Ṣe Ìpínlẹ̀ Rẹ Kúnnákúnná
1 Ní agbègbè tí àwọn ènìyàn ń gbé, a sábà máa ń rí àwọn ibi ìṣòwò kéékèèké, irú bí ilé ìtajà, ilé àrójẹ, tàbí ìsọ̀ níbẹ̀. Bí ìwọ yóò bá kárí àwọn ibi ìṣòwò wọ̀nyí pẹ̀lú ìyóókù ìpínlẹ̀ náà, o ní láti wàásù níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí o ti ń wàásù ní àwọn ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé.
2 O lè lo ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí, tí kò nira, bóyá kí o sọ pé: “Mo ní ohun kan tí n óò fẹ́ láti fi hàn ọ́.” Bí ọwọ́ onísọ̀ náà bá jọ bíi pé ó dí díẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, o kàn lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú lọ̀ ọ́, kí o sì sọ pé: “N óò padà wá nígbà tí ọwọ́ rẹ kò bá fi bẹ́ẹ̀ dí. N óò fẹ́ láti mọ ohun tí o rò nípa ìwé àṣàrò kúkúrú yìí.”
3 Kò sí ìdí láti ṣojo nípa ṣíṣe ìṣẹ́ yìí. Akéde kan ròyìn pé: “Mo ti lérò pé ìdáhùnpadà náà kò ní dára. Ṣùgbọ́n, sí ìyàlẹ́nu mi, òdìkejì pátápátá gbáà ni ìdáhùnpadà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà já sí. Wọ́n fi ọ̀wọ̀ àtinúwá hàn, wọ́n sì ṣe bí ọ̀rẹ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n ń tẹ́wọ́ gba ìwé ìròyìn.”
4 Obìnrin kan tí ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ tí ń bójú tó kíkọ́ ilé àti ríra ilẹ̀, ké sí àwọn Ẹlẹ́rìí wá sínú ọ́fíìsì rẹ̀. Ó tẹ́wọ́ gba àwọn ìwé ìròyìn, ó sì fìfẹ́ hàn nínú ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A fi ìwé Ìmọ̀ hàn án, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ lójú ẹsẹ̀, nínú ọ́fíìsì rẹ̀ gan-an!
5 Iṣẹ́ ṣíṣe ìpínlẹ̀ rẹ kúnnákúnná kan kíké sí àwọn ènìyàn tí ń ṣòwò pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ládùúgbò. (Ìṣe 10:42) Wéwèé láti wàásù ní àwọn ibi wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí o ti ń wàásù ní àwọn ibi tí àwọn ènìyàn ń gbé. Kì í ṣe pé èyí yóò jẹ́ kí o túbọ̀ kárí ìpínlẹ̀ rẹ kúnnákúnná sí i nìkan ni, ṣùgbọ́n o tún lè ní ìrírí alárinrin!