Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Apr. 15
“Ibi yòówù káwọn èèyàn máa gbé, ohun tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ ló máa ń jẹ wọ́n lógún, irú bíi níní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó tẹ́ wọn lọ́rùn, tí kò sì ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Àmọ́, ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú rí nípa bóyá orísun ìfọ̀kànbalẹ̀ pípẹ́ títí kan wà, èyí tó máa jẹ́ kí ọkàn rẹ lè balẹ̀ títí ayé? [Ka Sáàmù 16:8, 9.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ibi tá a ti lè rí ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀.”
Ilé Ìṣọ́ May 1
“Ǹjẹ́ o mọ ẹnikẹ́ni tó ń ṣàìsàn líle koko tàbí ẹnì kan tó jẹ́ aláàbọ̀ ara? Láìsí àní-àní, ìwọ náà gbà pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nílò ìṣírí. Ṣùgbọ́n kí la lè sọ láti tù wọ́n nínú? Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fúnni nírètí ńbẹ nínú Bíbélì. [Ka Aísáyà 35:5, 6.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ìdí tó fi lè dá wa lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa nímùúṣẹ.”
Jí! May 8
“Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń fi àwọn ìsìn tó ti wà látayébáyé sílẹ̀ kí wọ́n bàa lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ lójú wọn. Kí lo rò nípa àṣà tó gbòde kan yìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì fi hàn pé ojú kékeré kọ́ ni Ọlọ́run fi ń wo ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn rẹ̀ o. [Ka Jòhánù 4:24.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó dára jù lọ tó o lè gbà rí àwọn ohun tẹ̀mí tó o nílò.”
“Lọ́dún tó kọjá yìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé fi hàn pé, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ẹ̀mí àwọn èèyàn ti túbọ̀ wà nínú ewu. Ǹjẹ́ o rò pé agbára ìjọba èèyàn á ká mímú àlàáfíà kárí ayé wá? [Lẹ́yìn tí ó bá fèsì, ka Aísáyà 2:4.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí ṣàlàyé ìdí tá a fi lè ní ìdánilójú pé àlàáfíà kárí ayé yóò dé láìpẹ́ jọjọ.”