn ọjọ́ yẹn máa jẹ́ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú,+ irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá títí di àkókò yẹn, irú rẹ̀ kò sì ní ṣẹlẹ̀ mọ́.+ 20 Kódà, ẹran ara kankan ò ní là á já, àfi tí Jèhófà* bá dín àwọn ọjọ́ náà kù. Àmọ́ nítorí àwọn àyànfẹ́ tó yàn, ó dín àwọn ọjọ́ náà kù.+

21 “Bákan náà, tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín nígbà yẹn pé, ‘Ẹ wò ó! Kristi wà níbí’ tàbí ‘Ẹ wò ó! Òun nìyẹn,’ ẹ má gbà á gbọ́.+ 22 Torí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké máa dìde,+ wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu láti kó àwọn àyànfẹ́ pàápàá ṣìnà, tó bá ṣeé ṣe. 23 Torí náà, ẹ ṣọ́ra.+ Mo ti sọ gbogbo nǹkan fún yín ṣáájú.

24 “Àmọ́ nígbà yẹn, lẹ́yìn ìpọ́njú yẹn, oòrùn máa ṣókùnkùn, òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀,+ 25 àwọn ìràwọ̀ á máa já bọ́ láti ọ̀run, a sì máa mi àwọn agbára tó wà ní ọ̀run. 26 Nígbà náà, wọ́n máa wá rí Ọmọ èèyàn+ tó ń bọ̀ nínú àwọsánmà* pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+ 27 Ó máa rán àwọn áńgẹ́lì jáde, wọ́n sì máa kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun ayé títí dé ìkángun ọ̀run.+

28 “Ní báyìí, ẹ kọ́ àpèjúwe yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ọ̀mùnú, tó sì rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti sún mọ́lé.+ 29 Bákan náà, tí ẹ bá rí i tí àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ ẹnu ọ̀nà.+ 30 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó dájú pé ìran yìí ò ní kọjá lọ títí gbogbo nǹkan yìí fi máa ṣẹlẹ̀.+ 31 Ọ̀run àti ayé máa kọjá lọ,+ àmọ́ ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi ò ní kọjá lọ.+

32 “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àyàfi Baba.+ 33 Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò,+ torí ẹ ò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn jẹ́.+ 34 Ó dà bí ọkùnrin kan tó ń rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fún àwọn ẹrú rẹ̀ ní àṣẹ,+ tó yan iṣẹ́ fún kálukú, tó sì pàṣẹ fún aṣọ́nà pé kó máa ṣọ́nà.+ 35 Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà, torí pé ẹ ò mọ ìgbà tí baálé ilé náà ń bọ̀,+ bóyá alẹ́ ni àbí ọ̀gànjọ́ òru àbí àfẹ̀mọ́jú* àbí ní àárọ̀ kùtù,+ 36 kó má bàa bá yín lójú oorun tó bá dé lójijì.+ 37 Àmọ́ ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo èèyàn: Ẹ máa ṣọ́nà.”+

14 Ó ku ọjọ́ méjì+ kí wọ́n ṣe Ìrékọjá+ àti Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.+ Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì ń wá bí wọ́n ṣe máa fi ọgbọ́n àrékérekè* mú un,* kí wọ́n sì pa á;+ 2 torí wọ́n sọ pé: “Kì í ṣe nígbà àjọyọ̀; torí ariwo lè sọ látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn.”

3 Nígbà tó wà ní Bẹ́tánì, tó ń jẹun* ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀, obìnrin kan mú orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà sí wá, ojúlówó náádì tó wọ́n gan-an ni. Ó já orùba alabásítà náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da òróró náà sórí rẹ̀.+ 4 Ni àwọn kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìbínú sọ láàárín ara wọn pé: “Kí ló dé tó ń fi òróró onílọ́fínńdà yìí ṣòfò báyìí? 5 Torí à bá ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní iye tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) owó dínárì,* ká sì kó owó náà fún àwọn aláìní!” Inú bí wọn gidigidi sí obìnrin náà.* 6 Àmọ́ Jésù sọ pé: “Ẹ fi í sílẹ̀. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ máa yọ ọ́ lẹ́nu? Ohun tó dáa gan-an ló ṣe sí mi.+ 7 Torí ìgbà gbogbo ni àwọn aláìní wà láàárín yín,+ ẹ sì lè ṣe ohun rere sí wọn nígbàkigbà tí ẹ bá fẹ́, àmọ́ ìgbà gbogbo kọ́ ni màá wà láàárín yín.+ 8 Ó ṣe ohun tó lè ṣe; ó da òróró onílọ́fínńdà sí ara mi ṣáájú nítorí ìsìnkú.+ 9 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ibikíbi tí a bá ti ń wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ayé,+ wọ́n á máa sọ ohun tí obìnrin yìí ṣe láti fi rántí rẹ̀.”+

10 Júdásì Ìsìkáríọ́tù, ọ̀kan nínú àwọn Méjìlá náà, lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà láti fà á lé wọn lọ́wọ́.+ 11 Inú wọn dùn nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn máa fún un ní owó fàdákà.+ Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́.

12 Ní ọjọ́ kìíní Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ nígbà tí wọ́n máa ń fi ẹran Ìrékọjá rúbọ,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé: “Ibo lo fẹ́ ká lọ ṣètò fún ọ láti jẹ Ìrékọjá?”+ 13 Ó wá rán méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìṣà omi máa pàdé yín. Ẹ tẹ̀ lé e,+ 14 ibikíbi tó bá wọlé sí, ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ sọ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà, tí èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi ti lè jẹ Ìrékọjá?”’ 15 Ó sì máa fi yàrá ńlá kan hàn yín lókè, tó ti ní àwọn ohun tí a nílò, tó sì ti wà ní sẹpẹ́. Ẹ ṣètò rẹ̀ síbẹ̀ fún wa.” 16 Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà jáde lọ, wọ́n sì wọnú ìlú náà, wọ́n rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá.

17 Nígbà tó di alẹ́, òun àti àwọn Méjìlá náà wá.+ 18 Bí wọ́n sì ṣe jókòó* sídìí tábìlì, tí wọ́n ń jẹun, Jésù sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tó ń bá mi jẹun máa dà mí.”+ 19 Ẹ̀dùn ọkàn bá wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un lọ́kọ̀ọ̀kan pé: “Èmi kọ́ o, àbí èmi ni?” 20 Ó sọ fún wọn pé: “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin Méjìlá tí a jọ ń ki ọwọ́ bọ inú abọ́ ni.+ 21 Torí Ọmọ èèyàn ń lọ, bí a ṣe kọ ọ́ nípa rẹ̀, àmọ́ ọkùnrin tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi Ọmọ èèyàn léni lọ́wọ́ gbé!+ Ì bá sàn fún ọkùnrin náà ká ní wọn ò bí i.”+

22 Bí wọ́n ṣe ń jẹun, ó mú búrẹ́dì, ó súre, ó bù ú, ó sì fún wọn, ó sọ pé: “Ẹ gbà; èyí túmọ̀ sí ara mi.”+ 23 Ó mú ife kan, ó dúpẹ́, ó sì gbé e fún wọn, gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.+ 24 Ó sọ fún wọn pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀+ májẹ̀mú’ mi,+ tí a máa dà jáde nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn.+ 25 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé mi ò ní mu nínú ohun tí wọ́n fi àjàrà ṣe mọ́, títí di ọjọ́ yẹn tí màá mu ún ní tuntun nínú Ìjọba Ọlọ́run.” 26 Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n kọrin ìyìn,* wọ́n lọ sí Òkè Ólífì.+

27 Jésù sì sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín lẹ máa kọsẹ̀, torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Màá kọ lu olùṣọ́ àgùntàn,+ àwọn àgùntàn sì máa tú ká.’+ 28 Àmọ́ lẹ́yìn tí mo bá jíǹde, màá lọ sí Gálílì ṣáájú yín.”+ 29 Ṣùgbọ́n Pétérù sọ fún un pé: “Tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ kọsẹ̀, èmi ò ní kọsẹ̀.”+ 30 Ni Jésù bá sọ fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ pé lónìí, àní, lóru òní yìí, kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ 31 Àmọ́ ó ń sọ ṣáá pé: “Tó bá tiẹ̀ gba pé kí n kú pẹ̀lú rẹ, ó dájú pé mi ò ní sẹ́ ọ.” Ohun tí gbogbo àwọn yòókù náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ nìyẹn.+

32 Wọ́n wá dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Gẹ́tísémánì, ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jókòó síbí, kí èmi máa gbàdúrà.”+ 33 Ó mú Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù dání pẹ̀lú rẹ̀,+ ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ní ẹ̀dùn ọkàn gidigidi,* ìdààmú sì bá a gan-an. 34 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi* gan-an,+ àní títí dé ikú. Ẹ dúró síbí, kí ẹ sì máa ṣọ́nà.”+ 35 Ó lọ síwájú díẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé, tó bá ṣeé ṣe, kí wákàtí náà ré òun kọjá. 36 Ó sì sọ pé: “Ábà,* Bàbá,+ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, àmọ́ ohun tí ìwọ fẹ́.”+ 37 Ó pa dà wá, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, ó wá sọ fún Pétérù pé: “Símónì, ò ń sùn ni? Ṣé o ò lókun láti ṣọ́nà fún wákàtí kan ni?+ 38 Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa kó sínú ìdẹwò.+ Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń fẹ́,* àmọ́ ẹran ara jẹ́ aláìlera.”+ 39 Ó tún lọ gbàdúrà, ó ń sọ ohun kan náà.+ 40 Ó tún pa dà wá, ó sì rí i pé wọ́n ń sùn, torí oorun ń kùn wọ́n gan-an, torí náà, wọn ò mọ èsì tí wọ́n máa fún un. 41 Ó pa dà wá lẹ́ẹ̀kẹta, ó sì sọ fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ̀ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Ó tó! Wákàtí náà ti dé!+ Ẹ wò ó! A fi Ọmọ èèyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42 Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ. Ẹ wò ó! Ẹni tó máa dà mí ti dé tán.”+

43 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì, ọ̀kan lára àwọn Méjìlá náà dé pẹ̀lú èrò tí wọ́n kó idà àti kùmọ̀ dání, àwọn olórí àlùfáà, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbààgbà ló rán wọn wá.+ 44 Ẹni tó fẹ́ dà á ti fún wọn ní àmì kan tó jọ yé wọn, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; kí ẹ mú un, kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ bí ẹ ṣe ń mú un lọ.” 45 Ó wá tààràtà, ó sì sún mọ́ ọn, ó sọ pé: “Rábì!” ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 46 Torí náà, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un sọ́dọ̀. 47 Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n dúró nítòsí fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ dà nù.+ 48 Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣé èmi lẹ wá fi idà àti kùmọ̀ mú bí olè?+ 49 Ojoojúmọ́ ni mò ń wà pẹ̀lú yín nínú tẹ́ńpìlì, tí mò ń kọ́ni,+ àmọ́ ẹ ò mú mi. Ṣùgbọ́n kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ ni.”+

50 Gbogbo wọn fi í sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ.+ 51 Àmọ́ ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ pé aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa nìkan ló wọ láti bo ìhòòhò ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí, wọ́n sì fẹ́ mú un, 52 àmọ́ ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì sá lọ ní ìhòòhò.*

53 Wọ́n wá mú Jésù lọ sọ́dọ̀ àlùfáà àgbà,+ gbogbo àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbààgbà àti àwọn akọ̀wé òfin sì kóra jọ.+ 54 Àmọ́ Pétérù ń tẹ̀ lé e ní òkèèrè, títí wọnú àgbàlá àlùfáà àgbà; ó jókòó pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì ń yáná nídìí iná kan tó mọ́lẹ̀ yòò.+ 55 Àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sàhẹ́ndìrìn ń wá ẹ̀rí tí wọ́n máa fi mú Jésù kí wọ́n lè pa á, àmọ́ wọn ò rí ìkankan.+ 56 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ń jẹ́rìí èké sí i,+ àmọ́ ẹ̀rí wọn ò bára mu. 57 Bákan náà, àwọn kan ń dìde, wọ́n sì ń jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ń sọ pé: 58 “A gbọ́ tó sọ pé, ‘Màá wó tẹ́ńpìlì yìí tí wọ́n fi ọwọ́ kọ́ palẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ òmíràn tí wọn ò fi ọwọ́ kọ́.’”+ 59 Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n sọ yìí, ẹ̀rí wọn ò bára mu.

60 Àlùfáà àgbà wá dìde láàárín wọn, ó sì bi Jésù pé: “Ṣé o ò ní fèsì rárá ni? Ẹ̀rí tí àwọn èèyàn yìí ń jẹ́ lòdì sí ọ ńkọ́?”+ 61 Àmọ́ kò sọ̀rọ̀, kò sì fèsì rárá.+ Àlùfáà àgbà tún bẹ̀rẹ̀ sí í bi í ní ìbéèrè, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ẹni Ìbùkún?” 62 Jésù wá sọ pé: “Èmi ni; ẹ sì máa rí Ọmọ èèyàn+ tó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára,+ tó sì ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà* ojú ọ̀run.”+ 63 Ni àlùfáà àgbà bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Kí la tún fẹ́ fi àwọn ẹlẹ́rìí ṣe?+ 64 Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì náà. Kí lẹ pinnu?”* Gbogbo wọn dá a lẹ́bi pé ikú tọ́ sí i.+ 65 Àwọn kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í tutọ́ sí i lára,+ wọ́n sì bo ojú rẹ̀, wọ́n gbá a ní ẹ̀ṣẹ́, wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Sọ tẹ́lẹ̀!” Wọ́n gbá a lójú, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ sì mú un.+

66 Nígbà tí Pétérù wà nísàlẹ̀ nínú àgbàlá, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà wá.+ 67 Bó ṣe rí Pétérù tó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó sì sọ pé: “Ìwọ náà wà pẹ̀lú Jésù ará Násárẹ́tì yìí.” 68 Àmọ́ ó sẹ́, ó ní: “Mi ò mọ̀ ọ́n, ohun tí ò ń sọ ò sì yé mi,” ló bá jáde lọ sí ibi àbáwọlé.* 69 Ìránṣẹ́bìnrin náà rí i níbẹ̀, ló bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn tó dúró nítòsí pé: “Ọ̀kan lára wọn nìyí.” 70 Ó tún ń sẹ́. Lẹ́yìn tó ṣe díẹ̀, àwọn tó dúró nítòsí tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún Pétérù pé: “Ó dájú pé o wà lára wọn, torí ká sòótọ́, ará Gálílì ni ọ́.” 71 Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí!” 72 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ lẹ́ẹ̀kejì,+ Pétérù sì rántí ohun tí Jésù sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ Ló bá bara jẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.

15 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin, àní gbogbo Sàhẹ́ndìrìn, gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n de Jésù, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fà á lé Pílátù lọ́wọ́.+ 2 Pílátù wá bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?”+ Ó fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́.”+ 3 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sùn kàn án. 4 Pílátù tún bẹ̀rẹ̀ sí í bi í pé: “Ṣé o ò ní fèsì rárá ni?+ Wo adúrú ẹ̀sùn tí wọ́n ń fi kàn ọ́.”+ 5 Àmọ́ Jésù ò dáhùn mọ́, débi pé ó ya Pílátù lẹ́nu.+

6 Tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀, ó máa ń tú ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá fẹ́ sílẹ̀ fún wọn.+ 7 Ní àkókò yẹn, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bárábà wà nínú ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú àwọn tó dìtẹ̀ sí ìjọba, tí wọ́n sì pààyàn nígbà tí wọ́n ń dìtẹ̀. 8 Torí náà, àwọn èrò wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ohun tí Pílátù máa ń ṣe fún wọn. 9 Ó dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?”+ 10 Torí Pílátù mọ̀ pé àwọn olórí àlùfáà ń ṣe ìlara rẹ̀ ni wọ́n ṣe fà á lé òun lọ́wọ́.+ 11 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà ru àwọn èrò náà sókè pé kí wọ́n ní kó tú Bárábà sílẹ̀ fún àwọn dípò rẹ̀.+ 12 Pílátù tún fún wọn lésì pé: “Kí wá ni kí n ṣe sí ẹni tí ẹ̀ ń pè ní Ọba Àwọn Júù?”+ 13 Wọ́n ké jáde lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Kàn án mọ́gi!”*+ 14 Àmọ́ Pílátù sọ fún wọn pé: “Kí ló dé? Nǹkan burúkú wo ló ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ kígbe pé: “Kàn án mọ́gi!”+ 15 Torí náà, kí Pílátù lè tẹ́ àwọn èrò náà lọ́rùn, ó tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn; lẹ́yìn tó sì ní kí wọ́n na Jésù,+ ó fà á lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+

16 Àwọn ọmọ ogun wá mú un lọ sínú àgbàlá, ìyẹn inú ilé gómìnà, wọ́n sì pe gbogbo ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun jọ.+ 17 Wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù fún un, wọ́n wá fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n sì dé e sí i lórí; 18 wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “A kí ọ o,* ìwọ Ọba Àwọn Júù!”+ 19 Bákan náà, wọ́n ń fi ọ̀pá esùsú gbá a ní orí, wọ́n sì ń tutọ́ sí i lára, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì tẹrí ba* fún un. 20 Níkẹyìn, lẹ́yìn tí wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n bọ́ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ fún un. Wọ́n wá mú un jáde lọ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+ 21 Bákan náà, wọ́n fi dandan mú ẹnì kan tó ń kọjá lọ, ìyẹn Símónì ará Kírénè, pé kó gbé òpó igi oró* rẹ̀. Ó ń bọ̀ láti ìgbèríko, òun ni bàbá Alẹkisáńdà àti Rúfọ́ọ̀sì.+

22 Wọ́n wá mú un wá sí ibi tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, tó túmọ̀ sí “Ibi Agbárí.”+ 23 Ibẹ̀ ni wọ́n ti fẹ́ fún un ní wáìnì tí wọ́n fi òjíá sí kí wáìnì náà lè le,+ àmọ́ kò mu ún. 24 Wọ́n kàn án mọ́gi, wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ kí wọ́n lè pinnu ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa mú.+ 25 Ó ti wá di wákàtí kẹta,* wọ́n sì kàn án mọ́gi. 26 Wọ́n kọ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé: “Ọba Àwọn Júù.”+ 27 Bákan náà, wọ́n kan àwọn olè méjì mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+ 28* —— 29 Àwọn tó ń kọjá lọ ń bú u, wọ́n sì ń mi orí wọn,+ wọ́n ń sọ pé: “Ṣíọ̀! Ìwọ tí o fẹ́ wó tẹ́ńpìlì palẹ̀, kí o sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ,+ 30 gba ara rẹ là, kí o sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi oró.”* 31 Bákan náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ láàárín ara wọn, wọ́n ń sọ pé: “Ó gba àwọn ẹlòmíì là; kò lè gba ara rẹ̀ là!+ 32 Kí Kristi, Ọba Ísírẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi oró,* ká lè rí i, ká sì gbà gbọ́.”+ Àwọn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pàápàá ń fi ṣe ẹlẹ́yà.+

33 Nígbà tó di wákàtí kẹfà,* òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà títí di wákàtí kẹsàn-án.*+ 34 Ní wákàtí kẹsàn-án, Jésù ké jáde pé: “Élì, Élì, làmá sàbákìtanì?” tó túmọ̀ sí: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”+ 35 Nígbà tí àwọn kan lára àwọn tó dúró nítòsí gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ẹ wò ó! Ó ń pe Èlíjà.” 36 Ẹnì kan wá sáré lọ rẹ kànrìnkàn sínú wáìnì kíkan, ó fi sórí ọ̀pá esùsú, ó sì fún un pé kó mu ún,+ ó ní: “Ẹ fi sílẹ̀! Ká wò ó bóyá Èlíjà máa wá gbé e sọ̀ kalẹ̀.” 37 Àmọ́ Jésù ké jáde, ó sì gbẹ́mìí mì.*+ 38 Aṣọ ìdábùú ibi mímọ́+ ya sí méjì látòkè dé ìsàlẹ̀.+ 39 Nígbà tí ọ̀gágun tó dúró ní ọ̀ọ́kán rẹ̀ rí i pé ó ti gbẹ́mìí mì, pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó sọ pé: “Ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí.”+

40 Àwọn obìnrin kan tún wà, tí wọ́n ń wòran láti ọ̀ọ́kán, lára wọn ni Màríà Magidalénì, Màríà ìyá Jémíìsì Kékeré àti Jósè àti Sàlómẹ̀,+ 41 àwọn tó máa ń tẹ̀ lé e, tí wọ́n sì máa ń ṣe ìránṣẹ́ fún un+ nígbà tó wà ní Gálílì àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin míì tó bá a gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù.

42 Bó ṣe ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, tí ọjọ́ yẹn sì jẹ́ Ìpalẹ̀mọ́, ìyẹn ọjọ́ tó ṣáájú Sábáàtì, 43 Jósẹ́fù ará Arimatíà wá, ọ̀kan lára àwọn Ìgbìmọ̀ ni, ẹni tí wọ́n kà sí èèyàn dáadáa, tí òun náà ń retí Ìjọba Ọlọ́run. Ó fi ìgboyà wọlé lọ síwájú Pílátù, ó sì ní kó gbé òkú Jésù fún òun.+ 44 Àmọ́ Pílátù ń wò ó pé ó lè má tíì kú, ó wá ránṣẹ́ pe ọ̀gágun náà, ó bi í bóyá Jésù ti kú. 45 Torí náà, lẹ́yìn tí ọ̀gágun náà ti fi dá a lójú, ó gbà kí Jósẹ́fù máa gbé òkú náà lọ. 46 Lẹ́yìn tó ra aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa, tó sì gbé e sọ̀ kalẹ̀, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa náà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì* kan+ tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta; ó wá yí òkúta sí ẹnu ọ̀nà ibojì náà.+ 47 Àmọ́ Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jósè kò yéé wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.+

16 Torí náà, nígbà tí Sábáàtì+ ti kọjá, Màríà Magidalénì, Màríà+ ìyá Jémíìsì àti Sàlómẹ̀ ra àwọn èròjà tó ń ta sánsán kí wọ́n lè wá fi pa á lára.+ 2 Ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, nígbà tí oòrùn ti yọ, wọ́n wá síbi ibojì* náà.+ 3 Wọ́n ń sọ fún ara wọn pé: “Ta ló máa bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ọ̀nà ibojì náà?” 4 Àmọ́ nígbà tí wọ́n gbójú sókè, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta náà kúrò, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó tóbi gan-an.+ 5 Nígbà tí wọ́n wọnú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́kùnrin kan tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún, ó wọ aṣọ funfun, ẹnu sì yà wọ́n. 6 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kó yà yín lẹ́nu.+ Jésù ará Násárẹ́tì tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ̀ ń wá. A ti jí i dìde.+ Kò sí níbí. Ẹ wò ó, ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí.+ 7 Àmọ́ ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti Pétérù pé, ‘Ó ń lọ sí Gálílì ṣáájú yín.+ Ẹ máa rí i níbẹ̀, bó ṣe sọ fún yín.’”+ 8 Torí náà, nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n sá kúrò ní ibojì náà, jìnnìjìnnì bò wọ́n, wọn ò sì mọ ohun tí wọn ì bá ṣe. Wọn ò bá ẹnì kankan sọ nǹkan kan, torí ẹ̀rù ń bà wọ́n.*+

Ní Grk., “síwájú ojú rẹ.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ṣe batisí fún wọn.”

Tàbí kó jẹ́, “wọ́n mọ ẹni tó jẹ́.”

Tàbí “jókòó nídìí tábìlì.”

Tàbí “jókòó nídìí tábìlì.”

Ìyẹn, orí ọkà.

Tàbí “búrẹ́dì àfihàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “yan àwọn méjìlá.”

Tàbí “tó yàn.”

Tàbí “onítara.”

Orúkọ tí wọ́n ń pe Sátánì.

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n.”

Ìyẹn, orí ọkà.

Tàbí “tìmùtìmù.”

Tàbí “tí ẹ̀ ń ṣojo.”

Tàbí “àwọn ibojì ìrántí.”

Tàbí “gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “Agbègbè Tó Ní Ìlú Mẹ́wàá.”

Tàbí “ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.”

Tàbí “jẹ̀rora gan-an.”

Tàbí “Má fòyà mọ́.”

Tàbí “ó tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn létí.”

Ní Grk., “bàbà.”

Tàbí “aṣọ míì.”

Tàbí “àwọn tó jókòó sídìí tábìlì pẹ̀lú rẹ̀.”

Tàbí “àwọn tó jókòó nídìí tábìlì.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Wo Àfikún B14.

Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”

Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta òru títí dìgbà tí ilẹ̀ mọ́ ní nǹkan bí aago mẹ́fà àárọ̀.

Tàbí “ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́.”

Ìyẹn, láìtẹ̀ lé àṣà ìwẹ̀mọ́.

Tàbí “ẹni tó bá kẹ́gàn.”

Wo Àfikún A3.

Ó ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, por·neiʹa tí wọ́n bá lò ó fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọmọ bíbí.”

Tàbí “Agbègbè Tó Ní Ìlú Mẹ́wàá.”

Tàbí “pẹ̀lú ebi.”

Tàbí “rọ̀gbọ̀kú sórí ilẹ̀.”

Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìkẹ́rùsí.”

Tàbí “apẹ̀rẹ̀ ìkẹ́rùsí.”

Ní Grk., “Bọ́ sẹ́yìn mi.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “aláìṣòótọ́.”

Tàbí “Àwọsánmà.”

Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà mọ sáàárín wọn.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A3.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àfikún A3.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí kó jẹ́, “wọ́n sì sọ láàárín ara wọn.”

Tàbí “ní àsìkò tó ń bọ̀.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “àwọn tí wọ́n mọ̀ sí.”

Tàbí “ọkàn.”

Ó túmọ̀ sí “Olùkọ́.”

Tàbí “agódóńgbó.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A3.

Tàbí “àbí ó pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ èèyàn?”

Ní Grk., “olórí igun.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”

Tàbí “tọ́.”

Wo Àfikún B14.

Tàbí “ló ṣe pàtàkì jù.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “tó dáa jù.”

Tàbí “ohun ìní.”

Tàbí “bojúbojú.”

Tàbí “wúwo.”

Ní Grk., “lẹ́pítónì méjì, tó jẹ́ kúádíránì kan.” Wo Àfikún B14.

Tàbí “pé ó jẹ́ òtòṣì.”

Tàbí “tó fara dà á.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ìkùukùu.”

Ní Grk., “nígbà tí àkùkọ kọ.”

Tàbí “ẹ̀tàn.”

Tàbí “fàṣẹ ọba mú un.”

Tàbí “jókòó nídìí tábìlì.”

Tàbí “ìgò.”

Wo Àfikún B14.

Tàbí “Wọ́n fìbínú sọ̀rọ̀ sí i; Wọ́n fìbínú bá a wí.”

Tàbí “rọ̀gbọ̀kú.”

Tàbí “kọ orin ìjọsìn; kọ sáàmù.”

Tàbí “ọkàn rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í dà rú.”

Tàbí “ọkàn mi.”

Ọ̀rọ̀ Hébérù tàbí Árámáíkì tó túmọ̀ sí “Bàbá!”

Tàbí “ó ń wu ẹ̀mí.”

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “pẹ̀lú aṣọ jáńpé lára; pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ nìkan.”

Tàbí “ìkùukùu.”

Tàbí “Kí lèrò yín?”

Tàbí “gbọ̀ngàn àbáwọlé.”

Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “A júbà rẹ.”

Tàbí “forí balẹ̀.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀.

Wo Àfikún A3.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.

Tàbí “mí èémí àmíkẹ́yìn.”

Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Tàbí “ibojì ìrántí.”

Ẹsẹ kẹjọ ni ìwé Ìhìn Rere Máàkù parí sí, bó ṣe wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó kọ́kọ́ wà, tó sì ṣeé gbára lé. Wo Àfikún A3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́