Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí àwọn ọmọ Léfì kò ti ní ogún kankan ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, báwo ni Hánámélì tó jẹ́ ọmọ Léfì ṣe wá ta pápá fún Jeremáyà ọmọ Léfì tó jẹ́ ọmọ arákùnrin baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Jeremáyà 32:7 ṣe sọ?
Ohun tí Jèhófà sọ fún Áárónì nípa àwọn ọmọ Léfì ni pé: “Ìwọ kì yóò ní ogún nínú ilẹ̀ wọn, kò sì sí ìpín kankan tí yóò di tìrẹ láàárín wọn, [ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì].” (Númérì 18:20) Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì ní ìlú ńlá méjìdínláàádọ́ta àtàwọn ilẹ̀ ìjẹko wọn tó wà káàkiri Ilẹ̀ Ìlérí. Ánátótì ni ìlú Jeremáyà, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá tí wọ́n pín fún “àwọn ọmọ Áárónì, àwọn àlùfáà.”—Jóṣúà 21:13-19; Númérì 35:1-8; 1 Kíróníkà 6:54, 60.
Nínú Léfítíkù 25:32-34, Jèhófà pèsè àwọn ìtọ́ni pàtó nípa “ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà” àwọn ohun ìní tó jẹ́ ti àwọn ọmọ Léfì. Ẹ̀rí yìí fi hàn pé, ọ̀kọ̀ọ̀kan ìdílé àwọn ọmọ Léfì ló máa ní ẹ̀tọ́ ogún lórí níní àwọn ìpín pàtó kan, tí wọ́n á lè lò wọ́n tí wọ́n á sì lè tà wọ́n. Irú ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ sì kan títà àti ṣíṣe àtúnrà àwọn ohun ìní.a Ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ohun ìní, wọ́n sì ń lò wọn lọ́nà tó jọ ti ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù.
Ó sì ṣeé ṣe kí irú ohun ìní ọmọ Léfì bẹ́ẹ̀ jẹ́ èyí tó kàn wọ́n lára ogún ìdílé wọn. Ṣùgbọ́n ní ti ọ̀ràn “ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà,” àárín àwọn ọmọ Léfì nìkan ni èyí ti gbọ́dọ̀ wáyé. Bákan náà, ó jọ pé ilẹ̀ tó bá wà nínú ìlú nìkan ni ọ̀ràn pé ká ta ilẹ̀ tàbí ká tún ilẹ̀ rà kàn, nítorí pé wọn ò gbọ́dọ̀ ta “pápá ilẹ̀ ìjẹko ìlú ńlá wọn” torí pé “ohun ìní ni ó jẹ́ fún wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Léfítíkù 25:32, 34.
Nítorí náà, ó jọ pé pápá tí Jeremáyà tún rà lọ́wọ́ Hánámélì jẹ́ irú èyí tó lè di ti ẹlòmíràn nípasẹ̀ ìtúnrà. Ó lè jẹ́ pé ibi ààlà ìlú náà ni pápá ọ̀hún wà. Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́rìí sí i pé Hánámélì ló ni “pápá” tá à ń wí yìí àti pé Jeremáyà ní “ẹ̀tọ́ ìtúnrà.” Jèhófà lo ọ̀rọ̀ káràkátà yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti mú kó dáni lójú pé òun yóò mú ìlérí òun ṣẹ, pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò gba ilẹ̀ wọn padà lẹ́yìn sáà kan ní ìgbèkùn Bábílónì.—Jeremáyà 32:13-15.
Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ọ̀nà àìtọ́ ni Hánámélì fi ní ohun ìní ní Ánátótì. Kò sì sóhun tó fi hàn pé ó tẹ òfin Jèhófà lójú ní pípè tó pe Jeremáyà wá ra pápá ní Ánátótì, bẹ́ẹ̀ ni kò sóhun to fi hàn pé ọ̀nà àìtọ́ ni Jeremáyà gbà lo ẹ̀tọ́ ìtúnrà tó ní láti ra pápá náà.—Jeremáyà 32:8-15.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ọmọ Léfì náà Bánábà ta ilẹ̀ tó ní, ó sì fi owó rẹ̀ ṣètọrẹ láti fi ṣèrànwọ́ fáwọn tó jẹ́ aláìní lára àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ní Jerúsálẹ́mù. Ó lè jẹ́ pé Palẹ́sìnì ni ilẹ̀ náà wà tàbí kó wà ní Kípírọ́sì. Ilẹ̀ náà sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ilẹ̀ ìsìnkú kan tí Bánábà rà ní àgbègbè Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 4:34-37.