Wíwo Ayé
Àwọn Ọmọ Àfànítẹ̀ẹ̀tẹ́ àti Tẹlifíṣọ̀n
Ìwé ìròyìn The Toronto Star ròyìn pé Àjọ Tí Ń Tọ́jú Àrùn Ọmọdé Nílẹ̀ Amẹ́ríkà dá a lábàá pé káwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún méjì má ṣe máa wo tẹlifíṣọ̀n. Ìwádìí tó wáyé lórí ìdàgbàsókè ọpọlọ láàárọ̀ ọjọ́ fi hàn pé ó pọndandan káwọn ọmọ ọwọ́ àtàwọn ọmọ àfànítẹ̀ẹ̀tẹ́ máa wà lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn àtàwọn míì tó ń báni tọ́jú ọmọ. Wíwo tẹlifíṣọ̀n lè “ṣèdíwọ́ fún àjọṣepọ̀ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa ìwà ọmọlúwàbí láwùjọ, àti báa ṣe ń gbé èrò ẹni kalẹ̀, àti báa ṣe ń dá nǹkan mọ̀.” Amọ́ o, ẹnu àwọn ògbógi ò kò. Fún àpẹẹrẹ, Ẹgbẹ́ Tí Ń Tọ́jú Àrùn Ọmọdé Nílẹ̀ Kánádà sọ pé wíwo àwọn ètò tó gbámúṣé, pẹ̀lú àbójútó àwọn òbí, fún nǹkan tí kò ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lójúmọ́ á jẹ́ kí ọmọdé “láǹfààní gbígbẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ òbí.” Àmọ́ o, àjọ méjèèjì gbà pé kò dáa láti gbé tẹlifíṣọ̀n tàbí kọ̀ǹpútà sí yàrá àwọn ògo wẹẹrẹ, kò sì dáa láti sọ tẹlifíṣọ̀n di ohun tó ń báni tọ́jú ọmọ. Níwọ̀n bí wíwo tẹlifíṣọ̀n ti lè ṣàkóbá fún ìlera àwọn ọmọdé, wọ́n dá a lábàá pé “kí wọ́n fáwọn ọmọdé níṣìírí láti lọ máa ṣeré níta, láti máa kàwé, tàbí láti máa to àwọn àdììtú tàbí láti máa ṣe àwọn eré àṣedárayá míì.”
Ìjákulẹ̀ Níbi Iṣẹ́
Kí ló dé táwọn kan máa ń fárígá tàbí tí wọ́n tilẹ̀ máa ń hùwà ipá níbi iṣẹ́? Gẹ́gẹ́ bí afìṣemọ̀rònú kan ní Toronto, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sam Klarreich ti wí, ó lè máà jẹ́ másùnmáwo lásán ló ń fà á, ó lè jẹ́ àìrára gba ìjákulẹ̀. Ó gbà pé ohun tó máa ń fà á ni pé àwọn òṣìṣẹ́ kan gbà pé wọ́n “ń kó àwọn ṣe iṣẹ́ àṣefẹ́ẹ̀ẹ́kú, wọ́n á sì wá rí i lẹ́yìn náà pé owó tí wọ́n ń san kéré sí iṣẹ́ tí àwọ́n ṣe,” ìwé ìròyìn Globe and Mail ló gbé ìròyìn yìí jáde. Klarreich kìlọ̀ pé bíbínú fúngbà pípẹ́ “ń ṣe àkóbá ńlá fún ara,” ó sì lè yọrí sí àrùn ẹ̀gbà tàbí àrùn ọkàn-àyà. Ó rọ àwọn òṣìṣẹ́ pé kí wọ́n gba kámú bí ìjákulẹ̀ bá dé, kí àwọn àtàwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ jọ forí korí, kí wọ́n sì fẹ̀lẹ̀ jíròrò ìwọ̀n iṣẹ́ tí wọ́n lẹ́mìí àtiṣe. Lódìkejì, Klarreich gba àwọn agbanisíṣẹ́ nímọ̀ràn pé káwọn náà wà lójúfò láti lè tètè mọ ìgbà tí agara bá ń dá àwọn òṣìṣẹ́ kan, kí wọ́n gbárùkù tì wọ́n, kí wọ́n ràn wọ́n lẹ́rù, tàbí kí wọ́n dá a lábàá pé kí wọ́n lọ fi ọjọ́ kan sinmi.
Orin Kíkọ Ń Múni Lórí Yá
Ìwé ìròyìn Stuttgarter Nachrichten ròyìn pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti rí i pé orin kíkọ ń tú àwọn kẹ́míkà kan sínú ọpọlọ tó máa ń jẹ́ kí ara tuni, kéèyàn sì láyọ. Àwọn olùwádìí sọ pé nígbà téèyàn bá ń kọrin, ńṣe “làwọn èròjà tíntìntín tó ń pinnu bí nǹkan ṣe ń rí lára,” máa ń sọ kúlúkúlú nínú ọpọlọ. Fún ìdí yìí, ìròyìn náà sọ pé: “Kì í ṣe kìkì pé orin kíkọ ń fi bí nǹkan ṣe rí lára wa hàn nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń ṣẹ̀dá àwọn ìṣesí kan nínú ara wa.” Àwọn olùkọ́ni lórin ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló rò pé orin kíkọ ti di “nǹkan àtijọ́,” tàbí pé àwọn ò lóhùn orin, fún ìdí wọ̀nyí, wọ́n ní àwọn olórin ni kó máa kọrin o jàre. Àmọ́ o, ìwádìí yìí fi hàn pé àǹfààní wà nínú fífi ohùn ara ẹni kọrin.
Jíjí Irè Oko
Ìwé ìròyìn Siegener Zeitung ròyìn pé láwọn ìpínlẹ̀ kan nílẹ̀ Jámánì, àwọn àgbẹ̀ sọ pé ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń jí irè oko àwọn lọ. Àwọn olè ń kó ẹ̀kún korobá apálá lọ, wọ́n sì ń jí ẹ̀kún ọkọ̀ ewébẹ̀ asparagus lọ. Nígbà kan, àwọn olè jí ẹgbẹ̀rún méje àgbáyun lọ. Òótọ́ ni pé àwọn kan lè máa jí oúnjẹ nítorí ipò ìṣúnná owó tó dẹnu kọlẹ̀, ṣùgbọ́n ó jọ pé eré làwọn míì fi ń ṣe. Àwọn àgbẹ̀ sọ pé “ọ̀kan kò jọ̀kan ọkọ̀” làwọn ń rí nínú oko táwọn olè náà ti ń wá pitú. Oko sábà máa ń jìn sílé olóko, nítorí náà, fanda-fanda làwọn olè máa ń yan kiri nínú oko wọ̀nyí. Gbọ̀rànmirò kan dá a lábàá pé káwọn àgbẹ̀ da ìlẹ̀dú sára ọ̀gbìn wọn, bóyá èyí á jẹ́ fawọ́ àwọn olè sẹ́yìn.
Àjọṣe Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà Lè Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Gùn sí I
Ìwádìí kan tí Harvard University ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, sọ pé àwọn àgbàlagbà tó ń lọ́wọ́ sí ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, irú bíi lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ilé àrójẹ, ibi àwọn eré ìdárayá, àti sinimá, máa ń fi ọdún méjì ààbọ̀ pẹ́ sí i láyé ju àwọn tí kì í bẹ́gbẹ́ ṣe. Thomas Glass láti Harvard, tó jẹ́ olùdarí ìwádìí náà, sọ pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń méfò pé lílọ sókè sódò tí irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ mú lọ́wọ́ ló ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àmọ́, ó fi kún un pé ìwádìí yìí ti pèsè “ẹ̀rí tó jọ pé ó lágbára jù lọ tó wà lónìí, tó fi hàn pé níní ète gúnmọ́ ní apá ìparí ìgbésí ayé ẹni máa ń jẹ́ kéèyàn pẹ́ sí i láyé.” Ọ̀gbẹ́ni Glass sọ pé ṣíṣe púpọ̀ sí i, láìka irú ìgbòkègbodò tó jẹ́ sí, sábà máa ń mú ẹ̀mí ẹni gùn sí i.
Àwọn Ọkọ̀ Òkun Tó Ti Rì Tipẹ́tipẹ́
Ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Sciences et avenir, ròyìn pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òkun ti ṣàwárí àwókù ọkọ̀ òkun méjì tó jẹ́ tàwọn ará Foníṣíà, tó ti rì síbẹ̀ láti nǹkan bí ọdún 750 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn ọkọ̀ náà gùn ní mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti mítà méjìdínlógún, ibi tí wọ́n wà ò sì jìnnà púpọ̀ sétíkun Ísírẹ́lì, àmọ́ ibẹ̀ jìn tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mítà sísàlẹ̀, àwọn ló sì ti pẹ́ jù lọ lára àwọn ọkọ̀ òkun tó ti rì, táa tíì rí nínú agbami. Èbúté Tírè làwọn ọkọ̀ náà ti ṣí, wọ́n kó àwọn ìṣà wáìnì, ó sì jọ pé Íjíbítì tàbí ìlú Carthage ní Àríwá Áfíríkà ni wọ́n forí lé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn International Herald Tribune ti wí, ẹni tó ṣàwárí àwọn ọkọ̀ náà, Robert Ballard, sọ pé: “Ó dà bíi pé ibú òkun, ibi tí ìmọ́lẹ̀ oòrùn kò dé, àti ìsúnkì ńláǹlà, máa ń tọ́jú nǹkan pa mọ́ fún ọjọ́ pípẹ́ ju báa ṣe rò lọ.” Àwọn olùwádìí náà sọ pé ìwádìí yìí “lè jẹ́ kó ṣeé ṣe láti bẹ̀rẹ̀ àkọ̀tun ìwádìí nípa ìtàn ìrìn àjò ojú omi.”
Eré Ìtura Táa Yàn Láàyò
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, wọ́n béèrè lọ́wọ́ ẹgbẹ̀rún ènìyàn ní ọgbọ̀n orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé ohun wo ni wọ́n máa ń fẹ́ ṣe láti fi dín másùnmáwo kù tàbí láti mú kí ara tù wọ́n. Iléeṣẹ́ ìròyìn tó ń jẹ́ Reuters sọ pé kárí ayé, ìpín mẹ́rìndínlọ́gọ́ta lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé orin làwọn yàn láàyò. Ní Àríwá Amẹ́ríkà, ìpín mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ló fi orin sípò kìíní, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín mẹ́rìndínláàádọ́ta láwọn ibi tó ti gòkè àgbà nílẹ̀ Éṣíà. Lápapọ̀, wíwo tẹlifíṣọ̀n ló gbapò kejì, ẹ̀kẹta sì ni lílúwẹ̀ẹ́. Tom Miller, tí í ṣe olùdarí ìwádìí náà tí iléeṣẹ́ Roper Starch Worldwide ṣe, sọ pé: “Táa bá ro ti owó táṣẹ́rẹ́ tórin ń náni, àti pé ó ṣeé gbọ́ nínú rédíò, tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn ẹ̀rọ táa fi ń gbọ́ àwo orin, àti pé ó tún wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkànnì tuntun, kò yani lẹ́nu pé ó ju ìdajì iye àwọn olùgbé ayé tó ń gbọ́ orin fún ìtura.”
Ipò Òṣì Ti Di Ìṣòro Kárí Ayé
Ààrẹ Báńkì Àgbáyé, ìyẹn, James D. Wolfensohn, sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé ipò òṣì tó ń jà ràn-ìn lágbàáyé ń kọ òun lóminu. Ìwé ìròyìn Mexico City náà, La Jornada, ròyìn pé Wolfensohn ṣàkíyèsí pé ìdá mẹ́ta àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé ni òṣì paraku ń ta. Ó fi kún un pé ìdajì àwọn olùgbé ayé ni kò lè rí dọ́là méjì ná lóòjọ́; àti pé àwọn tí kò lè rí tó dọ́là kan ná lóòjọ́ jẹ́ bílíọ̀nù kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú Wolfensohn dùn pé Báńkì Àgbáyé ti tẹ̀ síwájú nínú rírẹ́yìn ipò òṣì, ó ṣe àwọn ìṣírò kan tó fi hàn pé ìṣòro náà gbilẹ̀, kò sì tíì ṣeé ṣẹ́pá. Ó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ gbà pé ipò òṣì jẹ́ ìṣòro kárí ayé.”
Bí Ọkàn Rẹ Ò Bá Jẹ Ẹ́, Sọ Ọ́ Nù
Àwọn oúnjẹ kan, bíi wàràkàṣì, bí wọ́n bá ti bu, kò lè ṣèèyàn ní nǹkan kan téèyàn bá jẹ wọ́n. Àmọ́ àwọn oúnjẹ kan tó ti bu lè ṣe jàǹbá, àgàgà fẹ́ni tára rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ le, ìwé ìròyìn UC Berkeley Wellness Letter ló ṣe ìkìlọ̀ yìí. Búrẹ́dì tó ti bu àtàwọn oúnjẹ oníhóró tó ti bu wà lára àwọn èyí tí májèlé wọ́n pọ̀ jù. Àwọn ohun táà ń rí wọ̀nyẹn, tó hù sára oúnjẹ tó ti bu, máa ń ní àwọn fọ́nrán tó rí bíi gbòǹgbò tó ti wọnú oúnjẹ náà lọ. Síwájú sí i, àwọn májèlé tó wà nínú oúnjẹ tó bu kì í kúrò bọ̀rọ̀, kódà béèyàn bá sè é. Ìwé ìròyìn Wellness Letter wá dá a lábàá pé:
◼ Tó bá ṣeé ṣe, fi nǹkan èèlò sínú fìríìjì, kí o sì lò ó kó tó bu.
◼ Sọ àwọn èso kéékèèké, bí àgbáyun tàbí èso àjàrà tó ti bu nù. Ìgbà tóo bá ti ṣe tán láti jẹ èso ni kóo tó fọ̀ ọ́, torí pé á tètè bu tó bá ní ọ̀rinrin.
◼ Bó bá jẹ́ ibi kékeré ló bu lára àwọn èso ńlá líle àtàwọn ọ̀gbìn bíi ápù, ànàmọ́, cauliflower, tàbí àlùbọ́sà, o lè rọra gé ojú ibẹ̀ dà nù. Bí àwọn èso rírọ̀ bíi peach àti ẹ̀gúsí, bá ti bu, ńṣe ni kóo kó o dà nù.
◼ Bí wàràkàṣì líle bá ti bu, apá kan rẹ̀ ṣì lè ṣeé jẹ, bóo bá gé ibi tó bu náà dà nù, tóo gé e, ó kéré tán, tó nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà mẹ́ta wọnú. Àmọ́ bí wàràkàṣì rírọ̀ àti yúgọ́ọ̀tì, àti búrẹ́dì, ẹran, oúnjẹ àjẹkù, àwọn oúnjẹ oníhóró, ẹ̀pà lílọ̀, àwọn nǹkan olómi tó dùn mẹ̀nẹ̀mẹ̀nẹ̀, àtàwọn èso inú agolo bá ti bu, kíkó ni kí o kó wọn dà nù.
Yíyan Ẹran Níwọ̀n Tó Tọ́
Ìwé ìròyìn National Post ti Kánádà sọ pé: “Ẹran tí kò jiná ló ti sábà máa ń ba àwọn èèyàn lẹ́rù láti jẹ, àmọ́ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, yíyan án gbẹ jù—pàápàá jù lọ sísun ẹran, ẹran adiyẹ àti ẹja jó tàbí kó tilẹ̀ jóná ráúráú lórí ayanran—ni a ti rí i pé ó ń ṣe àkóbá gidi fún ìlera.” Nígbà táa bá fi iná tó pọ̀ yan ẹran, ó máa ń mú àwọn èròjà tí ń fa àrùn jẹjẹrẹ tí a ń pè ní heterocyclic amines (HCAs) jáde. Ìròyìn náà dámọ̀ràn pé kéèyàn máa lo èròjà marinade tó ní nínú “èròjà kan tó ní omiró, irú bí omi ọsàn wẹ́wẹ́, omi ọsàn tàbí ọtí kíkan,” nǹkan wọ̀nyí lè jẹ́ kí ẹran yíyan dáa fára. Nínú àwọn àyẹ̀wò tí Iléeṣẹ́ Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Àrùn Jẹjẹrẹ ní Amẹ́ríkà ṣe léraléra, wọ́n “ṣàwárí pé àwọn oúnjẹ tí wọ́n fi èròjà marinade sí, ní èròjà HCAs tó fi ìpín méjìléláàádọ́rùn-ún sí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún dín sí irú àwọn oúnjẹ kan náà tí wọn kò fi èròjà marinade sí—kò sì mú ìyàtọ̀ kankan wá, yálà wọ́n fi èròjà marinade sí i fún ogójì ìṣẹ́jú tàbí fún ọjọ́ méjì.”