Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Ní Ohun Tí Ọlọ́run Ń Béèrè
1 A ṣì lè rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí a ti fi “gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa” dù. (Ámósì 8:11) Nígbà tí àwọn kan gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, wọn kò mọ̀ nípa ète rẹ̀ àti àwọn ohun tí ó ń béèrè. Nípa báyìí, àìní wà fún wa láti kọ́ wọn ní òtítọ́ Ìjọba tí ń gbẹ̀mí là. Nípa gbígbáradì àti mímúratán lọ́nà yíyẹ láti jẹ́rìí ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀, a lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Jèhófà ń béèrè.
2 Ní oṣù April àti May, a óò ní àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí ó bágbà mu láti pín kiri. Ní àfikún sí i, fún ìgbà àkọ́kọ́, a óò gbé ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? jáde lákànṣe. Àwọn àwòrán fífani mọ́ra àti àwọn ìbéèrè tí ń múni ronú tí ó ní mú kí ọ̀pọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìwé pẹlẹbẹ yìí. A fúnni ní àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí láti ràn wá lọ́wọ́ láti lo àwọn ìtẹ̀jáde àtàtà tí a ní lọ́nà gbígbéṣẹ́.
3 Wíwá Àwọn Ènìyàn Rí: Ní àwọn àgbègbè tí àwọn ènìyàn kì í ti í sí nílé nígbà tí a bá ń ké síni láti ilé dé ilé, ẹ̀rí ń fi hàn pé ó ṣàǹfààní láti wá àwọn ènìyàn rí, kí a sì bá wọn sọ̀rọ̀ níbikíbi tí a ti lè rí wọn—lójú pópó, nínú ọkọ̀ èrò, ní ibùdókọ̀, àti ní àwọn ibi iṣẹ́ ajé. A ní láti wá àǹfààní láti wàásù láìjẹ́ bí àṣà. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan nínú èyí, arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan lọ sí ọgbà ẹranko, ó sì kó ẹ̀dà Jí! ti August 8, 1996 dání, tí ó ní ọ̀wọ́ àkòrí náà, “Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Èrèdí Ìdàníyàn?” Láàárín wákàtí kan, ó fi 40 ẹ̀dà sóde fún àwọn kan tí wọ́n mọrírì, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹranko! Àṣeyọrí wo ni o ti ní nípa wíwàásù ìhìn rere náà dé ibi gbogbo? Ilé Ìṣọ́ àti Jí! títí kan ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ní pàtàkì bá gbogbo onírúurú ìjẹ́rìí mu, nítorí pé wọ́n ń gbé ìsọfúnni tí ó kan ìgbésí ayé àwọn ènìyàn jáde lákànṣe, tí ó sì ń sún agbára ìrònú ṣiṣẹ́.
4 Bíbẹ̀rẹ̀ Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀: Ojú ewé tí ó kẹ́yìn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996, pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ lórí bí o ṣe lè múra ìgbékalẹ̀ tìrẹ sílẹ̀ fún àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àbá kan náà yóò gbéṣẹ́ dáradára nígbà tí o bá ń múra ìgbékalẹ̀ tìrẹ fún ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Ohun tí a óò sọ lè ṣe ṣókí bíi gbólóhùn mélòó kan tàbí ó lè gùn díẹ̀ láti ní èrò Ìwé Mímọ́ kan nínú. Ó ṣe pàtàkì láti ṣàṣàyàn àwọn ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ dáradára, níwọ̀n bí wọ́n ti lè pinnu bóyá ẹni náà tí o tọ̀ lọ yóò máa bá a nìṣó láti tẹ́tí sí ọ. Àwọn kan ti ṣàṣeyọrí ní lílo gbólóhùn ìbẹ̀rẹ̀ yí: “Mo ka àpilẹ̀kọ kan tí ó fún mi níṣìírí, mo sì fẹ́ bá ọ ṣàjọpín rẹ̀.” Tàbí, o lè béèrè ìbéèrè kan tí ń fani lọ́kàn mọ́ra láti mú ẹnì kejì wọnú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀.
5 Bí ó bá bá àgbègbè rẹ mu, o lè gbìyànjú bíbéèrè àwọn ìbéèrè bí àwọn tí ó tẹ̀ lé e yìí nínú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ nínú oṣù yí:
◼ “Lónìí, a ń rí ọ̀pọ̀ ìdọ̀tí àti ìbàyíkájẹ́. Kí ni a nílò láti mú kí ilẹ̀ ayé mọ́ tónítóní, kí ó sì di ibì kan tí ó sàn jù láti máa gbé?” Jẹ́ kí ó fèsì, lẹ́yìn náà, ṣàlàyé pé o ní ìsọfúnni tí ó mú bí ilẹ̀ ayé yóò ṣe di ọgbà kan kárí ayé, àti ìgbà tí yóò dà bẹ́ẹ̀ dá wa lójú. Ṣàjọpín gbólóhùn kan pàtó, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ṣíṣe ṣókí, àti àwòrán fífani mọ́ra láti inú ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́, kí o sì fi àsansílẹ̀ owó lọ ẹni náà ní iye ọrẹ tí a ń fi í sóde. Kí o tó parí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ náà, gbìyànjú láti ṣètò láti máa bá a nìṣó ní àkókò míràn.
◼ “O ha rò pé Ọlọ́run pète pé kí a máa gbé nínú wàhálà, irú ìwọ̀nyí tí a ń dojú kọ lónìí bí?” Lẹ́yìn ìdáhùn ẹni náà, o lè sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí o mọ àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbà, ní bíbéèrè pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ní àmọ̀dunjú. O ha ti ronú nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ gan-an bí?” Ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 6, kí o sì ka àwọn ìbéèrè tí a tò sí ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà. Lẹ́yìn náà, bí o ti ń ka ìpínrọ̀ 1, tọ́ka sí ìdáhùn sí ìbéèrè àkọ́kọ́. Ṣàlàyé pé a dáhùn àwọn ìbéèrè yòó kù pẹ̀lú lọ́nà ṣíṣe ṣókí. Fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ fún ọrẹ ₦25, kí o sì yọ̀ǹda láti pa dà wá láti bá a ṣàjọpín ìsọfúnni púpọ̀ sí i nípa Ìjọba náà.
◼ “Ọ̀pọ̀ àwọn onírònú ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwọn ìsìn ayé gẹ́gẹ́ bí orísun àwọn ìṣòro tí ènìyàn ní, dípò kí wọ́n jẹ́ ojútùú sí wọn. Kí ni o rò nípa ìyẹn?” Lẹ́yìn títẹ́tí sí ojú ìwòye ẹni náà, fi ohun kan tí ó lè gba àfiyèsí rẹ̀ nípa kíkùnà tí ìsìn èké kùnà tàbí nípa ìṣubú rẹ̀ tí ó ń sún mọ́ etílé hàn án láti inú ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́, kí o sì fi àsansílẹ̀ owó lọ̀ ọ́. Ẹ sọ orúkọ fúnra yín, kí o sì yọ̀ǹda láti pa dà wá kí o lè ṣàlàyé bí ó ṣe jẹ́ tí ìsìn tòótọ́ kò fi tí ì já aráyé kulẹ̀.
◼ “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìṣòro nínú ìgbésí ayé ìdílé lónìí, o ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ohun tí ó jẹ́ àṣírí rírí ayọ̀ ìdílé?” Dúró kí ó fèsì, kí o sì ṣàlàyé pé nínú Bíbélì, Ọlọ́run fi àṣírí gidi ti ayọ̀ ìdílé hàn. Bóyá o lè ka Aísáyà 48:17. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 8, kí o sì tọ́ka sí mélòó kan nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí tí ó pèsè ìtọ́sọ́nà ṣíṣeé gbára lé fún mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé. Ka ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìbéèrè tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà. Béèrè bí ẹni náà yóò bá fẹ́ láti ka ìdáhùn wọn. Bí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ fún ọrẹ tí a fi ń fi sóde. Ṣètò láti pa dà wá ní àkókò míràn láti ṣàjọpín ìtọ́sọ́nà ṣíṣeé mú lò síwájú sí i tí Bíbélì ní fún ayọ̀ ìgbésí ayé ìdílé.
6 Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1997, fún wa níṣìírí láti máyà le láti ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ó dábàá lílo ìwé pẹlẹbẹ Béèrè láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí kò bá jẹ́ nígbà ìkésíni àkọ́kọ́, nígbà náà, kí ó jẹ́ nígbà ìpadàbẹ̀wò. Àìní aráyé tí ó ga jù lọ jẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè, kí wọ́n sì ṣe é. (Kól. 1:9, 10) A óò ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní gidigidi nínú oṣù April àti May bí a bá lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ohun tí a mọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè fún ìyè.—1 Kọ́r. 9:23.