ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 7/15 ojú ìwé 24-28
  • Ugarit—Ìlú Ìgbàanì Tó Wà Níbi Tí Ìjọsìn Báálì Ti Gbilẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ugarit—Ìlú Ìgbàanì Tó Wà Níbi Tí Ìjọsìn Báálì Ti Gbilẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbogbo Ọ̀nà Ló Wọbẹ̀
  • Dídá Ohun Tó Ti Kọjá Padà
  • Àwárí Àwọn Àkọlé Ṣíṣeyebíye
  • Ìsìn Nínú Ìlú Báálì
  • Ààbò Kúrò Lọ́wọ́ Ìbọ̀rìṣà
  • Fífi Ìwé Wọn àti Bíbélì Wéra
  • Ṣé Orí Rẹ̀ La Gbé Bíbélì Kà Ni?
  • Ìjọsìn Báálì Ìjọsìn Tó Jìjàdù Láti Gba Ìfọkànsìn Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ọlọ́run Ha Tẹ́wọ́ Gba Gbogbo Onírúurú Ìjọsìn Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 7/15 ojú ìwé 24-28

Ugarit—Ìlú Ìgbàanì Tó Wà Níbi Tí Ìjọsìn Báálì Ti Gbilẹ̀

NÍ ỌDÚN 1928, ohun èlò ìtúlẹ̀ àgbẹ̀ ará Síríà kan fọ́ òkúta tó bo sàréè kan tó kún fún àwọn tánńganran ayé àtijọ́ mọ́lẹ̀. Kò sí bó ṣe lè mọ bí nǹkan tó rí náà ti ṣe pàtàkì tó. Àmọ́ nígbà tí ìgbìmọ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn kan nílẹ̀ Faransé gbọ́ nípa ohun táwọn èèyàn ṣàdédé rí yìí, ńṣe ni wọ́n gbéra lábẹ́ ìdarí Claude Schaeffer, tí wọ́n sì mú ọ̀nà ibẹ̀ pọ̀n lọ́dún tó tẹ̀ lé e.

Kò pẹ́ kò jìnnà tí wọ́n fi rí àkọlé kan wà jáde, èyí tó jẹ́ kí ìgbìmọ̀ náà mọ ohun tí wọ́n ń fi ohun èlò wọn wà jáde. Àwókù Ugarit ni. Ó jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá ìgbàanì tó ṣe pàtàkì jù lọ ní Itòsí Ìlà Oòrùn ayé.” Kódà, òǹkọ̀wé Barry Hoberman sọ pé: “Kò sí àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn kankan, títí kan ti Àkájọ Ìwé Òkun Òkú pàápàá, tó tíì ní ipa tó jinlẹ̀ lórí òye wa nípa Bíbélì tó bẹ́ẹ̀ rí.”—The Atlantic Monthly.

Gbogbo Ọ̀nà Ló Wọbẹ̀

Ugarit tó jẹ́ ìlú ọlọ́lá tí gbogbo èèyàn máa ń rọ́ lọ sí ní ẹgbẹ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa wà lórí òkìtì kan tá a mọ̀ sí Ras Shamra, tó wà ní Etíkun Mẹditaréníà tá a wá mọ̀ sí Síríà ìhà àríwá báyìí. Ìpínlẹ̀ rẹ̀ gba àgbègbè tí ó tó ọgọ́ta kìlómítà láti Òkè Casius ní ìhà àríwá títí dé Tell Sukas ní ìhà Gúúsù àti nǹkan bí ọgbọ́n kìlómítà sí àádọ́ta kìlómítà láti Mẹditaréníà ní apá ìwọ̀ oòrùn sí Àfonífojì Orontes ní ìhà ìlà oòrùn.

Àwọn ohun ọ̀sìn pọ̀ ní Ugarit nítorí pé ojú ọjọ́ ibẹ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn ohun tí wọ́n máa ń gbìn lágbègbè náà ni oúnjẹ oníyangan, òróró ólífì, wáìnì, àti igi gẹdú—tó jẹ́ ohun kan tó ṣọ̀wọ́n ní Mesopotámíà àti ilẹ̀ Íjíbítì. Yàtọ̀ síyẹn bí ìlú ńlá náà ṣe wà ní ojúkò ibi táwọn oníṣòwò máa ń gbà kọjá ló sọ ọ́ di ọ̀kan lára àwọn èbúté ńlá tó kọ́kọ́ wà fún gbogbo ayé. Ugarit ni àwọn oníṣòwò láti Aegean, Anatolia, Bábílónì, Íjíbítì, àti láti àwọn apá ibòmíràn ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ti máa ń ta irin, àwọn ohun ọ̀gbìn àti ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe lágbègbè náà.

Pẹ̀lú bí Ugarit ṣe láásìkí tó yẹn, ìjọba tó wà lábẹ́ àkóso orílẹ̀-èdè mìíràn ni lọ́jọ́ gbogbo. Àgbègbè ẹ̀yìn ibùdó ni ìlú yìí jẹ́ fún Ilẹ̀ Ọba Íjíbítì ní ìhà àríwá lókè pátápátá títí tó fi di èyí tí wọ́n dà pọ̀ mọ́ Ilẹ̀ Ọba àwọn ará Hétì ní ọ̀rúndún kẹrìnlá ṣáájú Sànmánì Tiwa. Wọ́n fagbára mú Ugarit láti san ìṣákọ́lẹ̀ àti láti kó àwọn ọmọ ogun fún orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí “Àwọn Èèyàn Òkun”a tí ń gbógun tini bẹ̀rẹ̀ sí han Anatolia (àárín gbùngbùn Turkey) àti Síríà ìhà àríwá léèmọ̀, ńṣe làwọn ọmọ Hétì gba àwọn ọmọ ogun Ugarit àtàwọn ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun rẹ̀. Èyí ló fà á tí Ugarit fúnra rẹ̀ fi di aláìní ohun ìgbèjà kankan, tí wọ́n sì pa á run yán-ányán-án ní nǹkan bí ọdún 1200 ṣáájú Sànmánì Tiwa.

Dídá Ohun Tó Ti Kọjá Padà

Ìparun Ugarit fi òkìtì ńlá kan sílẹ̀, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ogún mítà tó sì wà lórí ilẹ̀ tó fẹ̀ ju ogún hẹ́kítà lọ. Kìkì ìdá mẹ́fà péré lára àgbègbè yìí ni wọ́n tíì wú jáde. Àwókù ààfin ńlá kan tí yàrá inú rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún tó ní àgbàlá bíi mẹ́fà tó sì fẹ̀ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá mítà níbùú lóòró wà lára ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí. Ààfin náà ní omi ẹ̀rọ, àwọn ilé ìwẹ̀, ilé ìyàgbẹ́, àti ibi tí omi ẹ̀gbin máa ń ṣàn sí. Wúrà, òkúta iyebíye, àti eyín erin ni wọ́n fi ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú rẹ̀. Wọ́n tún rí àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n fi eyín erin gbẹ́ sára ògiri rẹ̀. Ọgbà kan tí wọ́n ṣe ògiri yí ká rẹ̀ àti kòtò omi kan tí wọ́n ṣe síbẹ̀ tún fi kún ẹwà ààfin náà.

Tẹ́ńpìlì Báálì àti ti Daganb ló kún inú ìlú ńlá náà àtàwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó yí i ká. Àwọn ilé gogoro tẹ́ńpìlì yìí, tó ṣeé ṣe kó ga tó ogún mítà, ní ọ̀nà àbáwọlé kékeré kan tó jáde sí yàrá inú lọ́hùn-ún níbi tí wọ́n gbé ère òrìṣà wọn sí. Àtẹ̀gùn kan wà níbẹ̀ tó lọ sínú gbọ̀ngàn tí ọba ti máa ń ṣalága lákòókò onírúurú ààtò ìsìn. Wọ́n lè tan iná sí ibi ṣóńṣó orí òkè àwọn tẹ́ńpìlì náà lóru tàbí nígbà tí ìjì bá ń jà, kó lè ṣamọ̀nà àwọn ọkọ̀ òkun láti gúnlẹ̀ sí èbúté láìséwu. Ó dájú pé àwọn atukọ̀ òkun, tí wọ́n gbà pé Báálì-Hádádì ọlọ́run ìjì ló jẹ́ káwọn gúnlẹ̀ láyọ̀, ló fi àwọn ìdákọ̀ró olókùúta mẹ́tàdínlógún tó wà nínú ibùjọsìn rẹ̀ rúbọ sí ọlọ́run náà.

Àwárí Àwọn Àkọlé Ṣíṣeyebíye

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọpọ́n tá a fi amọ̀ ṣe ní wọ́n wú jáde nínú àwọn àwókù Ugarit. Wọ́n ti rí àwọn ìwé tó sọ nípa ìṣúnná owó, òfin, ọ̀ràn ìṣèlú, àti ọgbọ́n ìṣètò tí wọ́n fi èdè mẹ́jọ kọ sórí àwọn ìwé àfọwọ́kọ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìgbìmọ̀ tí Schaeffer darí yẹn rí èdè àìmọ̀ kan—èyí tí wọ́n pè ní Ugaritic—nípa lílo ọgbọ̀n àmì ara wàláà tó ní ọkàn lára ááfábẹ́ẹ̀tì tó lọ́jọ́ lórí jù lọ tá a tíì ṣàwárí rẹ̀ rí.

Láfikún sí ṣíṣàwárí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé ojoojúmọ́, àwọn ìwé àkọsílẹ̀ Ugaritic tún ní àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn nínú, èyí tó jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mọ̀ nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn àti àwọn àṣà ìgbà yẹn. Ó dà bíi pé ìsìn àwọn ará Ugarit fẹ́ bá ti àwọn ará Kénáánì tó múlé gbè wọ́n mu. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Roland de Vaux sọ, àwọn ìwé wọ̀nyí “jẹ́ àgbéyọ tó péye nípa bí ọ̀làjú ilẹ̀ Kénáánì ṣe rí kó tó di pé Ísírẹ́lì ṣẹ́gun rẹ̀.”

Ìsìn Nínú Ìlú Báálì

Ó lé ní igba ọlọ́run àtàwọn abo-ọlọ́run tí Ras Shamra mẹ́nu kàn nínú ìwé rẹ̀. Èyí tó jẹ́ olórí gbogbo wọn ni El, tí wọ́n pè ní bàbá àwọn ọlọ́run àti ti ènìyàn. Báálì-Hádádì tó jẹ́ ọlọ́run ìjì sì ni “ẹni tó ń yí àwọsánmà” àti “olúwa ilẹ̀ ayé.” Wọ́n ṣàpèjúwe El gẹ́gẹ́ bíi bàbá arúgbó kan tí orí rẹ̀ pé gan-an, tó ní irùngbọ̀n funfun tí ọ̀nà rẹ̀ sì jìn gan-an sí ọmọ aráyé. Báálì ní tiẹ̀ sì jẹ́ ọlọ́run tó lágbára tó máa ń fẹ́ jọba lórí àwọn ọlọ́run yòókù àti lórí àwọn èèyàn.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwé tí wọ́n ṣàwárí rẹ̀ yẹn ni wọ́n máa ń kà láwọn àkókò ayẹyẹ ìsìn wọn, ìyẹn ní àkókò ọdún tuntun tàbí nígbà ìkórè. Àmọ́, kò sẹ́ni tó mọ ohun tó túmọ̀ sí gan-an. Nínú ewì kan tí wọ́n kọ nípa awuyewuye tó wáyé lórí ẹni tó yẹ kí agbára ìṣàkóso wà lọ́wọ́ rẹ̀, Báálì ṣẹ́gun àyànfẹ́ ọmọ El, ìyẹn ni Yamm, ọlọ́run òkun. Ìṣẹ́gun yìí ló wá fi àwọn atukọ̀ ìlú Ugarit lọ́kàn balẹ̀ pé Báálì á dáàbò bo àwọn lójú òkun. Nínú ìjà àjàkú akátá kan tó wáyé láàárín òun àti Mot, wọ́n ṣẹ́gun Báálì, ó sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé. Bí ọ̀dá kan ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn tó sì jẹ́ kí gbogbo ìgbòkègbodò ọmọ aráyé ṣe wẹ́lo. Aya Báálì àti arábìnrin rẹ̀ Anat—ìyẹn abo-ọlọ́run ìfẹ́ àti ti ogun—wá pa Mot, ó sì jí Báálì tó ti kú dìde. Báálì wá pa àwọn ọmọ ìyàwó El tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Athirat (ìyẹn Áṣérà), ó sì padà sórí oyè. Àmọ́, Mot tún padà wá ní ọdún méje lẹ́yìn náà.

Àwọn kan túmọ̀ ewì yìí gẹ́gẹ́ bí àmì bí ojú ọjọ́ ṣe ń yí padà lọ́dọọdún nígbà tí òjò tí ń fúnni ní ìyè bá dáwọ́ dúró nítorí ooru gbígbóná janjan ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó sì tún padà wá ní ìgbà ìwọ́wé. Àwọn kan rò pé àyípoyípo ọdún méje yẹn ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ̀rù ìyàn àti ọ̀dá. Èyí ó wù kó jẹ́, wọ́n gbà pé ipò iwájú tí Báálì mú ṣe pàtàkì gan-an fún àṣeyọrí ohun tí ọmọ aráyé bá dáwọ́ lé. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Peter Craigie sọ pé: “Ohun tí ẹ̀sìn Báálì ń lépa ni kó lè máa wà nípò iwájú, pé kìkì ìgbà tó bá wà nípò iwájú nìkan làwọn olùjọsìn rẹ̀ gbà gbọ́ pé àwọn ohun ọ̀gbìn àtàwọn ẹran ọ̀sìn tó ṣe pàtàkì gan-an fún ìwàláàyè ọmọ aráyé tó lè máa gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀.”

Ààbò Kúrò Lọ́wọ́ Ìbọ̀rìṣà

Ohun tó hàn kedere nínú ìwé tí wọ́n wú jáde yẹn ni bí ìsìn ìlú Ugarit ṣe burú bògìrì tó. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, The Illustrated Bible Dictionary, sọ pé: “Ìwé náà fi àbájáde bíbaninínújẹ́ tí jíjọ́sìn àwọn ọlọ́run wọ̀nyí mú jáde hàn; pẹ̀lú bí wọ́n ṣe máa ń gbé ogun, iṣẹ́ aṣẹ́wó mímọ́, ìfẹ́ ìbálòpọ̀, àti jíjó tí àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ń jó àjórẹ̀yìn lárugẹ.” De Vaux sọ pé: “Lẹ́yìn kíka àwọn ewì wọ̀nyí, èèyàn wá lóye bí ìjọsìn yìí á ti ṣe jẹ́ ìríra tó lójú àwọn tó ń jọ́sìn Yáwè àtàwọn àgbà wòlíì ayé ìgbàanì.” Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì jẹ́ ààbò kúrò lọ́wọ́ irú ìsìn èké bẹ́ẹ̀.

Iṣẹ́ wíwò, wíwo ìràwọ̀, àti iṣẹ́ òkùnkùn jẹ́ àṣà tó gbòde kan ní Ugarit. Kì í ṣe ara àwọn ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lókè ọ̀run nìkan ni wọ́n ti máa ń kíyè sí àmì, wọ́n tún máa ń kíyè sí i lára oyún tó bà jẹ́ àti lára àwọn ẹ̀yà inú àwọn ẹranko tí wọ́n bá pa. Òpìtàn nì, Jacqueline Gachet, sọ pé: “Wọ́n gbà gbọ́ pé ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ máa ń di ara kan náà pẹ̀lú ọlọ́run tí wọ́n bá sọ pé àwọn ń rúbọ sí, àti pé ẹ̀mí ọlọ́run náà máa ń so pọ̀ mọ́ ẹ̀mí ẹran ọ̀hún. Nítorí ìdí èyí, wíwò tí wọ́n ń wo àwọn àmì tó hàn kedere lára àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí á mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti mọ ohun tí ẹ̀mí ọlọ́run náà fẹ́, èyí tá á lè fún wọn ní èsì rere tàbí èsì búburú sí ìbéèrè tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tàbí nípa ohun tó yẹ ní ṣíṣe nínú ipò kan pàtó.” (Le pays d’Ougarit autour de 1200 av.J.C.) Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, ńṣe la sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì sá fún irú àṣà bẹ́ẹ̀.—Diutarónómì 18:9-14.

Òfin Mósè ka bíbá ẹranko lò pọ̀ léèwọ̀ pátápátá. (Léfítíkù 18:23) Ojú wo ni wọn fi wo àṣà yìí ní Ugarit? Nínú ìwé tí wọ́n wú jáde yẹn, wọ́n rí ibi tí Báálì ti ń ní ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú màlúù kékeré kan níbẹ̀. Cyrus Gordon tó jẹ́ awalẹ̀pìtàn sọ pé: “Bí wọ́n bá fẹ́ jiyàn pé ńṣe ni Báálì gbé àwọ̀ akọ màlúù wọ̀, wọ́n ò ṣáà lè sọ ohun kan náà nípa àwọn àlùfáà rẹ̀ tí wọ́n ṣe àṣefihàn ohun tí Báálì ṣe gan-an.”

A pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ kọ ara yín lábẹ nítorí ọkàn tí ó ti di olóògbé.” (Léfítíkù 19:28) Àmọ́, nígbà tí Báálì kú, ńṣe ni El “fi ọ̀bẹ ya ara rẹ̀, tó fi abẹ sín gbẹ́rẹ́; tó sì gé ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti àgbọ̀n ara rẹ̀.” Fífi ọ̀bẹ aṣóró gé ara ẹni jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn olùjọsìn Báálì.—1 Àwọn Ọba 18:28.

Ó dà bíi pé ewì àwọn ará Ugarit kan sọ pé síse ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà jẹ́ ara ààtò ìbímọlémọ tó wọ́pọ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn ará Kénáánì. Bẹ́ẹ̀, ohun tá a pa láṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú Òfin Mósè ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ se ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀.”—Ẹ́kísódù 23:19.

Fífi Ìwé Wọn àti Bíbélì Wéra

Èdè Hébérù tá a fi kọ Bíbélì ni wọ́n kọ́kọ́ fi túmọ̀ ìwé àwọn ará Ugarit níbẹ̀rẹ̀. Peter Craigie sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni wọ́n lò nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí ìtumọ̀ rẹ̀ ò ṣe kedere, tí kò tiẹ̀ yé wọn rárá nígbà mìíràn; bí àwọn atúmọ̀ èdè tó wà ṣáájú ọ̀rúndún ogún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí méfò ohun tí ìtumọ̀ wọn lè jẹ́ nìyẹn. Àmọ́ nígbà tí àwọn ọ̀rọ̀ kan náà tún fara hàn nínú ìwé àwọn Ugarit, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti lóye ohun tí wọ́n túmọ̀ sí.”

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a lò nínú Aísáyà 3:18 ní gbogbo gbòò túmọ̀ sí “ọ̀já ìwérí.” Ọ̀rọ̀ kan tó fara jọ ìyẹn nínú ìwé àwọn Ugarit tọ́ka sí oòrùn àti abo ọlọ́run oòrùn. Nítorí náà, ó lè jẹ́ ẹ̀gbà ọrùn tó rọra ń tàn bí oòrùn àti “àwọn ohun ọ̀ṣọ́ onírìísí òṣùpá” la fi ṣe àwọn obìnrin Jerúsálẹ́mù tá a mẹ́nu kàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà lọ́ṣọ̀ọ́ láti bọlá fún àwọn ọlọ́run àwọn ará Kénáánì.

Ohun èlò amọ̀ tá a fi “fàdákà fẹ́ẹ́rẹ́” bò la fi “ètè tí ń jó fòfò àti ọkàn-àyà búburú” wé nínú ìwé Òwe 26:23 ti inú ìwé àwọn Mesorete. Irú rẹ̀ tó wà nínú ìwé àwọn Ugarit fàyè gba pé ká fi wé ohun kan, kí ibẹ̀ sì kà pé “bí ohun tó ń kọ mọ̀nà lórí ohun èlò amọ̀.” Ìtumọ̀ ti Ayé Tuntun gbé òwe yìí kalẹ̀ lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú pé: “Bí fàdákà fẹ́ẹ́rẹ́ tí a fi bo àpáàdì ni ètè tí ń jó belebele pa pọ̀ pẹ̀lú ọkàn-àyà búburú.”

Ṣé Orí Rẹ̀ La Gbé Bíbélì Kà Ni?

Ṣíṣàyẹ̀wò ìwé Ras Shamra ti mú káwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbà pé àwọn àyọkà kan nínú Bíbélì jẹ́ èyí tó bá ohun tó wà nínú ìwé ewì àwọn ará Ugarit mu. André Caquot, tó jẹ́ mẹ́ńbà Ilé Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Faransé sọ̀rọ̀ nípa bí “àṣà ìbílẹ̀ àwọn ará Kénáánì ṣe jẹ́ ìpìlẹ̀ ẹ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”

Nígbà tí Mitchell Dahood tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí Póòpù dá sílẹ̀ ní Róòmù ń sọ̀rọ̀ lórí Sáàmù Kọkàndínlọ́gbọ̀n, ó sọ pé: “Sáàmù yìí jẹ́ èyí tá a mú bá ọ̀rọ̀ nípa Yáwè tó wà nínú ìwé orin àwọn ará Kénáánì ìgbàanì mu títí dórí Báálì tó jẹ́ ọlọ́run ìjì . . . Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọ̀rọ̀ inú Sáàmù náà ni wọ́n lè ṣàdàkọ rẹ̀ báyìí sínú ìwé àwọn ará Kénáánì ìgbàanì.” Ǹjẹ́ irú ibi tí wọ́n forí ọ̀rọ̀ tì sí yẹn bọ́gbọ́n mu? Rárá o!

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ púpọ̀ sí i ló ti rí i pé àsọdùn gidi ni ìfiwéra tí wọ́n ṣe yẹn. Garry Brantley tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn sọ pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ inú ìwé àwọn Ugarit kankan tó bá ohun tó wà nínú Sáàmù Kọkàndínlọ́gbọ̀n mu lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Sísọ pé Sáàmù Kọkàndínlọ́gbọ̀n (tàbí àwọn ẹsẹ ìwé Bíbélì mìíràn) jẹ́ èyí tó bá ìtàn àròsọ kèfèrí kan mu kì í ṣe ohun tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá.”

Ṣé bó ṣe jẹ́ pé àwọn àkànlò èdè, ọ̀rọ̀ ewì, àti ọ̀nà ìgbàkọ̀wé wọn jọra jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé ọ̀kan náà ni wọ́n? Rárá o, jíjọra tí wọ́n jọra yẹn kì í ṣe ohun àjèjì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pé: “Àṣà ìbílẹ̀ ló mú kí ìrísí àti ọ̀rọ̀ inú wọn jọra: bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí Ugarit wà yàtọ̀ pátápátá sí ibi tí Ísírẹ́lì wà tí ẹ̀sìn wọn sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀ wọ́n jọ wà lára àwọn tó ní àṣà ìbílẹ̀ kan náà tí ewì wọn àtàwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò nínú ètò ìsìn sì bára mu.” Ohun tí Garry Brantley wá fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Ohun tí kò bójú mu rárá ni kéèyàn rin kinkin mọ́ ọn pé ìgbàgbọ́ àwọn kèfèrí ló pilẹ̀ ohun tó wà nínú Bíbélì kìkì nítorí pé èdè wọn bára mu.”

Ní òpin gbogbo rẹ̀, ó yẹ ká kíyè sí i pé bí ìjọra kankan bá wà láàárín àwọn ìwé Ras Shamra àti Bíbélì, wọ́n kan jọra ní olówuuru lásán ni, kì í ṣe ní ti ọ̀ràn ẹ̀sìn. Cyrus Gordon tó jẹ awalẹ̀pìtàn sọ pé: “Ìlànà ìwà híhù àti ti ìwà rere tó wà nínú Bíbélì [kì í ṣe] èyí tá a lè rí ní Ugarit.” Láìsí àní-àní, àwọn ìyàtọ̀ ibẹ̀ pọ̀ gan-an ju ìjọra èyíkéyìí tó lè wà níbẹ̀ lọ.

Ó ṣeé ṣe káwọn ẹ̀kọ́ Ugarit máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti lóye àwọn àṣà, ìtàn, àti bí ọ̀ràn ìsìn ṣe rí láyìíká àwọn tó kọ Bíbélì àti ní orílẹ̀-èdè Hébérù lápapọ̀. Ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìwé Ras Shamra síwájú sí i tún lè jẹ́ ká ní òye tuntun nípa èdè Hébérù ìgbàanì. Àmọ́, lékè gbogbo rẹ̀, ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí ní Ugarit jẹ́ ká rí i pé ìfọkànsìn Báálì tí ń sọni dìbàjẹ́ yàtọ̀ pátápátá sí ìjọsìn mímọ́ ti Jèhófà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn tó ń tu ọkọ̀ òkun láti erékùṣù Mẹditaréníà sí àwọn ilẹ̀ bèbè etíkun làwọn èèyàn máa ń pè ní “Àwọn Èèyàn Òkun.” Ó ṣeé ṣe káwọn Filísínì wà lára wọn.—Ámósì 9:7.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò àwọn èèyàn yàtọ̀ síra nípa rẹ̀, síbẹ̀ àwọn kan sọ pé tẹ́ńpìlì Dagan ni tẹ́ńpìlì El. Ọ̀gbẹ́ni Roland de Vaux, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní Ilẹ̀ Faransé àti ọ̀jọ̀gbọ́n ní Ilé Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Jerúsálẹ́mù, sọ pé Dagan—ìyẹn Dágónì tó wà nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ 16:23 àti ìwé 1 Sámúẹ́lì 5:1-5—ni orúkọ tí El ń jẹ́ gan-an. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀, The Encyclopedia of Religion sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “Dagan dà pọ̀ mọ́ [El] lọ́nà kan ṣáá tàbí kó wà nínú rẹ̀.” Ọmọ Báálì ni wọ́n pe Dagan nínú àwọn ìwé Ras Shamra, àmọ́ ohun tí “ọmọ” túmọ̀ sí níhìn-ín kò fi bẹ́ẹ̀ dáni lójú.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

Ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí ní Ugarit ti jẹ́ ká túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́ sí i

[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ilẹ̀ Ọba àwọn Hétì ní ọ̀rúndún kẹrìnlá ṣááju Sànmánì Tiwa

ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ

Yúfírétì

ÒKÈ CASIUS (JEBEL EL-AGRA)

Ugarit (Ras Shamra)

Tell Sukas

Orontes

SÍRÍÀ

ÍJÍBÍTÌ

[Àwọn Credit Line]

Ọwọ̀n Báálì àti àwo ìmumi tí wọ́n ṣe ní ìrísí orí ẹranko: Musée du Louvre, Paris; àwòrán ààfin: © D. Héron-Hugé pour “Le Monde de la Bible”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwókù ọ̀nà àbáwọlé ààfin náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ̀rọ̀ ewì àwọn ará Ugarit kan lè jẹ́ ká rí ìdí ohun tó wà nínú Ẹ́kísódù 23:19

[Credit Line]

Musée du Louvre, Paris

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ọwọ̀n Báálì

Àwo oníwúrà tó ń ṣàpèjúwe iṣẹ́ ọdẹ ṣíṣe

Ìdérí àpótí ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n fi eyín erin ṣe tó dúró fún abo-ọlọ́run ìbímọlémọ

[Credit Line]

Gbogbo àwòrán: Musée du Louvre, Paris

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́