Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 5
Lẹ́yìn oṣù méjì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá, wọ́n dé Òkè Sínáì. Níbẹ̀, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú pé wọ́n máa jẹ́ èèyàn òun. Ó dáàbò bò wọ́n, ó sì pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Bí àpẹẹrẹ, ó fún wọn ní mánà, kò jẹ́ kí aṣọ wọn gbó, ó sì tún fún wọn níbi tó dáa láti gbé. Tó o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kọ́mọ ẹ mọ ìdí tí Jèhófà fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin, àgọ́ ìjọsìn àtàwọn àlùfáà. Jẹ́ kó rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa mú ìlérí wa ṣẹ, ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì jẹ́ adúrósinsin sí Jèhófà.