Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
January–February 2013
© 2013 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania.
ÀPILẸ̀KỌ TÓ DÁ LÓRÍ ÀKÒRÍ Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Níwà Ọmọlúwàbí Lóde Òní 8-11
TÚN LỌ WO ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ÀWỌN Ọ̀DỌ́
ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ . . .
Kí Ni Mo Lè Ṣe Sọ́rọ̀ Àwọn Tó Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?
Ọmọ iléèwé girama kan tó ń jẹ́ Coretta sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin máa ń wá fa bùrèsíà mi látẹ̀yìn, wọ́n sì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ rírùn sí mi létí. Wọ́n lè máa sọ nípa bí màá ṣe gbádùn ẹ̀ tó tí n bá gbà pé káwọn bá mi sùn.” Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni wọ́n ń sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún, kí lo máa ṣe? Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lè má fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́ mọ́ tó o bá mọ ohun tó o lè ṣe sọ́rọ̀ wọn!
ÀWỌN ỌMỌDÉ
ERÉ ALÁWÒRÁN
Wa àwòrán yìí jáde, kó o sì fi ẹ̀rọ tẹ̀ ẹ́. Kí ìwọ àti ọmọ rẹ sì jọ ṣe ohun tó wà níbẹ̀. Fi àwọn àwòrán náà kọ́ ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn àti nípa ìwà rere.