Jẹ́rìí Níbikíbi Tí Àwọn Ènìyàn Bá Wà
1 Ní mímọ ipa tí ẹ̀mí Ọlọ́run kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.” Ó tún sọ pé: “Àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:5-9) Àǹfààní àgbàyanu ni èyí jẹ́. Báwo ni a ṣe lè fi hàn ní gbangba pé a mọrírì jíjẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run? Nípa pípolongo ìhìn rere náà fún gbogbo ẹni tí a bá bá pàdé nínú iṣẹ́ ilé dé ilé àti níbikíbi mìíràn.
2 A pàṣẹ fún wa láti “sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19) Bí ó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ni a kàn sí nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, a lè tètè rẹ̀wẹ̀sì kí a sì ronú pé a kò fi bẹ́ẹ̀ ṣàṣeparí nǹkan. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a máa ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa jù lọ nígbà tí a bá lè rí ọ̀pọ̀ ènìyàn kí a sì bá wọn jíròrò. Èyí lè jẹ́ ohun tí ó ṣòro, níwọ̀n bí ó ti ń béèrè ìdánúṣe díẹ̀ lọ́wọ́ wa láti lọ sí ibikíbi tí àwọn ènìyàn bá wà kí a baà lè kàn sí wọn.
3 Àwọn Àpẹẹrẹ Gbígbéṣẹ́: A lè jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn nínú ọjà, nínú ọgbà ìtura, ní ibi tí bọ́ọ̀sì gbé ń dúró, àti ní ìkòríta tí èrò ti ń wọkọ̀. Nígbà tí o bá wọkọ̀ èrò, o ha múra tán láti jẹ́rìí bí ẹ ti ń lọ bí? Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n wọ bọ́ọ̀sì tí ó kún fọ́fọ́ lọ sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ lórí àwòrán Párádísè tí ó wà nínú ìwé Ìmọ̀, ní jíjíròrò nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run fún ọjọ́ ọ̀la. Bí wọ́n ti retí pé yóò rí, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó dúró sí itòsí wọn fetí sílẹ̀, ohun tí ó sì gbọ́ wú u lórí. Kí ó tó bọ́ọ́lẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì náà, ó gba ìwé kan ó sì sọ pé kí ẹnì kan bẹ ilé òun wò.
4 Ọ̀pọ̀ akéde ti rí ìdùnnú nínú jíjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, arábìnrin kan lọ sí ibi tí àwọn ènìyàn ti ń rajà ládùúgbò, ó sì tọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ra ohun tí wọ́n fẹ́ rà tán ṣùgbọ́n tí kò dà bíi pé ojú ń kán wọn lọ. Ó fi gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà nínú àpò rẹ̀ síta. Ọkùnrin kan tí ó jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ láyọ̀ láti gba àwọn ìwé ìròyìn lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ti lọ sí àwọn ìpàdé rí, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wọn sì ta ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ jí lẹ́ẹ̀kan sí i.
5 Ó jẹ́ àǹfààní láti gbé orúkọ Jèhófà ga. Nípa fífi ìtara wa hàn fún iṣẹ́ ìwàásù, a ń fi hàn pé a kò tí ì tàsé ète inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run ní sí wa. Nítorí pé “Nísinsìnyí ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì” láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibikíbi tí àwọn ènìyàn bá wà kí a sì jẹ́rìí fún wọn nípa “ọjọ́ ìgbàlà” ti Jèhófà.—2 Kọ́r. 6:1, 2.