ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/03 ojú ìwé 7
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe ti Ọdún 2010
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 2/03 ojú ìwé 7

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun

1 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọrọ̀ ti ara ni àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn àtàwọn ọ̀mọ̀ràn nínú ayé ń gbé lárugẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá láti “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà.” (1 Tím. 6:18) Èyí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù March 2003. Ìṣírí wo la máa rí gbà ní àpéjọ yìí?

2 Alábòójútó àyíká yóò jíròrò ohun tó túmọ̀ sí láti “Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Lójú Ọlọ́run,” yóò sì fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn kan tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti lè ní ọrọ̀ tẹ̀mí. Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò sọ lọ́jọ́ náà, yóò jẹ́ ká rí i bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń ṣe “Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà ní Àkókò Ìkórè Yìí.” Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni a óò fún níṣìírí láti ronú nípa bí a ṣe lè túbọ̀ kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ ìkórè tí Ọlọ́run yàn fún wa, èyí tí à ń ṣe lónìí.

3 Inú wa máa ń dùn gan-an nígbà tá a bá rí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí wọ́n ń lépa ọrọ̀ tẹ̀mí! Èyí ń mú ògo wá fún Jèhófà ó sì ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti fi ìpìlẹ̀ tó dára lélẹ̀ fún àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ọjọ́ iwájú. Apá tó sọ pé, “Gbígbóríyìn fún Àwọn Ọ̀dọ́ Nítorí Iṣẹ́ Àtàtà Tí Wọ́n Fi Ń Yin Jèhófà” yóò ṣàlàyé àwọn iṣẹ́ àtàtà táwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ń gbé ṣe nínú ìjọ wọn.

4 Kí làwọn àbájáde tó ń wá látinú lílépa àwọn iṣẹ́ àtàtà? Olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò jíròrò èyí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó kẹ́yìn, “Máa Bá Ṣíṣe Iṣẹ́ Àtàtà Lọ Kí O sì Rí Ìbùkún Jèhófà Gbà.” Yóò gbé ọ̀nà mẹ́rin yẹ̀ wò tá a ti ń kórè ìbùkún jìngbìnnì: (1) gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, (2) gẹ́gẹ́ bí ìdílé, (3) gẹ́gẹ́ bí ìjọ, àti (4) gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ kan tó kárí ayé.

5 Àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà yóò láǹfààní láti ṣe batisí. Bó o bá ti múra tán láti gbé ìgbésẹ̀ yẹn, tètè jẹ́ kí alábòójútó olùṣalága mọ̀.

6 Nígbà tí a bá ṣèfilọ̀ déètì àpéjọ àkànṣe ti àgbègbè yín, ṣe àwọn ètò tó yẹ láìjáfara kó o lè wà níbẹ̀. Gbìyànjú láti tètè dé kó o lè kópa nínú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀. Wíwà níbẹ̀ àti fífetísílẹ̀ sí gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin yóò fún wa lókun láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣe àwọn ohun tí yóò jẹ́ ká jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní ti tòótọ́ lójú Ọlọ́run wa, Jèhófà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́