A Tóótun, A sì Gbára Dì Láti Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn
1 Nígbà tí a yan Mósè gẹ́gẹ́ bí aṣojú Jèhófà, kò rò pé òun tóótun láti polongo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún Fáráò. (Ẹ́kís. 4:10; 6:12) Jeremáyà fi àìní ìgbọ́kànlé nínú ìtóótun rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Jèhófà hàn, ní sísọ fún Ọlọ́run pé, òun kò mọ̀rọ̀ọ́ sọ. (Jer. 1:6) Láìka àìní ìgbọ́kànlé wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ sí, àwọn wòlíì méjèèjì wọ̀nyẹn fẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó gbóyà. Ọlọ́run mú wọn tóótun dáradára.
2 Lónìí, lọ́lá Jèhófà, a ní gbogbo ohun tí a nílò láti fi ìgbọ́kànlé ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (2 Kọ́r. 3:4, 5; 2 Tím. 3:17) Bíi mẹkáníìkì kan tí ó tóótun, tí irinṣẹ́ rẹ̀ pé, a ti mú wa gbára dì dáradára láti fi ìjáfáfá ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a yàn fún wa. Ní January, a óò ṣe àkànṣe ìfilọni ìwé Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, àti Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi? Bí àwọn irinṣẹ́ tẹ̀mí wọ̀nyí kì í tilẹ̀ í ṣe tuntun, àwọn ẹṣin ọ̀rọ̀ wọn tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ ṣì bá ìgbà mu, àwọn ìwé wọ̀nyí yóò sì ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. A lè mú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dámọ̀ràn nísàlẹ̀ yí bá ìwé èyíkéyìí tí a ń fi lọni mu.
3 A lè lo ọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ láti ru ìfẹ́ sókè nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. O lè bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ nípa sísọ pé:
◼ “A ń gbé ìjẹ́pàtàkì karí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ jíjíire lónìí. Ní èrò tìrẹ, irú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wo ni ó yẹ kí ẹnì kan lépa, tí yóò mú ayọ̀ gíga jù lọ àti àṣeyọrí nínú ìgbésí ayé dájú? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn tí ó gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú lè jèrè àǹfààní ayérayé. [Ka Òwe 9:10, 11.] Orí Bíbélì ni a gbé ìwé yìí, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, kà. Ó tọ́ka sì orísun ìmọ̀ kan ṣoṣo tí ó lè sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.” Ṣí i sí orí 3, kí o sì ka ìpínrọ̀ 1 àti 2, lábẹ́ àkòrí rẹ̀, “A Dá Eniyan Lati Wà Laaye.” Bí ó bá fi ojúlówó ìfẹ́ hàn, fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún ₦50, kí o sì ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò.
4 Nígbà tí o bá ń ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ onílé tí o bá jíròrò ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì, o lè sọ pé:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kọjá, a jíròrò pé Bíbélì jẹ́ orísun ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó lè mú ọjọ́ ọ̀la ayérayé dáni lójú. Ní tòótọ́, ó gba ìsapá láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí a ní láti mọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́. [Ka Òwe 2:1-5.] Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti lóye àwọn apá kan nínú Bíbélì. Èmi yóò fẹ́ láti fi ọ̀nà kan tí a ti lò dáradára láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì hàn ọ́.” Ní lílo ìwé tí o fi sílẹ̀ fún un, ṣí i sí orí 1, kí o sì ka ìpínrọ̀ 1 sí 3. Béèrè àwọn ìbéèrè mélòó kan láti mú onílé náà wọ inú ìjíròrò náà. Bí onílé bá ń fẹ́ láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé, ṣàlàyé pé ìwọ yóò pa dà wá pẹ̀lú ìwé tí a fi ń bá àwọn ènìyàn kẹ́kọ̀ọ́, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.
5 Ìyà tí ń jẹ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé nínú ayé ń ba ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú jẹ́. Bóyá o lè ran onílé lọ́wọ́ láti mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìṣòro yìí, nípa sísọ pé:
◼ “Kò sí àníàní pé o ti rí ìròyìn nípa àwọn ọmọdé yíká ayé tí ebi ń pa, tí àìsàn ń ṣe, tí wọn kò sì rí ẹni tọ́jú wọn. Èé ṣe tí kò fi ṣeé ṣe fún àwọn àjọ afẹ́nifẹ́re láti mú ipò náà sunwọ̀n sí i? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ohun tí ó dára jù lọ ni Ọlọ́run ń fẹ́ fún ènìyàn. Kíyè sí ohun tí ó ṣèlérí fún àwọn ọmọdé àti àgbà, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Bíbélì. [Ka Ìṣípayá 21:4.] Ìwé yìí, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, pèsè ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa ayé kan tí Ọlọ́run yóò mú wá, níbi tí kò ti ní sí ìjìyà mọ́.” Ṣí i sí àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 29, kí o sì fi bí ọjọ́ ayé ènìyàn tí ó kúrú kò ṣe bọ́gbọ́n mu hàn. Fi ìwé náà lọni fún ọrẹ ₦50, kí o sì ṣètò fún ìbẹ̀wò míràn.
6 Bí ó bá jẹ́ pé ìjìyà àwọn ọmọdé ni ẹ sọ̀rọ̀ lé lórí nígbà ìkésíni rẹ àkọ́kọ́, o lè máa bá ìjíròrò náà lọ, nígbà ìbẹ̀wò tí o ṣe tẹ̀ lé e, nípa sísọ pé:
◼ “Nígbà tí mo wá síbí lẹ́nu àìpẹ́ yìí, o ṣàníyàn nípa ipò àwọn ọmọdé tí wọ́n ń jìyà nítorí ìdílé fífọ́, ìyàn, àìsàn, àti ìwà ipá. Ó ń tuni nínú láti kà nínú Bíbélì nípa ayé kan níbi tí àwọn ọmọdé àti àgbàlagbà kì yóò ti jìyà lọ́wọ́ àìsàn, ìrora, tàbí ikú. Àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Aísáyà ṣàpèjúwe ìgbésí ayé dídára kan tí yóò wà lórí ilẹ̀ ayé.” Ka Aísáyà 65:20-25, kí o sì ṣàlàyé rẹ̀. Jẹ́ kí ó ṣamọ̀nà sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Ìmọ̀, nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
7 Níwọ̀n bí àṣà gbígbàdúrà ti wọ́pọ̀ láàárín àwọn onísìn, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lórí àkòrí yìí nípa sísọ pé:
◼ “Ní àkókò kan nínú ìgbésí ayé wa, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ti bá àwọn ìṣòro pàdé, tí ó ti sún wa láti gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nímọ̀lára pé a kò gbọ́ àdúrà àwọn. Ó tilẹ̀ hàn gbangba pé a kò gbọ́ àdúrà àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n ń gbàdúrà ní gbangba fún àlàáfíà. A sọ èyí nítorí pé, ogun àti ìwà ipá ń bá a lọ láti yọ aráyé lẹ́nu. Ọlọ́run ha ń gbọ́ àdúrà ní ti gidi bí? Bí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí ó fi jọ pé kì í dáhùn ọ̀pọ̀ àdúrà? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Orin Dáfídì 145:18 ṣàlàyé ohun tí a ń béèrè lọ́wọ́ wa bí a bá fẹ́ kí ó gbọ́ àdúrà wa. [Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà.] Ohun kan ni pé, àwọn àdúrà tí a ń gbà sí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ àtọkànwá, kí ó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì.” Fi ìwé Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi? han onílé. Tọ́ka sí àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ inú Mátíù 6:9, 10, àti ìjẹ́pàtàkì Ìjọba Ọlọ́run. Ṣí i sí ojú ìwé 155, lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Ete Iṣakoso Naa,” kí o sì ka ìpínrọ̀ 21 àti 22. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún ₦50.
8 Nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́ lórí ìjíròrò rẹ àkọ́kọ́ nípa àdúrà, o lè gbìyànjú ọ̀nà ìyọsíni yìí:
◼ “Mo gbádùn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wa nípa àdúrà. Ó dájú pé, ìwọ yóò rí èrò Jésù nípa ohun tí a lè gbàdúrà fún gẹ́gẹ́ bí amọ̀nà wíwúlò.” Ka Mátíù 6:9, 10 lẹ́ẹ̀kan sí i, ní títọ́ka sí àwọn ohun tí ó kanni gbọ̀ngbọ̀n tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Fi orí 16, “Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun,” nínú ìwé Ìmọ̀ hàn án, kí o sì béèrè bóyá o lè fi bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà hàn án.
9 Nígbà tí ó bá kan fífi ìmọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn ẹlòmíràn, a lè béèrè pé, “Ta ni . . . tóótun tẹ́rùntẹ́rùn fún nǹkan wọ̀nyí?” Ìwé Mímọ́ dáhùn pé: “Àwa ni.”—2 Kọ́r. 2:16, 17.