Inú Rẹ̀ Máa Ń Dùn sí Òfin Jèhófà
ARÁKÙNRIN Albert D. Schroeder tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà parí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ní Wednesday, March 8, 2006. Ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [94] ni, ó sì ti lo ohun tó lé ní ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin [73] nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún.
Ọdún 1911 ni wọ́n bí Arákùnrin Schroeder nílùú Saginaw, ní ìpínlẹ̀ Michigan, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.a Nígbà tó wà lọ́mọdé, ìyá ìyá rẹ̀ kọ́ ọ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó sì tún mú kó nífẹ̀ẹ́ sí kíka Ọ̀rọ̀ Jèhófà. Arákùnrin Schroeder lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa èdè Látìn, èdè Jámánì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ tó dá lórí iná mànàmáná ní Yunifásitì Michigan. Àmọ́ bí ìfẹ́ tó ní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i, ó fi ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ ní yunifásítì sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́dún 1932, ó di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn, nílùú New York.
Lọ́dún 1937, nígbà tí Arákùnrin Schroeder jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, wọ́n ní kó lọ máa bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ìtara tó ní fún iṣẹ́ ìwàásù mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn níbẹ̀ máa fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣiṣẹ́ ìwàásù bíi tirẹ̀. Orúkọ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí wọ́n jọ wà ní Bẹ́tẹ́lì nílùú London nígbà yẹn ni John E. Barr. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn méjèèjì ni wọ́n jọ wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí.
Láwọn ọdún tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ò ṣàìrí àwọn ohun tí Arákùnrin Schroeder ń ṣe láti ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ níbẹ̀. Nígbà tó wá di August 1942, wọ́n ní kó kúrò lórílẹ̀-èdè àwọn. Ó padà dé Brooklyn lóṣù September lẹ́yìn ìrìn àjò ìgbà ogun tó rìn lórí Òkun Àtìláńtíìkì.
Nígbà yẹn, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń wò ó pé iṣẹ́ bàǹtà-banta làwọn ṣì máa ṣe lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún Arákùnrin Schroeder nígbà tó gbọ́ iṣẹ́ tí wọ́n tún yàn fún un, síbẹ̀ tayọ̀tayọ̀ ló fi gbà á. Wọ́n sọ pé yóò wà lára àwọn tí yóò ṣètò ẹ̀kọ́ tí wọn yóò máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ olùkọ́ níbẹ̀, tó ń kọ́ àwọn tó máa di míṣọ́nnárì. Àwọn tó kọ́ ní Gílíádì àtàwọn tó tún kọ́ lẹ́yìn ìyẹn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ṣì máa ń rántí bó ṣe ń kọ́ àwọn. Inú rẹ̀ máa ń dùn láti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́nà tí wọ́n lè gbà nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run, ó sì máa ń tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn mọ Jèhófà.
Lọ́dún 1956, ó fẹ́ omidan Charlotte Bowin, nígbà tó sì di ọdún 1958, wọ́n bí ọmọ wọn ọkùnrin tí wọ́n sọ ní Judah Ben. Olórí ìdílé rere ni Arákùnrin Schroeder, ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Lọ́dún 1974, wọ́n ní kó wá di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, òye tó ní sì wúlò gan-an níbẹ̀. Ẹni pẹ̀lẹ́ ni, onírẹ̀lẹ̀ ni, ó sì jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ láti gbé orúkọ ńlá Jèhófà ga. Ó dá wa lójú pé Arákùnrin Schroeder ti gba èrè rẹ̀ lọ́run báyìí torí pé Kristẹni ẹni àmì òróró tó fi tọkàntọkàn ní ‘ìdùnnú sí òfin Jèhófà’ ni.—Sáàmù 1:2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn ìgbésí ayé arákùnrin Schroeder wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti March 1, 1988.