Ewu Tí Gbogbo Òbí Ń Kọminú Lé Lórí
ỌLỌ́YÀYÀ èèyàn tí inú wọn sì máa ń dùn ni Fẹ́mi àti ìyàwó rẹ̀, Dúpẹ́. Ọmọ wọn ọkùnrin ti pé ọmọ ọdún mẹ́ta, ọmọ náà já fáfá, ara rẹ̀ sì le dáadáa.a Wọn ò fi ìtọ́jú jẹ ẹ́ níyà rárá. Ìyẹn kì í ṣe ohun tó rọrùn nínú ayé tá à ń gbé yìí ṣáá o. Béèyàn ṣe ń já sókè lá á máa já sódò, ojúṣe ibẹ̀ ò sì kéré. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni òbí gbọ́dọ̀ fi kọ́ ọmọ! Èyí tó gba Fẹ́mi àti Dúpẹ́ lọ́kàn jù lọ lára ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí òbí rèé: Wọ́n fẹ́ láti dáàbò bo ọmọ wọn lọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Dúpẹ́ tó jẹ́ ìyá ọmọ náà sọ pé: “Ọ̀dájú ni bàbá mi, ọ̀mùtípara ni, ó sì máa ń tètè fara ya. Ó máa ń lù mí játijàti, ó sì máa ń bá èmi àtàwọn àbúrò mi ṣèṣekúṣe.”b Àwọn ọ̀mọ̀ràn níbi gbogbo gbà pé irú ìṣekúṣe bẹ́ẹ̀ lè múni banú jẹ́ lọ́nà kíkorò. Abájọ tí Dúpẹ́ fi pinnu pé òun á dáàbò bo ọmọ òun! Ọkọ ẹ̀ náà sì ṣe tán láti bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀.
Bíbá tí wọ́n ń bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe ti wá di ohun tí ọ̀pọ̀ òbí ń ṣàníyàn lé lórí báyìí. Bóyá ìwọ náà sì wà lára wọn. Wọ́n lè má tíì bá ẹ ṣèṣekúṣe rí bíi ti Dúpẹ́, ìyàwó Fẹ́mi, kó o má sì mọ bó ṣe máa ń rí lára. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ ìròyìn tó ń jáni láyà nípa bí ìwà tó ń kóni nírìíra náà ṣe gbilẹ̀ tó. Kárí ayé lọkàn àwọn òbí tí ò fọ̀rọ̀ ọmọ wọn ṣeré kì í ti í balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń gbọ́ nípa nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọdé níbi tí wọ́n ń gbé.
Abájọ, ẹnì kan tí iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ máa ń dá lórí fífi ìbálòpọ̀ fìtínà ẹni sọ nípa ibi tí bíbọ́mọdé ṣèṣekúṣe gogò dé, ó ní “ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni jù lọ tó tíì ṣẹlẹ̀ rí lákòókò tá à ń gbé yìí.” Ìròyìn tí ń bani nínú jẹ́ gbáà mà nìyẹn o! Àmọ́, ṣó yẹ kírú àwọn nǹkan bí èyí máa yani lẹ́nu? Kò jẹ́ jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fáwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé pé à ń gbé ní àkókò ìdààmú tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” tó kún fún ìwà “òǹrorò,” nínú èyí táwọn èèyàn á ti jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn” tí wọ́n á sì jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.”—2 Tímótì 3:1-5.
Ìṣòro tó ń muni lómi gbáà lọ̀rọ̀ ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe. Ìwà tó burú jáì ni fáwọn èèyàn kan láti máa wá àwọn ọmọdé tí wọ́n á bá ṣèṣekúṣe kiri. Báwọn òbí kan bá sì ṣe ń ronú nípa èyí, ńṣe lọkàn wọn máa ń dà rú. Ṣé a wá lè sọ pé ìṣòro yìí ti kọjá èyí ti apá àwọn òbí lè ká? Àbí àwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu kan wà táwọn òbí lè ṣe kí wọ́n bàa lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn? Àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn á tú iṣu ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí désàlẹ̀ ìkòkò.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí padà.
b Kí ọkùnrin tàbí obìnrin àgbàlagbà máa lo ọmọdé láti fi tẹ́ ìfẹ́ ara rẹ̀ fún ìbálòpọ̀ lọ́rùn ló ń jẹ́ bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Lára àṣà yìí náà ni ohun tí Bíbélì pè ní àgbèrè, tàbí por·neiʹa wà. Lára àwọn nǹkan tó túmọ̀ sí por·neiʹa ni fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbálòpọ̀, bíbáni lò pọ̀, fífi ẹnu pọ́n ẹ̀yà ìbálòpọ̀ lá, tàbí kí ọkùnrin máa ki nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ bọnú ihò ìdí obìnrin tàbí ọkùnrin bíi tiẹ̀. Àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe, bíi fífọwọ́ pani lọ́yàn, fífi ìṣekúṣe lọni, fífi àwòrán oníhòòhò han ọmọdé, yíyọjú wo ẹni tó bọ́ra sílẹ̀ tàbí yíyọjú wo àwọn tó ń bára wọn lò pọ̀ àti ṣíṣí ara sílẹ̀ níbi tí kò yẹ, lè já sí ohun tí Bíbélì dẹ́bi fún tó sì pè ní “ìwà àìníjàánu” tàbí fífi “ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.”—Gálátíà 5:19-21; Éfésù 4:19.