ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/99 ojú ìwé 3
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Irin Iṣẹ́ Tuntun Láti Ran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Mọ Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Ń béèrè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀, Láìjẹ́ Pé Ẹnì Kan Fi Mí Mọ̀nà?”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ṣé Ò Ń Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 7/99 ojú ìwé 3

Àpótí Ìbéèrè

◼ Àwọn ìtẹ̀jáde wo ló yẹ ká fi bá àwọn ẹni tuntun kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n tó lè ṣe batisí?

Kí ẹnì kan tó lè ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, kí ó sì ṣe batisí, ó gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ pípéye. (Jòh. 17:3) Yóò rí ìsọfúnni tí ó nílò gbà nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé méjì, èyíinì ni, ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? àti ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bó ti sábà máa ń rí, ìwé pẹlẹbẹ Béèrè la kọ́kọ́ máa ń kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti bẹ̀rẹ̀ nínú ìwé Ìmọ̀, a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lẹ́yìn táa bá kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ tán. Èé ṣe tí èyí fi pọndandan?

Ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ṣe àkópọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ inú Bíbélì. Bó bá jẹ́ òun ni akẹ́kọ̀ọ́ náà kọ́kọ́ kà, yóò jẹ́ kí ó lóye ìpìlẹ̀ nípa àwọn ohun tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ kí ó bàa lè wu Jèhófà. Bó bá jẹ́ òun ló kà gbẹ̀yìn, yóò jẹ́ àtúnyẹ̀wò tó gbámúṣé nípa ohun tó kà nínú ìwé Ìmọ̀. Èyí ó wù kó jẹ́, fún akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí láti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti kókó wọ̀nyẹn lẹ́yìn, kí ó sì ṣàṣàrò lórí wọn. Rí i dájú pé o pe àfiyèsí pàtàkì sáwọn àwòrán, torí pé wọ́n gbéṣẹ́ gan-an nínú kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.—Wo Ilé Ìṣọ́ January 15, 1997, ojú ìwé 16 àti 17.

Lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé méjèèjì, yóò lè dáhùn gbogbo ìbéèrè táwọn alàgbà yóò ṣàtúnyẹ̀wò pẹ̀lú rẹ̀ ní mímúra rẹ̀ sílẹ̀ fún batisí. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè má pọndandan láti bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àṣà nínú ìtẹ̀jáde mìíràn, ṣùgbọ́n olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní láti máa bá a lọ lójú méjèèjì ní wíwá ìtẹ̀síwájú akẹ́kọ̀ọ́ náà.—Wo Ilé Ìṣọ́nà, January 15, 1996, ojú ìwé 14 àti 17.

Ṣùgbọ́n o, a lè jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ kan tí kò kàwé púpọ̀ ṣe batisí lẹ́yìn tó bá parí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, kódà bí kò bá tíì kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ tán. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ní láti mọ òtítọ́ dunjú, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi lè lóye àwọn ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, èyí tó wà fáwọn tó fẹ́ ṣe batisí, kí ó sì lè dáhùn wọn. Ní ti irú ẹni bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó nínú ìwé Ìmọ́ títí yóò fi parí rẹ̀, àní lẹ́yìn táa bá ti batisí rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́