Ìpadàbẹ̀wò Tí Yóò Yọrí sí Rere Ń Béèrè fún Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Tí Ó Gbéṣẹ́
1 Ìpadàbẹ̀wò jẹ́ apá pàtàkì nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá wa ó sì kún fún ìdùnnú-ayọ̀. Èéṣe tí a fi níláti jẹ́ aláápọn nínú pípadà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí ó fi ìfẹ́ hàn? A ń sọ orúkọ Jehofa di mímọ̀ a sì ń bu ọlá fún un nípa iṣẹ́ sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn yìí, a sì ń ran àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà ìyè. (2 Kor. 2:17–3:3) Lílóye pé ó kan ìsọdimímọ́ orúkọ Jehofa àti ìwàláàyè àwọn ẹlòmíràn yẹ kí ó sún wa láti múra sílẹ̀ dáradára ṣáájú kí a tó padà lọ.
2 Olùkọ́ rere kan yóò ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mú ìmọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú lórí ìpìlẹ̀ tí ó tí fi lélẹ̀ tẹ́lẹ̀. Gan-an gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ti ń mú ìmọ̀ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń jèrè láti ọjọ́ dé ọjọ́ tẹ̀síwájú, àwa pẹ̀lú níláti ṣiṣẹ́ lórí ìkésíni wa àkọ́kọ́ pẹ̀lú àlàyé síwájú sí i lórí kókó-ẹ̀kọ́ kan náà. Èyí ń yọrí sí èrò tí ń bá a lọ àti ìrònú tí ń tẹ̀síwájú.
3 Nígbà tí o bá padà lọ lẹ́yìn tí o ti fi ìwé pẹlẹbẹ náà “Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?” síta, o lè rí èyí gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó gbéṣẹ́:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi ìṣáájú, a jíròrò nípa ‘awọn ọjọ́ ìkẹyìn’ tí a mẹ́nukàn nínú Bibeli àti ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa. O lè ṣe kàyéfì nípa bí a ṣe mọ̀ pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (2 Tim. 3:1) Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu háragàgà láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. [Ka Matteu 24:3.] Nínú ìdáhùn rẹ̀, Jesu ṣàpèjúwe àwọn ipò ti a ń rí ní àyíká wa lónìí. Hílàhílo àti ìwà-ipá tí a kò rí irú rẹ̀ rí wà lára wọn.” Ṣàlàyé àwọn apá-ẹ̀ka àmì náà tí a jíròrò ní ìpínrọ̀ 3 àti 4 ní ojú-ìwé 19. Bí ìdáhùnpadà náà bá dára, ṣàlàyé àwọn apá-ẹ̀ka àmì náà mìíràn ní ìpínrọ̀ 5 sí 8 ní ojú-ìwé 20. Dábàá pípadà wá láti dáhùn àwọn ìbéèrè tí a gbé dìde ní iwájú ìwé pẹlẹbẹ náà.
4 Láti ṣiṣẹ́ lórí ìfẹ́-ọkàn tí a fi hàn nínú ìwé pẹlẹbẹ náà “Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, o lè sọ pé:
◼ “Mo ti ń háragàgà láti tún bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wa nípa ète wa nínú ìgbésí-ayé lẹ́ẹ̀kan síi. Mo lérò pé a jọ gbà pé Ọlọrun ń fẹ́ kí a gbé lórí ilẹ̀-ayé yìí nínú ipò ayọ̀ àti àlàáfíà dípò nínú yánpọnyánrin tí a ń nírìírí rẹ̀ lónìí. Ìwọ ha rò pé òun yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ka Isaiah 55:11, lẹ́yìn náà kí o jíròrò àwọn èrò tí ó wà ní ìpínrọ̀ 25 sí 27 ní ojú-ìwé 30. Dámọ̀ràn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ara-ẹni gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti rí ète tí ó nítumọ̀ nínú ìgbésí-ayé.
5 Láti ṣíṣẹ lórí ìfẹ́-ọkàn tí a fi hàn ní ìṣáájú nínú ìwé pẹlẹbẹ náà “Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!” o lè fi í hàn lẹ́ẹ̀kan sí i kí o sì sọ pé:
◼ “A sọ̀rọ̀ nípa ayé ẹlẹ́wà tí a fi àwòrán ṣàpèjúwe síwájú ìwé pẹlẹbẹ yìí. Mo fẹ́ sọ fún ọ ìdí tí ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi fi ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn tí ó fẹ́ láti gbé níbẹ̀.” Ṣí i sí àwòrán 41, kí o sì ka Isaiah 9:6. Tọ́ka sí àwòrán 62, kí o sì ka Johannu 3:16, ní títẹnumọ́ ìdí tí ó fi yẹ láti ṣègbọràn. Ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn láti kọ́ bí wọn yóò ṣe lo ìgbàgbọ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti gbígbìyànjú láti tẹ̀lé àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀.
6 Lẹ́yìn ìpadàbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan, ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ète láti mú ìgbéṣẹ́ rẹ sunwọ̀n sí i. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: Mo ha ní ohun tí ó ṣe gúnmọ́ lọ́kàn láti sọ? Mo ha darí àfiyèsí sórí Bibeli bí? Mo ha mú ìmọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú lórí ìpìlẹ̀ tí mo fi lélẹ̀ nígbà ìkésíni àkọ́kọ́ bí? Mo ha gbé ọ̀rọ̀ mi kalẹ̀ ní ọ̀nà tí yóò ṣamọ̀nà sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bí? Dídáhùn bẹ́ẹ̀ni sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ń mú un dá ọ lójú pé o ń sapá láti jẹ́ olùkọ́ni rere ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.