A Gbọ́dọ̀ Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Ènìyàn Léraléra
1 Ṣé o dáhùn padà lọ́nà rere nígbà àkọ́kọ́ tí ẹnì kan bá ọ sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere náà? Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ kún fún ìmoore pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dé ọ̀dọ̀ rẹ léraléra títí tí o fi tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó yẹ kí o máa ronú nípa ìyẹn nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́ léraléra ní ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ọ.
2 Ìgbésí ayé àwọn ènìyàn ń yí padà léraléra. Onírúurú ìṣòro àti ipò ni ó ń dojú kọ wọ́n, wọ́n lè gbọ́ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń dààmú ẹni ní àgbègbè wọn tàbí nínú ayé, ọrọ̀ ajé wọn lè dẹnu kọlẹ̀, wọ́n lè ṣàìsàn, ikú sì lè pa ẹnì kan nínú ìdílé wọn. Irú àwọn nǹkan báyìí lè mú kí wọ́n fẹ́ láti mọ ìdí fún àwọn ohun tí ń múni sorí kọ́ wọ̀nyí. A gbọ́dọ̀ fòye mọ ohun tí ń ba àwọn ènìyàn lọ́kàn jẹ́ kí a sì fi ìhìn iṣẹ́ tí ń tuni nínú dáhùn padà.
3 Iṣẹ́ Ìgbẹ̀mílà Ni Èyí: Ronú nípa àwọn òṣìṣẹ́ tí ń gbẹ̀mí là ní ibi tí ìjábá ti ṣẹlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùlàájá lè má pọ̀ ní àgbègbè tí àwọn kan ti ń wá àwọn olùlàájá, síbẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà kì yóò dẹwọ́ kí wọ́n sì dá iṣẹ́ dúró nítorí pé àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ń rí àwọn olùlàájá púpọ̀ sí i ní apá ibòmíràn. Iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tí a ń ṣe kò tí ì dópin. Lọ́dọọdún, a ń rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún tí wọ́n fẹ́ láti la “ìpọ́njú ńlá náà” já.—Ìṣí. 7:9, 14.
4 “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” (Róòmù 10:13-15) Ó yẹ kí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tẹ̀ ẹ́ mọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́kàn pé ó yẹ kí a tẹra mọ́ wíwàásù. Láti ìgbà tí a ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ní ìpínlẹ̀ wa títí di ìsinsìnyí, àwọn ọmọ ti dàgbà, wọ́n sì ti gbọ́njú débi tí àwọn fúnra wọn fi lè ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wọn àti ète ìgbésí ayé. Kò sí bí a ṣe lè mọ ẹni tí yóò fetí sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Oníw. 11:6) Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó jẹ́ alátakò tẹ́lẹ̀ rí ni ó ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Kí a máa bá a nìṣó láti fún àwọn ènìyàn ní àǹfààní láti gbọ́ kí a sì gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ ayé ògbólógbòó yìí ni iṣẹ́ wa, kì í ṣe láti dá wọn lẹ́jọ́. Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti ṣe ní ìjímìjí, a gbọ́dọ̀ “lọ” sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn “léraléra” kí a sì gbìyànjú láti ru ọkàn-ìfẹ́ wọn sókè nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà.—Mát. 10:6, 7.
5 Pé a ṣì ní àǹfààní láti wàásù jẹ́ ìfihàn àánú Jèhófà. (2 Pét. 3:9) Bí a ṣe ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn gbọ́ ìhìn iṣẹ́ náà léraléra, a ń tànmọ́lẹ̀ sí ìfẹ́ Ọlọ́run, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ìyìn fún un.